Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu

Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu

Èrò Tó Yẹ Kó O Ní Nípa Ọtí Mímu

Ó ṢEÉ ṣe kí Tony tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ ṣì máa gbádùn ìgbésí ayé tó yàtọ̀ báyìí ká ní ó gbà pé òun níṣòro ọtí mímu. Àmọ́, torí pé ó lè mu ọtí tó pọ̀ tí nǹkan kan kò sì ní ṣe é, ó rò pé òun kò níṣòro. Kí nìdí tí èrò rẹ̀ kò fi tọ̀nà?

Ọtí àmujù kò jẹ́ kí Tony ronú dáadáa mọ́. Bóyá ó mọ̀ tàbí kò mọ̀, ọpọlọ rẹ̀ kò lè ṣiṣẹ́ dáadáa mọ́ nígbàkigbà tó bá ti mutí yó, ìyẹn sì máa ń ṣàkóbá fún àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ títí kan ìrònú àti ìhùwàsí rẹ̀. Bí Tony bá ṣe mutí yó tó, bẹ́ẹ̀ ló ṣe túbọ̀ ń ṣàkóbá fún ọpọlọ rẹ̀, èyí kò sì jẹ́ kó lè ronú lọ́nà tó tọ́ nípa ara rẹ̀.

Ohun kejì tí kò jẹ́ kí Tony lè ronú lọ́nà tó tọ́ nípa ara rẹ̀ ni pé kò fẹ́ láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù. Allen, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ àkọ́kọ́ náà kọ́kọ́ jiyàn pé òun kò níṣòro ọtí mímu. Ó ní: “Mo máa ń ṣe bí ẹni tí kì í mu ọtí, mo máa ń wá àwáwí, mo sì máa ń ṣe bí ẹni pé ọtí díẹ̀ ni mo máa ń mu. Ìdí tí mo fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé, mi ò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé mò ń mutí púpọ̀.” Nígbà míì pàápàá táwọn èèyàn bá kíyè sí i pé Tony àti Allen ti ń mutí lámujù, ńṣe ni wọ́n máa ń sọ pé àwọn ò níṣòro. Àwọn méjèèjì ní láti wá nǹkan kan ṣe sí ọtí àmujù wọn. Àmọ́ kí ni wọ́n máa ṣe sí i?

Wá Nǹkan Ṣe Sí I!

Ọ̀pọ̀ èèyàn tó ti fi ọtí àmujù sílẹ̀ ló ti ṣe ohun tí Jésù wí pé: “Wàyí o, bí ojú ọ̀tún rẹ yẹn bá ń mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ jáde, kí o sì sọ ọ́ nù kúrò lọ́dọ̀ rẹ. Nítorí ó ṣàǹfààní púpọ̀ fún ọ kí o pàdánù ọ̀kan nínú àwọn ẹ̀yà ara rẹ ju kí a gbé gbogbo ara rẹ sọ sínú Gẹ̀hẹ́nà.”—Mátíù 5:29.

Àmọ́ ṣá o, Jésù kò sọ pé ká gé ẹ̀yà ara wa sọ nù o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tó ń fi àkàwé yẹn kọ́ wa ni pé ká múra tán láti mú àwọn nǹkan tó máa ṣèpalára fún wa nípa tẹ̀mí kúrò nínú ayé wa. Lóòótọ́, àwọn àtúnṣe tá a bá ṣe lè fa ìnira tó pọ̀ gan-an, àmọ́ tá a bá ṣe é, ó máa dáàbò bò wá kúrò nínú àwọn ohun tó lè yọrí sí mímu ọtí lámujù. Torí náà, táwọn èèyàn bá sọ fún ẹ pé ọtí tó ò ń mu ti ń pọ̀ jù, wá nǹkan ṣe sí i. a Tó o bá sì rí i pé o ò lè ṣàtúnṣe sí bó o ṣe ń mutí, pinnu láti fi í sílẹ̀. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé èyí kò rọrùn, ó ṣì sàn ju pé kí ayé èèyàn bà jẹ́ lọ.

Ká ní o ò tiẹ̀ kì í ṣe ọ̀mùtí, ǹjẹ́ o máa ń mutí gan-an? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àwọn nǹkan wo lo lè ṣe tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa lo ọtí bó ṣe yẹ?

Ibi Tó O Ti Lè Rí Ìrànwọ́

1. Ní ìgbàgbọ́ nínú agbára àdúrà àtọkànwá tó ò ń gbà déédéé. Bíbélì gba gbogbo àwọn tó fẹ́ ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí nímọ̀ràn pé: “Nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:6, 7) Kí lo lè máa gbàdúrà nípa rẹ̀ kó o bàa lè nírú àlàáfíà ọkàn yìí?

Gbà pé òótọ́ lo níṣòro ọtí mímu, ìwọ fúnra rẹ lo sì máa bójú tó o. Tó o bá sọ ohun tó o fẹ́ ṣe nípa ọ̀rọ̀ náà fún Ọlọ́run, èyí á jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí kó o má bàa kó sínú ìṣòro púpọ̀ sí i. “Ẹni tí ó bá ń bo àwọn ìrélànàkọjá rẹ̀ mọ́lẹ̀ kì yóò kẹ́sẹ járí, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá jẹ́wọ́ tí ó sì fi wọ́n sílẹ̀ ni a ó fi àánú hàn sí.” (Òwe 28:13) Jésù tún sọ pé a lè gbàdúrà pé: “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 6:13) Àmọ́, báwo lo ṣe lè máa ṣe ohun tó bá àdúrà rẹ mu, ibo lo sì ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ẹ̀bẹ̀ rẹ?

2. Gba agbára látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. “Nítorí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yè, ó sì ń sa agbára, . . . ó sì lè fi òye mọ ìrònú àti àwọn ìpètepèrò ọkàn-àyà.” (Hébérù 4:12) Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń mutí lámujù ló ti rí ìrànwọ́ gbà nípa kíkà Bíbélì àti ríronú jinlẹ̀ lórí rẹ̀ lójoojúmọ́. Ọ̀kan lára àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run tó wà lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù sọ pé, “Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú. . . . Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. . . . Gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”—Sáàmù 1:1-3.

Allen, kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ẹ̀kọ́ yìí sì fún un lókun láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù, ó ní: “Ó dá mi lójú pé, tí kì í bá ṣe Bíbélì àtàwọn ìlànà Bíbélì tó ràn mí lọ́wọ́ láti jáwọ́ ọtí mímu, màá ti kú.”

3. Máa kó ara rẹ níjàánu. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn tó jẹ́ ọ̀mùtí nígbà kan rí nínú ìjọ Kristẹni ti dẹni tá a wẹ̀ mọ́ nípasẹ̀ “ẹ̀mí Ọlọ́run wa.” (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Lọ́nà kan, wọ́n ti rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù àti àríyá aláriwo torí pé wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ láti máa kóra wọn níjàánu, ipasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run sì ni èèyàn fi máa ń ní ànímọ́ yìí. “Ẹ má ṣe máa mu wáìnì ní àmupara, nínú èyí tí ìwà wọ̀bìà wà, ṣùgbọ́n ẹ máa kún fún ẹ̀mí.” (Éfésù 5:18; Gálátíà 5:21-23) Jésù Kristi ṣèlérí pé, “Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀.” Torí náà, “ẹ máa bá a nìṣó ní bíbéèrè, a ó sì fi í fún yín.”—Lúùkù 11:9, 13.

Àwọn tó bá fẹ́ jọ́sìn Jèhófà lọ́nà tó fẹ́ lè ní ìkóra-ẹni-níjàánu tí wọ́n bá ń ka Bíbélì, tí wọ́n sì ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń gbàdúrà àtọkànwá sí í nígbà gbogbo. Dípò tí wàá fi rẹ̀wẹ̀sì, jẹ́ kí ìlérí yìí tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dá ẹ lójú pé: “Ẹni tí ń fúnrúgbìn pẹ̀lú níní ẹ̀mí lọ́kàn yóò ká ìyè àìnípẹ̀kun láti inú ẹ̀mí. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ní àsìkò yíyẹ àwa yóò kárúgbìn bí a kò bá ṣàárẹ̀.”—Gálátíà 6:8, 9.

4. Yan àwọn ọ̀rẹ́ rere. “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ní ìbálò pẹ̀lú àwọn arìndìn yóò rí láburú.” (Òwe 13:20) Sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ nípa ìpinnu tó o ṣe láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù. Tipẹ́tipẹ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti kìlọ̀ fún wa pé tá a bá jáwọ́ “àṣejù nídìí wáìnì, àwọn àríyá aláriwo, [àti] ìfagagbága ọtí mímu,” ó lè ‘rú àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ wa lójú, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í bú wa.’ (1 Pétérù 4:3, 4) Pinnu láti jáwọ́ àjọṣe pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tí kò bọ̀wọ̀ fún ìpinnu rẹ láti ṣàtúnṣe sí bó o ṣe ń mutí lámujù.

5. Ṣe ìpinnu tó ṣe pàtó. “Ẹ sì jáwọ́ nínú dídáṣà ní àfarawé ètò àwọn nǹkan yìí, ṣùgbọ́n ẹ para dà nípa yíyí èrò inú yín padà, kí ẹ lè ṣàwárí fúnra yín ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Tó o bá jẹ́ kí àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó ṣe pàtó dípò tí wàá fi jẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ rẹ tàbí “ètò àwọn nǹkan yìí” ṣe é fún ọ, wàá gbádùn ìgbésí ayé tínú Ọlọ́run dùn sí. Báwo lo ṣe lè pinnu ìwọ̀n tí kò ní ṣèpalára fún ẹ?

Ìwọ̀n ọtí tí ò ní jẹ́ kó o lè ronú bó ṣe yẹ ti pọ̀ jù fún ẹ. Torí náà, tó o bá fẹ́ mutí, kò bọ́gbọ́n mu láti mutí débi tó fi máa wọ̀ ẹ́ lára. Gbà pé o níṣòro ọtí mímu, ìyẹn á jẹ́ kó o lè mọ ìwọ̀n ọtí tó yẹ kó o mu. Torí náà, mọ iye pàtó tó o lè mu, tí kò ní jẹ́ kó o di alámujù.

6. Mọ bá a ṣe ń sọ pé mi ò fẹ́. “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Mọ bó o ṣe lè fi ohùn pẹ̀lẹ́ kọ̀ jálẹ̀ nígbà tí ẹnì kan tó gbà ẹ́ lálejò bá ń rọ̀ ẹ́ pé kó o mutí. “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.”—Kólósè 4:6.

7. Jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì ràn ẹ́ lọ́wọ́. Ní kí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tó máa fún ẹ lókun láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù, tí wọ́n sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. “Ẹni méjì sàn ju ẹnì kan, nítorí pé wọ́n ní ẹ̀san rere fún iṣẹ́ àṣekára wọn. Nítorí, bí ọ̀kan nínú wọn bá ṣubú, èkejì lè gbé alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ dìde.” (Oníwàásù 4:9, 10; Jákọ́bù 5:14, 16) Àjọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà Tó Ń Rí sí Ọtí Àmupara àti Sísọ Ọtí Mímu Di Bárakú sọ pé: “Nígbà míì, ó lè ṣòro fún ẹnì kan láti dín ọtí tó ń mu kù. Ní kí ìdílé àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jáwọ́ nínú ọtí àmujù.”

8. Dúró lórí ìpinnu rẹ. “Ẹ di olùṣe ọ̀rọ̀ náà, kì í sì í ṣe olùgbọ́ nìkan, ní fífi èrò èké tan ara yín jẹ. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń wo inú òfin pípé tí í ṣe ti òmìnira ní àwòfín, tí ó sì tẹpẹlẹ mọ́ ọn, ẹni yìí, nítorí tí kò di olùgbọ́ tí ń gbàgbé, bí kò ṣe olùṣe iṣẹ́ náà, yóò láyọ̀ nínú ṣíṣe é.”—Jákọ́bù 1:22, 25.

Bó O Ṣe Lè Jáwọ́ Nínú Ọtí Àmujù

Kì í ṣe gbogbo àwọn tó máa ń mutí gan-an ló ń di ọ̀mùtí. Àmọ́ àwọn kan bẹ̀rẹ̀ sí í mutí léraléra débi pé ọtí mímu di bárakú fún wọn. Nítorí pé ẹni tó sọ ọtí mímu di bárakú ti jẹ́ kí èròjà kan tó lè ṣèpalára fún ìrònú àti ìhùwàsí èèyàn mọ́ òun lára, irú ẹni bẹ́ẹ̀ nílò ìrànlọ́wọ́ nípa tẹ̀mí àti ìpinnu gbòógì láti jáwọ́ nínú àṣà yìí. Allen rántí ohun tó ṣẹlẹ̀ sí òun, ó ní, “Nǹkan ò rọgbọ fún mi rára nígbà tí mo fi ọtí mímu sílẹ̀. Ìgbà yẹn ni mo wá rí i pé mo nílò ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà láfikún sí ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí tí mò ń gbà.”

Ọ̀pọ̀ ọ̀mùtí ló nílò ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà kí wọ́n lè lókun láti ja ìjà tẹ̀mí tó máa jẹ́ kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ọtí àmujù. b Àwọn kan ní láti lọ sílé ìwòsàn kí wọ́n bàa lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn nǹkan tí jíjáwọ́ nínú ọtí àmujù máa ń fà tàbí kí wọ́n gba ìtọ́jú láti lè dín bí ọtí ṣe máa ń wù wọ́n mu lódìlódì kù, kí wọ́n sì lè jáwọ́ pátápátá nínú ọtí mímu. Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ oníṣẹ́ ìyanu sọ pé: “Àwọn tí wọ́n lókun kò nílò oníṣègùn, ṣùgbọ́n àwọn tí ń ṣàmódi nílò rẹ̀.”—Máàkù 2:17.

Àǹfààní Tó Wà Nínú Ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run

Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́ tó fẹ́ ire fún wa, tó sì tún ń fẹ́ ká gbádùn nísinsìnyí àti títí ayérayé ni ìmọ̀ràn Bíbélì tó bọ́gbọ́n mu nípa ọtí mímu ti wá. Lẹ́yìn ọdún mẹ́rìnlélógún tí Allen ti jáwọ́ nínú ọtí mímu, ó sọ pé: “Ìyanu gbáà ló jẹ́ pé mo lè yí pa dà, pé Jèhófà fẹ́ láti ràn mí lọ́wọ́ láti tún ìgbésí ayé mi ṣe, pé . . .” Ó mí kanlẹ̀, kò fẹ́ kí omi bọ́ lójú òun, lẹ́yìn náà, ó wá sọ pé: “Ún-ùn, . . . ìyanu ńlá gbáà ló jẹ́ láti mọ̀ pé Jèhófà mọ ohun tó ń ṣe mi, pé ó bìkítà nípa mi, ó sì ń fún mi ní ìrànwọ́ tí mo nílò.”

Torí náà, tó o bá níṣòro ọtí àmujù tàbí tí ọtí bá ti di bárakú fún ẹ, má ṣe yára parí èrò sí pé kò sí ọ̀nà àbáyọ mọ́. Allen àti àìmọye èèyàn ló ti nírú ìṣòro tó o ní yìí rí, àmọ́ tí wọ́n ti dín ọtí tí wọ́n ń mu kù tàbí tí wọ́n ti jáwọ́ pátápátá nínú rẹ̀. Wọn ò kábàámọ̀ lórí ohun tí wọ́n ṣe, ìwọ náà ò sì ní kábàámọ̀.

Bóyá o yàn láti máa mutí níwọ̀ntúnwọ̀nsì tàbí o kò fẹ́ mu ún rárá, fi ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run fún wa yìí sílò, ó ní: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.”—Aísáyà 48:18.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpótí náà,  “Ṣé Mo Ti Ń Mu Àmujù?” ojú ìwé 8.

b Ọ̀pọ̀ ilé ìtọ́jú, ilé ìwòsàn àtàwọn ètò ló wà láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tó ń mutí àmujù. Àmọ́, ìwé ìròyìn yìí kò sọ pé irú ìtọ́jú kan pàtó ló dára jù. Ẹnì kọ̀ọ̀kàn ló yẹ kó fara balẹ̀ gbé oríṣiríṣi ìtọ́jú tó wà yẹ̀ wò, kó sì ṣe ìpinnu tí kò ta ko àwọn ìlànà Bíbélì.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

 Ṣé Mo Ti Ń Mu Àmujù?

O lè béèrè lọ́wọ́ ara rẹ pé:

• Ṣé ọtí tí mò ń mu ti ń pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

• Ṣé mo máa ń mutí níye ìgbà tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

• Ǹjẹ́ mo ti ń mu ọtí tó le ju ti tẹ́lẹ̀ lọ?

• Ṣé mo máa ń fi ọtí pàrònú rẹ́?

• Ǹjẹ́ ọ̀rẹ́ tàbí mọ̀lẹ́bí mi kan kọminú sí bí mo ṣe ń mutí?

• Ṣé ọtí ti dá ìṣòro sílẹ̀ fún mi rí ní ilé, ní ibi iṣẹ́ tàbí nígbà tí mo lọ kí àwọn èèyàn?

• Ṣé ó lè ṣòro fún mi láti wà láìmu ọtí fún ọ̀sẹ̀ kan?

• Ǹjẹ́ inú máa ń bí mi nígbà tí àwọn ẹlòmíì bá kọ̀ láti mutí?

• Ṣé mo máa ń fi bí ọtí tí mò ń mu ṣe pọ̀ tó pa mọ́ fún àwọn èèyàn?

Tó o bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni sí ọ̀kan tàbí ọ̀pọ̀ lára àwọn ìbéèrè yìí, ó yẹ kó o wá nǹkan ṣe sí bó o ṣe ń mutí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Bó O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Nípa Ọtí Mímu

Kó o tó mutí, gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò:

Ǹjẹ́ ó bọ́gbọ́n mu fún mi láti mu ọtí tàbí kí n má ṣe mutí rárá?

Àmọ̀ràn: Kí ẹni tí kò bá lè pinnu iye pàtó tó yẹ kóun mu má ṣe mutí rárá.

Báwo ni ọtí tí mo fẹ́ mu ṣe yẹ kó pọ̀ tó?

Àmọ̀ràn: Pinnu ìwọ̀n tó o máa mu kí ọtí tó ṣàkóbá fún ìrònú rẹ.

Ìgbà wo ló yẹ kí n mutí?

Àmọ̀ràn: Kò dára láti mutí tó o bá fẹ́ wa ọkọ̀ tàbí tó o bá fẹ́ ṣe àwọn ohun tó béèrè pé kó o wà lójúfò, kò dára láti mutí nígbà tó o bá fẹ́ lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìjọsìn, nígbà tó o bá lóyún, kò sì tún dára nígbà tó o bá ń lo oríṣi àwọn oògùn kan fún ìtọ́jú ara rẹ.

Ibo ló yẹ kí n ti mutí?

Àmọ̀ràn: Ní àwùjọ tó lọ́wọ̀, kì í ṣe ní ìkọ̀kọ̀ káwọn èèyàn má bàa mọ bí ọtí tí ò ń mu ṣe pọ̀ tó, kì í ṣe níbi tí àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí ọtí mímu bá wà.

Èmi àti ta ni a lè jọ mutí?

Àmọ̀ràn: Pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n jẹ́ ọmọlúwàbí, kì í ṣe pẹ̀lú àwọn tó níṣòro ọtí mímu.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ran Ọ̀mùtí Kan Lọ́wọ́

Ọ̀mùtí paraku ní Ọ̀gbẹ́ni Supot, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Thailand. Nígbà tó kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, ìrọ̀lẹ́ nìkan ló máa ń mutí. Nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í mutí láàárọ̀ àti lákòókò oúnjẹ ọ̀sán. Torí kó lè mutí yó ló ṣe máa ń mutí lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́ nígbà tó yá, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tí Supot kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà Ọlọ́run kò fọwọ́ sí àmupara, ó jáwọ́ nínú ọtí mímu. Síbẹ̀, lẹ́yìn àkókò díẹ̀, ó tún pa dà sídìí àmujù rẹ̀. Èyí sì jẹ́ kọ́rọ̀ náà sú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀.

Àmọ́, Supot ṣì nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì fẹ́ láti jọ́sìn rẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Àwọn ọ̀rẹ́ Supot ń ràn án lọ́wọ́, wọ́n sì gba ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ níyànjú pé kí wọ́n túbọ̀ máa lo àkókò tó pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí wọ́n má sì jẹ́ kó sú wọn. Ọ̀rọ̀ tó sojú abẹ níkòó tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 6:10 pé àwọn ‘ọ̀mùtípara kò ní jogún ìjọba Ọlọ́run’ ran Supot lọ́wọ́ láti rí i pé ọ̀rọ̀ òun ń fẹ́ àtúnṣe ní kíákíá. Ó wá rí i pé ó yẹ kóun ṣe gbogbo ohun tóun lè ṣe láti borí ìṣòro ọtí mímu.

Supot wá pinnu lákòókò yìí láti jáwọ́ pátápátá nínú ọtí mímu. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ agbára ẹ̀mí mímọ́, ìtọ́sọ́nà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ìrànwọ́ látọ̀dọ̀ ìdílé àti ìjọ Ọlọ́run, Supot rí okun tẹ̀mí gbà, ó sì borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tó ní fún ọtí mímu. Inú ìyàwó àtàwọn ọmọ rẹ̀ dùn gan-an nígbà tó ṣèrìbọmi láti fi hàn pé òun ti ya ara òun sí mímọ́ fún Ọlọ́run. Ní báyìí, Supot ti ń gbádùn ohun tó ti ń wù ú tipẹ́tipẹ́, ìyẹn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì tún ń lo àkókò rẹ̀ láti máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí.