Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Ni Ọ̀run Ṣe Rí?

Báwo Ni Ọ̀run Ṣe Rí?

Báwo Ni Ọ̀run Ṣe Rí?

ÀWỌN kan rò pé kò sí béèyàn ṣe lè mọ bí ọ̀run ṣe rí torí pé kò tíì sẹ́nì kankan látibẹ̀ tó wá sọ fún wa bó ṣe rí. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti gbàgbé ohun tí Jésù sọ pé: “Èmi sọ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.” (Jòhánù 6:38) Jésù tún sọ fáwọn aṣáájú ìsìn kan pé: “Ẹ̀yin wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso ìsàlẹ̀; èmi wá láti àwọn ilẹ̀ àkóso òkè.” (Jòhánù 8:23) Kí ni Jésù sọ nípa bí ọ̀run ṣe rí?

Jésù fi dá wa lójú pé ọ̀run ní ibi tí Jèhófà ń gbé. Ó pe Ọlọ́run ní “Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run.” (Mátíù 12:50) Àmọ́ onírúurú ọ̀nà ni Jésù gbà lo ọ̀rọ̀ náà “ọ̀run.” Bí àpẹẹrẹ, ó pe ojú sánmà ní “ọ̀run” nígbà tó sọ pé: “Ẹ fi tọkàntara ṣàkíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run.” (Mátíù 6:26) Síbẹ̀, ibi tí Jèhófà ń gbé kọjá sánmà fíìfíì. Bíbélì sọ pé: “Ẹnì kan wà tí ń gbé orí òbìrìkìtì ilẹ̀ ayé, tí àwọn olùgbé inú rẹ̀ dà bí tata.”—Aísáyà 40:22.

Ṣé inú àwọn ìràwọ̀ ni ‘Baba tí ń bẹ ní ọ̀run’ ń gbé? “Ọ̀run” ni Ìwé Mímọ́ tún pe àwọn nǹkan tó wà lójú sánmà. Bí àpẹẹrẹ, onísáàmù kan sọ pé: “Nígbà tí mo rí ọ̀run rẹ, àwọn iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tí o ti pèsè sílẹ̀, kí ni ẹni kíkú tí o fi ń fi í sọ́kàn, àti ọmọ ará ayé tí o fi ń tọ́jú rẹ̀?”—Sáàmù 8:3, 4.

Bí kò ti ṣeé ṣe fún káfíńtà kan láti máa gbé inú kọ́bọ́ọ̀dù tó ṣe, bẹ́ẹ̀ náà ni kò ṣeé ṣe fún Jèhófà Ọlọ́run láti máa gbé inú àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run. Ìyẹn ló mú kí Sólómọ́nì Ọba sọ ọ̀rọ̀ kan nígbà tó ń ya tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù sí mímọ́ fún Jèhófà, ó ní: “Ọlọ́run yóò ha máa gbé lórí ilẹ̀ ayé ní tòótọ́ bí? Wò ó! Àwọn ọ̀run, bẹ́ẹ̀ ni, ọ̀run àwọn ọ̀run, kò lè gbà ọ́; nígbà náà, áńbọ̀sìbọ́sí ilé yìí tí mo kọ́!” (1 Àwọn Ọba 8:27) Tí kì í bá ṣe inú àwọn nǹkan tó wà lójú ọ̀run ni Jèhófà ń gbé, ọ̀run wo ló ń gbé?

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn ti fi awò awọ̀nàjíjìn ṣèwádìí àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run, táwọn kan sì ti lọ sínú gbalasa òfuurufú, síbẹ̀ ohun tí Bíbélì sọ ṣì jóòótọ́ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó ti rí Ọlọ́run nígbà kankan rí.” (Jòhánù 1:18) Jésù sọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀ nígbà tó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ Ẹ̀mí.”—Jòhánù 4:24.

Ẹ̀mí jẹ́ oríṣi ìwàláàyè kan tó ju ti èèyàn lọ fíìfíì. Ẹ̀mí kì í ṣe nǹkan téèyàn lè rí tó sì lè fọwọ́ kàn, irú bí ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀. Nítorí náà, nígbà tí Jésù sọ pé òun ń gbé pẹ̀lú Baba òun ní “ọ̀run,” ohun tó ní lọ́kàn ni pé irú ìwàláàyè tó jẹ́ ológo ju ti èèyàn lọ fíìfíì lòun ní nígbà tóun wà lọ́run. (Jòhánù 17:5; Fílípì 3:20, 21) Ibi tí Jésù gbé pẹ̀lú baba rẹ̀ yìí ni Bíbélì pè ní “ọ̀run.” Báwo ló ṣe rí? Kí ló ń ṣẹlẹ̀ níbẹ̀?

Ibi Táwọn Nǹkan Ayọ̀ Ti Ń Ṣẹlẹ̀

Bíbélì sọ pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan ló ń ṣẹlẹ̀ lọ́run. Ó tún jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀kẹ́ àìmọye ẹ̀dá ẹ̀mí tó jẹ́ olóòótọ́ ń gbé ibẹ̀. (Dáníẹ́lì 7:9, 10) Ọ̀kọ̀ọ̀kan ẹ̀dá ẹ̀mí náà ló ní ànímọ́ tó yàtọ̀. Báwo la ṣe mọ̀ bẹ́ẹ̀? Nínú gbogbo ẹ̀dá tá a lè rí, kò sí ẹ̀dá alààyè méjì èyíkéyìí tó jọra délẹ̀délẹ̀, torí náà ó dá wa lójú pé onírúurú ànímọ́ làwọn ẹ̀dá ẹ̀mí tó wà lọ́run náà ní. Ohun tó tún jọni lójú gan-an ni pé, gbogbo ẹ̀dá ẹ̀mí tí wọ́n ní ànímọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí ń ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan, èyí sì yàtọ̀ gan-an sí tàwọn ọmọ aráyé tó jẹ́ pé wọn kì í sábà ṣiṣẹ́ ní ìṣọ̀kan.

Gbọ́ bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run, ó ní: “Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀, tí ẹ tóbi jọjọ nínú agbára, tí ẹ ń pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́, nípa fífetísí ohùn ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ẹ fi ìbùkún fún Jèhófà, gbogbo ẹ̀yin ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀, ẹ̀yin òjíṣẹ́ rẹ̀, tí ń ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” (Sáàmù 103:20, 21) Nítorí náà, ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ni wọ́n ń ṣe lọ́run. Kò sí àní-àní pé iṣẹ́ tó ń fúnni láyọ̀ ni wọ́n ń ṣe níbẹ̀.

Ọjọ́ ti pẹ́ gan-an táwọn áńgẹ́lì ti ń ṣe iṣẹ́ aláyọ̀ lọ́run, àní wọ́n ti ń ṣe é kí Ọlọ́run tó dá ayé. Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ṣe sọ, nígbà tí Jèhófà dá ilẹ̀ ayé, àwọn ọmọ Ọlọ́run “jùmọ̀ ń fi ìdùnnú ké jáde,” wọ́n sì “bẹ̀rẹ̀ sí hó yèè nínú ìyìn.” (Jóòbù 38:4, 7) Ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ọlọ́run yìí tiẹ̀ ní àǹfààní láti bá Ọlọ́run ṣiṣẹ́ nígbà tó ń dá àwọn nǹkan yòókù. (Kólósè 1:15-17) Bí Bíbélì ṣe ṣàpèjúwe nǹkan ayọ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́run yìí lè mú káwọn ìbéèrè kan máa jà gùdù lọ́kàn rẹ nípa ọmọ aráyé àti bí ọ̀run ṣe rí.

Ṣé Ọlọ́run Dá Èèyàn Láti Lọ sí Ọ̀run?

Níwọ̀n bí àwọn áńgẹ́lì ti ń sin Ọlọ́run lọ́run ṣáájú kó tó dá ayé, ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò dá ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́ láti bímọ sí ọ̀run káwọn èèyàn lè máa gbé ibẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run sọ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ pé: “Ẹ máa so èso, kí ẹ sì di púpọ̀, kí ẹ sì kún ilẹ̀ ayé.” (Jẹ́nẹ́sísì 1:28; Ìṣe 17:26) Ádámù ni èèyàn tí Ọlọ́run kọ́kọ́ dá sórí ilẹ̀ ayé tó lè mọ Ọlọ́run, tó sì lè sìn ín tọkàntọkàn. Òun ló máa di bàbá ìran gbogbo èèyàn táá máa gbé ayé. “Ní ti ọ̀run, ti Jèhófà ni ọ̀run, ṣùgbọ́n ilẹ̀ ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.”—Sáàmù 115:16.

Àwa èèyàn kì í fẹ́ kú, torí pé kò sẹ́ni tó máa rí ikú tí kò ní sá. Ìyà àìgbọràn ni Ọlọ́run sọ fún Ádámù pé ikú jẹ́. Ká ní Ádámù ṣègbọràn ni, kò ní kú.—Jẹ́nẹ́sísì 2:17; Róòmù 5:12.

Abájọ tí Ọlọ́run kò fi sọ fún Ádámù rárá pé ó máa lọ sọ́run. Nítorí náà, ayé yìí kì í ṣe ibi tá a ti ń dán àwọn èèyàn wò bóyá wọ́n á yẹ lẹ́ni tó ń lọ sọ́run. Ọlọ́run dá èèyàn láti wà láàyè títí láé lórí ilẹ̀ ayé, ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn yìí ṣì máa nímùúṣẹ. Bíbélì sọ pé, “àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.” (Sáàmù 37:29) Nítorí náà, ó ṣe kedere pé Ọlọ́run kò dá èèyàn níbẹ̀rẹ̀ láti lọ sọ́run. Kí wá nìdí tí Jésù fi ṣèlérí fáwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé wọ́n máa lọ sọ́run. Ṣé Jésù ní in lọ́kàn pé gbogbo èèyàn rere ló máa lọ sọ́run?