Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkùnrin Tó Ṣe Ohun Tó Ta Yọ Jù Lọ Fáráyé

Ọkùnrin Tó Ṣe Ohun Tó Ta Yọ Jù Lọ Fáráyé

Ọkùnrin Tó Ṣe Ohun Tó Ta Yọ Jù Lọ Fáráyé

Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ti gbé ayé yìí, wọ́n sì ti kú. Ọ̀pọ̀ nínú wọn làwọn èèyàn ti gbàgbé. Àmọ́ díẹ̀ lára wọn ti ṣe ohun tó nípa rere lórí àwọn èèyàn, èyí tó ṣeé ṣe kó nípa lórí ìgbésí ayé rẹ ojoojúmọ́.

O JÍ láàárọ̀, ò ń múra láti lọ sí ibi iṣẹ́. O tan iná bó o ṣe ń múra. O mú ìwé kan tó o máa kà nínú ọkọ̀. O rántí láti mú oògùn apakòkòrò àrùn tó ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti gbógun ti àrùn kan tó ń ṣe ẹ́. Ọjọ́ ò tíì lọ débì kan, àmọ́ o ti jàǹfààní látinú ipa rere táwọn sàràkí èèyàn kan ní lórí aráyé.

Michael Faraday Wọ́n bí ọ̀gbẹ́ni ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì yìí ní ọdún 1791, òun ni onímọ̀ ẹ̀kọ́ nípa físíìsì tó ṣàwárí ẹ̀rọ tó ń mú iná jáde. Àwárí tó ṣe yìí jẹ́ kí iná mànàmáná wà fún ìlò gbogbo èèyàn.

Ts’ai Lun Ọ̀gbẹ́ni Ts’ai Lun jẹ́ òṣìṣẹ́ ní ilé ẹjọ́ gíga jù lọ ní orílẹ̀-èdè Ṣáínà, òun ló mú ìtẹ̀síwájú bá bí wọ́n ṣe ń ṣe bébà ní nǹkan bí ọdún 105 Sànmánì Kristẹni, èyí tó mú kí wọ́n máa ṣe bébà jáde lọ́pọ̀ yanturu.

Johannes Gutenberg Ọ̀gbẹ́ni ará Jámánì yìí ló ṣe àwọn lẹ́tà ọ̀rọ̀ tí wọ́n máa ń tò pọ̀ láti fi tẹ ìwé ní nǹkan bí ọdún 1450. Ọ̀nà yìí mú kó rọrùn láti tẹ̀wé tí owó rẹ̀ kò gani lára, ó sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àwọn èèyàn láti rí ìsọfúnni nípa kókó ọ̀rọ̀ èyíkéyìí tí wọ́n bá fẹ́.

Alexander Fleming Lọ́dún 1928, ọ̀gbẹ́ni ọmọ ilẹ̀ Scotland yìí ló ṣàwárí oògùn apakòkòrò àrùn tó pè ní penicillin. Ibi gbogbo làwọn èèyàn ti ń lo oògùn apakòkòrò àrùn báyìí.

Kò sí àní-àní pé àwárí tí àwọn ọkùnrin yìí ṣe ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn láti ní àwọn àǹfààní kan tàbí ìlera tó dára sí i.

Àmọ́ ọkùnrin kan wà tó ta gbogbo wọn yọ. Kò ṣàwárí ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì tàbí oògùn ìtọ́jú ìlera èyíkéyìí ní tiẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ọkùnrin tálákà, tó kú ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn yìí jẹ́ iṣẹ́ alágbára kan tó ń fúnni ní ìrètí àti ìtùnú. Tá a bá gbé bí iṣẹ́ tó jẹ́ ṣe ní ipa rere lórí àwọn èèyàn kárí ayé sórí òṣùwọ̀n, ọ̀pọ̀ ló máa gbà pé òótọ́ ni pé ọkùnrin yìí ti ṣe ohun tó ta yọ jù lọ fáráyé.

Jésù Kristi ni ọkùnrin yìí. Kí ni iṣẹ́ tó jẹ́ náà? Ipa wo sì ni iṣẹ́ yẹn lè ní lórí rẹ?