Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Ní Ìfẹ́ Tí Kì Í Kùnà Láé

Ẹ Ní Ìfẹ́ Tí Kì Í Kùnà Láé

Ẹ Ní Ìfẹ́ Tí Kì Í Kùnà Láé

‘Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.’—1 KỌ́R. 13:7, 8.

1. (a) Kí làwọn èèyàn sábà máa ń ṣe nípa ìfẹ́? (b) Kí ni ọ̀pọ̀ èèyàn sábà máa ń nífẹ̀ẹ́?

 ÀÌMỌYE nǹkan ni wọ́n ti gbé jáde nípa ìfẹ́. Wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ orin àti ewì gbé ìfẹ́ lárugẹ. Kò sẹ́ni tí kì í fẹ́ káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ òun. Wọ́n sábà máa ń gbé ìtàn àròsọ nípa ìfẹ́ jáde nínú ìwé àti fíìmù, irú àwọn ìwé àti fíìmù bẹ́ẹ̀ sì pọ̀ lọ jàra lórí igbá. Àmọ́, ó bani lọ́kàn jẹ́ pé àwọn èèyàn kò ní ìfẹ́ tòótọ́ fún Ọlọ́run àti aládùúgbò wọn. À ń rí ìmúṣẹ ohun tí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tá a wà yìí, pé àwọn èèyàn yóò jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Tím. 3:1-5.

2. Kí ni Bíbélì kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe nífẹ̀ẹ́?

2 Ọlọ́run dá àwa èèyàn lọ́nà tá a fi lè nífẹ̀ẹ́ nǹkan kan, síbẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kìlọ̀ fún wa lórí ohun tá ò gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́. Bíbélì sì sọ ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ tí ìfẹ́ ohun tí kò yẹ ká nífẹ̀ẹ́ bá gbilẹ̀ lọ́kàn wa. (1 Tím. 6:9, 10) Ǹjẹ́ o rántí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa Démà? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Démà wà pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀, ó dẹni tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ohun tó wà nínú ayé. (2 Tím. 4:10) Àpọ́sítélì Jòhánù sì kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé kí wọ́n ṣọ́ra fún ewu yìí. (Ka 1 Jòhánù 2:15, 16.) Kò lè ṣeé ṣe láti ní ìfẹ́ ayé, àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti àwọn nǹkan inú rẹ̀ tó ń kọjá lọ, ká sì tún ní ìfẹ́ Ọlọ́run àtàwọn ohun tó wá látọ̀dọ̀ rẹ̀.

3. Ìṣòro wo ló wà níwájú wa, àwọn ìbéèrè wo ló sì jẹ yọ?

3 A kì í ṣe apá kan ayé yìí bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú rẹ̀ la ṣì ń gbé. Torí náà, ìṣòro kan tó wà níwájú wa ni bá a ṣe máa yẹra fún èrò òdì tí ayé ní nípa ìfẹ́. Ó ṣe pàtàkì pé ká ṣọ́ra, kó má lọ di pé ọ̀nà òdì là ń gbé ìfẹ́ wa gbà. Nígbà náà, ta ló yẹ ká ní ìfẹ́ tó dá lórí ìlànà sí? Àwọn ohun wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ní ìfẹ́ tó ń fara da ohun gbogbo, tí kì í sì í kùnà? Tá a bá ní irú ìfẹ́ yìí, àǹfààní wo ló máa ṣe wá nísinsìnyí, kí ló sì máa ṣe fún wa lọ́jọ́ iwájú? A nílò ìdáhùn tó bá èrò Ọlọ́run mu sáwọn ìbéèrè yìí, èyí ló máa tọ́ wa sọ́nà.

Bá A Ṣe Lè Gbin Ìfẹ́ fún Jèhófà Sọ́kàn Wa

4. Báwo ni ìfẹ́ wa fún Ọlọ́run ṣe lè máa pọ̀ sí i?

4 Kéèyàn tó lè gbin nǹkan, ó ní láti tún ibi tó fẹ́ gbìn ín sí ṣe, tó bá fẹ́ kí irúgbìn náà ṣe dáádáá. Wo àgbẹ̀ kan tó ṣíṣẹ́ àṣekára láti tọ́jú ilẹ̀ oko rẹ̀, tó sì gbin irúgbìn síbẹ̀. Ó retí pé kí irúgbìn náà dàgbà. (Héb. 6:7) Bákan náà, ó yẹ kí ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run máa pọ̀ sí i. Kí la ní láti ṣe kí èyí tó lè ṣẹlẹ̀? A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ọkàn wa dà bí ilẹ̀ rere, níbi tí wọ́n gbin irúgbìn òtítọ́ Ìjọba Ọlọ́run sí. Bá a ṣe lè ṣe èyí ni pé ká máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí ìmọ̀ wa nípa Ọlọ́run lè máa pọ̀ sí i. (Kól. 1:10) Bákan náà, ìmọ̀ wa á máa pọ̀ sí i tá a bá ń lọ sípàdé déédéé tá a sì ń dá sí ohun tó ń lọ níbẹ̀. Ṣé gbogbo wa là ń sapá gidigidi kí ìmọ̀ wa lè túbọ̀ máa jinlẹ̀ sí i?—Òwe 2:1-7.

5. (a) Báwo la ṣe lè mọ̀ nípa àwọn ànímọ́ Jèhófà mẹ́rin tó gbawájú jù lọ? (b) Kí lo lè sọ nípa ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n àti agbára Ọlọ́run?

5 Jèhófà ti jẹ́ ká mọ àwọn ànímọ́ òun nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ tá a sì ń tipa bẹ́ẹ̀ gba ìmọ̀ Jèhófà sínú nìṣó, a óò túbọ̀ mọyì àwọn ànímọ́ Jèhófà, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, agbára, ọgbọ́n àti ìfẹ́ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, tó jẹ́ olúborí gbogbo wọn. Ìdájọ́ òdodo Jèhófà hàn nínú gbogbo àwọn ọ̀nà rẹ̀ àti nínú òfin rẹ̀ pípé. (Diu. 32:4; Sm. 19:7) Tá a bá ronú jinlẹ̀ lórí gbogbo ẹ̀dá ọwọ́ Jèhófà, ọgbọ́n rẹ̀ tí kò láfiwé yóò jọ wá lójú. (Sm. 104:24) Ẹgbàágbèje ìràwọ̀ àtàwọn ohun míì tó wà ní sánmà fi ẹ̀rí hàn pé Jèhófà ni Orísun agbára ńlá àti pé agbára rẹ̀ kò lópin.—Aísá. 40:26.

6. Báwo ni Ọlọ́run ṣe nawọ́ ìfẹ́ rẹ̀ sí wa, ipa wo nìyẹn sì ní lórí rẹ?

6 Tá a bá tún wa ki ẹnu bọ ọ̀rọ̀ nípa ìfẹ́ Ọlọ́run tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ tó ta yọ ńkọ́? Ọ̀rọ̀ ìfẹ́ yẹn gbòòrò, kò sẹ́ni tí kò kàn. Ìfẹ́ yẹn ló lò tó fi pèsè ìràpadà fún aráyé. (Ka Róòmù 5:8.) Gbogbo aráyé ló pèsè ìràpadà yìí fún, àmọ́ àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tí wọ́n sì lo ìgbàgbọ́ nínú Ọmọ rẹ̀ nìkan ni yóò jàǹfààní ìràpadà yẹn. (Jòh. 3:16, 36) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní tó mú kó fi Jésù Ọmọ rẹ̀ rú ẹbọ ìpẹ̀tù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa yẹ kó sún àwa náà láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

7, 8. (a) Kí la ní láti máa ṣe láti fi hàn pé a ní ìfẹ́ Ọlọ́run? (b) Kí làwọn èèyàn Ọlọ́run ń kojú bí wọ́n ṣe ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́?

7 Báwo la ṣe lè fi ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run hàn, nítorí gbogbo ohun tó ti ṣe fún wa? Àgbà ọ̀rọ̀ tí Bíbélì fi dáhùn ìbéèrè yìí rèé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́; síbẹ̀ àwọn àṣẹ rẹ̀ kì í ṣe ẹrù ìnira.” (1 Jòh. 5:3) Òdodo ọ̀rọ̀ ni, ìfẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run ń mú ká máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́. Èyí jẹ́ ìdí kan tá a fi ń jẹ́rìí nípa orúkọ rẹ̀ àti Ìjọba rẹ̀, ìyẹn sì ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní. Tó bá jẹ́ pé ìfẹ́ Ọlọrun tó kúnnú ọkàn wa ló mú ká máa wàásù, ìyẹn fi hàn pé èrò tó tọ́ ló ń sún wa pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́.—Mát. 12:34.

8 Àwọn ará wa káàkiri ayé ń pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ nìṣó báwọn èèyàn ò tiẹ̀ kọbi ara sí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run tàbí tí wọn ò bá tiẹ̀ fẹ́ gbọ́. Wọn ò jáwọ́ nínú ìsapá wọn láti ṣàṣeparí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn ní kíkún. (2 Tím. 4:5) Bákan náà, a ń sapá láti jẹ́ káwọn èèyàn ní ìmọ̀ Ọlọ́run, a sì tún máa ń pa gbogbo àwọn àṣẹ rẹ̀ míì mọ́.

Ìdí Tá A Fi Nífẹ̀ẹ́ Jésù Kristi Olúwa Wa

9. Àwọn nǹkan wo ni Kristi fara dà, kí ló sì mú kó ṣe bẹ́ẹ̀?

9 Yàtọ̀ sí pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tá a fi ní ìfẹ́ Ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé a ò rí Jésù rí, síbẹ̀ bá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún un túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i. (1 Pét. 1:8) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí Jésù fara dà? Bó ti ń ṣe ìfẹ́ Baba rẹ̀, àwọn èèyàn kórìíra rẹ̀ láìnídìí, wọ́n ṣe inúnibíni sí i, wọ́n ka ẹ̀sùn èké sí i lọ́rùn, wọ́n kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì tún fi àwọn àbùkù míì kàn án. (Ka Jòhánù 15:25.) Ìfẹ́ tí Jésù ní fún Baba rẹ̀ ọ̀run mú kó fara da àwọn àdánwò yẹn. Ìfẹ́ tó sì ní yìí ló mú kó kú ikú ìrúbọ tó fi ra ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn pa dà.—Mát. 20:28.

10, 11. Nítorí ohun tí Kristi ti ṣe fún wa, kí la ń sapá láti ṣe?

10 Àwọn ohun tí Jésù ṣe nígbà tó wà láyé mú ká fẹ́ láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Bá a ti ń ronú lórí ohun tí Kristi ṣe fún wa, ìfẹ́ tá a ní fún un túbọ̀ ń jinlẹ̀ sí i. Torí pé a jẹ́ ọmọlẹ́yìn Kristi, a ní láti sapá láti ní irú ìfẹ́ tó ní ká sì máa lò ó. Èyí á mú ká lè lo ìfaradà bá a ti ń tẹ̀ lé àṣẹ rẹ̀ pé ká máa wàásù Ìjọba Ọlọ́run, ká sì máa sọ àwọn èèyàn di ọmọ ẹ̀yìn òun.—Mát. 28:19, 20.

11 Ìfẹ́ tí Kristi ní sí aráyé mú kó di dandan fún wa láti parí iṣẹ́ tó gbé lé wa lọ́wọ́ kí òpin tó dé. (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.) Ìfẹ́ tí Kristi fi hàn yìí ló jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tó máa gbà mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run fún aráyé ṣẹ. Bá a sì ṣe ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ tí Kristi fi lélẹ̀ fún wa, ó ń jẹ́ ká láǹfààní láti nípìn-ín nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Èyí gba pé ká sakun láti fi gbogbo ọkàn wa àti gbogbo okun wa nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run. (Mát. 22:37) Tá a bá ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Jésù tá a sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, ńṣe là ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ àti pé a ti pinnu láti máa fi hàn pé Ọlọ́run nìkan ni Ọba Aláṣẹ, láìka ohun yòówù kó ná wa sí, gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe.—Jòh. 14:23, 24; 15:10.

Máa Lépa Ìfẹ́ Tó Jẹ́ Ọ̀nà Títayọ Ré Kọjá

12. Kí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “ọ̀nà títayọ ré kọjá”?

12 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ aláfarawé Kristi. Nítorí pé ó ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Kristi pẹ́kípẹ́kí, ẹnu rẹ̀ gbà á láti sọ fáwọn ará rẹ̀ pé kí wọ́n máa fara wé òun náà. (1 Kọ́r. 11:1) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù rọ àwọn ará Kọ́ríńtì pé kí wọ́n máa fìtara wá àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí kan tí wọ́n ń rí gbà ní ọ̀rúndún kìíní, irú bí ìmúniláradá àti fífi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, ó jẹ́ kí wọ́n rí i pé ohun kan tó sàn ju ìwọ̀nyẹn wà tó yẹ kí wọ́n máa lépa. Ní 1 Kọ́ríńtì 12:31, ó ṣàlàyé pé: “Síbẹ̀, èmi fi ọ̀nà títayọ ré kọjá hàn yín.” Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú àwọn ẹsẹ tó tẹ̀ lé ibẹ̀ yẹn fi hàn pé ìfẹ́ ni ọ̀nà títayọ ré kọjá tó ń sọ yìí. Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ gbà ta yọ? Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ohun tó ní lọ́kàn. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:1-3.) Tí Pọ́ọ̀lù bá láwọn ẹ̀bùn kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ tó sì gbé àwọn iṣẹ́ takuntakun ṣe àmọ́ tí kò ní ìfẹ́, kí ló máa já mọ́? Òfo! Ẹ̀mí Ọlọ́run tó darí Pọ́ọ̀lù mú kó gbé kókó pàtàkì yìí yọ lọ́nà tó rinlẹ̀. Ẹ ò rí i pé bá a ṣe ń gbé ọ̀rọ̀ yìí yẹ̀ wò, ńṣe ni yóò máa wọ̀ wá lọ́kàn ṣinrá!

13. (a) Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2010? (b) Ọ̀nà wo ni ìfẹ́ kò fi ní kùnà láé?

13 Pọ́ọ̀lù wá jẹ́ ká mọ ohun tí ìfẹ́ máa ń ṣe àti ohun tí kì í ṣe. (Ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-8.) Nínú ọ̀rọ̀ tó sọ yẹn, fara balẹ̀ wo bó o ṣe ń hu àwọn ìwà tó ń fi hàn pé èèyàn ní ìfẹ́. Ìlà tó gbẹ̀yìn ẹsẹ keje àti gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ kẹjọ ni kó o kíyè sí jù lọ, èyí tó sọ pé: ‘Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.’ Òun la fi ṣe ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2010. Wàá kíyè sí i pé ní ẹsẹ kẹjọ, Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí, irú bí ìsọtẹ́lẹ̀ àti ahọ́n àjèjì, yóò wá sópin. Àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí yìí ni wọ́n ń lò nígbà tí ìjọ Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ ìfẹ́ ní tiẹ̀ yóò máa wà títí lọ. Jèhófà fúnra rẹ̀ ni olú ìfẹ́, Jèhófà sì wà títí láé. Torí náà, ìfẹ́ kò ní kùnà láé, kò ní dópin láé. Títí láé ni yóò máa wà gẹ́gẹ́ bí ànímọ́ Ọlọ́run ayérayé.—1 Jòh. 4:8.

Ìfẹ́ Máa Ń Fara Da Ohun Gbogbo

14, 15. (a) Báwo ni ìfẹ́ ṣe lè jẹ́ ká fara da àdánwò? (b) Kí nìdí tí ọ̀dọ́kùnrin kan kò fi juwọ́ sílẹ̀?

14 Kí ló máa ran àwọn Kristẹni lọ́wọ́ láti máa fara da àdánwò, ipò lílekoko tàbí ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n bá ní? Ní kúkúrú, ìfẹ́ tó dá lórí ìlànà ni. Ìfẹ́ tá à ń sọ yìí kọjá pé ká kàn yááfì àwọn nǹkan tara. Ó débi pé ká ṣe tán láti di ìwà títọ́ wa mú, kódà tó bá gba pé ká kú nítorí Kristi. (Lúùkù 9:24, 25) Ìwọ wo ìṣòtítọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fìyà jẹ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́, àgọ́ tí wọ́n ti ń fàwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó àti ọgbà ẹ̀wọ̀n nígbà Ogun Àgbáyé Kejì àti lẹ́yìn tógun náà parí.

15 Àpẹẹrẹ kan ni ti ọ̀dọ́kùnrin Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Jámánì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wilhelm. Dípò kó juwọ́ sílẹ̀ nígbà táwọn ọmọ ogun Násì fẹ́ yìnbọn pa á, ńṣe ló jẹ́ adúróṣinṣin. Nínú lẹ́tà ìdágbére tó kọ sáwọn ará ilé rẹ̀, ó sọ pé: “Leke ohun gbogbo a gbọdọ fẹran Ọlọrun, gẹgẹ bi Aṣaaju wa Jesu Kristi ti paṣẹ. Bi a bá mú iduro wa lọdọ rẹ̀, oun yoo san èrè-ẹ̀san fun wa.” Nígbà tó yá, ẹnì kan tó jẹ́ ará ilé ọmọkùnrin yìí sọ ọ̀rọ̀ kan tá a gbé jáde nínú Ilé Ìṣọ́, pé: “La awọn akoko laasigbo kọja, gẹgẹ bi idile kan a ti rí i si pe ifẹ wa fun Ọlọrun ni ó máa nfi igba gbogbo ṣaaju.” Irú ẹ̀mí yẹn náà ni ọ̀pọ̀ àwọn ará wa fi ń fara dà á bí wọ́n ṣe ń sọ wọ́n sẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Àméníà, Eritrea, South Korea àtàwọn ilẹ̀ míì. Àwọn ará wa yìí dúró ṣinṣin lórí ìfẹ́ wọn fún Jèhófà.

16. Kí láwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Màláwì fara dà?

16 Ohun tó ń dán ìgbàgbọ́ àti ìfaradà àwọn ará wa wò ní ọ̀pọ̀ ibi yàtọ̀ sí èyí. Bí àpẹẹrẹ, odindi ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n [26] ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Màláwì fi fara da ìfòfindè, àtakò gbígbóná janjan àtàwọn ìwà ìkà míì tí wọ́n hù sí wọn. Ìfaradà wọn ò já sásán. Nígbà tí inúnibíni bẹ̀rẹ̀, ẹgbàá mẹ́sàn-án [18,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló wà lórílẹ̀-èdè yẹn. Ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà, iye wọn ti ju ìlọ́po méjì lọ, wọ́n ti di ẹgbàá mọ́kàndínlógún, ó lé irinwó dín méje [38,393]. Bó ṣe ń ṣẹlẹ̀ láwọn ilẹ̀ míì náà nìyẹn.

17. Kí làwọn kan ti fara dà látọ̀dọ̀ àwọn ará ilé wọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí, kí ló sì mú kí wọ́n lè fara da ìyà yẹn?

17 Ọ̀tọ̀ ni pé kí wọ́n máa gbéjà ko àwa èèyàn Ọlọ́run lápapọ̀. Ohun míì ni pé kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan dojú kọ àtakò látọ̀dọ̀ àwọn ará ilé rẹ̀. Àwọn ará ilé èèyàn lè máa dà á láàmú. Ṣé kì í ṣohun tí Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé á máa ṣẹlẹ̀ náà nìyẹn? Bẹ́ẹ̀ ni, ó sì ti ṣẹ sí ọ̀pọ̀ nínú wa lára. (Mát. 10:35, 36) Ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló ti fara da àtakò látọ̀dọ̀ àwọn òbí wọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Wọ́n ti lé àwọn kan jáde kúrò nílé, àmọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí onínúure gbà wọ́n sílé. Wọ́n kọ àwọn míì lọ́mọ. Kí ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ láti fara da gbogbo ìyà yẹn? Kì í ṣe pé wọ́n ní ìfẹ́ ará nìkan, pàtàkì jù lọ ibẹ̀ ni ojúlówó ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀.—1 Pét. 1:22; 1 Jòh. 4:21.

18. Báwo ni ìfẹ́ tó ń fara da ohun gbogbo ṣe lè ran àwọn tọkọtaya Kristẹni lọ́wọ́?

18 Ọ̀pọ̀ nǹkan míì ló máa ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé èèyàn tó máa ń gba pé kó lo ìfẹ́ tó ń fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ ló máa ń mú káwọn lọ́kọláya fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ Jésù pé: “Ohun tí Ọlọ́run ti so pọ̀, kí ènìyàn kankan má ṣe yà á sọ́tọ̀.” (Mát. 19:6) Nígbà táwọn tọkọtaya tí wọ́n jẹ́ Kristẹni bá ń “ní ìpọ́njú nínú ẹran ara wọn,” ó yẹ kí wọ́n máa rán ara wọn létí pé Jèhófà jẹ́ ọ̀kan pàtàkì nínú ìdílé àwọn. (1 Kọ́r. 7:28) Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé ìfẹ́ máa ń “fara da ohun gbogbo,” tí ọkọ àti aya kan bá sì gbé ànímọ́ yìí wọ̀ bí ẹ̀wù, á ṣeé ṣe fún wọn láti wà pa pọ̀ tímọ́tímọ́, mìmì kan ò sì ní mi ìgbéyàwó wọn.—Kól. 3:14.

19. Kí làwa èèyàn Ọlọ́run máa ń ṣe nígbà tí àjálù bá wáyé?

19 Ìfẹ́ máa ń ran wá lọ́wọ́ láti fara da ohun gbogbo nígbà àjálù. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nìyẹn nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ wáyé ní apá gúúsù orílẹ̀-èdè Peru àti ìgbà tí ìjì líle kan tí wọ́n ń pè ní Katrina ba apá ibi kan jẹ́ ní gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ni ilé àti ohun ìní wọn bá àwọn àjálù yìí lọ. Ìfẹ́ mú káwọn ará wa nínú ìjọ jákèjádò ayé pèsè àwọn nǹkan ìrànwọ́, tó sì ń mú káwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tún àwọn ilé àti Gbọ̀ngàn Ìjọba tó bà jẹ́ kọ́. Èyí jẹ́ ẹ̀rí pé àwa Kristẹni nífẹ̀ẹ́ láàárín ara wa, a sì máa ń bójú tó ara wa ní gbogbo ìgbà, láìka ohun yòówù tíì báà ṣẹlẹ̀ sí.—Jòh. 13:34, 35; 1 Pét. 2:17.

Ìfẹ́ Kì Í Kùnà Láé

20, 21. (a) Kí nìdí tí ìfẹ́ fi ta yọ lọ́lá? (b) Kí nìdí tó o fi pinnu láti máa lépa ọ̀nà ìfẹ́ tó ta yọ ré kọjá?

20 Àwa èèyàn Jèhófà lóde òní ti rí ọgbọ́n tó wà nínú lílépa ìfẹ́ tó jẹ́ ọ̀nà títayọ ré kọjá. Ní tòótọ́, ìfẹ́ máa ń ta yọ nínú ohun gbogbo. Kíyè sí bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe fa kókó yìí yọ. Lákọ̀ọ́kọ́, ó sọ pé àwọn ẹ̀bùn ẹ̀mí yóò dópin àti pé ìjọ Kristẹni tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ nígbà yẹn yóò fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Lẹ́yìn náà, ó wá parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Nísinsìnyí, bí ó ti wù kí ó rí, àwọn tí ó ṣì wà ni ìgbàgbọ́, ìrètí, ìfẹ́, àwọn mẹ́ta wọ̀nyí; ṣùgbọ́n èyí tí ó tóbi jù lọ nínú ìwọ̀nyí ni ìfẹ́.”—1 Kọ́r. 13:13.

21 Bó pẹ́ bó yá, àwọn ohun tá a ti ní ìgbàgbọ́ nínú wọn yóò ṣẹlẹ̀, táá sì wá di pé a ò ní láti nígbàgbọ́ nínú wọn mọ́. Bákan náà, nígbà tá a bá ti rí ìmúṣẹ àwọn ìlérí tá a ti ń retí tipẹ́, tí ohun gbogbo sì ti dọ̀tun, a ò ní nílò ìrètí nínú wọn mọ́. Àmọ́ ìfẹ́ ńkọ́? Kò ní kùnà láé. Títí láé ló máa wà. Torí pé a máa wà láàyè títí láé, ó dájú pé a óò túbọ̀ máa rí oríṣiríṣi ọ̀nà tí ìfẹ́ Ọlọ́run pín sí, bẹ́ẹ̀ la ó sì máa lóye wọn. Tó o bá ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nípa lílépa ọ̀nà ìfẹ́ tó ta yọ ré kọjá, tí kì í kùnà láé, yóò ṣeé ṣe fún ọ láti dúró títí láé.—1 Jòh. 2:17.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká ṣọ́ra nípa ohun tá a máa nífẹ̀ẹ́?

• Kí ni ìfẹ́ máa mú wa fara dà?

• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé ìfẹ́ kì í kùnà láé?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 27]

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ọdún 2010 ni: ‘Ìfẹ́ a máa fara da ohun gbogbo. Ìfẹ́ kì í kùnà láé.’—1 Kọ́r. 13:7, 8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ń sún wa láti máa jẹ́rìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Ìfẹ́ tí kì í kùnà mú káwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa ní Màláwì fara da àdánwò