Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Jẹ́ Olóòótọ́ ní Gbogbo Ìgbà?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Jẹ́ Olóòótọ́ ní Gbogbo Ìgbà?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kó O Jẹ́ Olóòótọ́ ní Gbogbo Ìgbà?

GBOGBO èèyàn ló máa ń ṣòótọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, àmọ́ ọ̀pọ̀ ló jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ni wọ́n máa ń ṣòótọ́. Àmọ́, àwọn mélòó lo mọ̀ tí wọ́n ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ìgbà?

Lóde òní ìwà àìṣòótọ́ wà nínú gbogbo nǹkan táwọn èèyàn ń ṣe. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, gbogbo èèyàn ló mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ káwa èèyàn jẹ́ olóòótọ́. Bí àpẹẹrẹ, nínú Òfin Mẹ́wàá, ọ̀pọ̀ ló mọ òfin kẹjọ dáadáa, òfin náà sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ jalè.” (Ẹ́kísódù 20:15) Àmọ́ èrò ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé kò burú bí ẹni tí nǹkan kò sàn fún bá jalè tàbí tó bá hùwà àìṣòótọ́. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ olè jíjà mẹ́ta táwọn èèyàn sábà máa ń gbójú fò dá.

Ṣó Yẹ Kéèyàn Máa Jalè Torí Pé Ó Jẹ́ Aláìní?

Àgbà olóṣèlú ọmọ ilẹ̀ Róòmù kan sọ nígbà kan pé: “Ìṣẹ́ ló ń fa ìwà ọ̀daràn.” Ẹnì kan tó jẹ́ aláìní lè máa dá ara rẹ̀ láre pé olè tóun jà kò burú. Àwọn èèyàn sì lè gbà pẹ̀lú irú ẹni bẹ́ẹ̀. Kí ni èrò Jésù lórí ọ̀ràn yìí? Ó fi àánú hàn sáwọn aláìní. “Àánú wọn ṣe é.” (Mátíù 9:36) Síbẹ̀, kò fìgbà kankan rí fọwọ́ sí olè jíjà. Kí wá ló yẹ kí ẹni tó jẹ́ aláìní ṣe?

Ọlọ́run máa ń fi àánú hàn sí àwọn tó bá ń sapá láti ṣègbọràn sí àṣẹ rẹ̀ tọkàntọkàn, ó sì máa ń bù kún ìsapá wọn kí wọ́n lè rí ohun tí wọ́n nílò. (Sáàmù 37:25) Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Jèhófà kì yóò jẹ́ kí ebi pa ọkàn olódodo, ṣùgbọ́n ìfàsí-ọkàn àwọn ẹni burúkú ni yóò tì kúrò.” (Òwe 10:3) Ṣé aláìní lè gbọ́kàn lé ìlérí yìí? Obìnrin kan tó ń jẹ́ Victorine rí i pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

Opó ni Victorine, ó sì ní ọmọ márùn-ún tí wọ́n ń lọ síléèwé, nítorí náà nǹkan ò rọrùn fún un rárá. Orílẹ̀-èdè tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà ló ń gbé, níbi tí ìrànlọ́wọ́ téèyàn ń rí látọ̀dọ̀ ìjọba kò ti tó nǹkan. Àárín ọ̀pọ̀ èèyàn níbi tí àǹfààní wà láti jalè ló máa ń wà lọ́pọ̀ ìgbà. Àmọ́, Victorine kò jẹ́ kí ojú òun wọ nǹkan oní-nǹkan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń tajà ní òpópónà kó bàa lè rí owó gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Kí nìdí tó fi ń ṣòótọ́?

Ó ní: “Ìdí àkọ́kọ́ ni pé, Ọlọ́run jẹ́ olóòótọ́, òótọ́ ni yóò sì máa fi bá mi lò tí mo bá ń fara wé e. Ìkejì ni pé, àwọn ọmọ mi á lè kọ́ béèyàn ṣe lè jẹ́ olóòótọ́ tí wọ́n bá rí i pé mo jẹ́ olóòótọ́.”

Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Ó sọ pé, “A ní oúnjẹ, aṣọ àti ibi tá à ń gbé. Síbẹ̀, àwọn ìgbà kan wà tí mo máa ń ní káwọn ọ̀rẹ́ mi ràn mí lọ́wọ́, bí àpẹẹrẹ, láti sanwó fún ìtọ́jú àìlera tó dé lójijì. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń rí ohun tí mo nílò. Kí nìdí? Ìdí ni pé, àwọn ọ̀rẹ́ mi mọ̀ pé bí ọ̀rọ̀ mi bá ṣe rí ni mo ṣe máa ń ṣàlàyé, kì í ṣe pé mo fẹ́ ṣàbùmọ́ kí n lè rí ohun tó pọ̀ gbà.”

“Àwọn ọmọ mi ń di ẹni tó ṣeé fọkàn tán bí wọ́n ṣe ń dàgbà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, aládùúgbò wa kan rí owó ẹyọ díẹ̀ lórí tábìlì wa, ó sì bi mí pé, ṣé ẹ̀rù ò bà mí pé àwọn ọmọ mi lè jí owó náà? Ó ṣòro fún un láti gbà nígbà tí mo sọ pé àwọn ọmọ mi ò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé. Nítorí náà, ó dán àwọn ọmọ náà wò láìjẹ́ kí n mọ̀. Obìnrin yìí dọ́gbọ́n fi ọgọ́rùn-ún méjì owó ẹyọ ilẹ̀ Faransé síbi táwọn ọmọ mi ti lè tètè rí wọn. Nígbà tó pa dà wá lọ́jọ́ kejì, ó yà á lẹ́nu láti rí i pé àwọn owó ẹyọ náà ṣì wà níbẹ̀. Kéèyàn ní àwọn ọmọ tó ṣeé fọkàn tán ṣàǹfààní ju kéèyàn ní ohun ìní rẹpẹtẹ lọ.”

“Gbogbo Èèyàn Ló Ń Ṣe É”

Olè jíjà níbi iṣẹ́ wọ́pọ̀ kárí ayé. Nítorí náà, èrò ọ̀pọ̀ ni pé, “Kí ló dé témi náà ò lè ṣe é nígbà tó jẹ́ pé gbogbo èèyàn ló ń ṣe é?” Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ yàtọ̀, ó ní: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀ fún ète ibi.” (Ẹ́kísódù 23:2) Obìnrin kan tó ń jẹ́ Victoire tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí. Ṣé èyí ṣe é láǹfààní?

Nígbà tí Victoire wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], ó rí iṣẹ́ sí ilé iṣẹ́ kan tí wọ́n ti máa ń ṣe epo pupa. Nígbà tó yá, ó ṣàkíyèsí pé àwọn ogójì [40] obìnrin tí wọ́n gbà síbẹ̀ máa ń fi apẹ̀rẹ̀ wọn jí ẹyìn látinú ilé iṣẹ́ náà. Lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀, wọ́n máa ń ta ẹyìn náà, owó tí wọ́n sì máa ń rí níbẹ̀ tó owó iṣẹ́ ọjọ́ mẹ́ta sí ọjọ́ mẹ́rin. Victoire sọ pé: “Ká sòótọ́, gbogbo èèyàn ló ń ṣe é. Wọ́n retí pé kémi náà ṣe é, àmọ́ mo kọ̀, mo sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òtítọ́ ni mo fi ń ṣèwàhù. Wọ́n fi mi ṣe yẹ̀yẹ́, wọ́n sọ pé èmi ló máa pàdánù.”

“Lọ́jọ́ kan tí à ń jáde nínú ọgbà ilé iṣẹ́ náà, ọ̀gá ilé iṣẹ́ náà dé lójijì. Ó yẹ apẹ̀rẹ̀ gbogbo wa wò, ó sì rí ẹyìn nínú apẹ̀rẹ̀ àwọn yòókù, inú apẹ̀rẹ̀ tèmi nìkan ni kò ti rí nǹkan kan. Ó ní, òun máa lé gbogbo àwọn tó jalè náà lọ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tàbí kí wọ́n ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ méjì láìgba owó. Láàárín ọ̀sẹ̀ méjì yẹn, àwọn obìnrin yìí gbà pé mi ò pàdánù.”

“Ẹní Rí Nǹkan He Ìfà Tiẹ̀ Ni”

Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ nígbà tó o bá rí ohun iyebíye tó sọ nù he? Ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń rò pé ó ti di tàwọn nìyẹn, èyí kì í sì í jẹ́ kí wọ́n ronú láti wá bí wọ́n ṣe lè dá a pa dà fẹ́ni tó ni ín. Èrò wọn ni pé “ẹni rí nǹkan he ìfà tiẹ̀ ni.” Àwọn kan lè rò pé ìyẹn ò burú. Wọ́n á ní, ó kúkú ṣe tán, ẹni tó ni ín ti gbà pé ó ti sọ nù. Àwọn kan sọ pé, kì í ṣe tàwọn láti wá ẹni tó ni ín torí pé wàhálà yẹn á ti pọ̀ jù.

Kí ni èrò Ọlọ́run lórí ọ̀ràn yìí? Ìwé Diutarónómì 22:1-3 jẹ́ ká mọ̀ pé kì í ṣe pé kí ẹni tó rí nǹkan he tọ́jú rẹ̀ nìkan ni, àmọ́ kó tọ́jú rẹ̀ pa mọ́ “títí [oní nǹkan] yóò fi wá a. Kí [ó] sì dá a padà fún un.” Ẹ̀sùn olè ni wọ́n máa fi kan ẹni tó rí nǹkan he àmọ́ ti kò sọ pé òun rí nǹkan náà. (Ẹ́kísódù 22:9) Ṣé ìlànà yìí ṣì wúlò lóde òní? Obìnrin kan tó ń jẹ́ Christine gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí.

Ọ̀gá ilé ẹ̀kọ́ àdáni kan ni Christine jẹ́. Lọ́jọ́ Wednesday kan, ó gba owó oṣù rẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àṣà àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, ó kó owó náà sínú báàgì rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó gun ọ̀kadà, ó sì gba ìpàdé kan lọ. Nígbà tó dé ibẹ̀, obìnrin yìí kọwọ́ bọ inú báàgì rẹ̀ láti mú owó tó máa san fún ọlọ́kadà náà, ṣùgbọ́n kò mọ̀ pé béèlì owó oṣù tó gbà náà ti já bọ́ nínú òkùnkùn.

Ní ìṣẹ́jú mélòó kan lẹ́yìn ìgbà náà, ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] kan tó ń jẹ́ Blaise, wá sí òpópónà yẹn, àlejò ló sì jẹ́ lágbègbè náà. Ó ti ṣàdéhùn láti pàdé ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ní ìpàdé kan náà tí Christine wá. Ó rí owó náà, ó sì kó o sínú àpò rẹ̀. Nígbà tí ìpàdé náà parí, ó sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé òun rí nǹkan ní ìta, pé kẹ́ni tó bá sọ nǹkan nù pe òun lórí fóònù, kẹ́ni náà sì ṣàlàyé ohun tó sọ nù lọ́wọ́ rẹ̀.

Nígbà tí Christine délé lálẹ́ ọjọ́ yẹn, ó yà á lẹ́nu gan-an pé òun ti sọ owó oṣù òun nù. Nígbà tó fi ọ̀ràn náà tó Josephine ọ̀rẹ́ rẹ̀ létí lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ kan sígbà náà, ó sọ fún Christine pé àlejò kan tó wá sí ìpàdé lọ́jọ́ náà rí nǹkan he. Torí náà, Christine pe Blaise lórí fóònù, ó sì ṣàlàyé báwọn owó náà ṣe rí. Inú rẹ̀ dùn gan-an nígbà tí Blaise dá owó náà pa dà fún un. Báwo lọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára Blaise? Ó ti tọ́jú owó náà fún ọ̀sẹ̀ kan, àmọ́ ó sọ pé, “Ayọ̀ tí mo ní nígbà tí mo dá owó náà pa dà pọ̀ ju èyí tí mo ní nígbà tí mo tọ́jú owó náà.”

Kí Nìdí Tí Wọ́n Fi Ń Sapá Láti Jẹ́ Olóòótọ́ ní Gbogbo Ìgbà

Ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Victorine, Victoire àti Blaise ń gbé, wọn ò sì mọ ara wọn rí. Àmọ́, ohun kan wà tó mú kí ọ̀rọ̀ wọn jọra. Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fọwọ́ pàtàkì mú ohun tí Bíbélì sọ lórí jíjẹ́ olóòótọ́ ni gbogbo wọn. Wọ́n ń fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run pé òun ń mú ayé tuntun kan bọ̀. Bíbélì sọ pé, “Ṣùgbọ́n ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” Àwọn olódodo àti olóòótọ́ ni wọ́n á máa gbé ibẹ̀.—2 Pétérù 3:13.

Kò fi bẹ́ẹ̀ dá Victorine lójú pé ipò ọrọ̀ ajé òun lé dára títí Ọlọ́run fi máa ṣàtúnṣe àwọn nǹkan. Àmọ́, ó lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí, ìyẹn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, owó kò sì lè ra èyí láé. Àwọn ọmọ rẹ̀ jẹ́ olóòótọ́, wọ́n sì níwà ọmọlúwàbí. Inú wọ́n máa ń dùn gan-an lọ́jọ́ Sunday nígbà tí wọ́n bá ń sọ fún àwọn aládùúgbò wọn nípa oore Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe máa tẹ́ “àwọn tí ń ké pè é ní òótọ́” lọ́rùn, tó sì máa dáàbò bo “gbogbo àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.”—Sáàmù 145:7, 18, 20.

Nígbà tó yá, Victoire kúrò nílé iṣẹ́ tí wọ́n ti ń ṣe epo pupa. Ó dá dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ta gaàrí lọ́jà. Jíjẹ́ tó jẹ́ olóòótọ́ mú kí ọ̀pọ̀ oníbàárà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kódà, ó tún dín àkókò tó ń lò lọ́jà kù, ó sì wá ń lo ọ̀pọ̀ àkókò sí i láti máa wàásù fún àwọn èèyàn nípa ìrètí láti gbé nínú ayé kan tí kò ti ní sí àìṣòótọ́ mọ́. Nígbà tó yá, ó lọ́kọ, ní báyìí, òun àti ọkọ rẹ̀ jọ ń lo àkókò tó pọ̀ láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Iwájú Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni owó Christine já bọ́ sí. Blaise mọ àwọn díẹ̀ tó wà ní ìpàdé yẹn, ó mọ̀ pé àwọn arákùnrin àti arábìnrin òun tí wọ́n ń sapá láti jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ìgbà ni wọ́n.

Àwọn mélòó lo mọ̀ tí wọ́n ń sapá tọkàntọkàn láti jẹ́ olóòótọ́ ní gbogbo ìgbà? Fojú inú wò ó pé o wà pẹ̀lú àwọn àádọ́ta [50], ọgọ́rùn-ún [100] tàbí igba [200] èèyàn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́. Ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbádùn láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wa nìyẹn. O ò ṣe lọ sí ibẹ̀ kó o lè mọ̀ wọ́n dáadáa.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 12]

“Kéèyàn ní àwọn ọmọ tó ṣeé fọkàn tán ṣàǹfààní ju kéèyàn ní ohun ìní rẹpẹtẹ lọ.”—VICTORINE

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]

Ǹjẹ́ Ìwé Òwe 6:30 Fọwọ́ sí Olè Jíjà?

Ìwé Òwe 6:30 sọ pé: “Àwọn ènìyàn kì í tẹ́ńbẹ́lú olè kìkì nítorí pé ó jalè láti fi tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọ́rùn nígbà tí ebi ń pa á.” Ṣé ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí pé kéèyàn máa jalè? Rárá o. Àwọn ohun tó wà láyìíká ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé Ọlọ́run kò ní jẹ́ kí olè náà lọ láìsan nǹkan kan fún ìwà tó hù. Ẹsẹ tó tẹ̀ lé e sọ pé: “Ṣùgbọ́n, nígbà tí a bá rí i, òun yóò san án padà ní ìlọ́po méje; gbogbo àwọn ohun tí ó níye lórí nínú ilé rẹ̀ ni yóò fi lélẹ̀.” (Òwe 6:31) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kéèyàn jalè torí pé ebi ń pa á lè má burú tó kéèyàn jalè nítorí ìwọra tàbí torí pé ó fẹ́ ṣèpalára fún ẹni tó jà lólè, síbẹ̀ náà, ẹni tó jalè torí pé ebi ń pa á ṣì máa san ohun tó jí pa dà. Nítorí náà, àwọn tó ń fẹ́ ojú rere Ọlọ́run gbọ́dọ̀ rí i pé àwọn kò jalè láìka ipò èyíkéyìí tí wọ́n bá wà sí.