Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì Ni Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ka ara wọn sí ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì, ìyẹn àwọn ìsìn tó ń ta ko àṣẹ Póòpù. Kí nìdí?

Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún àwọn tó ń ta ko àṣẹ Póòpù yapa kúrò nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní ilẹ̀ Yúróòpù, nítorí àtúnṣe tí wọ́n gbìyànjú láti ṣe. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Ọ̀gbẹ́ni Martin Luther ni wọ́n kọ́kọ́ pè ní “Pùròtẹ́sítáǹtì” níbi àpérò kan tí wọ́n ṣe nílùú Speyer ní ọdún 1529. Látìgbà yẹn ni wọ́n ti ń lo ọ̀rọ̀ náà láti fi ṣàpèjúwe gbogbo àwọn tó bá ti ń tẹ̀ lé òfin àti ìlànà ẹgbẹ́ tó fẹ́ ṣe àtúnṣe sí ìsìn Kátólíìkì. Ìdí nìyẹn tí ìwé atúmọ̀ èdè Merriam-Webster’s Collegiate Dictionary, Ìdìpọ̀ Kọkànlá fi túmọ̀ Pùròtẹ́sítáǹtì gẹ́gẹ́ bí “ọmọ ìjọ èyíkéyìí lára onírúurú ṣọ́ọ̀ṣì tó ń ta ko Póòpù tó jẹ́ aláṣẹ gbogbo gbòò, tó sì gbà pẹ̀lú ìlànà àwọn Alátùn-ún-tò pé ìgbàgbọ́ ẹni ló lè jẹ́ kéèyàn rí ojú rere Ọlọ́run, pé gbogbo onígbàgbọ́ ló gbọ́dọ̀ jẹ́ àlùfáà àti pé Bíbélì nìkan ni orísun òtítọ́.”

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ka póòpù sí aláṣẹ gbogbo gbòò, tí wọ́n sì fi tọkàntọkàn gbà pé Bíbélì ṣe pàtàkì ká tó lè lóye òtítọ́, síbẹ̀ wọ́n yàtọ̀ pátápátá sí àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì. Kódà ìwé The Encyclopedia of Religion sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà “yàtọ̀ pátápátá.” Jẹ́ ká gbé ọ̀nà mẹ́ta tí wọ́n gbà yàtọ̀ yẹ̀ wò.

Àkọ́kọ́, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí àwọn onísìn Pùròtẹ́sítáǹtì gbà gbọ́ kò bá àwọn nǹkan kan nínú ìjọsìn Kátólíìkì mu, àwọn aṣáájú Alátùn-ún-tó yìí ṣì gba àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Kátólíìkì kan gbọ́, irú bíi Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀run àpáàdì àti ẹ̀kọ́ pé ẹ̀mí èèyàn kì í kú. Àmọ́ yàtọ̀ sí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀kọ́ yìí kò bá Bíbélì mu, àwọn ẹ̀kọ́ náà kò fi òtítọ́ kọ́ni nípa Ọlọ́run.—Wo ojú ìwé 4 sí 7 nínú ìwé ìròyìn yìí.

Ìkejì ni pé, ìsìn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ta ko ìsìn èyíkéyìí, ńṣe ni wọ́n ń fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́. Ọwọ́ pàtàkì ni wọ́n fi mú ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé: ‘Ìránṣẹ́ Olúwa kò sì gbọ́dọ̀ jà. Ṣùgbọ́n ó ní láti máa ṣe jẹ́jẹ́ sí gbogbo èèyàn, kí ó jẹ́ olùkọ́ni rere, tí ó ní ìfaradà. Kí ó fi ìfarabalẹ̀ bá àwọn tí ó bá lòdì sí i wí.’ (2 Tímótì 2:24, 25, Ìròhìn Ayọ̀) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń sọ ìyàtọ̀ tó wà nínú ohun tí Bíbélì sọ àti ohun tí ọ̀pọ̀ ìsìn fi ń kọ́ni. Síbẹ̀, ìdí tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ kì í ṣe láti ṣe àtúntò ètò ìsìn èyíkéyìí. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n fẹ́ láti ran ẹnikẹ́ni tó bá dìídì nífẹ̀ẹ́ òtítọ́ lọ́wọ́ láti ní ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Kólósè 1:9, 10) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń yẹra fún àríyànjiyàn nígbà tí àwọn ẹlẹ́sìn míì bá ta kò wọ́n.—2 Tímótì 2:23.

Ẹ̀kẹta ni pé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń bá a nìṣó láti wà níṣọ̀kan gẹ́gẹ́ bí ètò kan ṣoṣo jákèjádò ayé, wọn kò dà bí àwọn onísìn Pùròtẹ́sítáǹtì tí wọ́n ti pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní ilẹ̀ tó ju igba-ó-lé-ọgbọ̀n [230] lọ ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù tó sọ pé kí àwọn Kristẹni máa “sọ̀rọ̀ ní ìfohùnṣọ̀kan” tó bá di ọ̀rọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì. Ìsìn wọn kò pín yẹ́lẹyẹ̀lẹ. Kàkà bẹ́ẹ̀, tọkàntọkàn ni wọ́n fi “ṣọ̀kan rẹ́gírẹ́gí nínú èrò inú kan náà àti nínú ìlà ìrònú kan náà.” (1 Kọ́ríńtì 1:10) Wọ́n máa ń gbìyànjú láàárín ara wọn láti ‘pa ìṣọ̀kan ti ẹ̀mí mọ́ nínú àlàáfíà tí ó so wọ́n pọ̀.’—Éfésù 4:3, Ìròhìn Ayọ̀.