Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lè Máa Láyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ọlọ́run Bí Ọwọ́ Rẹ Tiẹ̀ Dí

O Lè Máa Láyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ọlọ́run Bí Ọwọ́ Rẹ Tiẹ̀ Dí

O Lè Máa Láyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ọlọ́run Bí Ọwọ́ Rẹ Tiẹ̀ Dí

JÈHÓFÀ fẹ́ kó o máa láyọ̀. (Sm. 100:2) Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, ó tún ṣeé ṣe kí ọwọ́ rẹ dí. Ọwọ́ rẹ lè ṣàìdí tó báyìí nígbà tó o ṣẹ̀ṣẹ̀ ya ìgbésí ayé rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Àmọ́ ní báyìí, àwọn ojúṣe rẹ nínú ètò Ọlọ́run àti láwọn ibòmíì ti fẹ́ mú kó máa ṣe ọ́ bíi pé ọrùn ń wọ̀ ọ́. Ó tiẹ̀ lè máa dùn ọ́ kó o sì fẹ́ máa dá ara rẹ lẹ́bi nígbà tí o kò bá lè parí gbogbo ohun tó o dáwọ́ lé. Báwo lo ṣe lè ṣe é tí ojúṣe kan ò ní pa òmíràn lára tí wàá sì máa ní “ìdùnnú Jèhófà”?—Neh. 8:10.

Àkókò tá a wà yìí le koko, ìyẹn sì lè mú kí wàhálà pọ̀ níwájú èèyàn, tórí náà a ní láti jẹ́ ẹni tó wà létòlétò. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fúnni ní ìmọ̀ràn kan tí kò ṣe fọwọ́ rọ́ sẹ́yìn lórí ọ̀ràn yìí, ó ní: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí ẹ ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.”—Éfé. 5:15, 16.

Lójú ìmọ̀ràn tó bọ́gbọ́n mu yẹn, báwo lo ṣe lè ní àwọn àfojúsùn tọ́wọ́ rẹ á tẹ̀, tí wàá sì ṣètò ara rẹ, tí ìdákẹ́kọ̀ọ́, àbójútó ìdílé, òde ẹ̀rí, iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àtàwọn ìgbòkègbodò míì tó pọn dandan kò fi ní máa pa ara wọn lára?

Ǹjẹ́ o rántí ayọ̀ tó o ní nígbà tó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run tó o sì ṣe batisí? Ayọ̀ rẹ ń pọ̀ sí i bó o ṣe ń ní ìmọ̀ nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó fẹ́ ṣe. Ó ṣeé ṣe kó o ti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ fún ọ̀pọ̀ oṣù kó o tó ní ìmọ̀ àti ayọ̀ yẹn. Síbẹ̀, o ti rí i pé ìsapá yẹn tó bẹ́ẹ̀, ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn ti mú kí ìgbésí rẹ yí pa dà sí rere.

Kó o má bàa pàdánù ayọ̀ tó o ti ní, o ní láti máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé. Tó bá jẹ́ pé tipátipá lo fi ń ráyè fún kíka Bíbélì àti kíkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, ó yẹ kó o yẹ ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ wò dáadáa. Kódà tó o bá ń fi ìṣẹ́jú mélòó kan lójúmọ́ kẹ́kọ̀ọ́ tó o sì ń ṣàṣàrò, yóò mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ó sì dájú pé ìyẹn yóò fi kún ayọ̀ rẹ.

Ọ̀pọ̀ àwa ìránṣẹ́ Ọlọ́run ló ṣeé ṣe fún láti ra àkókò pa dà ká lè máa fi ṣe àwọn ohun tó ṣe pàtàkì. A lè ṣe èyí nípa dídín àkókò tá a fi ń ṣe àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì kù. Bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni àkókò tí mo ń lò lórí kíka àwọn ìwé ìròyìn ayé, wíwo tẹlifíṣọ̀n, gbígbọ́ orin àti ṣíṣe eré àfipawọ́ ṣe pọ̀ tó?’ Àwọn ohun tá a sọ yìí máa ń dùn mọ́ni téèyàn bá ṣe é níwọ̀ntúnwọ̀nsì. (1 Tím. 4:8) Tó o bá rí i pé ó ń ṣòro fún ọ láti fi ọgbọ́n lo àkókò rẹ, ṣe àwọn ohun táá jẹ́ kó o lè máa tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ rẹ.

Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Adam, tó ní aya àtọmọ mẹ́ta, tó sì tún jẹ́ alàgbà, ṣàlàyé ohun tó ràn án lọ́wọ́, ó ní: “Mo gbìyànjú láti mú kí ìgbésí ayé mi rọrùn. Mi ò kì í ṣe àwọn eré àfipawọ́ tó máa gba gbogbo àkókò mi, mi ò sì ní dúkìá tí yóò máa nílò àbójútó ìgbà gbogbo. Kì í ṣe pé mò ń ṣẹ́ ara mi níṣẹ̀ẹ́ o, ó kàn jẹ́ pé eré ìnàjú tí kò máyé nira ni mo nífẹ̀ẹ́ sí ni.”

Tó o bá ń ṣàṣàrò lórí ohun rere tó ń tìdí ìpinnu rẹ wá, ó lè sọ ayọ̀ rẹ dọ̀tun kó sì mú kó o máa ní èrò tó tọ́. Bí àpẹẹrẹ, arákùnrin kan tó ń jẹ́ Mariusz, tó jẹ́ alàgbà tó sì ní ọmọ mẹ́ta sọ pé: “Nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo dẹni tó ń ní èrò rere nípa ọjọ́ iwájú. Lóòótọ́, mo máa ń níṣòro lọ́pọ̀ ìgbà, Jèhófà nìkan ni ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìṣòro náà sì yé. Àmọ́ mo dúpẹ́ pé kò fi mí sílẹ̀, inú mi ń dùn bí mo ti ń retí ọjọ́ iwájú.”

Bíi ti Mariusz, téèyàn bá ní èrò tó dáa, ìyẹn ò ní kí gbogbo àníyàn èèyàn fò lọ. Àmọ́, ó lè jẹ́ kára tuni, téèyàn á sì túbọ̀ mọ bí yóò ṣe máa bójú tó àwọn ìṣòro ìgbésí ayé. Bíbélì sọ pé: “Búburú ni gbogbo ọjọ́ ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́; ṣùgbọ́n ẹni tí ọkàn-àyà rẹ̀ yá gágá a máa jẹ àsè nígbà gbogbo.” (Òwe 15:15) Tún ronú jinlẹ̀ lórí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ti fi hàn sí ọ. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ yóò tún mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run àti ayọ̀ rẹ túbọ̀ jinlẹ̀.—Mát. 22:37.

Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá fi ti Jèhófà ṣáájú nígbèésí ayé wọn, ayọ̀ wọn á túbọ̀ máa pọ̀ sí i. Tí wọ́n bá ń fi àwọn ànímọ́ Kristẹni ṣèwà hù, èdèkòyédè á dín kù, á sì mú kí ìrẹ́pọ̀ àti adùn wà nínú ìdílé wọn. Nípa báyìí, ilé wọn á jẹ́ ibùjókòó àlàáfíà àti ìṣọ̀kan fún gbogbo ará ilé.—Sm. 133:1.

Bí àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń ṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run pa pọ̀, yóò fi kún ojúlówó ayọ̀ wọn. Mariusz sọ pé: “Mo mọyì àkókò tá à ń lò pa pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdílé. Ìyàwó mi máa ń tì mí lẹ́yìn gbágbáágbá. Kò síbi tí mo wà tí kì í sí lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi tó bá ṣeé ṣe, ì báà ṣe òde ẹ̀rí, ìgbà tí mo bá fẹ́ ṣàtúnṣe pápá ìṣeré tá a ti fẹ́ ṣe àpéjọ, kódà ó máa ń tẹ̀ lé mi lọ sọ àsọyé ní ìjọ míì. Èyí máa ń fún mi níṣìírí gan-an ni.”

Ìwé Mímọ́ pàṣẹ fáwa Kristẹni pé ká máa pèsè fún ìdílé wa. (1 Tím. 5:8) Àmọ́ tí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ bá ń gba àkókò àti okun rẹ ju bó ṣe yẹ lọ, ó lè ba ayọ̀ tó yẹ kó o ní nínú iṣẹ́ Ọlọ́run jẹ́ mọ́ ọ lọ́wọ́. Gbàdúrà sí Jèhófà nípa ọ̀ràn náà. (Sm. 55:22) Àwọn kan ti wá rí i pé táwọn bá fẹ́ fi ọ̀ràn Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, àyàfi káwọn wá iṣẹ́ míì. Kò sí Kristẹni kankan tó yẹ kó tìtorí owó táá máa rí nídìí iṣẹ́ tó ń gba gbogbo àkókò rẹ̀, kó wá pa àwọn nǹkan tẹ̀mí tó ṣe pàtàkì jù tì.—Òwe 22:3.

Ohun kan tó lè ràn ọ́ lọ́wọ́ ni pé kó o ṣàkọsílẹ̀ àwọn àǹfààní àti ìṣòro tó wà nídìí iṣẹ́ kan tó ṣeé ṣe kó o gbà tàbí èyí tó ò ń ṣe lọ́wọ́. Lóòótọ́, kò sẹ́ni tí kò fẹ́ iṣẹ́ tó ń mówó wọlé tó sì ń gbádùn mọ́ni. Àmọ́, ṣé iṣẹ́ tó ò ń ṣe báyìí ń fún ọ láyè láti máa bójú tó ipò tẹ̀mí ìdílé rẹ? Yẹ gbogbo ohun tó wé mọ́ ọ̀ràn náà wò dáadáa, kó o sì ṣèpinnu tó máa jẹ́ kó o lè fi àjọṣe àárín ìwọ àti Jèhófà ṣáájú.

Tó o bá rí i pé iṣẹ́ tó wà lọ́wọ́ rẹ báyìí kò jẹ́ kó rọrùn fún ọ láti máa tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó yẹ kó o tún èrò ara rẹ pa. Ọ̀pọ̀ àwọn ará wa ló ti ṣe ìyípadà tó lágbára torí kí wọ́n lè ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí. Arákùnrin kan lórílẹ̀-èdè Poland sọ pé: “Ìgbà kan wà tó di dandan fún mi láti fi ilé iṣẹ́ tí mo ti ń ṣiṣẹ́ sílẹ̀ torí pé gbogbo ìgbà ni iṣẹ́ máa ń gbé mi rìnrìn àjò. Mi ò ní àkókò tó pọ̀ tó láti bójú tó àwọn nǹkan tẹ̀mí àti ìdílé mi bó ṣe yẹ.” Ní báyìí, iṣẹ́ tí kò gba àkókò àti okun rẹ̀ tó bẹ́ẹ̀ ló fi ń gbọ́ bùkátà.

Wàá Láyọ̀ Tó O Bá Ń Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́

Jésù sọ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ọ̀pọ̀ àǹfààní làwa Kristẹni ní láti máa fúnni ní nǹkan, tó sì máa fún wa láyọ̀. Nígbà míì, tó o bá kàn rẹ́rìn-ín múṣẹ́ sẹ́nì kan, tó o bọ̀ ọ́ lọ́wọ́ tàbí tó o kí i tọkàntọkàn fún iṣẹ́ àṣekára rẹ̀ tó jẹ mọ́ ọ̀ràn ìjọsìn, ìyẹn lásán lè fún ìwọ àti onítọ̀hún láyọ̀.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera.” (1 Tẹs. 5:14) Àwọn tí ìdààmú ọkàn mú kí wọ́n sorí kọ́ lè máa rò pé àwọn ò lè dá nìkan kojú ìṣòro àwọn. Ǹjẹ́ o lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́? Tó o bá rí i pé ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin rẹ kò fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀ mọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, gbìyànjú láti fún un níṣìírí. Ìwọ náà á rí ìṣírí tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn ìṣòro kan wà tí kò sẹ́dàá tó lè yanjú rẹ̀. Àmọ́, o lè ṣe àánú fún arákùnrin rẹ kó o sì rọ̀ ọ́ pé kó gbára lé Jèhófà tí kì í jáni kulẹ̀. Ojú kò ní ti àwọn tó bá gbára lé e láé.—Sm. 27:10; Aísá. 59:1.

Ohun míì tó tún lè ṣàǹfààní ni pé kó o ní kẹ́nì tó dà bíi pé kò láyọ̀ mọ́ jẹ́ kẹ́ ẹ jọ lọ sóde ẹ̀rí. Nígbà tí Jésù rán àwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn jáde, “méjìméjì” ló rán wọn. (Lúùkù 10:1) Ṣé o ò gbà pé ọ̀nà tí wọ́n á fi lè máa fún ara wọn níṣìírí ló fìyẹn ṣe? Ṣé ìwọ náà lè gba ọ̀nà yẹn láti mú káwọn kan tún pa dà ní ayọ̀?

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà lóde òní téèyàn lè torí rẹ̀ máa ṣàníyàn. Síbẹ̀ Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!” (Fílí. 4:4) Nítorí pé o nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, tó o ń gbọ́ràn sí i lẹ́nu tó o sì ń fi ìtara lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ tó gbé lé ọ lọ́wọ́, gbà pé ohun rere lò ń fayé rẹ ṣe. Ó sì yẹ kíyẹn máa fún ọ láyọ̀. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti bójú tó àwọn ìṣòro àti ìdààmú tó ń dojú kọ ẹ́.—Róòmù 2: 6, 7.

À ń fojú ìgbàgbọ́ wo bá a ti ṣe sún mọ́ ayé tuntun tí Jèhófà ṣèlérí rẹ̀ tó. Ẹ ò rí i pé ọ̀pọ̀ ìbùkún nìyẹn máa mú wá, tí yóò sì máa fún wa láyọ̀! (Sm. 37:34) Torí náà, ẹ jẹ́ ká tura ká, ká máa rántí bí Jèhófà ṣe ń bù kún wa tó, kódà nísinsìnyí. Nípa báyìí, a ó lè máa “fi ayọ̀ yíyọ̀ sin Jèhófà.”—Sm. 100:2.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

O lè ní láti ṣàtúnṣe sí bó o ṣe ń lo àkókò rẹ kó o lè máa láyọ̀

ERÉ ÌTURA àti ERÉ ÌNÀJÚ

ÀBOJÚTÓ ILÉ àti ÌDÍLÉ

IṢẸ́ OÚNJẸ ÒÒJỌ́

ÌPÀDÉ ÌJỌ

ÌDÁKẸ́KỌ̀Ọ́

ÒDE Ẹ̀RÍ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ǹjẹ́ o lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti tún pa dà máa láyọ̀?