Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè

Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè

Mèsáyà! Ọ̀nà Ìgbàlà Tí Ọlọ́run Pèsè

“Nítorí gan-an gẹ́gẹ́ bí gbogbo ènìyàn ti ń kú nínú Ádámù, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni a ó sọ gbogbo ènìyàn di ààyè nínú Kristi.”—1 KỌ́R. 15:22.

1, 2. (a) Kí ni Áńdérù àti Fílípì ṣe nígbà tí wọ́n rí Jésù? (b) Kí nìdí tá a fi sọ pé a ní ẹ̀rí tó ju ti àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní lọ, pé Jésù ni Mèsáyà?

 Ó DÁ Áńdérù lójú pé Jésù ará Násárétì ni Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run, torí náà ó sọ fún Pétérù pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà.” Fílípì náà gbà pé Jésù ni Mèsáyà, nígbà tó rí Nàtáníẹ́lì ọ̀rẹ́ rẹ̀, ó sọ fún un pé: “Àwa ti rí ẹni tí Mósè, nínú Òfin, àti àwọn Wòlíì kọ̀wé nípa rẹ̀, Jésù, ọmọkùnrin Jósẹ́fù, láti Násárétì.”—Jòh. 1:40, 41, 45.

2 Ṣé ó dá ìwọ náà lójú ṣáká pé Jésù ni Mèsáyà tí Jèhófà ṣèlérí, pé òun ni “Olórí Aṣojú ìgbàlà”? (Héb. 2:10) Ní àkókò wa yìí, ẹ̀rí tá a ní tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà pọ̀ gan-an ju ti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ti ọ̀rúndún kìíní lọ. Ohun tá a rí nínú Ìwé Mímọ́ nípa Jésù, bẹ̀rẹ̀ láti orí ìbí rẹ̀ títí dórí àjíǹde rẹ̀ fún wa ní ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ pé òun ni Kristi. (Ka Jòhánù 20:30, 31.) Bíbélì tún fi hàn pé tí Jésù bá pa dà dé ọ̀run, yóò máa bá iṣẹ́ rẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà. (Jòh. 6:40; Ka 1 Kọ́ríńtì 15:22.) Lóde òní, látàrí ohun tó o ti kọ́ nínú Bíbélì, ìwọ náà lè sọ pé o “ti rí Mèsáyà náà.” Àmọ́, kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù àkọ́kọ́ lè sọ ní tòótọ́ pé àwọn ti rí Mèsáyà.

Díẹ̀díẹ̀ Ni Ọlọ́run Ṣí “Àṣírí Ọlọ́wọ̀” Nípa Mèsáyà Payá

3, 4. (a) Kí ló mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní lè sọ pé ‘a ti rí Mèsáyà’? (b) Kí nìdí tó o fi lè sọ pé Jésù nìkan ni gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣẹ sí lára?

3 Kí ló mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ti ọ̀rúndún kìíní lè sọ dájú pé àwọn ti rí Mèsáyà? Ohun tó jẹ́ kí wọ́n lè sọ bẹ́ẹ̀ ni pé díẹ̀díẹ̀, Jèhófà ti ń tipasẹ̀ àwọn wòlíì rẹ̀ sọ ohun táwọn èèyàn yóò fi dá Mèsáyà tó ń bọ̀ mọ̀. Ọkùnrin kan tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì sọ pé ọ̀ràn náà dà bí ìgbà tí àwọn ọkùnrin kan fẹ́ to àwọn òkúta kan pọ̀ kó lè di odindi ère. Ká sọ pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn èèyàn yẹn kò tíì bá ara wọn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ rí, olúkúlùkù wọn sì wá mú òkúta tirẹ̀ wọnú yàrá tí wọ́n ti fẹ́ tò wọ́n pa pọ̀. Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé bí wọ́n ṣe ń to òkúta tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mú dání sórí ara wọn, ó ń ṣe rẹ́gí títí tó fi di ère, ó dájú pé wàá gbà pé ẹnì kan tó ti mọ bí ère yẹn ṣe máa rí ló pín àwọn òkúta náà fún ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ọkùnrin yẹn. Ọ̀kọ̀ọ̀kan òkúta yẹn dà bí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà, gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ló sọ ohun pàtàkì kan nípa Mèsáyà.

4 Nígbà náà, ṣé a wá lè sọ pé gbogbo àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà yẹn kàn lè ṣèèṣì ṣẹ sí ẹnì kan lára? Ẹnì kan tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì sọ pé gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà yẹn kò lè ṣèèṣì ṣẹ sí ẹnì kan lára. “Nínú gbogbo èèyàn tó tíì gbé ayé yìí rí, Jésù nìkan ṣoṣo ni àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣẹ sí lára, kò tún sí ẹlòmíràn.”

5, 6. (a) Báwo ni ìdájọ́ Sátánì ṣe máa wáyé? (b) Báwo ni Ọlọ́run ṣe ń jẹ́ kí aráyé mọ ìlà ìdílé tí “irú ọmọ” náà yóò ti wá?

5 Ohun tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà dá lé lórí ni “àṣírí ọlọ́wọ̀” kan tó pín sí oríṣiríṣi ọ̀nà, tó sì kan gbogbo ẹ̀dá láyé àtọ̀run. (Kól. 1:26, 27; Jẹ́n. 3:15) Ara ohun tó wà nínú àṣírí yẹn ni ìdájọ́ tó máa dé bá Sátánì Èṣù tó jẹ́ “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” tó kó aráyé sínú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. (Ìṣí. 12:9) Báwo ni ìdájọ́ náà ṣe máa wáyé? Jèhófà sọ tẹ́lẹ̀ pé “obìnrin” kan yóò bí “irú-ọmọ” kan tí yóò pa Sátánì ní orí. “Irú-ọmọ” tí Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀ yìí yóò fọ́ orí ejò náà, yóò sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ohun tó fa ọ̀tẹ̀, àìsàn àti ikú kúrò. Àmọ́ pẹ̀lú ìyọ̀ǹda Ọlọ́run, Sátánì yóò kọ́kọ́ ṣe ohun kan fún “irú-ọmọ” obìnrin yẹn tí yóò dà bíi pípa á ní gìgísẹ̀.

6 Díẹ̀díẹ̀ ni Jèhófà ń jẹ́ kí aráyé mọ ẹni tí yóò jẹ́ “irú-ọmọ” tó ṣèlérí yẹn. Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù pé: “Nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ sì ni gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ ayé yóò bù kún ara wọn.” (Jẹ́n. 22:18) Mósè náà sọ tẹ́lẹ̀ pé Ẹni náà yóò jẹ́ “wòlíì kan,” ó sì máa tóbi ju Mósè lọ. (Diu. 18:18, 19) Ọlọ́run tún mú un dá Dáfídì lójú pé Mèsáyà náà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ rẹ̀, yóò sì jogún ìtẹ́ Dáfídì títí láé. Lẹ́yìn náà, Ọlọ́run lo àwọn wòlíì láti fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀.—2 Sám. 7:12, 16; Jer. 23:5, 6.

Àwọn Ẹ̀rí Tó Fi Jésù Hàn Gẹ́gẹ́ Bíi Mèsáyà

7. Ọ̀nà wo ni Jésù gbà wá látara “obìnrin” Ọlọ́run?

7 Látara ètò Ọlọ́run tó dà bí ìyàwó rẹ̀, èyí tó kún fún àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí lọ́run ni Ọlọ́run ti rán Ọmọ rẹ̀, tó jẹ́ ẹ̀dá tó kọ́kọ́ dá, láti wá di “irú-ọmọ” tó ṣèlérí náà. Èyí gba pé kí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run bọ́ gbogbo ògo tó ní lọ́run sílẹ̀, kó sì wá dẹni tí wọ́n máa bí gẹ́gẹ́ bí èèyàn pípé. (Fílí. 2:5-7; Jòh. 1:14) Bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ‘ṣíji bo’ Màríà yẹn jẹ́ kó dájú pé ẹni “mímọ́, Ọmọ Ọlọ́run” ni a ó máa pe ọmọ tó máa bí.—Lúùkù 1:35.

8. Báwo ni Jésù ṣe mú àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà ṣẹ nígbà tó wá sọ́dọ̀ Jòhánù láti ṣe batisí?

8 Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà sọ ibi tí Jésù ti máa fara hàn àti ìgbà tó máa fara hàn. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀, Bẹ́tílẹ́hẹ́mù ni wọ́n bí Jésù sí. (Míkà 5:2) Kí Mèsáyà tó dé, àwọn Júù ti ń retí rẹ̀ lójú méjèèjì. Àwọn kan ń béèrè nípa Jòhánù Oníbatisí pé: “Àbí òun ni Kristi náà ni?” Àmọ́ Jòhánù dáhùn pé: “Ẹni tí ó lágbára jù mí lọ ń bọ̀.” (Lúùkù 3:15, 16) Nígbà tí Jésù pé ẹni ọgbọ̀n ọdún, ó fara hàn gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà ní àkókò tó yẹ, nígbà tó wá sọ́dọ̀ Jòhánù lápá ìparí ọdún 29 Sànmánì Kristẹni pé kó batisí òun. (Dán. 9:25) Lẹ́yìn náà ló bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ alárinrin, ó sọ pé: “Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé, ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé.”—Máàkù 1:14, 15.

9. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ò tíì yé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù dáadáa, kí ló dá wọn lójú kedere?

9 Lóòótọ́, àwọn èèyàn ò ṣàṣìṣe bí wọ́n ṣe pe Jésù ni Ọba tí wọ́n sì yìn ín, àmọ́ àwọn ohun kan wà tí kò tíì yé wọn dáadáa nígbà yẹn. Kò tíì yé wọn pé ìṣàkóso Jésù ṣì di ọjọ́ iwájú àti pé ọ̀run ló ti máa ṣàkóso. (Jòh. 12:12-16; 16:12, 13; Ìṣe 2:32-36) Síbẹ̀, nígbà tí Jésù béèrè pé: “Ta ni ẹ sọ pé mo jẹ́?” Kíá ni Pétérù dáhùn pé: “Ìwọ ni Kristi náà, Ọmọ Ọlọ́run alààyè.” (Mát. 16:13-16) Bó ṣe dáhùn náà nìyẹn nígbà tí ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ ẹ̀yìn pa Jésù tì nígbà tí wọ́n kọsẹ̀ nítorí ẹ̀kọ́ rẹ̀ kan.—Ka Jòhánù 6:68, 69.

Bí A Ṣe Lè Máa Fetí sí Mèsáyà

10. Kí nìdí tí Jèhófà fi sọ fún wa pé á gbọ́dọ̀ máa fetí sí Ọmọ òun?

10 Nígbà tí Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run ṣì wà lọ́run, ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ni. Nígbà tó wá sáyé “aṣojú Baba” rẹ̀ ni. (Jòh. 16:27, 28) Ó sọ pé: “Ohun tí mo fi ń kọ́ni kì í ṣe tèmi, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti ẹni tí ó rán mi.” (Jòh. 7:16) Nígbà ìyípadà ológo Jésù, Jèhófà sọ ọ̀rọ̀ kan láti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jésù ni Mèsáyà, lẹ́yìn náà ó pàṣẹ pé: “Ẹ fetí sí i.” (Lúùkù 9:35) Bẹ́ẹ̀ ni o, a ní láti máa fetí sí Ẹni tí Ọlọ́run yàn, ká máa gbọ́ràn sí i lẹ́nu. Èyí gba pé ká ní ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ Ọlọ́run, ká sì máa fi iṣẹ́ rere tì í lẹ́yìn, méjèèjì yìí ló ṣe pàtàkì kí inú Ọlọ́run lè dùn sí wa, ká sì lè jèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòh. 3:16, 35, 36.

11, 12. (a) Kí làwọn nǹkan tó mú káwọn Júù ọ̀rúndún kìíní kọ Jésù ní Mèsáyà? (b) Àwọn wo ló gba Jésù gbọ́?

11 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀rí pọ̀ lọ jàńtìrẹrẹ pé Jésù ni Mèsáyà, síbẹ̀ àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn Júù ọ̀rúndún kìíní kò gbà á ní Mèsáyà. Kí ló fà á? Ohun tó fà á ni pé wọ́n ti ní àwọn èrò kan tí kò tọ́ nípa Mèsáyà tẹ́lẹ̀. Lára rẹ̀ ni pé wọ́n gbà pé mèsáyà ní láti jẹ́ olóṣèlú tó máa yọ àwọn lábẹ́ àjàgà ìjọba àwọn ará Róòmù amúnisìn. (Ka Jòhánù 12:34.) Ìdí rèé tí wọn ò fi fara mọ́ Mèsáyà tí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Ìwé Mímọ́ máa ṣẹ sí lára, pé ayé máa kórìíra rẹ̀, àwọn èèyàn á yẹra fún un, ó máa jẹ̀rora ó sì máa dojúlùmọ̀ àìsàn, tí wọ́n á sì wá pa á nígbẹ̀yìngbẹ́yín. (Aísá. 53:3, 5) Kódà, ó dun àwọn kan lára àwọn adúróṣinṣin ọmọ ẹ̀yìn Jésù pé kò yọ àwọn lábẹ́ àjàgà amúnisìn. Àmọ́ wọ́n ṣì jẹ́ adúróṣinṣin síbẹ̀, nígbà tó sì yá, wọ́n wá ní ẹ̀kún rẹ́rẹ́ òye.—Lúùkù 24:21.

12 Ohun míì tí kò jẹ́ káwọn èèyàn gbà pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí ni àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ tó nira fún ọ̀pọ̀ wọn láti fara mọ́. Ó sọ pé ẹni tó bá máa wọnú Ìjọba Ọlọ́run gbọ́dọ̀ ‘sẹ́ ara rẹ̀,’ ó gbọ́dọ̀ ‘jẹ ẹran ara’ òun, kó sì ‘mu ẹ̀jẹ̀’ òun, a gbọ́dọ̀ ‘tún un bí,’ kò sì ‘gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé.’ (Máàkù 8:34; Jòh. 3:3; 6:53; 17:14, 16) Àwọn agbéraga, ọlọ́rọ̀ àtàwọn alágàbàgebè wò ó pé nǹkan wọ̀nyẹn ti nira jù fáwọn láti ṣe. Àmọ́ àwọn tó nírẹ̀lẹ̀ lára àwọn Júù gba Jésù ní Mèsáyà, bí àwọn ará Samáríà náà ti gbà á, àwọn tó sọ pé: “Ọkùnrin yìí dájúdájú ni olùgbàlà ayé.”—Jòh. 4:25, 26, 41, 42; 7:31.

13. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa pa Jésù ní gìgísẹ̀ ṣe ní ìmúṣẹ?

13 Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn olórí àlùfáà yóò dá òun lẹ́bi, àwọn Kèfèrí yóò kàn òun mọ́gi, àmọ́ òun máa jí dìde lọ́jọ́ kẹta. (Mát. 20:17-19) Bó ṣe sọ gbangba gbàǹgbà níwájú Ìgbìmọ̀ Sànhẹ́dírìn pé òun ni “Kristi Ọmọ Ọlọ́run,” wọ́n kà á sí asọ̀rọ̀ òdì. (Mát. 26:63-66) Pílátù sọ pé “kò sí nǹkan kan tí ó ṣe tí ó yẹ fún ikú,” àmọ́ nítorí pé ẹ̀sùn ìdìtẹ̀ sí ìjọba wà lára ẹ̀sùn táwọn Júù fi kàn án, Pílátù “fi Jésù lé wọn lọ́wọ́ fún ìfẹ́ wọn.” (Lúùkù 23:13-15, 25) Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ kọ “Olórí Aṣojú ìyè” tí wọ́n sì gbìmọ̀ pọ̀ láti pa á, pẹ̀lú gbogbo ẹ̀rí tó pọ̀ jàńtìrẹrẹ tó wà pé Ọlọ́run ló rán an wá sáyé. (Ìṣe 3:13-15) Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú àsọtẹ́lẹ̀, wọ́n “ké Mèsáyà kúrò,” wọ́n kàn án mọ́gi ní Ọjọ́ Ìrékọjá ọdún 33 Sànmánì Kristẹni. (Dán. 9:26, 27; Ìṣe 2:22, 23) Ìgbà tí wọ́n fi ikú oró pa á yìí ni àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 3:15, pé wọ́n máa pa á “ní gìgísẹ̀,” ní ìmúṣẹ.

Ìdí Tí Mèsáyà Fi Ní Láti Kú

14, 15. (a) Ìdí méjì wo ni Jèhófà fi yọ̀ǹda pé kí Jésù kú? (b) Kí ni Jésù ṣe lẹ́yìn tó jíǹde?

14 Ìdí pàtàkì méjì ni Jèhófà fi yọ̀ǹda pé kí Jésù kú. Ìdí àkọ́kọ́ ni pé: Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú yanjú apá pàtàkì kan nínú “àṣírí ọlọ́wọ̀” náà. Ó fẹ̀rí hàn títí dójú ikú, pé ó ṣeé ṣe fún ẹni pípé kan láti dúró lórí “fífọkànsin Ọlọ́run” kó sì fi hàn pé Ọlọ́run nìkan ni Ọba Aláṣẹ, láìfi ti ìdánwò gbígbóná janjan látọ̀dọ̀ Sátánì pè. (1 Tím. 3:16) Ìdì kejì rèé: Jésù sọ pé ‘Ọmọ ènìyàn wá, kó lè fi ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.’ (Mát. 20:28) “Ìràpadà tí ó ṣe rẹ́gí” yìí ló san gbèsè ẹ̀ṣẹ̀ táwa ọmọ Ádámù jogún, òun ló sì ṣí àǹfààní ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ fún gbogbo àwọn tó bá gbà pé Jésù ni ọ̀nà ìgbàlà tí Ọlọ́run pèsè.—1 Tím. 2:5, 6.

15 Lẹ́yìn tí Kristi ti lo ọjọ́ mẹ́ta nínú ibojì, ó jíǹde, ogójì ọjọ́ ló fi fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé ó ti jíǹde, ó sì fún wọn láwọn ìtọ́ni míì. (Ìṣe 1:3-5) Lẹ́yìn náà, ó gòkè re ọ̀run, láti gbé ìtóye ẹbọ rẹ̀ tó ṣeyebíye lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, ó sì ń dúró de àkókò wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà Ọba. Láàárín àkókò tó fi ń dúró yẹn, ó ṣì ní ohun púpọ̀ láti ṣe.

Bó Ṣe Máa Parí Iṣẹ́ Rẹ̀ Gẹ́gẹ́ Bíi Mèsáyà

16, 17. Sọ àwọn iṣẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà látìgbà tó ti gòkè re ọ̀run.

16 Láti ẹ̀yìn ìgbà àjíǹde Jésù, ó ti ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí Ọba lórí ìjọ Kristẹni, ó ń darí àwọn ohun tó ń lọ níbẹ̀ bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ. (Kól. 1:13) Ní àkókò tí Ọlọ́run ti yàn kalẹ̀, Jésù yóò bẹ̀rẹ̀ sí í lo agbára rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé fi hàn pé Jésù ti wà níhìn-ín gẹ́gẹ́ bí Ọba láti ọdún 1914, wọ́n sì tún fi hàn pé àkókò “ìparí ètò àwọn nǹkan” ti bẹ̀rẹ̀. (Mát. 24:3; Ìṣí. 11:15) Láìpẹ́ sígbà yẹn ló kó àwọn áńgẹ́lì mímọ́ lẹ́yìn láti lé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ kúrò lọ́run.—Ìṣí. 12:7-10.

17 Iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tí Jésù bẹ̀rẹ̀ lọ́dún 29 Sànmánì Kristẹni ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé ìparí ológo rẹ̀. Láìpẹ́, yóò ṣèdájọ́ gbogbo alààyè. Ìgbà yẹn ló máa sọ fún àwọn ẹni bí àgùntàn tó gbà pé Jésù ni ọ̀nà ìgbàlà tí Jèhófà pèsè, pé kí wọ́n “jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún [wọn] láti ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Mát. 25:31-34, 41) Ìparun ló máa jẹ́ ti àwọn tí kò gba Jésù ní Ọba nígbà tó bá kó ẹgbẹ́ ọmọ ogun ọ̀run lẹ́yìn láti fòpin sí gbogbo ìwà ibi. Lẹ́yìn náà ni yóò de Sátánì tí yóò sì ju òun pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sínú “ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.”—Ìṣí. 19:11-14; 20:1-3.

18, 19. Àwọn nǹkan wo ni Jésù máa gbé ṣe tó fi máa parí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà, kí nìyẹn sì máa yọrí sí fáwọn ọmọ aráyé onígbọràn?

18 Nígbà Ìṣàkóso Ẹgbẹ̀rún Ọdún Kristi, yóò wá máa lo ipò rẹ̀ lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ gẹ́gẹ́ bí “Àgbàyanu Agbani-nímọ̀ràn, Ọlọ́run Alágbára Ńlá, Baba Ayérayé, Ọmọ Aládé Àlàáfíà.” (Aísá. 9:6, 7) Ìjọba rẹ̀ yóò sọ àwọn èèyàn di ẹni pípé, títí kan àwọn òkú tí yóò jí dìde. (Jòh. 5:26-29) Mèsáyà yóò ṣamọ̀nà àwọn tó bá ń tẹ̀ lé e lọ sí “àwọn ìsun omi ìyè,” èyí tó máa jẹ́ káwọn ọmọ aráyé onígbọràn máa gbádùn àjọṣe alálàáfíà pẹ̀lú Jèhófà. (Ka Ìṣípayá 7:16, 17.) Lẹ́yìn ìdánwò ìkẹyìn, Kristi yóò fi àwọn ọlọ̀tẹ̀, títí kan Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ “sọ̀kò sínú adágún iná,” tó máa já sí fífọ́ orí “ejò” náà yán-án yán-án, tó túmọ̀ sí ìparun rẹ̀.—Ìṣí. 20:10.

19 Ẹ ò rí i bí Jésù ṣe ṣiṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà láṣepé lọ́nà àgbàyanu! Àwọn èèyàn tí Ọlọ́run ti rà pa dà yóò kún Párádísè orí ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa wà láàyè títí láé pẹ̀lú ayọ̀ àti ìlera tó jí pépé. Kò ní sí ẹ̀gàn kankan mọ́ lórí orúkọ mímọ́ Jèhófà, yóò sì ti dá ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run láre pátápátá. Ogún iyebíye mà ló ń dúró de gbogbo àwọn tó bá ṣègbọràn sí Jésù Ẹni Àmì Òróró Ọlọ́run o!

Ṣé Ìwọ Náà Ti Rí Mèsáyà?

20, 21. Àwọn ìdí wo lo fi ní láti sọ fáwọn èèyàn nípa Mèsáyà?

20 Àtọdún 1914 la ti wà ní àkókò pa·rou·siʹa Kristi, ìyẹn wíwàníhìn-ín rẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wíwàníhìn-ín rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run kò ṣeé fojú rí, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń nímùúṣẹ jẹ́ ká rí i kedere pé ó ti wà níhìn-ín. (Ìṣí. 6:2-8) Síbẹ̀síbẹ̀, bíi tàwọn Júù ọ̀rúndún kìíní, ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ni kò kọbi ara sí ẹ̀rí tó fi hàn pé Mèsáyà ti wà níhìn-ín. Mèsáyà olóṣèlú làwọn náà ń fẹ́, tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ èyí tó máa lo àwọn olóṣèlú tó ń ṣàkóso. Àmọ́ ìwọ ti mọ̀ pé Jésù ti ń ṣàkóso báyìí gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run. Ǹjẹ́ inú rẹ ò dùn nígbà tó o mọ̀ bẹ́ẹ̀? Bíi ti àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní, ó ṣe ìwọ náà bíi kó o polongo pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà.”

21 Nígbà tó o bá ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, ṣé o máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà ṣe kedere sí wọn? Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, yóò jẹ́ kó o túbọ̀ mọrírì àwọn ohun tó ti ṣe fún ọ́, èyí tó ń ṣe báyìí àtèyí tó máa ṣe lọ́jọ́ iwájú. Bíi ti Áńdérù àti Fílípì, ó dájú pé ìwọ náà á ti sọ̀rọ̀ nípa Mèsáyà fáwọn ẹbí àtọ̀rẹ́ rẹ. Pẹ̀lú ìtara rẹ tó ti di àkọ̀tun, kí ló dé tí o kò tún lọ fi hàn wọ́n pé Jésù Kristi ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí, pé òun ni ọ̀nà ìgbàlà tí Ọlọ́run pèsè?

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Kí ló mú káwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní ọ̀rúndún kìíní lè sọ pé ‘a ti rí Mèsáyà’?

• Ìdí pàtàkì méjì wo ni Jésù fi kú?

• Àwọn nǹkan wo ni Jésù ṣì máa gbé ṣe tó fi máa parí iṣẹ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Báwo làwọn ará ọ̀rúndún kìíní ṣe mọ̀ pé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Nígbà tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, ṣé o máa ń jẹ́ kí iṣẹ́ Jésù gẹ́gẹ́ bíi Mèsáyà ṣe kedere sí wọn?