Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Oúnjẹ Àti Àlùmọ́ọ́nì Inú Ilẹ̀ Máa Tó Èèyàn Lò Títí Ayé?

Ǹjẹ́ Oúnjẹ Àti Àlùmọ́ọ́nì Inú Ilẹ̀ Máa Tó Èèyàn Lò Títí Ayé?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ǹjẹ́ Oúnjẹ Àti Àlùmọ́ọ́nì Inú Ilẹ̀ Máa Tó Èèyàn Lò Títí Ayé?

▪ Ilẹ̀ ayé wa ẹlẹ́wà yìí lágbára tó gadabú láti pèsè ohun táwọn ẹ̀dá alààyè nílò. Síbẹ̀ bí iye èèyàn ṣe ń pọ̀ sí i, tí wọ́n sì túbọ̀ ń lo àwọn àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ lọ́nà tó bùáyà, o lè máa ṣe kàyéfì pé: ‘Ǹjẹ́ ṣàǹgbá ò ní fọ́ lọ́jọ́ kan? Ṣé oúnjẹ àti àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ kò ní tán lọ́jọ́ kan báyìí?’

Téèyàn bá ronú lórí ìbéèrè yìí, ìlérí tí Ọlọ́run ṣe fún aráyé ní ohun tó lé ní ẹgbàajì [4,000] ọdún sẹ́yìn lè fọkàn ẹni balẹ̀, ó sọ pé: “Ní gbogbo ọjọ́ tí ilẹ̀ ayé yóò máa bá a lọ ní wíwà, fífún irúgbìn àti ìkórè, àti òtútù àti ooru, àti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn àti ìgbà òtútù, àti ọ̀sán àti òru, kì yóò kásẹ̀ nílẹ̀ láé.” (Jẹ́nẹ́sísì 8:22) Bẹ́ẹ̀ ni, bó ṣe dájú pé oòrùn á máa yọ lójoojúmọ́, bẹ́ẹ̀ ló dájú pé oúnjẹ àti àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ téèyàn á máa lò kò ní tán láé.

Nínú ìròyìn ọdún 2004 tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní “Ṣé Ilẹ̀ Ayé Yìí Lè Bọ́ Wa?” Ọ̀gbẹ́ni Alex Kirby, tó ń kọ̀ròyìn nípa àyíká ilẹ̀ ayé, sọ pé: “Ayé yìí ń pèsè oúnjẹ tó tó láti bọ́ gbogbo èèyàn. Ṣùgbọ́n ọwọ́ àwọn tí kò yẹ ni oúnjẹ náà sábà máa ń bọ́ sí tàbí kí owó rẹ̀ wọ́n jù tàbí kí wọ́n má ṣeé tọ́jú fún ìgbà pípẹ́. Nítorí náà, ohun tó fà á tí gbogbo èèyàn kò fi lè rí oúnjẹ tó pọ̀ tó jẹ kò sí lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ọwọ́ àwọn olóṣèlú ló wà.” Tá a bá bójú tó ilẹ̀ ayé bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, tá a sì lo àwọn àlùmọ́ọ́nì inú rẹ̀ dáadáa, kò ní sí ìdí tí oúnjẹ kò fi ní tó. Bí àpẹẹrẹ, nígbà ayé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, Ọlọ́run fún wọn ní ìtọ́ni nípa bí wọ́n ṣe lè lo ilẹ̀ lọ́nà tó tọ́. Gẹ́gẹ́ bó ṣe wà ní Léfítíkù 25:4, Ọlọ́run sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ní ọdún keje kí sábáàtì ìsinmi pátápátá wà fún ilẹ̀ náà . . . Ìwọ kò gbọ́dọ̀ fún irúgbìn sí pápá rẹ.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò ní máa ṣiṣẹ́ lórí ilẹ̀ náà ní ọdún keje, Ọlọ́run ṣèlérí pé òun á rí sí i pé inú àwọn èèyàn náà á dùn pé ọ̀pọ̀ ohun rere wà, wọn kò sì ní máa ṣàníyàn pé oúnjẹ kò ní tó.—Léfítíkù 26:3-5.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan ń sapá gidigidi lónìí láti tún ilẹ̀ ayé àtàwọn àlùmọ́ọ́nì inú rẹ̀ tó ti bà jẹ́ ṣe, àwọn kan rò pé ohun tó bà jẹ́ ti bà jẹ́ ná, ẹ̀pa kò bóró mọ́. Ojútùú kan ṣoṣo tó lè yanjú ọ̀ràn náà wà nínú Ìṣípayá 11:18. Bíbélì sọ níbẹ̀ pé Jèhófà yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” Yàtọ̀ sí pé Jèhófà máa fòpin sí bíba ayé àtàwọn àlùmọ́ọ́nì inú rẹ̀ jẹ́, ó tún máa mú kí ilẹ̀ ayé mú oúnjẹ tó pọ̀ jáde, àwọn ohun àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ á sì pọ̀ yanturu fún ìlò aráyé. Kò ní sí gbogbo àìgbọràn sí Ọlọ́run mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kò ní sí ṣíṣe ayé níṣekúṣe torí ìmọtara ẹni nìkan mọ́. Lọ́wọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àwọn tó ń ti ìṣàkóso Jèhófà lẹ́yìn yóò rí i nígbà tí ọ̀rọ̀ inú Sáàmù 72:16 bá ṣẹ pé: “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”

Jèhófà ti pinnu nínú ìfẹ́ àti ọgbọ́n rẹ̀ tí kò lópin pé aráyé yóò máa gbé nínú ilé wọn, ìyẹn Párádísè orí ilẹ̀ ayé, tí wọ́n á sì máa bójú tó o. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀, aráyé onígbọràn á kọ́ bí wọ́n á ṣe máa lo àwọn àlùmọ́ọ́nì inú ilẹ̀ lọ́nà tó tọ́, láìlò wọ́n gbẹ ráúráú. A dúpẹ́ a tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Olùpèsè onífẹ̀ẹ́ tó máa tẹ́ ìfẹ́ gbogbo ohun aláàyè lọ́rùn!—Sáàmù 145:16.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

“Ohun tó fà á tí gbogbo èèyàn kò fi lè rí oúnjẹ tó pọ̀ tó jẹ kò sí lọ́wọ́ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì, ọwọ́ àwọn olóṣèlú ló wà”