Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ Fún Jèhófà?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ Fún Jèhófà?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Ya Ara Rẹ Sí Mímọ́ Fún Jèhófà?

“Ní òru yìí, áńgẹ́lì kan ti Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀ . . . dúró tì mí.”—ÌṢE 27:23.

1. Kí ni àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi ti kọ́kọ́ ṣe, àwọn ìbéèrè wo lèyí sì mú wá?

 “LỌ́LÁ ẹbọ Jésù Kristi, ǹjẹ́ o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣé o sì ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?” Èyí jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìbéèrè méjì tí àwọn tó fẹ́ ṣèrìbọmi máa ń dáhùn ní ìparí àsọyé ìrìbọmi. Kí nìdí táwa Kristẹni fi ní láti ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà? Àǹfààní wo ló wà nínú yíya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run? Kí nìdí tó fi pọn dandan kéèyàn ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run kí ìjọsìn rẹ̀ tó lè ní ìtẹ́wọ́gbà? Láti lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí, ó yẹ ká kọ́kọ́ mọ ohun tí ìyàsímímọ́ túmọ̀ sí.

2. Kí ló túmọ̀ sí láti ya ara ẹni sí mímọ́ fún Jèhófà?

2 Kí ló túmọ̀ sí láti ya ara ẹni sí mímọ́ fún Ọlọ́run? Kíyè sí ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa àjọṣe tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Nígbà kan tó ń bá àwọn èrò tó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ojú omi kan tí ìjì líle ń gbé sọ̀rọ̀, ó pe Jèhófà ní “Ọlọ́run tí mo jẹ́ tirẹ̀.” (Ka Ìṣe 27:22-24.) Gbogbo Kristẹni tòótọ́ ló jẹ́ ti Jèhófà. Àmọ́, àwọn èèyàn ayé lápapọ̀, wà “lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòh. 5:19) Àwọn Kristẹni ń di ti Jèhófà nígbà tí wọ́n bá ya ara wọn sí mímọ́ fún un lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà, nípasẹ̀ àdúrà. Irú ìyàsímímọ́ bẹ́ẹ̀ jẹ́ ẹ̀jẹ́ téèyàn fúnra rẹ̀ jẹ́ fún Jèhófà. Ìrìbọmi ló sì máa ń tẹ̀ lé e.

3. Kí ni ìrìbọmi Jésù ṣàpẹẹrẹ, báwo sì ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

3 Jésù fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ fún wa nígbà tó dìídì pinnu láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Torí pé inú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà ni wọ́n bí i sí, ó ti dẹni tá a yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run látìgbà tí wọ́n ti bí i. Síbẹ̀, nígbà tó ṣèrìbọmi, ó ṣe kọjá ohun tí Òfin Mósè là kalẹ̀ pé káwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ṣe. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi hàn pé ohun tó sọ ni pé: “Wò ó! Mo dé . . . láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.” (Héb. 10:7; Lúùkù 3:21) Torí náà, ohun tí ìrìbọmi Jésù ṣàpẹẹrẹ ni bó ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún Ọlọ́run láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Àpẹẹrẹ rẹ̀ ni àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ náà ń tẹ̀ lé nígbà tí wọ́n bá ṣe ìrìbọmi. Àmọ́ ṣá o, ohun tí wọ́n ń fi hàn ní gbangba nípasẹ̀ ìrìbọmi tiwọn ni pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run nípasẹ̀ àdúrà.

Àǹfààní Tá À Ń Rí Nínú Ìyàsímímọ́

4. Kí ni ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó wà láàárín Dáfídì àti Jónátánì kọ́ wa nípa ṣíṣe ojúṣe ẹni?

4 Ọ̀ràn pàtàkì ni ìyàsímímọ́ àwa Kristẹni jẹ́. Kì í wulẹ̀ ṣe àdéhùn ṣákálá kan lásán. Àmọ́ àǹfààní wo là ń rí nínú ṣíṣe ìyàsímímọ́? Ẹ jẹ́ ká fọ̀rọ̀ yìí wé àǹfààní tó wà nínú pé kí àwọn èèyàn tó bára wọn ṣàdéhùn máa ṣe ojúṣe wọn. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ìwọ àti ẹnì kan yàn láti máa bára yín ṣọ̀rẹ́. Kó o tó lè gbádùn ọ̀rẹ́ rẹ dáadáa, o ní láti máa ṣe ohun tó fi ẹ́ hàn bí ọ̀rẹ́ gidi. Èyí fi hàn pé o gbọ́dọ̀ máa fi ọ̀rọ̀ ọ̀rẹ́ rẹ sọ́kàn, kó o sì máa gba tiẹ̀ rò. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀rẹ́ tí ọ̀rọ̀ wọn wọ̀ jù lọ tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn ni Dáfídì àti Jónátánì. Kódà, wọ́n bára wọn dá májẹ̀mú. (Ka 1 Sámúẹ́lì 17:57; 18:1, 3.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú ọ̀rẹ́ tí wọ́n bára wọn ṣe yẹn kò wọ́pọ̀, síbẹ̀ táwọn tó ń bára wọn ṣọ̀rẹ́ bá ń fi ọwọ́ pàtàkì mú àjọṣe tó wà láàárín àwọn méjèèjì, tí wọ́n ń ṣe ojúṣe wọn, àárín wọn á gún régé.—Òwe 17:17; 18:24.

5. Báwo ni ẹrú kan ṣe lè jàǹfààní títí láé bó bá wà lábẹ́ ọ̀gá tó ń ṣe dáadáa sí i?

5 Nínú Òfin tí Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, a tún rí irú àjọṣe míì tó máa ń ṣe àwọn èèyàn láǹfààní bí wọ́n bá fọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn tí wọ́n bára wọn ṣe. Bí àpẹẹrẹ, tí ẹrú kan bá fẹ́ máa gbé títí lọ pẹ̀lú ọ̀gá rẹ̀ tó ń ṣe dáadáa sí i, ó lè bá ọ̀gá náà ṣe àdéhùn tí kò lè yí pa dà pé títí ayé ni òun á fi máa sìn ín. Òfin yẹn sọ pé: “Bí ẹrú náà bá fi ìtẹpẹlẹmọ́ wí pé, ‘Mo nífẹ̀ẹ́ ọ̀gá mi, aya mi àti àwọn ọmọ mi ní ti gidi; èmi kò fẹ́ jáde lọ gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a dá sílẹ̀ lómìnira,’ nígbà náà, kí ọ̀gá rẹ̀ mú un sún mọ́ Ọlọ́run tòótọ́, kí ó sì mú un wá síbi ilẹ̀kùn tàbí òpó ilẹ̀kùn; kí ọ̀gá rẹ̀ sì fi òòlu lu etí rẹ̀, kí ó sì jẹ́ ẹrú rẹ̀ fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Ẹ́kís. 21:5, 6.

6, 7. (a) Báwo làwọn èèyàn ṣe ń jàǹfààní látinú bíbá ara wọn ṣe àdéhùn? (b) Kí nìyẹn fi hàn nípa àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà?

6 Ìgbéyàwó jẹ́ àjọṣe tó gba pé kéèyàn fọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn. Kì í ṣe àdéhùn orí ìwé tó dá lórí iṣẹ́ kan lásán, àdéhùn pẹ̀lú ẹlòmíì ni. Àmọ́ tẹ́ni méjì bá kàn ń gbé pa pọ̀ láìṣe ìgbéyàwó, kò lè sí ìbàlẹ̀ ọkàn gidi kan fún àwọn àtàwọn ọmọ wọn. Àmọ́, ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ mú kó pọn dandan fún tọkọtaya tó bá fọwọ́ pàtàkì mú àdéhùn tí wọ́n bára wọn ṣe nínú ìgbéyàwó tó lọ́lá, pé kí wọ́n máa fi ìfẹ́ yanjú aáwọ̀ èyíkéyìí tó bá wáyé láàárín wọn.—Mát. 19:5, 6; 1 Kọ́r. 13:7, 8; Héb. 13:4.

7 Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, a rí àwọn tó jàǹfààní látinú àdéhùn láti gbani síṣẹ́ tàbí láti jọ dòwò pọ̀. (Mát. 20:1, 2, 8) Bọ́rọ̀ sì ṣe rí lónìí náà nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, ká tó lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣe òwò kan tàbí ká tó lè bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ níléeṣẹ́ kan, ó máa ṣàǹfààní tá a bá kọ́kọ́ tọwọ́ bọ ìwé àdéhùn. Torí náà, bí ṣíṣe àdéhùn bá ń mú kí àjọṣe tó wà láàárín ọ̀rẹ́ àtọ̀rẹ́, tọkọtaya àti ẹni tá a gbà síṣẹ́ àti ọ̀gá tó gbà á síṣẹ́ gún régé, ó dájú pé àǹfààní tó ju ìyẹn lọ máa wà nínú àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà bó o bá ya ara rẹ sí mímọ́ fún un pátápátá! Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá ṣàgbéyẹ̀wò báwọn tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run látijọ́ ṣe jàǹfààní, ká bàa lè rí bí èyí ṣe yàtọ̀ sí àdéhùn ṣákálá lásán.

Báwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Ṣe Jàǹfààní Látinú Ìyàsímímọ́

8. Kí ni bá a ṣe ya orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí?

8 Ìgbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì lápapọ̀ jẹ́jẹ̀ẹ́ pé àwọn á máa ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ni wọ́n di orílẹ̀-èdè tá a yà sí mímọ́ fún Jèhófà. Jèhófà ní kí wọ́n kóra jọ sí tòsí Òkè Sínáì, ó wá sọ fún wọn pé: “Bí ẹ̀yin yóò bá ṣègbọràn délẹ̀délẹ̀ sí ohùn mi, tí ẹ ó sì pa májẹ̀mú mi mọ́ ní ti gidi, dájúdájú, nígbà náà, ẹ̀yin yóò di àkànṣe dúkìá mi nínú gbogbo àwọn ènìyàn yòókù.” Gbogbo wọn sì panu pọ̀ dáhùn pé: “Gbogbo ohun tí Jèhófà sọ ni àwa ti múra tán láti ṣe.” (Ẹ́kís. 19:4-8) Bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣe di èyí tá a yà sí mímọ́ yìí, kọjá kéèyàn ṣe àdéhùn pé òun á máa ṣe ojúṣe kan. Ohun tó túmọ̀ sí ni pé wọ́n ti di ti Jèhófà, Jèhófà sì kà wọ́n sí “àkànṣe dúkìá” rẹ̀.

9. Báwo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe jàǹfààní látinú bá a ṣe yà wọ́n sí mímọ́ fún Ọlọ́run?

9 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí àǹfààní látinú jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ti Jèhófà. Jèhófà ò yẹ àdéhùn rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó sì ń tọ́jú wọn bí òbí tó mọyì ọmọ ṣe máa ń tọ́jú ọmọ rẹ̀. Ọlọ́run sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Aya ha lè gbàgbé ọmọ ẹnu ọmú rẹ̀ tí kì yóò fi ṣe ojú àánú sí ọmọ ikùn rẹ̀? Àní àwọn obìnrin wọ̀nyí lè gbàgbé, síbẹ̀, èmi kì yóò gbàgbé” yín. (Aísá. 49:15) Jèhófà fún wọn ní Òfin tá máa tọ́ wọn sọ́nà, ó rán àwọn wòlíì sí wọn láti máa fún wọn níṣìírí, ó sì tún rán àwọn áńgẹ́lì sí wọn láti máa dáàbò bò wọ́n. Onísáàmù kan sọ pé: “Ó ń sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ fún Jékọ́bù, ó ń sọ àwọn ìlànà rẹ̀ àti àwọn ìpinnu ìdájọ́ rẹ̀ fún Ísírẹ́lì. Kò ṣe bẹ́ẹ̀ fún orílẹ̀-èdè èyíkéyìí mìíràn.” (Sm. 147:19, 20; ka Sáàmù 34:7, 19; 48:14.) Bí Jèhófà ṣe bójú tó orílẹ̀-èdè tó jẹ́ tirẹ̀ látijọ́ bẹ́ẹ̀ náà ni yóò ṣe máa bójú tó àwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún un lóde òní.

Ìdí Tó Fi Yẹ Ká Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run

10, 11. Ṣé inú agboolé Ọlọrun tó jẹ́ tàwọn ẹ̀dá pípé ni wọ́n bí wa sí? Ṣàlàyé.

10 Bí àwọn kan bá ń ronú nípa ìyàsímímọ́ àti ìrìbọmi, wọ́n lè máa dà á rò pé, ‘Kí ló dé tó fi jẹ́ pé mi ò lè sin Ọlọ́run láì ya ara mi sí mímọ́ fún un?’ A óò rí ìdí tí èyí fi ṣe kedere tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò ipò tá a wà níwájú Ọlọ́run. Má ṣe gbàgbé pé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, wọn ò bí wa sínú agbo ilé àwọn ẹ̀dá pípé tó jẹ́ ti Ọlọ́run. (Róòmù 3:23; 5:12) Torí náà, kí Ọlọ́run tó lè gbà wá sínú agboolé rẹ̀ yìí, ó pọn dandan pé ká ya ara wa sí mímọ́. Ẹ jẹ́ ka wo ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀.

11 Kò sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó ní bàbá tá a lè jogún ìyè tòótọ́ látọ̀dọ̀ rẹ̀. (1 Tím. 6:19) A kò bí wa gẹ́gẹ́ bí ọmọ Ọlọ́run torí pé nígbà tí tọkọtaya àkọ́kọ́ ti dẹ́ṣẹ̀, wọ́n ti ya ìran ènìyàn nípa kúrò lọ́dọ̀ Baba àti Ẹlẹ́dàá wọn tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́. (Fi wé Diutarónómì 32:5.) Látìgbà náà wá ló ti di pé ẹ̀yìn òde agboolé Jèhófà ni gbogbo ọmọ aráyé, tá a ti sọ di àjèjì sí Ọlọ́run wà.

12. (a) Báwo ni àwa èèyàn aláìpé ṣe lè di ara agboolé Ọlọ́run? (b) Àwọn nǹkan wo la gbọ́dọ̀ ṣe ká tó ṣèrìbọmi?

12 Síbẹ̀síbẹ̀, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó gbà wá sínú agboolé rẹ̀, nínú èyí táwọn tó tẹ́wọ́ gbà bí ìránṣẹ́ rẹ̀ wà. a Báwo nìyẹn ṣe lè ṣeé ṣe fáwa tá a jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nígbà tí àwa jẹ́ ọ̀tá, a mú wa padà bá Ọlọ́run rẹ́ nípasẹ̀ ikú Ọmọ rẹ̀.” (Róòmù 5:10) Nígbà ìrìbọmi, ńṣe là ń bẹ Ọlọ́run pé kó fún wa ní ẹ̀rí ọkàn rere tó máa jẹ́ kó tẹ́wọ́ gbà wá. (1 Pét. 3:21) Àmọ́ ṣáájú ìrìbọmi, àwọn nǹkan kan wà tá a gbọ́dọ̀ ṣe. A gbọ́dọ̀ mọ Ọlọ́run, ká máa fọkàn tán an, ká ronú pìwà dà ká sì yí pa dà. (Jòh. 17:3; Ìṣe 3:19; Héb. 11:6) Ó tún wá ku nǹkan kan tá a gbọ́dọ̀ ṣe kí Ọlọ́run tó lè gbà wá sínú agboolé rẹ̀, nínú èyí táwọn tó tẹ́wọ́ gbà bí ìránṣẹ́ rẹ̀ wà. Kí ni nǹkan náà?

13. Kí nìdí tó fi bá a mu pé kẹ́nì kan jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run kó tó lè di ara àwọn olùjọsìn tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà sínú agboolé rẹ̀?

13 Kí ẹnì kan tó jẹ́ àjèjì sí Ọlọ́run tó lè di ẹni tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà sínú agboolé rẹ̀, ó ní láti kọ́kọ́ jẹ́jẹ̀ẹ́ pàtàkì kan fún Jèhófà. Láti lè lóye ìdí tó fi gbọ́dọ̀ rí bẹ́ẹ̀, jẹ́ ká sọ pé bàbá kan táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún láwùjọ kíyè sí ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ ọmọ òrukàn, ó sì pinnu láti gbà á ṣọmọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni rere la mọ bàbá náà sí, síbẹ̀ kó tó gba ọ̀dọ́kùnrin náà ṣọmọ, ó fẹ́ kó ṣèlérí kan fóun. Torí náà bàbá yẹn sọ pé, “Kí n tó lè kà ọ́ sí ọmọ mi, mo fẹ́ mọ̀ bóyá wàá fẹ́ràn mi tí wàá sì máa bọ̀wọ̀ fún mi gẹ́gẹ́ bí bàbá rẹ.” Àyàfi tí ọmọ náà bá ṣèlérí látọkàn wá fún bàbá náà ló tó lè gbà kó di ara ìdílé òun. Ǹjẹ́ a lè sọ pé ohun tí bàbá yẹn ṣe kò bọ́gbọ́n mu? Bákan náà, kìkì àwọn tó bá ṣe tán láti jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run ni Jèhófà máa gbà sínú agboolé rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.”—Róòmù 12:1.

Ìyàsímímọ́ Fi Hàn Pé A Ní Ìgbàgbọ́ àti Ìfẹ́

14. Báwo ni ìyàsímímọ́ ṣe ń fi hàn pé èèyàn nífẹ̀ẹ́ Jèhófà?

14 Téèyàn bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run, ó jẹ́ ẹ̀rí pé èèyàn ní ìfẹ́ àtọkànwá fún Jèhófà. Èyí sì fi àwọn nǹkan kan jọ ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Bí àpẹẹrẹ, bí ọkọ ìyàwó bá jẹ́jẹ̀ẹ́ pé òun máa dúró ti aya òun lọ́jọ́ dídùn àti lọ́jọ́ kíkan, ńṣe ló ń fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ obìnrin yẹn. Irú ẹ̀jẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣe ìlérí kan lásán, ẹ̀jẹ́ tó jẹ́ fún ẹnì kan ni. Kristẹni tó bá fẹ́ di ọkọ ìyàwó mọ̀ pé kí òun tó lè máa bá obìnrin gbélé, àfi kóun bá a jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó. Bí ọ̀rọ̀ ìyàsímímọ́ náà ṣe rí nìyẹn, èèyàn ò lè ní àǹfààní jíjẹ́ ara agboolé Jèhófà tí kò bá jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ fún Ọlọ́run. Ìdí nìyẹn tá a fi ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, bí a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé. Ó wù wá láti jẹ́ tirẹ̀ títí láé, a sì ti pinnu láti máa sìn ín láìyẹsẹ̀, ohun yòówù tí ì báà ná wa.—Mát. 22:37.

15. Báwo ni ìyàsímímọ́ ṣe jẹ́ ẹ̀rí pé a ní ìgbàgbọ́?

15 Nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run, ohun tó fi hàn pé a nígbàgbọ́ la ṣe yẹn. Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀? Ìgbàgbọ́ tá a ní nínú Jèhófà mú kó dá wa lójú pé ohun tó dára fún wa ni pé ká sún mọ́ Ọlọ́run. (Sm. 73:28) A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà lá máa rọrùn fún wa láti bá Ọlọ́run rìn bá a ti ń gbé “láàárín ìran oníwà wíwọ́ àti onímàgòmágó” yìí, àmọ́ ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé òun á máa tì wá lẹ́yìn fi wá lọ́kàn balẹ̀. (Fílí. 2:15; 4:13) A mọ̀ pé aláìpé ni wá, síbẹ̀ ó dá wa lójú pé Jèhófà á máa fi àánú hàn sí wa, kódà nígbà tá a bá ṣe àṣìṣe. (Ka Sáàmù 103:13, 14; Róòmù 7:21-25.) A nígbàgbọ́ pé bá a ṣe ń sapá láti di ìwà títọ́ wa mú a máa gba èrè lọ́dọ̀ Jèhófà.—Jóòbù 27:5.

A Máa Láyọ̀ Tá A Bá Ya Ara Wa sí Mímọ́ fún Ọlọ́run

16, 17. Kí nìdí tí yíya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà fi ń mú ká láyọ̀?

16 A máa láyọ̀ tá a bá ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà torí pé ńṣe la jọ̀wọ́ ara wa fún un. Òótọ́ kan tí kò ṣeé já ní koro ni Jésù sọ nígbà tó sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Jésù fúnra rẹ̀ rí ayọ̀ yìí lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé. Nígbà míì, ó máa ń pa oúnjẹ, ìsinmi àti ìtura tì kó bàa lè ran àwọn míì lọ́wọ́ láti rí ọ̀nà tó lọ sí ìyè. (Jòh. 4:34) Inú Jésù máa ń dùn bó ṣe ń ṣe ohun tó ń mú kí Bàbá rẹ̀ láyọ̀. Jésù sọ pé: “Nígbà gbogbo ni mo ń ṣe ohun tí ó wù ú.”—Jòh. 8:29; Òwe 27:11.

17 Jésù ṣàlàyé fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè gbé ìgbé ayé tó ń tẹ́ni lọ́rùn nígbà tó sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀.” (Mát. 16:24) Ṣíṣe bẹ́ẹ̀ á jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Ǹjẹ́ a rí ẹlòmíì tó lè fìfẹ́ bójú tó wa lọ́nà tó ju ti Ọlọ́run àti ti Jésù lọ?

18. Kí nìdí tí ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa fi ń fún wa láyọ̀ tó pọ̀ ju pé ká wulẹ̀ fi ara wa jìn fún ohun kan tàbí ẹnikẹ́ni?

18 Bá a ṣe ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà, tá a sì ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run ní ìbámu pẹ̀lú ìyàsímímọ́ wa, ń mú ká túbọ̀ láyọ̀ ju wíwulẹ̀ fi ara wa jìn fún ohun kan tàbí ẹnikẹ́ni. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń fi ìgbésí ayé wọn lépa ọrọ̀ síbẹ̀ ọwọ́ wọn ò tẹ ojúlówó ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn. Àmọ́ àwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ń rí ayọ̀ tó wà pẹ́ títí. (Mát. 6:24) Àǹfààní ló jẹ́ fún wọn bí wọ́n ṣe jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run.” Síbẹ̀, kì í ṣe iṣẹ́ ni wọ́n fi ara wọn jìn fún bí kò ṣe Ọlọ́run tó mọyì wa. (1 Kọ́r. 3:9) Kò sẹ́ni tó lè mọrírì ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn bí Ọlọ́run. Kódà, àwọn adúróṣinṣin ìránṣẹ́ rẹ̀ máa pa dà di ọ̀dọ́ kí wọn bàa lè máa jàǹfààní ìtọ́jú táá máa fún wọn títí láé.—Jóòbù 33:25; ka Hébérù 6:10.

19. Àǹfààní wo làwọn tó ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà ń gbádùn?

19 Bó o ṣe ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà á mú kó o ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Ják. 4:8; Sm. 25:14) Nínú àpilẹ̀kọ tó kàn, a máa ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí kò fi yẹ ká mikàn torí bá a ṣe pinnu láti jẹ́ ti Jèhófà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ṣì di òpin ẹgbẹ̀rún ọdún Ìjọba Jésù kí “àwọn àgùntàn mìíràn” tó di ọmọ Ọlọ́run. Àmọ́, níwọ̀n bí wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ láti máa pe Ọlọ́run ní “Baba,” a sì lè kà wọ́n sí ara agboolé àwọn olùjọsìn Jèhófà.—Jòh. 10:16; Aísá. 64:8; Mát. 6:9; Ìṣí. 20:5.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni yíya ara ẹni sí mímọ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí?

• Àǹfààní wo ló wà nínú yíya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run?

• Kí nìdí táwa Kristẹni fi gbọ́dọ̀ ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Tá a bá ń ṣe ohun tó bá ìyàsímímọ́ wa mu, a máa ní ayọ̀ tó wà pẹ́ títí