Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máàkù ‘Wúlò fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́’

Máàkù ‘Wúlò fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́’

Máàkù ‘Wúlò fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́’

ÌJỌ tó wà ní Áńtíókù ti ní àwọn ìṣòro kan, àmọ́ èdèkòyédè tó wáyé láàárín àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Bánábà yàtọ̀ sí tiwọn. Àwọn ọkùnrin méjèèjì yìí ń múra ìrìn àjò míṣọ́nnárì, àmọ́ nígbà tí wọ́n fẹ́ yan àwọn tó máa bá wọn rin ìrìn àjò náà, “ìbújáde ìbínú mímúná” wáyé láàárín wọn. (Ìṣe 15:39) Àwọn méjèèjì bá pínyà wọ́n sì gba ọ̀nà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Orí Máàkù tó jẹ́ ẹnì kẹta wọn ni awuyewuye náà dá lé.

Ta ni Máàkù? Kí ló fà á táwọn àpọ́sítélì méjì ò fi gbọ́ra wọn yé nítorí rẹ̀? Kí nìdí tí èrò wọn nípa rẹ̀ fi yàtọ̀ síra. Ǹjẹ́ èrò wọn pàpà yí pa dà? Kí lo lè rí kọ́ látinú ìtàn Máàkù?

Nígbà Tí Máàkù Wà Nílé ní Jerúsálẹ́mù

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdílé tó rí já jẹ ni wọ́n bí Máàkù sí, nílùú Jerúsálẹ́mù. Ohun tá a kọ́kọ́ mọ̀ nípa rẹ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ìtàn ìjọ Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Ní nǹkan bí ọdún 44, Sànmánì Kristẹni, nígbà tí áńgẹ́lì Jèhófà tú àpọ́sítélì Pétérù sílẹ̀ ní akóló Hẹ́rọ́dù Àgírípà Kìíní, Pétérù kọrí sí “ilé Màríà ìyá Jòhánù tí a fún ní orúkọ àpèlé náà Máàkù, níbi tí àwọn púpọ̀ díẹ̀ kóra jọpọ̀ sí, tí wọ́n sì ń gbàdúrà.”—Ìṣe 12:1-12. a

Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ilé ìyá Máàkù ni ìjọ tó wà ní Jerúsálẹ́mù ti ń ṣe ìpàdé. Ti pé “àwọn púpọ̀ díẹ̀” ń ṣèpàdé níbẹ̀ fi hàn pé ilé náà tóbi. Màríà ní ìránṣẹ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ródà, òun ló dá Pétérù lóhùn nígbà tó kan “ilẹ̀kùn ojú ọ̀nà àbáwọlé.” Èyí fi hàn pé obìnrin tó rí já jẹ ni Màríà. Wọ́n sì tún pe ilé náà ní ilé rẹ̀, dípò kí wọ́n pè é ní ilé ọkọ rẹ̀, torí náà ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọkọ rẹ̀ ti kú àti pé Máàkù ṣì kéré gan-an.—Ìṣe 12:13.

Ó ṣeé ṣe kí Máàkù wà lára àwọn tó kóra jọ láti gbàdúrà. Ó ti ní láti mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù, àtàwọn míì tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù ṣojú wọn, ní àmọ̀dunjú. Kódà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Máàkù ni ọ̀dọ́kùnrin tí aṣọ kò bo ara rẹ̀ dáadáa tó gbìyànjú láti tẹ̀ lé Jésù nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ mú un, tó sì sá lọ nígbà tí wọ́n gbìyànjú láti gbá òun náà mú.—Máàkù 14:51, 52.

Àwọn Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Tó Ní Nínú Ìjọ

Kò sí àní-àní pé bí Máàkù ṣe ń kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí ní ipa rere lórí rẹ̀. Ó dàgbà nípa tẹ̀mí, àwọn arákùnrin tó wà nípò àbójútó sì mọyì rẹ̀. Nǹkan bí ọdún 46 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà wá fi “ìpèsè a-dín-ìṣòro-kù” táwọn ará Áńtíókù fi ránṣẹ́ sí Jerúsálẹ́mù jíṣẹ́ kí wọ́n lè dín ìyàn tó ń mú kù, ni wọ́n ti rí i pé Máàkù máa wúlò. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì pa dà sí ìlú Áńtíókù, wọ́n mú Máàkù dání lọ.—Ìṣe 11:27-30; 12:25.

Béèyàn bá ka àkọsílẹ̀ yìí lóréfèé, ó lè máa wò ó pé, kò sí ohun tó pa àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta pọ̀ kọjá pé wọ́n jọ jẹ́ ará àti pé ẹ̀bùn tí Máàkù ní ló mú kí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà yàn án. Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù fi hàn pé mọ̀lẹ́bí Bánábà ni Máàkù jẹ́. (Kól. 4:10) Èyí á jẹ́ ká lóye ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí awuyewuye kan dá lórí Máàkù.

Ní nǹkan bí ọdún kan lẹ́yìn náà, ẹ̀mí mímọ́ darí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà pé kí wọ́n rìnrìn àjò míṣọ́nnárì. Wọ́n wá gbéra ìrìn àjò náà láti Áńtíókù, wọ́n sì forí lé Kípírù. Jòhánù Máàkù sì bá wọn lọ “gẹ́gẹ́ bí ẹmẹ̀wà.” (Ìṣe 13:2-5) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ìpèsè tara ni Máàkù ń bójú tó nígbà ìrìn àjò náà, káwọn àpọ́sítélì lè gbájú mọ́ àwọn nǹkan tẹ̀mí.

Pọ́ọ̀lù, Bánábà àti Máàkù gba ìlú Kípírù kọjá, wọ́n ń wàásù bí wọ́n ṣe ń lọ, lẹ́yìn náà wọ́n forí lé Éṣíà Kékeré. Ibẹ̀ ni Jòhánù Máàkù ti ṣe ìpinnu kan tí inú Pọ́ọ̀lù kò dùn sí. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé nígbà tí wọ́n dé sí Pẹ́gà, “Jòhánù fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà sí Jerúsálẹ́mù.” (Ìṣe 13:13) Àkọsílẹ̀ náà kò sọ ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù, Bánábà àti Máàkù pa dà sí Áńtíókù. Àwọn àpọ́sítélì méjèèjì ń jíròrò ìrìn àjò míṣọ́nnárì wọn ẹlẹ́ẹ̀kejì, kí wọ́n lè pa dà lọ fún àwọn ará tó wà níbẹ̀ lókun. Bánábà fẹ́ mú Máàkù tí í ṣe mọ̀lẹ́bí rẹ̀ dání, àmọ́ Pọ́ọ̀lù kò fara mọ́ ọn, torí pé Máàkù ti fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kan. Ohun tó fa èdèkòyédè tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí nìyẹn. Ni Bánábà bá mú Máàkù, ó lọ ṣiṣẹ́ ní Kípírù tó jẹ́ ìlú rẹ̀, Pọ́ọ̀lù sì kọjá lọ sí Síríà. (Ìṣe 15:36-41) Kò sí àní-àní pé èrò Pọ́ọ̀lù àti Bánábà kò ṣọ̀kan lórí ohun tó mú kí Máàkù ṣe ìpinnu tó ṣe nígbà yẹn.

Wọ́n Yanjú Èdèkòyédè Náà

Ó dájú pé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ba Máàkù lọ́kàn jẹ́ gan-an. Síbẹ̀, ó jẹ́ òjíṣẹ́ olóòótọ́. Ní nǹkan bí ọdún mọ́kànlá tàbí méjìlá lẹ́yìn tí ọ̀ràn náà ti wáyé, ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún jẹ yọ nínú ìtàn àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní. Ibo ló ti jẹ yọ? Ibi téèyàn ò lè ronú pé ó jẹ́ ni, ìyẹn inú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù!

Lọ́dún 60 sí 61 Sànmánì Kristẹni, nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà lẹ́wọ̀n nílùú Róòmù, ó fi àwọn lẹ́tà kan ránṣẹ́ tó ti wá di ara Ìwé Mímọ́ báyìí. Nínú lẹ́tà tó kọ sáwọn ará Kólósè, ó sọ pé: “Àrísítákọ́sì òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi kí yín, Máàkù mọ̀lẹ́bí Bánábà sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú, (nípa ẹni tí ẹ rí àwọn àṣẹ gbà pé kí ẹ fi inú dídùn tẹ́wọ́ gbà á bí ó bá wá sọ́dọ̀ yín) . . . Àwọn wọ̀nyí nìkan ni alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi fún ìjọba Ọlọ́run, àwọn wọ̀nyí gan-an sì ti di àrànṣe afúnnilókun fún mi.”—Kól. 4:10, 11.

Ìyípadà ńlá mà lèyí o! Máàkù tó mú inú bí Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀ wá di alábàáṣiṣẹ́pọ̀ tí Pọ́ọ̀lù mọyì gan-an. Ó hàn gbangba pé Pọ́ọ̀lù ti sọ fún àwọn ará Kólósè pé ó ṣeé ṣe kí Máàkù wá bẹ̀ wọ́n wò. Bí Máàkù bá lọ, ó máa ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí aṣojú Pọ́ọ̀lù.

Ṣé Pọ́ọ̀lù ti ń ṣàríwísí Máàkù ju bó ṣe yẹ lọ láti ọ̀pọ̀ ọdún wá ni? Ǹjẹ́ Máàkù tiẹ̀ jàǹfààní látinú ìbáwí tó tọ́ tí wọ́n fún un? Àbí ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ọ̀dọ̀ àwọn méjèèjì lọ̀rọ̀ náà fì sí? Ohun yòówù kó ṣẹlẹ̀, bí àwọn méjèèjì ṣe yanjú aáwọ̀ náà fi hàn pé Pọ́ọ̀lù àti Máàkù dàgbà nípa tẹ̀mí. Wọ́n gbàgbé ohun tó ti kọjá, wọ́n sì tún pa dà ṣiṣẹ́ pọ̀. Ẹ ò rí i pé àpẹẹrẹ àtàtà lèyí jẹ́ fún ẹnikẹ́ni tó bá ti ní èdèkòyédè pẹ̀lú ẹni tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni!

Máàkù Arìnrìn-Àjò

Bó o tí ń kà nípa ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìrìn àjò tí Máàkù rìn, wàá rí i pé àwọn ìrìn àjò náà kì í ṣe kékeré. Láti Jerúsálẹ́mù, ó kọjá lọ sí Áńtíókù, ó sì ti ibẹ̀ wọkọ̀ ojú omi lọ sí Kípírù àti Pẹ́gà. Lẹ́yìn náà ó lọ sí Róòmù. Ibẹ̀ ló wà tí Pọ́ọ̀lù ti fẹ́ rán an lọ sí Kólósè. Àmọ́ kò tán síbẹ̀ o!

Ní nǹkan bí ọdún 62 sí 64 Sànmánì Kristẹni ni àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́. Ó kọ̀wé pé: “Obìnrin tí ń bẹ ní Bábílónì . . . kí yín, Máàkù ọmọkùnrin mi ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú.” (1 Pét. 5:13) Èyí jẹ́ ká mọ̀ pé Máàkù lọ sí Bábílónì kó lè lọ ṣiṣẹ́ ìsìn pẹ̀lú Pétérù tó máa ń wá ṣe ìpàdé ní ilé ìyá rẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn.

Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń ṣẹ̀wọ̀n ẹlẹ́ẹ̀kejì ní ìlú Róòmù ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, ó kọ̀wé sí Tímótì tó wà ní Éfésù pé kó wá, ó sì fi kún un pé: “Mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú rẹ.” (2 Tím. 4:11) Èyí fi hàn pé Éfésù ni Máàkù wà nígbà yẹn. Kò sì sí iyè méjì pé Máàkù bá Tímótì lọ sí ìlú Róòmù gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ. Kò rọrùn láti rìnrìn àjò nígbà yẹn, àmọ́ Máàkù fínnú fíndọ̀ rin àwọn ìrìn àjò náà.

Àǹfààní Àrà Ọ̀tọ̀ Mìíràn

Àǹfààní àrà ọ̀tọ̀ kan tí Máàkù ní ni pé Jèhófà mí sí i láti kọ ọ̀kan lára àwọn ìwé Ìhìn Rere. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé kò sí orúkọ ẹni tó kọ ìwé Ìhìn Rere kejì yìí nínú ìwé náà, síbẹ̀ ìtàn fi hàn pé Máàkù ló kọ ọ́ àti pé Pétérù ló fún un láwọn ìsọfúnni tó kọ síbẹ̀. Ó ṣe tán gbogbo ohun tí Máàkù kọ ló ṣojú Pétérù.

Àwọn tó ṣe àrúnkúnná ìwé Ìhìn Rere Máàkù gbà pé torí àwọn Kèfèrí ló ṣe kọ ìwé náà; ó ṣe àlàyé tó jẹ́ kéèyàn lóye àṣà àwọn Júù síbẹ̀. (Máàkù 7:3; 14:12; 15:42) Máàkù túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ èdè Árámáíkì kan èyí tí ì bá ṣòro fáwọn tí kì í ṣe Júù láti lóyè. (Máàkù 3:17; 5:41; 7:11, 34; 15:22, 34) Ó lo ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ Látìn, kódà ó fi èdè Látìn ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó wọ́pọ̀. Ó sọ iye tí owó àwọn Júù jẹ́ ní owó àwọn ará Róòmù. (Máàkù 12:42) Ó jọ pé gbogbo èyí bá ohun tí wọ́n ti máa ń sọ tipẹ́tipẹ́ mu pé ìlú Róòmù ni Máàkù wà nígbà tó kọ ìwé Ìhìn Rere náà.

“Ó Wúlò fún Mi fún Iṣẹ́ Ìránṣẹ́”

Máàkù ṣe ohun mìíràn ní ìlú Róòmù yàtọ̀ sí ìwé Ìhìn Rere tó kọ níbẹ̀. Má ṣe gbàgbé pé Pọ́ọ̀lù ní kí Tímótì, “mú Máàkù, kí o sì mú un wá pẹ̀lú [rẹ̀].” Kí nìdí? Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nítorí ó wúlò fún mi fún iṣẹ́ ìránṣẹ́.”—2 Tím. 4:11.

Bá a bá fojú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa Máàkù wò ó, ibí yìí ló ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ kẹ́yìn, ohun tó sì sọ jẹ́ ká mọ púpọ̀ sí i nípa Máàkù. Kò sígbà kankan nínú ìtàn iṣẹ́ òjíṣẹ́ Máàkù tí wọ́n ti tọ́ka sí i gẹ́gẹ́ bí àpọ́sítélì, aṣáájú tàbí wòlíì. Òjíṣẹ́ ni, ìyẹn ẹni tó máa ń jíṣẹ́ tó sì máa ń sin àwọn míì. Níbi tọ́rọ̀ sì dé yìí, gẹ́rẹ́ ṣáájú kí Pọ́ọ̀lù tó kú, ó jàǹfààní látinú ìrànlọ́wọ́ tí Máàkù ṣe fún un.

Tá a bá ṣàkójọ onírúurú ìsọfúnni nípa Máàkù, a ó rí i pé ọkùnrin kan tó nítara fún pípolongo ìhìn rere láwọn apá ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ilẹ̀ ayé ni, ó sì máa ń láyọ̀ láti sin àwọn ẹlòmíì. Ká sòótọ́, Máàkù gbádùn àwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó mérè wá torí pé kò juwọ́ sílẹ̀!

Bíi ti Máàkù, àwa tá a jẹ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run lónìí ń fi irú ẹ̀mí ìmúratán kan náà wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn kan lára wa náà ń ṣe bíi ti Máàkù nípa ṣíṣí lọ sí àgbègbè míì, tàbí orílẹ̀-èdè míì pàápàá, kí wọ́n lè lọ wàásù ìhìn rere níbẹ̀. Bó tílẹ̀ jẹ́ pé gbogbo wa kọ́ ló lè ṣípò pa dà bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ gbogbo wa la lè fara wé Máàkù láwọn ọ̀nà míì. Bó ṣe sapá lákànṣe láti ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fáwọn arákùnrin rẹ̀, àwa náà máa ń sapá ká lè ran àwọn ará wa lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà tó lè ṣe wọ́n láǹfààní, kí wọ́n lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run. Bá a ti ń ṣe bẹ́ẹ̀, ó dá wa lójú pé a ó máa rí ìbùkún Jèhófà gbà.—Òwe 3:27; 10:22; Gál. 6:2.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn ìgbà yẹn láti ní orúkọ kejì tó jẹ́ èdè Hébérù tàbí orúkọ ilẹ̀ òkèèrè míì. Orúkọ Júù tí Máàkù ń jẹ́ ni Yohanan, tá a mọ̀ sí Jòhánù lédè Yorùbá. Orúkọ àpèlé rẹ̀ lédè Látìn ni Marcus, tàbí Máàkù.—Ìṣe 12:25.

[Àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Díẹ̀ Lára Àwọn Ìlú Tí Máàkù Ṣèbẹ̀wò Sí

Róòmù

Éfésù

Kólósè

Pẹ́gà

Áńtíókù (ti Síríà)

Kípírù

ÒKUN MẸDITARÉNÍÀ

Jerúsálẹ́mù

Bábílónì