Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Ọ̀nà wo ni Ọlọ́run lè gbà sọ ọ́ di ọlọ́rọ̀?

Nígbà ìgbà àtijọ́, Jèhófà fi ọrọ̀ jíǹkí àwọn kan bí Ábúráhámù àti Sólómọ́nì. Ṣùgbọ́n ọrọ̀ tí àwa Kristẹni nílò jù lọ tí Ọlọ́run sì lè jẹ́ ká ní, làwọn nǹkan bí ìgbàgbọ́, àlááfíà, ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀.—9/1, ojú ìwé 3 sí 7.

• Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú bí Jésù ṣe fa Pétérù jáde nígbà tó ń rì sínú òkun? (Mát. 14:28-31)

Tá a bá kíyè sí i pé arákùnrin kan ń ṣe ohun tó fi hàn pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ kò tó, àwa náà lè ràn án lọ́wọ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ lè pọ̀ sí i, bí Jésù ti nawọ́ jáde láti fi ran Pétérù lọ́wọ́.—9/15, ojú ìwé 8.

• Kí ni ìdáǹdè wa ná Jèhófà?

Jèhófà fara dà á bí wọ́n ṣe ń dá Ọmọ rẹ̀ lóró tí wọ́n sì ń fi ṣe yẹ̀yẹ́. Gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù sì ṣe múra tán láti fi ọmọ rẹ̀ rúbọ, ó ṣàpẹẹrẹ ohun tí Jèhófà fara dà bí wọ́n ṣe pa Ọmọ rẹ̀ bí ọ̀daràn.—9/15, ojú ìwé 28 àti 29.

• Kí nìdí tí Ìwé Àfọwọ́kọ Vatican fi ṣeyebíye?

Ó jẹ́ ìwé àfọwọ́kọ lédè Gíríìkì. Kò tíì tó ọ̀ọ́dúnrún [300] ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kọ Bíbélì tán tí wọ́n fi kọ ọ́. Gbogbo Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù àti Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì ló fẹ́rẹ̀ẹ́ wà nínú ìwé yìí. Ó jẹ́ ohun táwọn ọ̀mọ̀wé máa ń lò láti fi mọ ohun tó wà nínú ọ̀rọ̀ Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ fọwọ́ kọ sílẹ̀.—10/1, ojú ìwé 18 sí 20.

• Ẹ̀kọ́ wo ni Òwe 24:27 ń kọ́ni nípa ‘gbígbé agbo ilé ró’?

Ọkùnrin kan tó fẹ́ ṣègbéyàwó ní láti múra sílẹ̀ dáadáa láti ṣe ojúṣe rẹ̀. Ara rẹ̀ ni pé kó múra sílẹ̀ láti pèsè nǹkan tara fún ìdílé rẹ̀ kó sì jẹ́ olórí ìdílé táá máa múpò iwájú nínú ìjọsìn.—10/15, ojú ìwé 12.

• Kí nìdí tí kò fi tọ̀nà láti pe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ẹlẹ́sìn Pùròtẹ́sítáǹtì?

Ní ọ̀rúndún kẹrìndínlógún, àwọn tó ń ta ko àṣẹ Póòpù yapa kúrò nínú Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì ní ilẹ̀ Yúróòpù, nítorí àtúnṣe tí wọ́n gbìyànjú láti ṣe. Àwọn tí wọ́n ń lo ọ̀rọ̀ náà “Pùròtẹ́sítáǹtì” fún ni àwọn tó bá ti ń tẹ̀ lé ìlànà ẹgbẹ́ tó fẹ́ ṣe àtúnṣe sí ìsìn Kátólíìkì. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ka póòpù sí aláṣẹ gbogbo gbòò, wọ́n sì fi tọkàntọkàn gbà pé Bíbélì ṣe pàtàkì ká tó lè lóye òtítọ́, síbẹ̀ wọn ò fara mọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ mu tó wọ́pọ̀ nínú àwọn ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì.—11/1, ojú ìwé 19.

• Ṣó pọn dandan kéèyàn kọ́ èdè Hébérù àti Gíríìkì kó tó lè lóye Bíbélì?

Rárá o. Kìkì pé ẹnì kan gbọ́ àwọn èdè yẹn kò ní kó ṣeé ṣe fún onítọ̀hún láti lóye ohun tó wà nínú Bíbélì. Ẹni tó kọ́ àwọn èdè yẹn ṣì máa nílò àwọn ìwé atúmọ̀ èdè àti àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé gírámà. Òtítọ́ náà pé Ọlọ́run rí sí i pé kò sí nǹkan kan tó ṣe ọ̀rọ̀ Ìránṣẹ́ rẹ̀ atóbilọ́lá jù lọ tí wọ́n túmọ̀ sí èdè míì, jẹ́ ẹ̀rí pé èèyàn lè kọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì tí wọ́n túmọ̀ sí àwọn èdè tó wà báyìí kó sì fi í sílò.—11/1, ojú ìwé 20 sí 23.

• Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ ìwà tó bójú mu lélẹ̀ fún wa?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé òun ni Ọba Aláṣẹ ayé òun ọ̀run, inú rere rẹ̀ sí ẹ̀dá èèyàn pọ̀, ó sì ń yẹ́ wọn sí. Nígbà tó ń bá Ábúráhámù àti Mósè sọ̀rọ̀, ó lo ọ̀rọ̀ èdè Hébérù kan tá a sábà máa ń túmọ̀ sí “jọ̀wọ́.” (Jẹ́n. 13:14; Ẹ́kís. 4:6) Ọlọ́run tún máa ń tẹ́tí gbọ́ ẹ̀dá èèyàn. (Jẹ́n. 18:23-32) Jésù náà ṣe bẹ́ẹ̀, ó sì múra tán láti ran àwọn tó wà nítòsí rẹ̀ lọ́wọ́, orúkọ wọn gan-gan ló fi ń pè wọ́n.—11/15, ojú ìwé 25.

• Kì nìdí táwọn Kristẹni tòótọ́ kì í fi í ṣayẹyẹ Ọdún Tuntun?

Ọdún Òṣùpá Tuntun jẹ́ àjọ̀dún pàtàkì táwọn ará Éṣíà máa ń ṣe lọ́dọọdún. Nígbà ayẹyẹ yìí, wọ́n sábà máa ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé àwọn ṣoríire, àwọn sì bọ̀wọ̀ fún ẹ̀mí àwọn òkú. Àwọn Kristẹni tòótọ́ ń bọ̀wọ̀ fún àwọn òbí wọn, wọ́n sì ń bọlá fún wọn, àmọ́ wọn kì í lọ́wọ́ nínú àsè tó dá lórí níní ìfararora pẹ̀lú àwọn bàbá ńlá wọn tó ti kú, torí kí wọ́n lè dáàbò bò wọ́n tàbí kí wọ́n lè rí ojúure àwọn òòṣà ìdílé.—12/1, ojú ìwé 20 sí 23.