Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ọlọ́run

Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ọlọ́run

Ohun Tí Jésù Kọ́ni Nípa Ọlọ́run

“Ọmọ nìkan ló mọ ẹni tí Baba jẹ́. Àmọ́ Ọmọ fẹ́ láti sọ nípa Baba fún àwọn èèyàn, kí àwọn náà bàa lè mọ̀ ọ́n.”—LÚÙKÙ 10:22, CONTEMPORARY ENGLISH VERSION.

KÍ ÀKỌ́BÍ Ọlọ́run tó wá sáyé, ọ̀kẹ́ àìmọye ọdún ló ti fi wà pẹ̀lú Baba rẹ̀ lọ́run. (Kólósè 1:15) Èyí mú kí Ọmọ yìí mọ èrò Baba rẹ̀, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára rẹ̀ àti ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan. Àmọ́, nígbà tí Ọmọ yìí wá sáyé, tá a sì wá mọ̀ ọ́n sí Jésù, ó fẹ́ láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Baba rẹ̀. A lè kọ́ ohun tó pọ̀ nípa Ọlọ́run tá a bá fetí sí ohun tí Ọmọ yìí fẹ́ sọ.

Orúkọ Ọlọ́run Orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà ṣe pàtàkì sí Jésù gan-an. Ọmọ àtàtà yìí fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ orúkọ Baba rẹ̀ kí wọ́n sì máa lò ó. Ohun tí orúkọ Jésù fúnra rẹ̀ túmọ̀ sí ni “Ti Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Ìyẹn ló mú kí Jésù lè gbà á ládùúrà sí Jèhófà lálẹ́ tó ṣáájú ọjọ́ ikú rẹ̀ pé, ‘Mo ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀.’ (Jòhánù 17:26) Ìdí nìyẹn tí Jésù fi lo orúkọ Ọlọ́run, tó sì jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀. Kò sí bí àwọn tí Jésù ń bá sọ̀rọ̀ ṣe lè mọ òtítọ́ nípa Jèhófà tí wọn ò bá mọ orúkọ rẹ̀ àti ohun tí orúkọ náà dúró fún. a

Ìfẹ́ Ọlọ́run tó ga jù lọ Jésù sọ nígbà kan nínú àdúrà tó gbà sí Ọlọ́run pé: “Baba, . . . nífẹ̀ẹ́ mi ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Jòhánù 17:24) Lẹ́yìn tí Jésù ti rí bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe jinlẹ̀ tó nígbà tó wà ní ọ̀run, ó fẹ́ fi ìfẹ́ yìí hàn lónírúurú ọ̀nà nígbà tó wà láyé.

Jésù fi hàn pé ìfẹ́ Jèhófà gbòòrò. Ó sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí wọ́n pè ní “ayé” nínú ẹsẹ Bíbélì yìí kò túmọ̀ sí “ilẹ̀ ayé.” Ohun tó túmọ̀ sí ni aráyé. Torí náà, ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí aráyé pọ̀ gan-an débi pé ó fi Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n fún wọn kí àwọn olóòótọ́ èèyàn bàa lè bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí wọ́n sì lè ní ìrètí láti wà láàyè títí láé. Kò sí bá a ṣe lè díwọ̀n bí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí ẹ̀dá èèyàn ṣe jinlẹ̀ tó.—Róòmù 8:38, 39.

Jésù mú kí òtítọ́ kan dá wa lójú pé, Jèhófà nífẹ̀ẹ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olùjọ́sìn rẹ̀. Jésù kọ́ni pé Jèhófà dà bí olùṣọ́ àgùntàn tó mọ ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àgùntàn rẹ̀, tí wọ́n sì ṣeyebíye lójú rẹ̀. (Mátíù 18:12-14) Jésù sọ pé, kò sí ẹyẹ ológoṣẹ́ kan tó máa já bọ́ tí Jèhófà kì í mọ̀. Jésù fi kún un pé: “Gbogbo irun orí yín gan-an ni a ti kà.” (Mátíù 10:29-31) Bí Jèhófà bá lágbára láti mọ̀ pé ológoṣẹ́ kan ti já bọ́ látinú ìtẹ́ tó wà, ṣé kò wá ní kíyè sí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olùjọ́sìn rẹ̀ kó sì máa bójú tó wọn? Bí Jèhófà bá lè mọ iye irun orí wa, ǹjẹ́ ohun kan wà nípa ìgbésí ayé wa, ìyẹn àwọn ohun tá a fẹ́, akitiyan wa, ìdààmú tó bá wa, tí kò ní mọ̀?

Bàbá tí ń bẹ ní ọ̀run Gẹ́gẹ́ bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú, Jésù ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Ọlọ́run. Abájọ tí Ọmọ àtàtà yìí fi sábà máa ń pe Jèhófà ní “Baba” òun nígbà tó bá ń bá a sọ̀rọ̀ àti nígbà tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Kódà, nínú ọ̀rọ̀ Jésù tí wọ́n kọ́kọ́ ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀, èyí tó sọ nínú tẹ́ńpìlì nígbà tó wà ní ọmọ ọdún méjìlá, ó pe Jèhófà ní “Baba mi.” (Lúùkù 2:49) Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́wàá [190] ìgbà tí ọ̀rọ̀ náà “Baba” fara hàn nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà, onírúurú ọ̀nà ló gbà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ó pè é ní “Baba yín,” “Baba wa” àti “Baba mi.” (Mátíù 5:16; 6:9; 7:21) Bí Jésù ṣe ń lo orúkọ yìí fàlàlà jẹ́ ká mọ̀ pé ó ṣeé ṣe fún ẹ̀dá èèyàn ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ tó máa wà pẹ́ títí pẹ̀lú Jèhófà.

Aláàánú ni, ó sì múra tán láti dárí jini Jésù mọ̀ pé ẹ̀dá èèyàn aláìpé nílò àánú Jèhófà lọ́pọ̀ yanturu. Nínú àkàwé ọmọ onínàákúnàá tí Jésù sọ, ó fi Jèhófà wé baba aláàánú tó ń dárí jini, tó ṣe tán láti gba ọmọ kan tó ronú pìwà dà pa dà. (Lúùkù 15:11-32) Ọ̀rọ̀ Jésù yìí mú kó dá wa lójú pé Jèhófà máa ń kíyè sí ìrònúpìwàdà àtọkànwá tí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan bá fi hàn, èyí ló máa jẹ́ kó fi àánú hàn sí i. Jèhófà fẹ́ láti dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ronú pìwà dà. Jésù ṣàlàyé pé: “Mo sọ fún yín pé báyìí ni ìdùnnú púpọ̀ yóò ṣe wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà ju lórí mọ́kàndínlọ́gọ́rùn-ún àwọn olódodo tí wọn kò nílò ìrònúpìwàdà.” (Lúùkù 15:7) Ta ni kò ní fẹ́ láti sún mọ́ irú Ọlọ́run aláàánú yìí?

Olùgbọ́ àdúrà Láti ìgbà tí Jésù ti wà ní ọ̀run kó tó wà sáyé ló ti mọ̀ pé Jèhófà jẹ́ “Olùgbọ́ Àdúrà,” ó sì nífẹ̀ẹ́ sí àdúrà àwọn olóòótọ́ tó ń jọ́sìn rẹ̀. (Sáàmù 65:2) Torí náà, nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, ó kọ́ àwọn olùgbọ́ rẹ̀ bí wọ́n ṣe lè gbàdúrà àti ohun tí wọ́n lè gbàdúrà nípa rẹ̀. Ó fún wọ́n nímọ̀ràn pé tí wọ́n bá ń gbàdúrà kí wọ́n, “má ṣe sọ ohun kan náà ní àsọtúnsọ.” Ó sọ fún wọn pé, kí wọ́n máa gbàdúrà pé “kí ìfẹ́ [Ọlọ́run] ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” A tún lè gbàdúrà fún oúnjẹ òòjọ́, ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa àti pé kí Ọlọ́run gbà wá lọ́wọ́ ìdẹwò. (Mátíù 6:5-13) Jésù kọ́ni pé bí baba ṣe máa ń fetí sí ọmọ rẹ̀ ni Jèhófà ṣe máa ń fetí sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó máa ń dáhùn àdúrà tí wọ́n fi ìgbàgbọ́ gbà látọkàn wá.—Mátíù 7:7-11.

Ó dájú pé Jésù fẹ́ láti kọ́ni ní òtítọ́ nípa Jèhófà àti irú Ọlọ́run tó jẹ́. Àmọ́ ohun míì wà tí Jésù fẹ́ kọ́ni nípa Jèhófà, ìyẹn ohun tí Jèhófà fẹ́ lò láti fi ṣàtúnṣe ayé kó bàa lè mú ohun tó fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé yìí àti aráyé ṣẹ. Kódà, apá yìí gan-an ni kókó ẹ̀kọ́ ìwàásù Jésù dá lé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méje [7,000] ìgbà ni orúkọ náà, Jèhófà, fara hàn nínú ọ̀rọ̀ Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. Ìtumọ̀ orúkọ náà ni, “Èmi yóò jẹ́ ohun tí èmi yóò jẹ̀.” (Ẹ́kísódù 3:14) Ọlọ́run lè di ohunkóhun tó bá fẹ́ kó bàa lè mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Orúkọ yìí mú un dáni lójú pé Ọlọ́run kò lè purọ́ àti pé gbogbo ohun tó bá ṣèlérí ló máa ṣẹ.