Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí Kó O Sì Mú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Rẹ Ṣẹ

Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí Kó O Sì Mú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Rẹ Ṣẹ

Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí Kó O Sì Mú Ẹ̀jẹ́ Ìyàsímímọ́ Rẹ Ṣẹ

“Ẹ máa rìn nípa ẹ̀mí, ẹ kì yóò sì ṣe ìfẹ́-ọkàn ti ẹran ara rárá.”—GÁL. 5:16.

1. Irú ìbatisí wo ló wáyé ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì?

 ÀWỌN ọmọlẹ́yìn Jésù fi ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì, ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, lẹ́yìn tá a ti fi ẹ̀mí mímọ́ batisí wọn. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé a ti fún wọn ní ẹ̀bùn ẹ̀mí lọ́nà ìyanu. (1 Kọ́r. 12:4-10) Kí ló jẹ́ àbájáde ẹ̀bùn ẹ̀mí tí wọ́n rí gbà yìí àti àsọyé tí Pétérù sọ? Ọ̀rọ̀ rẹ̀ gún ọ̀pọ̀ àwọn tó wà níbẹ̀ “dé ọkàn-àyà.” Pétérù rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n ronú pìwà dà, ká sì batisí wọn, wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Àwọn tí wọ́n fi tọkàntọkàn gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni a batisí, ní ọjọ́ yẹn nǹkan bí ẹgbẹ̀ẹ́dógún ọkàn ni a sì fi kún wọn.” (Ìṣe 2:22, 36-41) Bí Jésù ṣe pa á láṣẹ, wọ́n ti ní láti batisí wọn nínú omi ní orúkọ Baba, ọmọ àti ẹ̀mí mímọ́.—Mát. 28:19.

2, 3. (a) Sọ ìyàtọ̀ tó wà nínú ká fi ẹ̀mí mímọ́ batisí èèyàn àti ká batisí èèyàn ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́. (b) Kí nìdí tó fi pọn dandan pé kí àwọn tó di Kristẹni tòótọ́ lónìí ṣèrìbọmi?

2 Àmọ́, ǹjẹ́ ìyàtọ̀ wà nínú ká fi ẹ̀mí mímọ́ batisí èèyàn àti ká batisí èèyàn ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn tá a fi ẹ̀mí mímọ́ batisí di àtúnbí, ìyẹn àwọn ọmọ Ọlọ́run tá a fẹ̀mí bí. (Jòh. 3:3) A fòróró yàn wọ́n láti di ọba tí yóò bá Jésù ṣàkóso àti àwọn àlùfáà tó máa wà lábẹ́ rẹ̀ nínú Ìjọba Ọlọ́run lókè ọ̀run, wọ́n sì di apá kan ará Kristi nípa tẹ̀mí. (1 Kọ́r. 12:13; Gál. 3:27; Ìṣí. 20:6) Torí náà, ìbatisí yìí, ìyẹn fífi ẹ̀mí mímọ́ batisí, ni ohun tí Jèhófà ṣe nígbà tó yan àwọn kan láti jẹ́ ajùmọ̀jogún pẹ̀lú Kristi ní ọjọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì àti lẹ́yìn náà. (Róòmù 8:15-17) Àmọ́, ìbatisí nínú omi ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́, èyí táwa èèyàn Jèhófà lóde òní máa ń ṣe ní gbogbo àpéjọ àyíká, àkànṣe àti àgbègbè ńkọ́?

3 Ìrìbọmi jẹ́ ìgbésẹ̀ kan táwọn Kristẹni máa ń gbé láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run láìkù síbì kan. Ìyẹn làwọn tó gba ìpè ti ọ̀run fi gbọ́dọ̀ ṣèrìbọmi. Àmọ́, ó tún pọn dandan pé kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkùnrin àtobìnrin lóde òní tí wọ́n nírètí gbígbé títí láé lórí ilẹ̀ ayé ṣèrìbọmi. Láìka ìrètí yòówù kẹ́nì kan ní sí, ìrìbọmi ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, jẹ́ ìgbésẹ̀ tó pọn dandan téèyàn gbọ́dọ̀ gbé kó tó lè ní ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. Torí náà, gbogbo Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ “máa rìn nípa ẹ̀mí.” (Ka Gálátíà 5:16.) Ṣé ò ń rìn nípa ẹ̀mí tó o sì ń mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ?

Ohun Tó Túmọ̀ sí Láti “Máa Rìn Nípa Ẹ̀mí”

4. Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn “máa rìn nípa ẹ̀mí”?

4 Béèyàn ṣe lè “máa rìn nípa ẹ̀mí” ni pé kó jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí ìgbésí ayé òun. A lè sọ pé ó túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí gbogbo ohun tó bá ń ṣe lójoojúmọ́. Gálátíà orí 5 sọ ìyàtọ̀ tó wà nínú kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí èèyàn àti kí ẹran ara máa darí èèyàn.—Ka Gálátíà 5:17, 18.

5. Wíwà lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí mímọ́ gba pé kéèyàn máa sá fún àwọn iṣẹ́ wo?

5 Tí ẹ̀mí mímọ́ bá ń darí rẹ, wàá máa sá fún àwọn iṣẹ́ ti ara. Àwọn nǹkan bí “àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìwà àìníjàánu, ìbọ̀rìṣà, bíbá ẹ̀mí lò, ìṣọ̀tá, gbọ́nmi-si omi-ò-to, owú, ìrufùfù ìbínú, asọ̀, ìpínyà, ẹ̀ya ìsìn, ìlara, mímu àmuyíràá, àwọn àríyá aláriwo.” (Gál. 5:19-21) Èyí tó máa já sí pé o “fi ikú pa àwọn ìṣe ti ara nípasẹ̀ ẹ̀mí.” (Róòmù 8:5, 13) Ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti máa fọkàn sí àwọn nǹkan ti ẹ̀mí, wàá sì jẹ́ kó máa darí rẹ dípò àwọn ìfẹ́ ti ẹran ara.

6. Ṣàpèjúwe ohun tá a nílò ká lè máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù.

6 Bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú rẹ, wàá máa fi àwọn ànímọ́ Ọlọ́run, ìyẹn “èso ti ẹ̀mí” ṣèwà hù. (Gál. 5:22, 23) Ó yẹ kó yé ẹ pé o máa ní láti sapá gan-an. Bí àpẹẹrẹ: Ilẹ̀ ni àgbẹ̀ kọ́kọ́ máa ń ro kó tó gbin irúgbìn. Síbẹ̀, ó máa nílò oòrùn àti omi, torí pé láìsí àwọn nǹkan méjèèjì yìí, kò lè rí irè kó. A lè fi ẹ̀mí mímọ́ wé oòrùn. A nílò ẹ̀mí mímọ́ ká lè máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù. Àmọ́, ṣé àgbẹ̀ yẹn á rí irè kó tí òun fúnra rẹ̀ kò bá ṣiṣẹ́ kára? (Òwe 10:4) Dájúdájú, bó o ṣe ń múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀ tó ló máa pinnu bí ẹ̀mí mímọ́ tá máa ṣiṣẹ́ nínú rẹ á ṣe pọ̀ tó àti bá a ṣe jẹ́ ojúlówó tó. Wá bi ara rẹ pé, ‘Ṣé mò ń gba ẹ̀mí mímọ́ láyè láti so èso rẹ̀ nínú mi nípa fífọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀?’

7. Kí nìdí tí ìkẹ́kọ̀ọ́ àti àṣàrò fi ṣe pàtàkì tó o bá fẹ́ máa fi èso ẹ̀mí mímọ́ ṣèwà hù?

7 Kí àwọn àgbẹ̀ tó lè rí ohun tó pọ̀ kórè, wọ́n tún máa nílò omi fún àwọn irúgbìn wọn. Kó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti máa fi èso ti ẹ̀mí ṣèwà hù, o nílò omi òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì tá a sì ń rí gbà nípasẹ̀ ìjọ Kristẹni lóde òní. (Aísá. 55:1) Ó ṣeé ṣe kó o ti máa sọ fáwọn èèyàn pé ẹ̀mí mímọ́ ló darí àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́. (2 Tím. 3:16) Bákan náà, ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń pèsè ìlàlóye tá a nílò nípa òtítọ́ inú Bíbélì èyí tó dà bí omi tó mọ́ gaara. (Mát. 24:45-47) A sì mọ ohun tí èyí túmọ̀ sí. Ká lè dẹni tí ẹ̀mí mímọ́ ń darí, a gbọ́dọ̀ máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ká sì máa ṣàṣàrò lórí rẹ̀. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe lò ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà táwọn wòlíì fi lélẹ̀ torí pé wọ́n ṣe “ìwádìí aláápọn àti ìwákáàkiri àfẹ̀sọ̀ṣe” nípa àwọn ìsọfúnni tí wọ́n pèsè. Ó tún gbàfiyèsí pé àwọn ańgẹ́lì pàápàá fi ìfẹ́ tó jinlẹ̀ hàn sí ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Irú Ọmọ náà tí Ọlọ́run ṣèlérí àti ìjọ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró.—Ka 1 Pétérù 1:10-12.

Báwo Ni Ẹ̀mí Mímọ́ Ṣe Lè Máa Darí Rẹ?

8. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o béèrè ẹ̀mí mímọ́ lọ́dọ̀ Jèhófà?

8 Kì í wulẹ̀ ṣe pé kó o máa kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́ kó o sì máa ṣàṣàrò lé e lórí. O ní láti máa béèrè ìrànlọ́wọ́ àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Jèhófà sì lè “ṣe ju ọ̀pọ̀ yanturu ré kọjá gbogbo ohun tí a béèrè tàbí tí a wòye rò.” (Éfé. 3:20; Lúùkù 11:13) Báwo lo ṣe máa dáhùn nígbà tí ẹnì kan bá bi ẹ́ pé, “Kí nìdí tí màá tún fi máa béèrè nǹkan lọ́wọ́ Ọlọ́run níwọ̀n bó ti mọ ‘ohun tí mo ṣe aláìní kí n tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá’?” (Mát. 6:8) Ohun kan ni pé, tó o bá ń gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́, ńṣe lò ń fi hàn pé o gbọ́kàn lé Jèhófà. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan bá wá ìrànlọ́wọ́ wá sọ́dọ̀ rẹ, wàá ṣe gbogbo ohun tó o bá lè ṣe láti ràn án lọ́wọ́, ìdí ni pé ó ní kó o ran òun lọ́wọ́, tó fi hàn pé ó fọkàn tán ẹ. (Fi wé Òwe 3:27.) Bákan náà, inú Jèhófà máa ń dùn tó o bá béèrè fún ẹ̀mí rẹ̀, á sì fún ẹ.—Òwe 15:8.

9. Báwo ni lílọ sáwọn ìpàdé Kristẹni ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti dẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí?

9 Wàá tún gbà pé ọ̀nà míì tá a fi lè dẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí ní í ṣe pẹ̀lú àwọn ìpàdé wa, tó fi mọ́ àpéjọ àyíká, àkànṣe àti àgbègbè. Sísapá láti pésẹ̀ síbẹ̀ ká sì máa fọkàn bá ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà lọ ṣe pàtàkì gan-an. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá dẹni tó lóye “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 2:10) Àǹfààní tún wà nínú pé kéèyàn máa dáhùn àwọn ìbéèrè déédéé ní ìpàdé. Ronú nípa àwọn ìpàdé tó o lọ láàárín ọ̀sẹ̀ mẹ́rin tó kọjá. Ìgbà mélòó lo nawọ́ sókè láti dáhùn, kó o lè sọ ohun tó o gbà gbọ́? Ǹjẹ́ o rí ibi tó o ti lè sunwọ̀n sí i lápá ibí yìí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, pinnu ohun tó o máa ṣe láwọn ọ̀sẹ̀ tó ń bọ̀. Jèhófà á ri bó o ṣe múra tán láti kópa, á sì fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ táá jẹ́ kó o túbọ̀ máa jàǹfààní láwọn ìpàdé tó o bá lọ.

10. Ìkésíni wo ni rírìn nípa ẹ̀mí gbà pé ká máa ṣe?

10 Rírìn nípa ẹ̀mí gba pé kó o dáhùn sí ìpè tá a kà nínú Ìṣípayá 22:17, tó sọ pé: “Ẹ̀mí àti ìyàwó ń bá a nìṣó ní sísọ pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ bẹ́ẹ̀ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.” Ẹ̀mí tó ń ṣiṣẹ́ nípasẹ̀ àwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ ẹgbẹ́ ìyàwó, ló ń ké sí àwọn èèyàn láti wá gba omi ìyè. Tó o bá ti tẹ́wọ́ gba ìpè náà pé “máa bọ̀!” ṣé o ti múra tán láti ké sí àwọn míì pé, “Máa bọ̀!”? Àǹfààní ńlá ló jẹ́ fún wa láti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìgbẹ̀mílà yìí!

11, 12. Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú iṣẹ́ ìwàásù?

11 Ẹ̀mí mímọ́ ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ pàtàkì yìí láṣeyọrí. A kà nípa bí ẹ̀mí mímọ́ ṣe kópa nínú ṣíṣí ìpínlẹ̀ ìwàásù tuntun sílẹ̀ fún àwọn míṣọ́nnárì ọ̀rúndún kìíní. “Ẹ̀mí mímọ́ ka sísọ ọ̀rọ̀ náà ní àgbègbè Éṣíà léèwọ̀ fún” àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n jọ rìnrìn àjò, kò sì tún gbà wọ́n láyè láti lọ sí Bítíníà. A kò mọ bí ẹ̀mí mímọ́ kò ṣe jẹ́ kí wọ́n lọ sáwọn àgbègbè yẹn gan-an, síbẹ̀ ó ṣe kedere pé ẹ̀mí darí Pọ́ọ̀lù láti lọ sí ilẹ̀ Yúróòpù tó gbòòrò gan-an. Nínú ìran, ó rí ọkùnrin ará Makedóníà kan tó ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́.—Ìṣe 16:6-10.

12 Lóde òní, ẹ̀mí Jèhófà náà ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù jákèjádò ayé. Ọlọ́run kò lo ìran kankan lọ́nà ìyanu láti darí wa. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀mí mímọ́ ló fi ń tọ́ àwọn ẹni àmì òróró sọ́nà. Ẹ̀mí yìí náà ló sì ń darí àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin láti ṣe gbogbo ohun tí agbára wọn ká lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Ó dájú pé wàá ti máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ pàtàkì yìí. Ṣé o lè fi kún ayọ̀ tó ò ń rí lẹ́nu iṣẹ́ amóríyá yìí?

13. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí rẹ? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.

13 O lè jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ máa darí rẹ tó o bá ń fi àwọn ìsọfúnni táwọn èèyàn Ọlọ́run ń pèsè sílò. Gbé àpẹẹrẹ Mihoko, ọ̀dọ́ kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Japan yẹ̀ wò. Nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di aṣáájú-ọ̀nà, ó máa ń ṣòro fún un láti ṣe ìpadàbẹ̀wò, ó lérò pé òun ò mọ bí òun ṣe lè mú kí onílé nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ òun. Láàárín àkókò yẹn ni wọ́n gbé àwọn àbá kan tó wúlò jáde nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa lórí béèyàn ṣe lè ṣe ìpadàbẹ̀wò ṣókí. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìwé pẹlẹbẹ tó sọ̀rọ̀ nípa béèyàn ṣe lè gbé ìgbé ayé tó nítumọ̀, ìyẹn A Satisfying Life—How to Attain It. Ìwé yìí wúlò gan-an lórílẹ̀-èdè Japan. Mihoko lo àwọn àbá tó dá lórí béèyàn ṣe lè lo ìwé pẹlẹbẹ náà, àgàgà lórí béèyàn ṣe lè fi ṣe ìpadàbẹ̀wò ṣókí. Kò pẹ́ tó fi bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwọn tí kò ní fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ tẹ́lẹ̀. Ó sọ pé, “Mo ti wá ní ìkẹ́kọ̀ọ́ tó pọ̀ gan-an, kódà ó tó méjìlá lẹ́ẹ̀kan, débi pé ńṣe ni mo máa ń bẹ àwọn kan pé kí wọ́n ní sùúrù!” Ní tòótọ́, tó o bá ń rìn nípa ẹ̀mí, tó ò ń fi àwọn ìtọ́ni táwọn èèyàn Jèhófà ń rí gbà sílò, wàá kóre tó pọ̀ yanturu.

Gbára Lé Ẹ̀mí Ọlọ́run

14, 15. (a) Báwo ló ṣe lè ṣeé ṣe fún àwọn ẹ̀dá aláìpé láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wọn ṣẹ? (b) Báwo lo ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà?

14 Gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn, o ní iṣẹ́ òjíṣẹ́ kan láti ṣe. (Róòmù 10:14) Ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé o ò kúnjú ìwọ̀n láti ṣe iṣẹ́ náà. Àmọ́ bíi ti àwọn ẹni àmì òróró, Ọlọ́run ló mú kó o kúnjú ìwọ̀n. (Ka 2 Kọ́ríńtì 3:5.) O lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ tó o bá ń ṣe gbogbo ohun tágbára rẹ gbé, tó o sì gbára lé ẹ̀mí Ọlọ́run.

15 A gbà pé kò rọrùn fún àwa èèyàn aláìpé láti mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ wa ṣẹ sí Jèhófà Ọlọ́run wa tó jẹ́ ẹni pípé. Ohun táá mú kó ṣòro ni pé ìgbésí ayé tuntun tó ò ń gbé lè máa rú àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ rẹ àtijọ́ lójú kí wọ́n sì máa ‘sọ̀rọ̀ rẹ tèébútèébú.’ (1 Pét. 4:4) Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé o ti ní àwọn tó ṣe pàtàkì jù lọ lọ́rẹ̀ẹ́, ìyẹn Jèhófà àti Jésù Kristi. (Ka Jákọ́bù 2:21-23.) Ó tún ṣe pàtàkì pé kó o mọ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ rẹ, àwọn tí wọ́n jẹ́ ara “ẹgbẹ́ àwọn ará,” kárí ayé. (1 Pét. 2:17; Òwe 17:17) Jèhófà á fi ẹ̀mí rẹ̀ ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ní àwọn ọ̀rẹ́ táá máa nípa rere lórí rẹ.

16. Bíi ti Pọ́ọ̀lù báwo lo ṣe lè “ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera”?

16 Kódà, bó o bá ní àwọn ọ̀rẹ́ àtàtà nínú ìjọ, ó ṣì lè ṣòro fún ẹ láti máa fara da àwọn ìṣòro ojoojúmọ́. Nígbà míì àwọn ohun tó ò ń bá yí lè tán ẹ lókun, àfi bíi pé ò ń tinú ìṣòro kan bọ́ sínú ìṣòro míì láìsí ọ̀nà àbájáde. Ìgbà yẹn gan-an ló yẹ kó o gbàdúrà sí Jèhófà, kó o béèrè fún ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.” (Ka 2 Kọ́ríńtì 4:7-10; 12:10.) Pọ́ọ̀lù mọ̀ pé bá a tilẹ̀ jẹ́ aláìpé, ẹ̀mí Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn àìlera ẹ̀dá tá a ní. Torí náà, ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run lè fún wa lókun nígbà tá a bá ń ṣàárẹ̀ tàbí nígbà tá a bá nílò ìrànwọ́. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun máa ń “ní ìdùnnú nínú àwọn àìlera.” Ìgbà tí Pọ́ọ̀lù ṣàárẹ̀, ó rí i pé ẹ̀mí mímọ́ fún òun lókun. Ẹ̀mí mímọ́ lè fún ìwọ náà lókun!—Róòmù 15:13.

17. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ bó o ti ń forí lé ibi tó ò ń lọ?

17 A nílò ẹ̀mí Ọlọ́run ká bàa lè máa gbé ìgbé ayé wa gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún un. Wò ó pé o jẹ́ atukọ̀ ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi ń gbafẹ́. Wọ́n máa ń ta aṣọ sára ọkọ̀ ojú omi yìí, ẹ̀fúùfù tó ń bì lu aṣọ náà á sì ran atukọ̀ lọ́wọ́ láti máa darí ọkọ rẹ̀ síbi tó fẹ́ kó lọ. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àfojúsùn rẹ ni láti máa sin Jèhófà títí láé, ńṣe ni ẹ̀mí mímọ́ wá dà bí ẹ̀fúùfù táá máa darí rẹ kó o lè gúnlẹ̀ sí èbúté láyọ̀. O kò ní fẹ́ kí ẹ̀mí ayé Sátánì máa tì ẹ́ síhìn-ín sọ́hùn-ún. (1 Kọ́r. 2:12) Bíi ti atukọ̀ ojú omi yẹn, o gbọ́dọ̀ tukọ̀ rẹ gba ibi tí ẹ̀fúùfù á ti darí rẹ lọ síbi tó yẹ. Iṣẹ́ tí ẹ̀mí mímọ́ ń ṣe gan-an nìyẹn. Nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ètò rẹ̀ tó ń fẹ̀mí darí, ẹ̀mí mímọ́ máa darí rẹ gba ibi tó yẹ.

18. Kí lo ti pinnu láti ṣe báyìí, kí sì nìdí?

18 Tó o bá ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ò ń gbádùn àjọṣe tẹ̀mí pẹ̀lú wọn, àmọ́ tó ò tíì gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì láti ya ara rẹ sí mímọ́ kó o sì ṣe ìrìbọmi, bi ara rẹ pé: ‘Kí ló ń dá mi dúró?’ Tó o bá ti mọ ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó nínú mímú àwọn ìpinnu Jèhófà ṣẹ lóde òní, tó o sì mọrírì àwọn iṣẹ́ tó ń ṣe, nígbà náà ṣe àwọn nǹkan tó o ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó tọ́. Jèhófà á sì bù kún ẹ jìngbìnnì. Ó máa fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ lọ́fẹ̀ẹ́. Yálà ó ti pẹ́ tó o ti ṣèrìbọmi tàbí kò tíì pẹ́, ó dájú pé o ti rí ipa tí ẹ̀mí mímọ́ ń kó. O ti rí bí Ọlọ́run ṣe ń fi ẹ̀mí rẹ̀ fúnni lókun, ìwọ náà sì ti rí irú okun bẹ́ẹ̀ gbà. O sì lè máa jàǹfààní irú okun bẹ́ẹ̀ títí ayérayé. Torí náà, pinnu láti máa bá a lọ ní rírìn nípa ẹ̀mí mímọ́.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ló túmọ̀ sí láti máa “rìn nípa ẹ̀mí”?

• Kí ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti “máa rìn nípa ẹ̀mí”?

• Báwo lo ṣe lè mú ẹ̀jẹ́ ìyàsímímọ́ rẹ ṣẹ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ó gba ìsapá láti múra ọkàn-àyà rẹ sílẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

Ṣé ẹ̀mí Ọlọ́run ń darí rẹ?