Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá Ò Ṣe Ní Pàdánù Ojúure Ọlọ́run Bí Ìyípadà Bá Tiẹ̀ Dé Bá Wa

Bá Ò Ṣe Ní Pàdánù Ojúure Ọlọ́run Bí Ìyípadà Bá Tiẹ̀ Dé Bá Wa

Bá Ò Ṣe Ní Pàdánù Ojúure Ọlọ́run Bí Ìyípadà Bá Tiẹ̀ Dé Bá Wa

ǸJẸ́ àwọn ìyípadà kan ti dé bá ẹ? Ṣé ó ṣòro fún ẹ láti fara mọ́ àwọn ìyípadà náà? Èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wa ni nǹkan ti yí pa dà fún tàbí kó jẹ́ pé nǹkan máa tó yí pa dà fún wa. Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá sí àwọn kan lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ àwọn ànímọ́ tó máa ṣe wá láǹfààní.

Bí àpẹẹrẹ, gbé ọ̀ràn Dáfídì àtàwọn ìyípadà tó dé bá a yẹ̀ wò. Ọmọkùnrin kékeré kan tó ń da àgùntàn ló jẹ́ nígbà tí Sámúẹ́lì fòróró yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la. Nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti bá Gòláyátì òmìrán ọmọ ilẹ̀ Filísínì jà. (1 Sám. 17:26-32, 42) Wọ́n ní kí Dáfídì wá máa gbé láàfin Sọ́ọ̀lù Ọba nígbà tó ṣì wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n sì tún fi ṣe olórí àwọn ọmọ ogun. Ó dájú pé Dáfídì ò lè ronú pé àwọn ìyípadà yìí máa dé bá òun, kò sì lè mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí òun lẹ́yìn náà.

Nígbà tó yá, àárín Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù kò gún mọ́. (1 Sám. 18:8, 9; 19:9, 10) Dáfídì ní láti máa sá kiri fún ọdún mélòó kan kí Sọ́ọ̀lù má bàa pa á. Kódà lẹ́yìn tó ti di ọba lórí Ísírẹ́lì, àwọn ìyípadà kan dé bá a lójijì, ní pàtàkì jù lọ nígbà tó ṣe panṣágà, tó sì di apànìyàn torí kó lè bo ẹ̀ṣẹ̀ náà mọ́lẹ̀. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tí òun fúnra rẹ̀ dá, àjálù dé bá ìdílé rẹ̀. Lára wọn ni ọ̀tẹ̀ tí Ábúsálómù ọmọ rẹ̀ ṣe. (2 Sám. 12:10-12; 15:1-14) Síbẹ̀, lẹ́yìn tí Dáfídì ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà àti ìpànìyàn tó dá, Jèhófà dárí jì í, ó sì pa dà rí ojúure Ọlọ́run.

Nǹkan lè yí pa dà fún ìwọ náà. Lára àwọn ohun tó máa ń fa ìyípadà nígbèésí ayé wa ni ìṣòro ìlera, àìrówóná tàbí àwọn ìṣòro ìdílé míì, títí kan àṣìṣe tiwa fúnra wa. Àwọn ànímọ́ wo ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti túbọ̀ wà ní ìmúrasílẹ̀ ká lè kojú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀?

Ẹ̀mí Ìrẹ̀lẹ̀ Á Jẹ́ Ká Mọ Ohun Tó Fa Ìyípadà

Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ gba pé ká jẹ́ onítẹríba. Ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ ò ní jẹ́ ká máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ, a óò sì lè máa fojú tó tọ́ wo àwọn èèyàn. Tí a kì í bá fojú tẹ́ńbẹ́lú ànímọ́ àti àṣeyọrí àwọn ẹlòmíì, a ó máa mọrírì irú ẹni tí wọ́n jẹ́ àtohun tí wọ́n ń ṣe. Bákan náà, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ á jẹ́ ká mọ ìdí tí ohun kan fi ṣẹlẹ̀ sí wa àti bá a ṣe máa bójú tó o.

Àpẹẹrẹ àtàtà ni Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù jẹ́ bó bá dọ̀ràn níní ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan tó kọjá agbára rẹ̀ mú kí ìyípadà dé bá a. Nígbà tí Sámúẹ́lì sọ fún Sọ́ọ̀lù pé Jèhófà máa gba ìjọba kúrò lọ́wọ́ rẹ̀, kò sọ pé Jónátánì ni ipò ọba máa bọ́ sí lọ́wọ́. (1 Sám. 15:28; 16:1, 12, 13) Yíyàn tí Ọlọ́run yan Dáfídì gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la lórí Ísírẹ́lì mú kí ipò náà fo Jónátánì ru. Lọ́nà kan, àìgbọ́ràn Sọ́ọ̀lù ṣàkóbá fún Jónátánì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónátánì kò lọ́wọ́ nínú ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe, síbẹ̀ òun kọ́ ló máa gbapò bàbá rẹ̀. (1 Sám. 20:30, 31) Kí ni Jónátánì wá ṣe sí ọ̀ràn náà? Ṣé ó di Dáfídì sínú torí àǹfààní tó pàdánù yìí, kó sì wá máa jowú rẹ̀? Rárá o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ju Dáfídì lọ, tó sì ní ìrírí jù ú lọ, síbẹ̀ ó ti Dáfídì lẹ́yìn. (1 Sám. 23:16-18) Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ jẹ́ kó mọ ẹni tí Ọlọ́run fọwọ́ sí, kò sì “ro ara rẹ̀ ju bí ó ti yẹ ní rírò lọ.” (Róòmù 12:3) Jónátánì mọ ohun tí Jèhófà ń rétí látọ̀dọ̀ òun, ó sì fara mọ́ ìpinnu Ọlọ́run lórí ọ̀ràn náà.

Lóòótọ́, ọ̀pọ̀ ìyípadà máa ń mú àwọn ìnira kan wá. Lákòókò kan, àjọṣe wà láàárín Jónátánì àtàwọn ọkùnrin méjì kan tó sún mọ́ ọn. Ọ̀kan lára wọn ni Dáfídì, ọ̀rẹ́ Jónátánì, ẹni tí Jèhófà ti yàn gẹ́gẹ́ bí ọba lọ́la. Ẹnì kejì ni Sọ́ọ̀lù, tó jẹ́ bàbá rẹ̀, tó ṣì ń ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti kọ̀ ọ́. Ọ̀rọ̀ yìí ti ní láti kó ẹ̀dùn ọkàn bá Jónátánì, bó ti ń sapá láti má ṣe pàdánù ojúure Jèhófà. Àwọn ìyípadà tó máa dé bá àwa náà lè kó ìdààmú bá wa, ó sì lè mú kí ẹ̀rù máa bà wá. Àmọ́ tá a bá gbìyànjú láti mọ ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan, a ó lè máa fi ìṣòtítọ́ sìn ín, bá a ti ń bá àwọn ìyípadà náà yí.

Ìmọ̀wọ̀n-Ara-Ẹni Ṣe Pàtàkì

Ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni túmọ̀ sí pé kéèyàn mọ ibi tí òun kù sí. Àmọ́ ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni yàtọ̀ sí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, torí pé ẹni tó lẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ lè má fi bẹ́ẹ̀ mọ ibi tí òun kù sí.

Dáfídì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ti yàn án gẹ́gẹ́ bí ọba, ọ̀pọ̀ ọdún ni ipò náà kò fi tẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́. A kò rí i kà pé Jèhófà ṣàlàyé ohun tó fa ìdádúró yìí fún Dáfídì. Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ipò ti Dáfídì wà yìí ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán an ní sùúrù, kò jẹ́ kó yọ òun lẹ́nu. Ó mọ ibi tágbára òun mọ, ó sì mọ̀ pé Jèhófà tó fàyè gba ipò náà, mọ bó ṣe máa yanjú rẹ̀. Torí náà, Dáfídì ò pa Sọ́ọ̀lù kó bàa lè gbara rẹ̀ lọ́wọ́ Sọ́ọ̀lù, kò sì jẹ́ kí Ábíṣáì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà pa á.—1 Sám. 26:6-9.

Nígbà míì ohun kan lè ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ wa tí kò yé wa dáadáa tàbí tó jọ pé wọn ò bójú tó bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, lójú tiwa. Ṣé ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni á mú ká gbà pé Jésù ni Orí ìjọ àti pé ó ń lo ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà tá a yàn sípò láti máa darí ìjọ? Ṣé a ó fi hàn pé a mọ̀wọ̀n ara wa, ká gbà pé tá ò bá fẹ́ pàdánù ojúure Jèhófà, a gbọ́dọ̀ jẹ́ kó máa darí wa nípasẹ̀ Jésù Kristi? Ṣé ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni á jẹ́ ká máa tẹ̀ lé ìdarí rẹ̀, bí kò tiẹ̀ rọrùn fún wa láti ṣe bẹ́ẹ̀?—Òwe 11:2.

Ọkàn Tútù Ò Ní Jẹ́ Ká Sọ̀rètí Nù

Ọkàn tútù túmọ̀ sí ìwà tútù. Ó máa ń jẹ́ ká fi sùúrù fara dà á bí ẹnì kan bá ṣẹ̀ wá, ká sì yẹra fún ìbínú, dídi kùnrùngbùn àti ẹ̀mí ìgbẹ̀san. Kò rọrùn láti jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Ó dùn mọ́ni pé nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, a ké sí àwọn “ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé,” pé kí wọ́n “wá ọkàn tútù.” (Sef. 2:3) Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ni ọkàn tútù, ìrẹ̀lẹ̀ àti ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni fi jọra, wọ́n sì tún tan mọ́ àwọn ànímọ́ míì bí ìwà rere àti ìwà tútù. Ọlọ́kàn tútù èèyàn lè dàgbà nípa tẹ̀mí, torí pé á máa fi hàn pé òun jẹ́ ẹni tó ṣeé kọ́ lẹ́kọ̀ọ́, á sì jẹ́ kí Ọlọ́run máa darí òun.

Báwo ni ọkàn tútù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìyípadà tó bá dé bá wa? O lè ti kíyè sí i pé ojú tí kò tọ́ lọ̀pọ̀ èèyàn fi máa ń wo ìyípadà tó bá dé bá wọn. Ká sòótọ́, ó lè jẹ́ ọ̀nà nìyẹn fún wa láti túbọ̀ dẹni tí Jèhófà dá lẹ́kọ̀ọ́. A rí àpẹẹrẹ èyí nínú ìgbésí ayé Mósè.

Nígbà tí Mósè wà lẹ́ni ogójì [40] ọdún, ó ti láwọn ànímọ́ tó dára gan-an. Ó ti fi hàn pé òun mọ ìṣòro táwọn èèyàn Ọlọ́run ń kojú, ó sì ti fi hàn pé òun lẹ́mìí ìfara-ẹni-rúbọ. (Héb. 11:24-26) Síbẹ̀, kí Jèhófà tó yàn án pé kó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, àwọn ìyípadà kan ní láti kọ́kọ́ wáyé nínú ìgbésí ayé rẹ̀, èyí tó máa mú kó túbọ̀ lọ́kàn tútù. Ó sá kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì lọ sí ilẹ̀ Mídíánì tí wọn ò ti mọ̀ ọ́n, ó sì ṣe olùṣọ́ àgùntàn níbẹ̀ fún ogójì [40] ọdún. Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Ìyípadà yìí jẹ́ kí ìwà rẹ̀ dáa sí i. (Núm. 12:3) Ó kọ́ láti máa fi àwọn nǹkan tẹ̀mí ṣáájú àwọn nǹkan tara.

Láti mọ bí ọkàn tútù Mósè ṣe pọ̀ tó, jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhófà sọ pé òun fẹ́ pa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìgbọràn run, kóun sì sọ àwọn àtọmọdọ́mọ Mósè di orílẹ̀-èdè ńlá. (Núm. 14:11-20) Mósè bẹ̀bẹ̀ fún orílẹ̀-èdè náà. Àwọn ọ̀rọ̀ tó sọ fi hàn pé orúkọ rere Ọlọ́run àti àlááfíà àwọn arákùnrin rẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún ju ohun tó máa ṣàǹfààní fún un lọ. Èèyàn tó jẹ́ ọlọ́kàn tútù bíi Mósè ló lè ṣe aṣáájú orílẹ̀-èdè náà kó sì tún jẹ́ alárinà láàárín wọn àti Ọlọ́run. Míríámù àti Áárónì kùn sí Mósè, síbẹ̀ Bíbélì sọ pé ó “fi gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ jẹ́ ọlọ́kàn tútù jù lọ nínú gbogbo ènìyàn.” (Núm. 12:1-3, 9-15) Ó jọ pé ọkàn tútù Mósè mú kó fara da gbogbo àbùkù tí wọ́n fi kàn án. Báwo ni nǹkan ì bá ṣe rí ká sọ pé Mósè kì í ṣe ọlọ́kàn tútù?

Lákòókò míì, ẹ̀mí Jèhófà wọnú àwọn ọkùnrin kan, ó sì mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ tẹ́lẹ̀. Jóṣúà, tó jẹ́ òjíṣẹ́ Mósè, ronú pé ohun tí kò tọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì yìí ń ṣe. Àmọ́, ọkàn tútù Mósè mú kó fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wò ó, kò sì torí rẹ̀ dààmú pé ìyẹn lè mú kí àṣẹ bọ́ mọ́ òun lọ́wọ́. (Núm. 11:26-29) Ká ní Mósè kì í ṣe ọlọ́kàn tútù ni, ṣé á ṣeé ṣe fún un láti fara mọ́ ìyípadà yìí nínú ìṣètò Jèhófà?

Ọkàn tútù mú kí Mósè lo agbára àti ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ lọ́nà rere. Jèhófà sọ fún un pé kó gun Òkè Hórébù, kó sì dúró níwájú àwọn èèyàn náà. Ọlọ́run gbẹnu Mósè bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ áńgẹ́lì kan, ó sì yàn án gẹ́gẹ́ bí alárinà májẹ̀mú. Ọkàn tútù Mósè jẹ́ kó tẹ́wọ́ gba ìyípadà ńlá tó ní í ṣe pẹ̀lú àṣẹ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́ yìí, síbẹ̀ kò pàdánù ojúure Ọlọ́run.

Àwa ńkọ́? Ọkàn tútù ṣe pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ẹnì kọ̀ọ̀kan wa. Gbogbo àwọn tó ní ojúṣe tí wọ́n ń bójú tó, tí wọ́n sì ní àṣẹ láàárín àwọn èèyàn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù. Ọkàn tútù kì í jẹ́ ká gbéra ga bí ìyípadà bá dé bá wa, ó sì máa ń jẹ́ ká fi ẹ̀mí tó tọ́ bójú tó ohun tó bá yọjú. Ọwọ́ tá a bá fi mú ìyípadà náà ṣe pàtàkì. Ṣé a máa fara mọ́ ìyípadà náà? Ṣé a máa wò ó bí ọ̀nà tá a lè gbà mú ara wa sunwọ̀n sí i? Ó lè jẹ́ àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ fún wa láti ní ọkàn tútù!

Kò sígbà tí ìyípadà ò ní máa dé bá wa. Nígbà míì kì í rọrùn láti mọ ìdí tí àwọn nǹkan fi wáyé. Ìkùdíẹ̀ káàtó tiwa fúnra wa àti ìnira tó bá wa lè mú kó ṣòro fún wa láti fi ojú tí Jèhófà fi ń wo nǹkan wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Síbẹ̀, àwọn ànímọ́ bí ìrẹ̀lẹ̀, ìmọ̀wọ̀n-ara-ẹni àti ọkàn tútù máa jẹ́ ká lè fara mọ́ ìyípadà tó bá dé bá wa, ká má sì pàdánù ojúure Ọlọ́run.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Ojúlówó ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ kò ní jẹ́ ká máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 5]

Ọkàn tútù ṣe pàtàkì nínú ìdàgbàsókè ẹnì kọ̀ọ̀kan wa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Mósè kojú àwọn ìṣòro tó mú kó túbọ̀ jẹ́ ọlọ́kàn tútù