Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Tó Ń Bá Wọn Fínra

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Tó Ń Bá Wọn Fínra

Ran Àwọn Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Láti Kojú Àwọn Ìṣòro Tó Ń Bá Wọn Fínra

ÀWỌN ọmọ wa ń kojú ìṣòro tó le gan-an. Ẹ̀mí ayé búburú tí Sátánì ń darí máa ń fẹjú mọ́ wọn, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ń bá “àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” jìjàkadì. (2 Tím. 2:22; 1 Jòh. 5:19) Láfikún sí i, torí pé wọ́n ń sapá láti ‘rántí Ẹlẹ́dàá wọn Atóbilọ́lá,’ àwọn tó ń ta ko ohun tí wọ́n gbà gbọ́ máa ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, kódà wọ́n máa ń pọ́n wọn lójú. (Oníw. 12:1) Arákùnrin kan tó ń jẹ́ Vincent rántí ìgbà tó wà lọ́mọdé, ó wá sọ pé: “Ẹnì kan máa ń halẹ̀ mọ́ mi ní gbogbo ìgbà, ó máa ń fòòró ẹ̀mí mi, tàbí kó tiẹ̀ bá mi jà torí pé mo jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lọ́pọ̀ ìgbà, ìnilára náà máa ń pọ̀ débi pé mi ò ní fẹ́ lọ síléèwé.” a

Yàtọ̀ sí àwọn ìṣòro tá a mẹ́nu kàn lókè yìí, àwọn ìṣòro míì tún lè máa bá àwọn ọmọ wa lọ́kùnrin tàbí lóbìnrin fínra, irú bíi fífẹ́ láti dà bí àwọn ojúgbà wọn. Arábìnrin kan tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún, ìyẹn Cathleen, sọ pé: “Kì í rọrùn kí wọ́n máa wo èèyàn bí ẹni tó dá yàtọ̀.” Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Alan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn ọmọléèwé mi máa ń sọ fún mi pé ká jọ ṣeré jáde lópin ọ̀sẹ̀, ó sì máa ń wù mí gan-an láti bá wọn lọ.” Síwájú sí i, ó máa ń wu àwọn ọmọdé gan-an láti lọ́wọ́ nínú eré ìdárayá níléèwé, èyí sì lè yọrí sí kíkó ẹgbẹ́ búburú. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Tanya sọ pé: “Mo fẹ́ràn eré ìdárayá. Gbogbo ìgbà làwọn tó ń kọ́ wa léré ìdárayá níléèwé máa ń fẹ́ kí n bá wọn lọ́wọ́ nínú eré ìdárayá. Ó sì máa ń ṣòro fún mi láti sọ pé mi ò ṣe.”

Báwo lẹ̀yin òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tó ń bá wọn fínra? Jèhófà pàṣẹ fáwọn òbí pé kí wọ́n máa tọ́ àwọn ọmọ wọn sọ́nà. (Òwe 22:6; Éfé. 6:4) Ohun tí àwọn òbí tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run ń fẹ́ ni bí wọ́n á ṣe gbìn ín sọ́kàn àwọn ọmọ wọn láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà. (Òwe 6:20-23) Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ á fẹ́ láti dènà ipa búburú tí ayé lè ní lórí wọn, kódà bí àwọn òbí wọn ò bá sí lọ́dọ̀ wọn.

Ìṣòro ló jẹ́ fáwọn òbí láti gbọ́ bùkátà ìdílé, kí wọ́n tọ́ àwọn ọmọ, kí wọ́n sì tún bójú tó iṣẹ́ nínú ìjọ, lẹ́ẹ̀kan náà. Àdágbé àdásọ̀ lọ̀ràn náà jẹ́ fáwọn òbí míì, bóyá nítorí ikú ọkọ tàbí aya wọn tàbí nítorí àtakò látọ̀dọ̀ ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. Síbẹ̀, Jèhófà fẹ́ káwọn òbí wá àyè láti kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́. Torí náà, kí lẹ lè ṣe láti ran àwọn ọmọ yín lọ́wọ́ kí wọ́n lè dáàbò bo ara wọn kúrò lọ́wọ́ fífẹ́ láti hùwà bí àwọn ojúgbà wọn, kúrò lọ́wọ́ ìdẹwò àti àwọn ohun tó ń pọ́n wọn lójú lójoojúmọ́?

Àjọṣe Tímọ́tímọ́ Pẹ̀lú Jèhófà Ṣe Pàtàkì

Ó yẹ kí àwọn ọmọ wa kọ́kọ́ mọ̀ pé Jèhófà wà ní tòótọ́. A gbọ́dọ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́ láti “rí Ẹni tí a kò lè rí.” (Héb. 11:27) Arákùnrin tá a pè ní Vincent lẹ́ẹ̀kan rántí báwọn òbí rẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Ó sọ pé: “Àwọn òbí mi kọ́ mi pé ó ṣe pàtàkì láti máa gbàdúrà. Mo rántí pé látìgbà tí mo ti wà lọ́mọdé ni mo ti máa ń gbàdúrà sí Jèhófà lálaalẹ́ kí n tó sùn. Mo mọ̀ pé Jèhófà wà ní tòótọ́.” Ṣé àwọn ọmọ rẹ máa ń wà pẹ̀lú rẹ bó o bá ń gbàdúrà? Báwọn náà bá sì ń gbàdúrà, o ò ṣe fetí sí ohun tí wọ́n ń sọ? Ṣé ohun kan náà ni wọ́n máa ń tún sọ bí wọ́n bá ń gbàdúrà? Àbí ó máa ń hàn nínú àdúrà wọn pé òótọ́ ni wọ́n gbà pé Jèhófà wà? Bó o bá ń fetí sí àdúrà wọn, wàá lè fòye mọ̀ bóyá lóòótọ́ ni wọ́n ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.

Ọ̀nà pàtàkì míì táwọn ọmọ lè gbà sún mọ́ Jèhófà ni pé kí àwọn náà máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Cathleen tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Kíka Bíbélì látìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí nígbà tí mo wà lọ́mọdé ràn mí lọ́wọ́. Ó mú kó dá mi lójú pé, bí àwọn èèyàn ò tiẹ̀ gba tèmi, gbágbáágbá ni Jèhófà dúró tì mí.” Ṣé àwọn ọmọ rẹ ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tiwọn?—Sm. 1:1-3; 77:12.

Òótọ́ ni pé, ọwọ́ tí ọmọ kọ̀ọ̀kan fi ń mú ìtọ́sọ́nà àwọn òbí máa ń yàtọ̀ síra, bẹ́ẹ̀ sì ni ìtẹ̀síwájú wọn nípa tẹ̀mí lè sinmi lórí ọjọ́ orí wọn. Síbẹ̀, tí àwọn òbí ò bá tọ́ wọn sọ́nà, ó máa ṣòro fún wọn láti mọ̀ pé Jèhófà wà ní tòótọ́. Àwọn òbí gbọ́dọ̀ máa fi ìtẹnumọ́ gbin ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sínú àwọn ọmọ wọn, kó bàa lè máa dà bíi pé wọ́n ń gbọ́ tí Jèhófà ń bá wọn sọ̀rọ̀ níbikíbi tí wọ́n bá wà. (Diu. 6:6-9) Ó yẹ kó dá àwọn ọmọ yín lójú pé ọ̀rọ̀ wọn jẹ Jèhófà lógún.

Bá A Ṣe Lè Jẹ́ Kí Ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ Gbádùn Mọ́ni

Ọ̀nà pàtàkì míì táwọn òbí lè gbà ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ ni pé kí wọ́n máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ pẹ̀lú wọn. Àmọ́ ṣa o, ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ kọjá kéèyàn wulẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣákálá lásán. Ó tún gba pé kéèyàn máa béèrè ìbéèrè kó sì máa fara balẹ̀ tẹ́tí sí ìdáhùn, kódà bí ìdáhùn náà bá yàtọ̀ sí ohun tó fẹ́ gbọ́. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Anne, tó ní ọmọkùnrin méjì, sọ pé: “Mo máa ń béèrè ìbéèrè títí tí máa fi mọ ohun táwọn ọmọ mi ń rò lọ́kàn àti ìṣòro tí wọ́n ní.” Ṣé ó hàn sáwọn ọmọ rẹ pé ọ̀rọ̀ wọ́n máa ń yé ẹ? Ọ̀dọ́bìnrin tá a pè ní Tanya lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń fara balẹ̀ gbọ́ ọ̀rọ̀ mi, wọ́n sì máa ń rántí àwọn nǹkan tá a jọ sọ. Wọ́n mọ orúkọ àwọn tá a jọ wà ní kíláàsì. Wọ́n máa ń béèrè wọn lọ́wọ́ mi, wọ́n sì tún máa ń béèrè àwọn ohun tá a ti jọ sọ nípa wọn.” Ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa fetí sílẹ̀, kó sì máa rántí nǹkan, bó bá fẹ́ kí ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ yọrí sí rere.

Ọ̀pọ̀ ìdílé ti rí i pé àwọn máa ń láǹfààní láti jọ sọ àwọn nǹkan tó lè wúlò fún àwọn ní àkókò oúnjẹ. Vincent sọ pé: “Ńṣe ni gbogbo wa jọ máa ń jẹun pa pọ̀ nínú ìdílé wa. Gbogbo wa la máa ń pésẹ̀ sídìí tábìlì oúnjẹ, àfi ẹni tí kò bá sí nílé. Wọn kì í jẹ́ ká wo tẹlifíṣọ̀n, gbọ́ rédíò tàbí kàwé nígbà oúnjẹ. Nítorí pé a máa ń sọ̀rọ̀ atura nídìí oúnjẹ, ó máa ń mú kára tù mí lẹ́yìn gbogbo wàhálà tí mo ti ṣe níléèwé lọ́jọ́ yẹn.” Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Bó ṣe mọ́ mi lára láti máa bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀ nígbà tá a bá ń jẹun ti mú kó rọrùn fún mi láti bá wọn sọ̀rọ̀ nígbà tí mo bá fẹ́ kí wọ́n ràn mí lọ́wọ́ lórí àwọn ọ̀ràn tó ṣe pàtàkì gan-an.”

Wá bi ara rẹ pé, ‘Ìgbà mélòó ni èmi àti ìdílé mi jọ máa ń jẹun lọ́sẹ̀?’ Tó o bá ṣe ìyípadà lórí ọ̀ràn yìí, ǹjẹ́ á mú kó ṣeé ṣe fún ẹ láti lè túbọ̀ máa bá àwọn ọmọ rẹ sọ ọ̀rọ̀ táá túbọ̀ ṣe wọ́n láǹfààní?

Ìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Láti Fi Ohun Tẹ́ Ẹ̀ Ń Kọ́ Dánra Wò

Ìjọsìn Ìdílé tó ń wáyé lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ tún máa ń mú kí ìdílé lè bára wọn sọ̀rọ̀ fàlàlà, ó sì ń ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti mọ bí wọ́n ṣe lè kojú àwọn ìṣòro tó bá yọjú. Ọ̀dọ́kùnrin tá a pè ní Alan lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Àwọn òbí mi máa ń lo ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láti fi mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Wọ́n máa ń bá wa sọ àwọn ohun tó lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìṣòro tá a bá ní.” Màmá Alan sọ pé: “A máa ń lo díẹ̀ lára àkókò tá a fi ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ìdílé láti fi ohun tá a ń kọ́ dánra wò. Èyí sì máa ń ran àwọn ọmọ wa lọ́wọ́ láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì, kí wọ́n sì fi hàn pé ohun tí wọ́n gbà gbọ́ jóòótọ́. Èyí mú kí wọ́n ní ìgboyà láti lè kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń dojú kọ.”

Ohun tó yẹ káwọn ọmọ ṣe kọjá kí wọ́n kàn sọ pé rárá kí wọ́n sì máa bá tiwọn lọ nígbà táwọn ojúgbà wọn bá fi ohun tí kò dáa lọ̀ wọ́n. Ó yẹ kí wọ́n lè ṣàlàyé ìdí tí wọ́n fi gbà tàbí kọ̀ láti ṣe nǹkan ọ̀hún. Bí wọ́n bá fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ nítorí ìgbàgbọ́ wọn, ohun tí wọ́n máa ṣe gbọ́dọ̀ dá wọn lójú. Bí wọn ò bá lè gbèjà ìgbàgbọ́ wọn, á ṣòro fún wọn láti máa rin nìṣó ní ọ̀nà òtítọ́. Wọ́n máa ní irú ìdánilójú yẹn, bẹ́ ẹ bá ń fi ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ dánra wò.

Ẹ lè fi àwọn àpẹẹrẹ tá a tò sínú  àpótí tó wà lójú ìwé 18 dánra wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé. Máa ju ìbéèrè sáwọn ọmọ rẹ lọ́nà táá jẹ́ kó dà bíi pé ńṣe ni ohun tẹ́ ẹ fi ń dánra wò ń wáyé ní ti gidi. Bẹ́ ẹ ṣe ń fi ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ dánra wò, kẹ́ ẹ tún máa gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn àpẹẹrẹ wíwúlò tó wà nínú Bíbélì. Irú ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí á mú káwọn ọmọ yín gbára dì láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n bá bá pàdé níléèwé àti níbòmíì.

Ṣé Ibi Ìtura Ni Ilé Rẹ?

Ṣé ibi tí inú àwọn ọmọ rẹ máa ń dùn láti pa dà sí lẹ́yìn iléèwé ni ilé rẹ? Bó bá jẹ́ ibi ìtura, ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa kojú ìṣòro tí wọ́n ń bá pàdé lójoojúmọ́. Arábìnrin kan tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì báyìí ṣàlàyé pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, ọ̀kan lára àwọn ohun tó ràn mí lọ́wọ́ ni bí ilé wa ṣe máa ń tù mí lára. Kò sí bí nǹkan ṣe nira tó níléèwé, mo mọ̀ pé ara á tù mí tí mo bá délé.” Ilé tìẹ ńkọ́, báwo ló ṣe rí? Ṣé ilé tí “ìrufùfù ìbínú, asọ̀ [àti] ìpínyà” pọ̀ sí ni tàbí èyí tí “ìfẹ́, ìdùnnú, [àti] àlàáfíà” ti ń jọba? (Gál. 5:19-23) Tí ẹ kì í bá fi bẹ́ẹ̀ gbọ́ ara yín yé nínú ìdílé, o ò ṣe sa gbogbo ipá rẹ láti ṣe àwọn ìyípadà tó bá pọn dandan, kí ilé rẹ lè máa tu àwọn ọmọ rẹ lára?

Ọ̀nà míì tó o lè gbà ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ ni pé kó o yan ọ̀rẹ́ tó máa ṣe wọ́n láǹfààní fún wọn. Bí àpẹẹrẹ, ǹjẹ́ o lè pe àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn láti wá bá yín ṣeré ìnàjú? Àbí o lè ké sí alábòójútó arìnrìn-àjò tàbí àwọn míì tó wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún láti wá kẹ́ ẹ lè jọ fi nǹkan panu? Ǹjẹ́ o mọ míṣọ́nnárì èyíkéyìí tàbí àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó o lè ní káwọn ọmọ rẹ yàn lọ́rẹ̀ẹ́, bóyá nípa kíkọ lẹ́tà orí ìwé tàbí ti orí kọ̀ǹpútà sí wọn tàbí kí wọ́n máa pè wọ́n sórí fóònù lóòrèkóòrè? Irú àjọṣe bẹ́ẹ̀ lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti ṣe ipa ọ̀nà títọ́ fún ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n sì ní àwọn àfojúsùn tẹ̀mí. Ronú nípa bí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún Tímótì. (2 Tím. 1:13; 3:10) Àjọṣe tímọ́tímọ́ tí Pọ́ọ̀lù ní pẹ̀lú Tímótì mú kó ṣeé ṣe fún Tímótì láti lè pọkàn pọ̀ sórí lílépa àwọn nǹkan tẹ̀mí.—1 Kọ́r. 4:17.

Máa Gbóríyìn Fáwọn Ọmọ Rẹ

Inú Jèhófà máa ń dùn láti rí bí àwọn ọ̀dọ́mọdé ṣe ń di ìṣòtítọ́ wọn mú láìka ìṣòro tí wọ́n ń kojú nínú ayé Sátánì sí. (Sm. 147:11; Òwe 27:11) Ó dájú pé tí ìwọ náà bá rí àwọn ọmọ tó jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run wọ̀nyí, inú tìẹ náà máa ń dùn. (Òwe 10:1) Jẹ́ káwọn ọmọ rẹ mọ ojú tó o fi ń wò wọ́n, kó o sì máa gbóríyìn fún wọn. Jèhófà fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ fáwọn òbí. Nígbà ìrìbọmi Jésù, Jèhófà sọ pé: “Ìwọ ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n; mo ti tẹ́wọ́ gbà ọ́.” (Máàkù 1:11) Ẹ sì wo bí ọ̀rọ̀ tí Bàbá rẹ̀ sọ yìí ti máa fún Jésù lókun tó, tá sì ràn án lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìṣòro tó wà níwájú rẹ̀! Bíi ti Jèhófà, jẹ́ kó dá àwọn ọmọ rẹ lójú pé o nífẹ̀ẹ́ wọn àti pé o mọrírì ohun tí wọ́n ń gbé ṣe.

Ó dájú pé o kò lè dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ pátápátá kúrò lọ́wọ́ ìnilára, ìpọ́nnilójú àti ìfiniṣẹ̀sín. Síbẹ̀, ohun púpọ̀ lo lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́. Lọ́nà wo? Ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Máa wá àkókò láti ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ tó gbámúṣé pẹ̀lú wọn. Jẹ́ kí wọ́n mọ bí ohun tẹ́ ẹ̀ ń kọ́ nígbà Ìjọsìn Ìdílé ṣe kàn wọ́n, kó o sì jẹ́ kí ilé yín jẹ́ ibi ìtura. Ó dájú pé ṣíṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí á mú káwọn ọmọ rẹ gbára dì láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n ń bá pàdé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

 ṢÍṢE ÌFIDÁNRAWÒ LÈ RÀN YÍN LỌ́WỌ́

Díẹ̀ rèé lára ohun táwọn ọ̀dọ́ máa ń bá pàdé. Ẹ ò ṣe fi díẹ̀ nínú wọn dánra wò nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín?

▸ Ẹni tó ń kọ́ni ní eré ìdárayá ní iléèwé ní kí ọmọ rẹ obìnrin wá dara pọ̀ mọ́ wọn.

▸ Wọ́n fi sìgá lọ ọmọ rẹ nígbà tó ń bọ̀ láti iléèwé.

▸ Àwọn ọmọdékùnrin kan sọ pé àwọn máa na ọmọ rẹ ọkùnrin bí àwọn bá tún rí i tó ń wàásù.

▸ Nígbà tí ọmọ rẹ obìnrin ń wàásù láti ilé dé ilé, ó bá ọmọléèwé ẹ̀ kan pàdé.

▸ Wọ́n ní kí ọmọ rẹ sọ ìdí tí kì í fi í kí àsíá lójú gbogbo ọmọ kíláàsì.

▸ Ọmọdékùnrin kan ń fi ọmọ rẹ ọkùnrin ṣe yẹ̀yẹ́ lemọ́lemọ́ torí pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ṣé àwọn ọmọ rẹ ní ìtòlẹ́sẹẹsẹ Bíbélì kíkà tiwọn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Ṣé o máa ń pe àwọn tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn láti wá bá yín ṣeré ìnàjú?