Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ mú kí ọmọ ẹgbẹ́ Rastafarian kan gé irun dàda tó wà lórí rẹ̀, tó sì jáwọ́ nínú ẹ̀tanú tó ń ṣe sáwọn aláwọ̀ funfun? Kí ló jẹ́ kí ọ̀dọ́kùnrin oníwà ipá tó máa ń gba owó fún àwọn tó ń ta oògùn olóró yí ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? Gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.

“Mo jáwọ́ nínú ẹ̀tanú tí mo máa ń ṣe sáwọn aláwọ̀ funfun pàápàá.”—HAFENI NGHAMA

ỌJỌ́ ORÍ: 34

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: SÁŃBÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ỌMỌ ẸGBẸ́ RASTAFARIAN

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò nílùú tó wà lórílẹ̀-èdè Sáńbíà ni wọ́n bí mi sí. Orílẹ̀-èdè Nàmíbíà ni màmá mi sá lọ nígbà ogun, ó di ọmọ ẹgbẹ́ àjọ kan ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Áfíríkà tó ń jẹ́ South West Africa People’s Organization (ìyẹn àjọ SWAPO). Àjọ yìí ló ń bá ìjọba Gúúsù Áfíríkà kan tó ń ṣàkóso Nàmíbíà lákòókò yẹn jà.

Inú oríṣiríṣi àgọ́ àwọn tí ogun lé kúrò lórílẹ̀-èdè wọn ni mo gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé mi. Ohun tí wọ́n sì ń gbìn sọ́kàn àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú àgọ́ tó jẹ́ ti àjọ SWAPO ni bí wọ́n ṣe máa gba òmìnira. Wọ́n kọ́ wa láti nígbàgbọ́ nínú ìṣèlú, wọ́n sì kọ́ wa láti kórìíra àwọn aláwọ̀ funfun.

Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kànlá, mo fẹ́ di Kristẹni nínú ṣọ́ọ̀ṣì kan táwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì, ẹlẹ́sìn Luther, Áńgílíkà àtàwọn ẹlẹ́sìn míì ti jọ ń ṣe ìsìn. Pásítọ̀ tí mo sọ ohun tí mo fẹ́ ṣe fún kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá mi, ni mo bá jáwọ́. Látìgbà yẹn, ni mo ti di ẹni tí kò gbà pé Ọlọ́run wà. Àmọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ Rastafarian a torí ìfẹ́ tí mo ní sí orin régè àti ìfẹ́ ọkàn mi láti gba àwọn aláwọ̀ dúdú lọ́wọ́ àwọn tó ń ni wọ́n lára. Mo fi irun mi sílẹ̀ títí tó fi di irun dàda, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mugbó, mi ò jẹ ẹran mọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í wá òmìnira fún àwọn aláwọ̀ dúdú. Síbẹ̀, mi ò yí ọ̀nà ìgbésí ayé mi pa dà tàbí jáwọ́ nínú wíwo fíìmù oníwà ipá. Bákan náà, mo ṣì máa ń lo èdè aṣa.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Ní ọdún 1995 tí mo wà ní nǹkan bí ọmọ ogún ọdún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an lórí ohun tó yẹ kí n fi ìgbésí ayé mi ṣe. Mò ń ka gbogbo ìwé ọmọ ẹgbẹ́ Rastafarian tí mo bá rí. Àwọn kan lára wọn tọ́ka sí Bíbélì, àmọ́ lójú mi, àlàyé táwọn ìwé yìí ṣe nípa Bíbélì kò mọ́gbọ́n dání. Nítorí náà, mo pinnu láti ka Bíbélì fúnra mi.

Nígbà tó yá, ọ̀kan lára ọmọ ẹgbẹ́ Rastafarian fún mi ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tó dá lórí Bíbélì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ṣe ìwé náà. Mo ka ìwé yìí, mo sì ka àwọn ẹsẹ Bíbélì tó wà nínú rẹ̀. Lẹ́yìn náà, mo rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, mo sì ní kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Mo sapá gan-an láti jáwọ́ nínú igbó mímu àti ọtí àmujù. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Mo tún ìrísí mi ṣe, mo gé irun dàda tó wà lórí mi, mo jáwọ́ nínú wíwo àwòrán oníhòòhò àti fíìmù oníwà ipá, mo sì tún jáwọ́ nínú lílo èdè aṣa. (Éfésù 5:3, 4) Nígbà tó yá, mo jáwọ́ nínú ẹ̀tanú tí mo máa ń ṣe sáwọn aláwọ̀ funfun pàápàá. (Ìṣe 10:34, 35) Àtúnṣe yìí gba pé kí n kó àwọn orin tó ń gbé kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lárugẹ dà nù kí n má sì bá àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀ kẹ́gbẹ́ mọ́, ìyẹn àwọn tó lè fà mí pa dà sínú ìwàkíwà tí mo ń hù tẹ́lẹ̀.

Lẹ́yìn tí mo ti ṣe àwọn ìyípadà yìí, mo wá Gbọ̀ngàn Ìjọba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kàn, mo sì sọ fún wọn pé mo fẹ́ di ara wọn. Inú àwọn ará ilé mi kò dùn nígbà tí mo sọ pé mo fẹ́ ṣe ìrìbọmi láti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Màmá mi sọ fún mi pé mo lè ṣe ẹ̀sìn Kristẹni míì tó wù mí, àmọ́ mi ò gbọ́dọ̀ ṣe ẹ̀sìn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìgbà gbogbo ni ọkùnrin kan tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí màmá mi tó tún jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn tó ń ṣàkóso nínú ìjọba lórílẹ̀-èdè wa máa ń ta kò mí nítorí mo sọ pé mo fẹ́ di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àmọ́ ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nípa bí Jésù ṣe bá àwọn èèyàn lò ràn mí lọ́wọ́ láti fara da àtakò àti ọ̀rọ̀ ẹ̀gàn táwọn èèyàn ń sọ. Nígbà tí mo fi ohun táwọn Ẹlẹ́rìí fi ń kọ́ni wé ohun tí Bíbélì sọ, mo gbà pé mo ti rí ìsìn tòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n máa ń tẹ̀ lé àṣẹ Bíbélì tó sọ pé ká wàásù fún àwọn èèyàn. (Mátíù 28:19, 20; Ìṣe 15:14) Wọn kì í sì í lọ́wọ́ nínú ọ̀ràn ìṣèlú.—Sáàmù 146:3, 4; Jòhánù 15:17, 18.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ láti máa gbé ìgbésí ayé mi lọ́nà tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an. Bí àpẹẹrẹ, bí mo ṣe jáwọ́ nínú igbó mímu ti gbà mí lọ́wọ́ fífi ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ owó ṣòfò lóṣooṣù. Nítorí pé mi ò lo oògùn olóró mọ́, mi ò ṣèrànrán mọ́, ara mi túbọ̀ le, ọpọlọ mi sì ń ṣiṣẹ́ dáadáa.

Ní báyìí, ìgbésí ayé mi ti nítumọ̀, mo ti ń fi ayé mi ṣe ohun tó dára, ìyẹn ohun tí mo ti fẹ́ ṣe látìgbà èwe mi. Èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé, mo ti wá sún mọ́ Ọlọ́run gan-an báyìí.—Jákọ́bù 4:8.

“Mi ò bínú sódì mọ́.”—MARTINO PEDRETTI

ỌJỌ́ ORÍ: 43

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ỌSIRÉLÍÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MÒ Ń TA OÒGÙN OLÓRÓ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Àwọn ìdílé mi ń ṣí kiri bí mo ti ń dàgbà. Mo gbé ní ìlú kékeré, ìlú ńlá àti fúngbà díẹ̀ ní ìgbèríko nílé ẹ̀kọ́ táwọn ẹlẹ́sìn kan dá sílẹ̀ láti la àwọn ọmọ ìbílẹ̀ lójú. Mo ṣì máa ń rántí àwọn nǹkan tí mo gbádùn nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí ìyá mi àtàwọn ẹ̀gbọ́n rẹ̀, a máa ń pẹja, a máa ń ṣọdẹ, a máa ń gbẹ́ igi kan tó jẹ́ pé tá a bá jù ú, ńṣe ló tún máa ń pa dà wá bá ẹni tó jù ú, a sì tún máa ń fi igi gbẹ́ onírúurú nǹkan.

Ẹ̀ṣẹ́ kíkàn ni bàbá mi kọ́, láti kékeré ló sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi ní ìjà. Mo wá di oníwà ipá. Ọ̀pọ̀ àkókò ni mo máa ń lò nílé ọtí nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàlá sí mọ́kàndínlógún. Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń wá ìjà kiri. A máa ń fi ọ̀bẹ àti ọ̀pá tí wọ́n fi ń gbá bọ́ọ̀lù gbéjà ko ogún èèyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ.

Mo máa ń ta oògùn olóró àtàwọn ọjà táwọn òṣìṣẹ́ èbútékọ̀ ń jí, nǹkan wọ̀nyí ló ń mú owó wọlé fún mi. Mo tún máa ń bá àwọn tó ń ta oògùn olóró gba owó lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n bá tajà fún, mo sì máa ń fi ìbọn ṣakabùlà àti ìbọn ìléwọ́ halẹ̀ mọ́ àwọn tó bá jẹ wọ́n lówó. Àfojúsùn mi ni pé mo fẹ́ di agbanipa. Ohun tí mo fi ṣe àkọmọ̀nà mi ni, Pa èèyàn tàbí kéèyàn pa ẹ́.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Mo ti gbọ́ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí mò ń dàgbà. Mo rántí pé nígbà tí mo lé díẹ̀ lọ́mọ ogún ọdún, mo béèrè lọ́wọ́ màmá mi bóyá o mọ ibi tí èyíkéyìí nínú wọn ń gbé. Lọ́jọ́ méjì lẹ́yìn náà, Ẹlẹ́rìí kan tó ń jẹ́ Dixon kan ilẹ̀kùn yàrá mi. Lẹ́yìn tá a ti sọ̀rọ̀ fúngbà díẹ̀, ó ní kí n wá sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Mo lọ sí ìpàdé yẹn, ó sì ti lé lógún ọdún báyìí ti mo ti ń lọ sí ìpàdé náà. Gbogbo ìbéèrè mi làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dáhùn látinú Bíbélì.

Inú mi dùn láti mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa, tó fi mọ́ àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (2 Pétérù 3:9) Mo wá rí i pé Jèhófà jẹ́ Baba onífẹ̀ẹ́ tó ń dáàbò bò mí, bí kò bá tiẹ̀ sí ẹnì kankan tó bìkítà nípa mi. Ará tún tù mí láti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó máa dárí ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí tí mo bá yí ìwà mi pa dà. Àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Éfésù 4:22-24 ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni. Àwọn ẹsẹ yẹn gbà mí níyànjú pé kí n “bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀” kí n sì “gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀, èyí tí a dá ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run.”

Àkókò kékeré kọ́ ló gbà mí láti yí ìwà mi pa dà. Mi ò kì í lo oògùn olóró láàárín ọ̀sẹ̀, àmọ́ tó bá ti di òpin ọ̀sẹ̀ nígbà tí mo bá wà pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́ mi, màá tún bẹ̀rẹ̀ sí í lò ó. Ó wá yé mi pé mo ní láti kúrò nítòsí àwọn ọ̀rẹ́ mi yìí tí mo bá fẹ́ fọ ìgbésí ayé mi mọ́, nítorí náà, mo pinnu láti kó lọ sí ìpínlẹ̀ míì. Àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi sọ pé àwọn fẹ́ sìn mí lọ nígbà tí mò ń kó lọ, mo gbà kí wọ́n bá mi lọ. Nígbà tá à ń lọ lọ́nà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í mu igbó, wọ́n sì ní kí èmi náà mu díẹ̀. Mo sọ fún wọn pé mo ti jáwọ́ nínú irú ìwà yìí, nígbà tá a dé ẹnú ibodè ìpínlẹ̀ náà, kálukú bá tiẹ̀ lọ. Lákòókò díẹ̀ lẹ́yìn náà, mo gbọ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ mi lọ fi ìbọn ja ilé ìfowópamọ́ kan lólè.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Lẹ́yìn tí mi ò bá àwọn ọ̀rẹ́ mi yìí rìn mọ́, ó túbọ̀ rọrùn fún mi láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ nígbèésí ayé mi. Lọ́dún 1989, mo ṣèrìbọmi mo sì di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn ti mo ti ṣèrìbọmi, àbúrò mi obìnrin, màmá mi àti baba mi náà di Ẹlẹ́rìí, gbogbo wá sì jọ ń sin Jèhófà.

Ọdún kẹtàdínlógún rèé tí mo ti gbéyàwó, mo ní ọmọ mẹ́ta tó fani mọ́ra. Inú ṣì máa ń bí mi, ṣùgbọ́n mi ò bínú sódì mọ́. Mo sì ti mọ bá a ṣe ń nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó wá láti gbogbo ‘ẹ̀yà, ìran àti èdè.’ (Ìṣípayá 7:9) Mo ti rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ Jésù nínú ọ̀ràn tèmi. Jésù sọ pé: “Bí ẹ bá dúró nínú ọ̀rọ̀ mi, ọmọ ẹ̀yìn mi ni ẹ̀yin jẹ́ ní ti tòótọ́, ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—Jòhánù 8:31, 32.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn Rastafarian jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ ẹ̀ya ìsìn kan lórílẹ̀-èdè Jàmáíkà, wọ́n sábà máa ń ní irun dàda, wọ́n sì ka Haile Selassie ti Etiópíà sí Ọlọ́run.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]

Àtúnṣe yìí gba pé kí n kó àwọn orin tó ń gbé kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà lárugẹ dànù

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]

Èmi àtàwọn ọ̀rẹ́ mi máa ń wá ìjà kiri. A máa ń fi ọ̀bẹ àti ọ̀pá tí wọ́n fi ń gbá bọ́ọ̀lù gbéjà ko ogún èèyàn tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ