Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Batisí Wọn Ní Orúkọ Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́

A Batisí Wọn Ní Orúkọ Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́

A Batisí Wọn Ní Orúkọ Baba, Ọmọ àti Ẹ̀mí Mímọ́

“Nítorí náà, ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.”—MÁT. 28:19.

1, 2. (a) Kí ló ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù ní Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni? (b) Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ lára àwùjọ àwọn èèyàn náà ṣe batisí?

 JERÚSÁLẸ́MÙ kún fún ogunlọ́gọ̀ èèyàn tó ti ọ̀pọ̀ ilẹ̀ wá. Ìdí ni pé àjọyọ̀ pàtàkì kan ń lọ lọ́wọ́ níbẹ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sì torí àjọyọ̀ náà wá síbẹ̀. Àmọ́, ohun àrà ọ̀tọ̀ kan ṣẹlẹ̀, lẹ́yìn rẹ̀ sì ni àpọ́sítélì Pétérù sọ àsọyé kan tó múni lórí yá, tó sì nípa lórí àwọn èèyàn náà lọ́nà tó ga lọ́lá. Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] àwọn Júù àti aláwọ̀ṣe ni àsọyé náà wọ̀ lọ́kàn, wọ́n ronú pìwà dà, a sì fi omi batisí wọn. Nípa báyìí, a fi wọ́n kún ìjọ Kristẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀. (Ìṣe 2:41) Ẹ sì wo bí ẹsẹ̀ gìrìgìrì ọ̀pọ̀ èèyàn yìí á ṣe pọ̀ tó ní Jerúsálẹ́mù bí wọ́n ṣe ń batisí wọn nínú àwọn odò adágún tàbí àwọn ibòmíì tí omi wà!

2 Kí ló fà á tí àwọn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ fi ṣe batisí? Ṣáájú ká tó batisí wọn, “ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì.” Nǹkan bí ọgọ́fà [120] ọmọ ẹ̀yìn tó wà ní yàrá òkè, nínú ilé kan, kún fún ẹ̀mí mímọ́. Lẹ́yìn náà, àwọn ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n jẹ́ olùfọkànsìn kóra jọ, ẹnu sì yà wọ́n bí wọ́n ti gbọ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyí ń “fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ Pétérù, tó fi mọ́ ohun tó sọ láìfọ̀rọ̀-sábẹ́-ahọ́n nípa ikú Jésù, ọ̀pọ̀ lára wọn ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ ‘gún dé ọkàn-àyà.’ Kí wá ni ṣíṣe? Pétérù dáhùn pé: “Ẹ ronú pìwà dà, kí a sì batisí olúkúlùkù yín ní orúkọ Jésù Kristi . . . , ẹ ó sì gba ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ẹ̀mí mímọ́.”—Ìṣe 2:1-4, 36-38.

3. Kí ló pọn dandan pé kí àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tó ronú pìwà dà ṣe ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì?

3 Ronú nípa bí ọ̀ràn ìjọsìn àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù ṣe rí. Wọ́n ti gba Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run wọn. Wọ́n sì mọ̀ látinú Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, èyí tó lò nígbà ìṣẹ̀dá àti lẹ́yìn ìgbà náà. (Jẹ́n. 1:2; Oníd. 14:5, 6; 1 Sám. 10:6; Sm. 33:6) Àmọ́, kò tíì tán síbẹ̀. Ó ṣe pàtàkì pé kí wọ́n mọ ẹni tí Ọlọ́run máa tipasẹ̀ rẹ̀ gba aráyé là, ìyẹn Jésù tí í ṣe Mèsáyà, kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á. Torí náà, Pétérù mú kí wọ́n rí ìdí tó fi pọn dandan pé ká ‘batisí wọn ní orúkọ Jésù Kristi.’ Lọ́jọ́ díẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn, Jésù tí Ọlọ́run jí dìde pàṣẹ fún Pétérù àtàwọn yòókù pé kí wọ́n máa batisí àwọn èèyàn “ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́.” (Mát. 28:19, 20) Àṣẹ yẹn ní ìtumọ̀ pàtàkì ní ọ̀rúndún kìíní, bẹ́ẹ̀ náà ló sì nítumọ̀ lónìí. Kí ni ìtumọ̀ náà?

Ní Orúkọ Baba

4. Ìyípadà wo ló wáyé nínú ọ̀nà táwọn èèyàn lè gbà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà?

4 Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ, olùjọsìn Jèhófà làwọn tó gbọ́ àsọyé Pétérù, wọ́n sì ti wọnú àjọṣe pẹ̀lú Ọlọ́run kó tó dìgbà yẹn. Wọ́n ti ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé Òfin Ọlọ́run, ìyẹn ló sì fà á táwọn tó ń gbé ilẹ̀ míì lára wọn fi wá sí Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 2:5-11) Àmọ́, Ọlọ́run ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìyípadà tó kàmàmà nípa ọ̀nà tí yóò máa gbà bá ẹ̀dá èèyàn lò ni. Ó kọ àwọn Júù sílẹ̀ pé wọn kì í ṣe orílẹ̀-èdè àkànṣe fún òun mọ́; pé kì í tún ṣe nípa pípa òfin mọ́ ni wọ́n fi lè rí ìtẹ́wọ́gbà òun. (Mát. 21:43; Kól. 2:14) Bí àwọn tó gbọ́rọ̀ Pétérù bá fẹ́ láti máa ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà, ohun mìíràn ṣì wà tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe.

5, 6. Kí ni ọ̀pọ̀ lára àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe ọ̀rúndún kìíní ṣe kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run?

5 Kì í ṣe pé kí wọ́n fi Jèhófà, tó jẹ́ Olùfúnni-ní-ìyè wọn sílẹ̀ là ń sọ o. (Ìṣe 4:24) Ó ti yé àwọn tó gbọ́ àlàyé tí Pétérù ṣe ju ti tẹ́lẹ̀ lọ pé Baba olóore-ọ̀fẹ́ ni Jèhófà. Ó rán Mèsáyà láti gbà wọ́n, ó sì múra tán láti dárí ji àwọn tí Pétérù sọ nípa wọn pé: “Kí gbogbo ilé Ísírẹ́lì mọ̀ dájúdájú pé, Jésù yìí tí ẹ kàn mọ́gi ni Ọlọ́run fi ṣe Olúwa àti Kristi.” Kódà, àwọn tó bá yé pé àwọn lọ̀rọ̀ Pétérù ń bá wí, á ti wá rí i pé àwọn ní ìdí tó pọ̀ láti máa dúpẹ́ torí ohun tí Baba ti ṣe fún gbogbo àwọn tó fẹ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀!—Ka Ìṣe 2:30-36.

6 Àwọn Júù àtàwọn aláwọ̀ṣe wọ̀nyẹn ti wá rí i báyìí pé gbígbà pé Jèhófà ló ń tipasẹ̀ Jésù fúnni ní ìgbàlà, wà lára ọ̀nà téèyàn lè gbà ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. A lè wá rí ìdí tí wọ́n fi ronú pìwà dà kúrò nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tó fi mọ́ ẹ̀bi tí wọ́n pín nínú pípa tí wọ́n pa Jésù, yálà wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀ọ́mọ̀. Èyí sì tún jẹ́ ká rí ìdí tó fi jẹ́ pé látìgbà náà lọ, “wọ́n . . . ń bá a lọ ní fífi ara wọn fún ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì.” (Ìṣe 2:42) Wọ́n di ẹni tó lè “sún mọ́ ìtẹ́ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí pẹ̀lú òmìnira ọ̀rọ̀ sísọ,” ó sì dájú pé ohun tí wọ́n á fẹ́ láti ṣe nìyẹn.—Héb. 4:16.

7. Báwo ni ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí ṣe yí èrò wọn nípa Ọlọ́run pa dà, tá a sì batisí wọn ní orúkọ Baba?

7 Lóde òní, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tí wọ́n wá láti ibi tó yàtọ̀ síra ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Jèhófà látinú Bíbélì. (Aísá. 2:2, 3) Àwọn kan gbà pé kò sí Ọlọ́run tàbí pé ọ̀rọ̀ ẹ̀dá ò kan Ọlọ́run, a àmọ́ wọ́n wá gbà pé Ẹlẹ́dàá wà àti pé àwọn lè ní àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn míì ń sin ọlọ́run mẹ́talọ́kan tàbí kí wọ́n máa bọ onírúurú òrìṣà. Wọ́n kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run Olódùmarè, wọ́n sì ti ń fi orúkọ rẹ̀ pè é báyìí. Ìyẹn ṣe wẹ́kú pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ pé a gbọ́dọ̀ batisí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ní orúkọ Baba.

8. Kí ló pọn dandan pé kí àwọn tí kò mọ̀ pé àwọn ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ Ádámù mọ̀ nípa Baba?

8 Wọ́n tún ti kẹ́kọ̀ọ́ pé àwọn jogún ẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Ádámù. (Róòmù 5:12) Ohun tuntun lèyí jẹ́ fún wọn, wọ́n sì gbọ́dọ̀ gbà pé òótọ́ ni. A lè fi irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ wé ọkùnrin aláìsàn kan tí kò mọ̀ pé àìsàn ń ṣe òun. Ó ti lè máa rí fìrìfìrì pé ara òun ò fẹ́ yá, bíi kí ara máa rò ó lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Síbẹ̀, torí pé kò ṣe àyẹ̀wò táá fi mọ irú àìsàn tó ń ṣe òun, ó lè máa rò pé ara òun yá. Àmọ́, ẹ̀rí fi hàn pé ara rẹ̀ kò yá. (Fi wé 1 Kọ́ríńtì 4:4.) Bó bá wá rẹ́ni sọ irú àìsàn tó ń ṣe é fún un ńkọ́? Ǹjẹ́ kò ní bọ́gbọ́n mu kó wá bó ṣe máa gba ìtọ́jú tó dáa, tó ti ran àwọn míì lọ́wọ́, tó sì gbéṣẹ́? Bákan náà, lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún, wọ́n fara mọ́ àlàyé kínníkínní tí Bíbélì ṣe nípa rẹ̀, wọ́n sì ti wá lóye pé Ọlọ́run ti ṣe tán láti dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ náà ji àwọn. Bẹ́ẹ̀ ni, gbogbo àwọn tó ti di àjèjì sí Baba gbọ́dọ̀ wá ìrànlọ́wọ́ Ẹni náà tó lè ṣe àwòtán ẹ̀ṣẹ̀ wọn.—Éfé. 4:17-19.

9. Kí ni Jèhófà ṣe ká bàa lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀?

9 Bó o bá ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run tó o sì ti di Kristẹni tá a batisí, wàá ti mọ bó ṣe jẹ́ ohun àgbàyanu tó pé kéèyàn ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Wàá sì mọrírì bí Baba rẹ, Jèhófà, ṣe jẹ́ onífẹ̀ẹ́ tó. (Ka Róòmù 5:8.) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ádámù àti Éfà ti dẹ́ṣẹ̀ sí Jèhófà, Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló kọ́kọ́ gbé ìgbésẹ̀, kí gbogbo àtọmọdọ́mọ wọ́n, tó fi mọ́ àwa, lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú rẹ̀. Èyí mú kó dun Ọlọ́run bó ṣe ń wò ó tí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ń jìyà tó sì kú. Ǹjẹ́ mímọ èyí kò tó láti mú ká mọyì àṣẹ Ọlọ́run kí ìfẹ́ sì sún wa láti máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́? Bí o kò bá tíì ṣe bẹ́ẹ̀, ìdí púpọ̀ wà tó fi yẹ kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run kó o sì ṣèrìbọmi.

Ní Orúkọ Ọmọ

10, 11. (a) Báwo ni gbèsè ọpẹ́ tó o jẹ Jésù ṣe pọ̀ tó? (b) Báwo ni ikú ìrúbọ tí Jésù kú ṣe rí lára rẹ?

10 Wàyí o, tún ronú nípa ohun tí Pétérù sọ fáwọn ogunlọ́gọ̀ náà. Ó sọ fún wọn bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n gba Jésù, èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú dídi ẹni tá a batisí “ní orúkọ . . . Ọmọ.” Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì nígbà yẹn, kí sì nìdí tó fi ṣe pàtàkì báyìí? Ó ṣe pàtàkì ká mọ̀ pé dídi ẹni tá a batisí lórúkọ Jésù túmọ̀ sí pé ká lóye ipa tí Jésù kó nínú bá a ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá. Wọ́n gbé Jésù kọ́ sórí òpó igi oró kó bàa lè mú ègún Òfin kúrò fún àwọn Júù; àmọ́, àǹfààní tí ikú rẹ̀ mú wá ju ìyẹn lọ. (Gál. 3:13) Ó pèsè ẹbọ ìràpadà tí gbogbo aráyé nílò. (Éfé. 2:15, 16; Kól. 1:20; 1 Jòh. 2:1, 2) Kí ìyẹn lè ṣeé ṣe, ó fara da ìwà ìrẹ́jẹ, ìkẹ́gàn, ìdálóró àti lẹ́yìn náà, ikú. Báwo lo ṣe mọrírì ẹbọ rẹ̀ tó? Jẹ́ ká sọ pé ìwọ ni ọmọdékùnrin, ọmọ ọdún méjìlá tó ń rìnrìn àjò nínú ọkọ̀ òkun Titanic, èyí tó forí sọ òkìtì yìnyín tó sì rì lọ́dún 1912. Bí ọkọ̀ náà ṣe ń rì, o gbìyànjú láti bẹ́ sínú ọkọ̀ ojú omi kékeré tí wọ́n fi ń gbẹ̀mí àwọn èèyàn là, àmọ́ ọkọ̀ náà ti kún. Lẹ́yìn náà ni ọkùnrin kan tó ti wà nínú ọkọ̀ kékeré yẹn fẹnu ko ìyàwó rẹ̀ lẹ́nu, ó bẹ́ sínú ọkọ̀ ńlá tó ń rì náà, ó sì gbé ẹ sínú ọkọ̀ kékeré. Báwo ló ṣe máa rí lára rẹ? Ó dájú pé wàá mọrírì ohun tó ṣe! Èyí á jẹ́ kó o mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára ọmọdékùnrin kan tí ohun tá a sọ yìí ṣẹlẹ̀ sí gan-an. b Síbẹ̀, ohun tí Jésù ṣe fún ẹ ju ìyẹn lọ fíìfíì. Ó kú kó o lè máa wà láàyè títí láé.

11 Báwo ló ṣe rí lára rẹ nígbà tó o mọ ohun tí Ọmọ Ọlọ́run ṣe fún ẹ? (Ka 2 Kọ́ríńtì 5:14, 15.) Kò sí iyè méjì pé o mọrírì rẹ̀ gan-an. Ìyẹn sì mú kó o ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, tí o kò sì ‘wà láàyè fún ara rẹ mọ́, bí kò ṣe fún ẹni tí ó kú nítorí rẹ.’ Ṣíṣe batisí ní orúkọ Ọmọ túmọ̀ sí pé kó o nígbàgbọ́ nínú ohun tí Jésù ti ṣe fún ẹ kó o sì fi ara rẹ sábẹ́ àṣẹ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí “Olórí Aṣojú ìyè.” (Ìṣe 3:15; 5:31) Kò sí àjọṣe kankan láàárín ìwọ àti Ẹlẹ́dàá tẹ́lẹ̀, o kò sì ní ìrètí kan tó ṣe gúnmọ́. Àmọ́, nípa lílo ìgbàgbọ́ nínú ẹ̀jẹ̀ tí Jésù Kristi ta sílẹ̀ tó o sì ṣe batisí, ó ti wá dẹni tó ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Baba. (Éfé. 2:12, 13) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin tí a sọ di àjèjì àti ọ̀tá nígbà kan rí nítorí tí èrò inú yín wà lórí àwọn iṣẹ́ tí ó burú, ni [Ọlọ́run] tún ti mú padà rẹ́ nísinsìnyí nípasẹ̀ ẹran ara [Jésù] nípasẹ̀ ikú rẹ̀, kí ó lè mú yín wá ní mímọ́ àti ní àìlábààwọ́n.”—Kól. 1:21, 22.

12, 13. (a) Báwo ló ṣe yẹ kí ṣíṣe batisí ní orúkọ Ọmọ nípa lórí ohun tí wàá ṣe bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ẹ́? (b) Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tá a batisí ní orúkọ Jésù, àwọn nǹkan wo lo gbọ́dọ̀ máa ṣe?

12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a batisí rẹ ní orúkọ Ọmọ, o mọ̀ dáadáa pé o ṣì lè dẹ́ṣẹ̀. Mímọ̀ tó o mọ̀ bẹ́ẹ̀, á máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ẹ́, ǹjẹ́ o máa ń rántí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ẹ̀yin méjèèjì? Ẹ̀yin méjèèjì nílò ìdáríjì Ọlọ́run, ó sì yẹ kẹ́ ẹ lè dárí ji ara yín. (Máàkù 11:25) Láti sọ bí èyí ti ṣe pàtàkì tó, Jésù fúnni ní àpèjúwe kan, ó ní: Ọ̀gá kan fagi lé gbèsè ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá tálẹ́ńtì (ọgọ́ta mílíọ̀nù dínárì) tí ẹrú rẹ̀ jẹ ẹ́. Nígbà tí ẹrú yìí rí ẹrú ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó jẹ ẹ́ ní gbèsè ọgọ́rùn-ún dínárì, ó ní kí wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n títí tó máa fi san gbèsè náà. Kókó tí Jésù fà yọ níbẹ̀ ni pé: Jèhófà kò ní dárí ji ẹni tí kò bá dárí ji arákùnrin rẹ̀. (Mát. 18:23-35) Bó ṣe rí gan-an nìyẹn, bíbatisí ẹnì kan ní orúkọ Ọmọ túmọ̀ sí pé kó mọyì àṣẹ Jésù, kó sì sapá láti máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀ àti ẹ̀kọ́ tó fi kọ́ni, títí kan bó ṣe máa ń múra tán láti dárí ji àwọn ẹlòmíì.—1 Pét. 2:21; 1 Jòh. 2:6.

13 Torí pé o jẹ́ aláìpé, kò lè ṣeé ṣe fún ẹ láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù délẹ̀délẹ̀. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, torí pé tọkàntọkàn lo fi ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, wàá fẹ́ láti fara wé Jésù débi tí agbára rẹ bá gbé e dé. Èyí kan pé kó o máa bá a nìṣó láti bọ́ ògbólógbòó àkópọ̀ ìwà sílẹ̀ kó o sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. (Ka Éfésù 4:20-24.) Bó o bá ní ọ̀rẹ́ kan tó o bọ̀wọ̀ fún gidigidi, ó ṣeé ṣe kó o kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ rẹ̀ àtàwọn ànímọ́ rere rẹ̀. Bákan náà ló ṣe yẹ kó o fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ lára Kristi kó o sì máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

14. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọyì àṣẹ Jésù gẹ́gẹ́ bí Ọba Ìjọba Ọlọ́run?

14 Ọ̀nà mìíràn wà tó o lè gbà fi hàn pé o lóye ohun tó wé mọ́ dídi ẹni tá a batisí ní orúkọ Ọmọ. Ọlọ́run “fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ [Jésù], ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ.” (Éfé. 1:22) Torí náà, o gbọ́dọ̀ mọyì ọ̀nà tí Jésù ń gbà darí àwọn tó bá ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà. Kristi ń lo àwọn èèyàn aláìpé nínú ìjọ, pàápàá jù lọ àwọn àgbà ọkùnrin tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn, ìyẹn àwọn alàgbà tá a yàn sípò. Nítorí àtilè “ṣe ìtọ́sọ́nàpadà àwọn ẹni mímọ́, . . . fún gbígbé ara Kristi ró,” la ṣe ń yan irú àwọn ọkùnrin bẹ́ẹ̀ sípò. (Éfé. 4:11, 12) Kódà, béèyàn aláìpé bá ṣe àṣìṣe, Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run lágbára láti bójú tó ọ̀ràn náà lákòókò tó tọ́ àti lọ́nà tó yẹ. Ǹjẹ́ o gbà bẹ́ẹ̀?

15. Bí o kò bá tíì ṣe batisí, àwọn ìbùkún wo lo lè máa fojú sọ́nà fún lẹ́yìn tó o bá ṣe batisí?

15 Títí di báyìí, àwọn kan ò tíì ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, a kò sì tíì batisí wọn. Bí o kò bá tíì ṣe batisí, ǹjẹ́ o rí i látinú ohun tá a ti jíròrò yìí pé mímọ ẹni tí Ọmọ jẹ́ ni ohun tó bọ́gbọ́n mu pé kí ìmọrírì tó o ní sún ẹ láti ṣe? Bó o bá di ẹni tá a batisí ní orúkọ ọmọ, á ṣeé ṣe fún ẹ láti rí ìbùkún àgbàyanu gbà.—Ka Jòhánù 10:9-11.

Ní Orúkọ Ẹ̀mí Mímọ́

16, 17. Kí ló túmọ̀ sí pé kó o ṣe batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́?

16 Kí ló túmọ̀ sí láti di ẹni tá a batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́? Bá a ṣe sọ tẹ́lẹ̀, àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ Pétérù nígbà Pẹ́ńtíkọ́sì, mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ wà. Kódà, wọ́n fojú ara wọn rí i kedere pé Ọlọ́run ṣì ń lo ẹ̀mí mímọ́. Pétérù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó “kún fún ẹ̀mí mímọ́, [tí] wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀.” (Ìṣe 2:4, 8) Gbólóhùn náà, “ní orúkọ” kò fi dandan túmọ̀ sí orúkọ èèyàn kan pàtó. Lóde òní, ọ̀pọ̀ nǹkan là ń ṣe “ní orúkọ ìjọba,” bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe èèyàn kan là ń pè bẹ́ẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun tó túmọ̀ sí ni pé àṣẹ ìjọba la fi ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ẹni tá a batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́ mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan, àmọ́ ó jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Irú ìbatisí bẹ́ẹ̀ sì túmọ̀ sí pé èèyàn mọ ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ.

17 Ǹjẹ́ kì í ṣe ẹ̀kọ́ tó o kọ́ látinú Bíbélì ló jẹ́ kó o mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ wà? Bí àpẹẹrẹ, ó ti wá yé ẹ pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́. (2 Tím. 3:16) Bó o ti ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó ṣeé ṣe kó o ti túbọ̀ mọrírì rẹ̀ pé ‘Baba tí ń bẹ ní ọ̀run máa ń fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀,’ títí kan ìwọ náà. (Lúùkù 11:13) Bóyá o sì ti rí i pé ẹ̀mí mímọ́ ń darí ìgbésí ayé rẹ. Tó bá sì jẹ́ pé o kò tíì ṣe batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́, a jẹ́ pé ìbùkún ńláǹlà ń dúró dè ẹ́ láti rí ẹ̀mí mímọ́ gbà torí Jésù mú kó dá wa lójú pé Baba máa ń fúnni ní ẹ̀mí mímọ́.

18. Ìbùkún wo làwọn tá a batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́ máa ń gbádùn?

18 Lónìí pẹ̀lú, ó ṣe kedere pé Jèhófà ń fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí ìjọ Kristẹni, ó sì ń lò ó láti tọ́ ọ sọ́nà. Ẹ̀mí yẹn sì tún ń ran ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lọ́wọ́ nínú ìgbòkègbodò wa ojoojúmọ́. Ohun míì tó wé mọ́ ṣíṣe batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́ ni pé ká mọyì ipa tó ń kó nínú ìgbésí ayé wa, kí ìmọrírì tá a ní sì mú ká máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀. Àmọ́, àwọn kan lè máa ṣiyè méjì bóyá á ṣeé ṣe fún wa láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa sí Jèhófà ṣẹ, kí wọ́n má sì lóye ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó kàn táá máa jíròrò nìyẹn.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn tó gbà pé ọ̀rọ̀ ẹ̀dá ò kan Ọlọ́run mọ̀ pé Ọlọ́run wà, àmọ́ èrò wọn ni pé ọ̀rọ̀ àwa ẹ̀dá èèyàn kò jẹ ẹ́ lógún.

b Wo Jí! (Gẹ̀ẹ́sì) October 22, 1981, ojú ìwé 3 sí 8.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe batisí ní orúkọ Baba?

• Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe batisí ní orúkọ Ọmọ?

• Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì bó ti ṣe pàtàkì tó láti ṣe batisí ní orúkọ Baba àti Ọmọ?

• Kí ló túmọ̀ sí láti ṣe batisí ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Lẹ́yìn Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, àjọṣe wo ló wà láàárín Jèhófà àti àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn?

[Credit Line]

Nípasẹ̀ ìyọ̀ọ̀da ibi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí ìlú Ísírẹ́lì, ní Jerúsálẹ́mù