Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Irọ́ Ni Àbí Òótọ́?—Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Jésù

Ṣé Irọ́ Ni Àbí Òótọ́?—Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Jésù

Ṣé Irọ́ Ni Àbí Òótọ́?—Ohun Tó Jẹ́ Òótọ́ Nípa Jésù

KÍ NI ÈRÒ RẸ? ṢÉ ÒÓTỌ́ NI ÀWỌN Ọ̀RỌ̀ TÓ WÀ NÍSÀLẸ̀ YÌÍ ÀBÍ IRỌ́?

Wọ́n bí Jésù ní December 25.

Amòye mẹ́ta ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Jésù nígbà ìbí rẹ̀.

Jésù nìkan ṣoṣo ni òbí rẹ̀ bí.

Jésù jẹ́ Ọlọ́run tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀.

Jésù kì í kàn ṣe èèyàn rere.

Ọ̀PỌ̀ èèyàn ló máa sọ pé òótọ́ ni gbogbo ọ̀rọ̀ yẹn. Àwọn míì lè sọ pé ó ṣòro láti mọ̀, àní kò tiẹ̀ ṣeé ṣe láti mọ̀ bóyá irọ́ ni tàbí òótọ́. Èrò wọn ni pé tí èèyàn bá ti gba Jésù gbọ́, kò nílò ìdáhùn kankan mọ́.

Àmọ́, ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀ràn yìí yàtọ̀. Ó gbà wá níyànjú pé ká ní “ìmọ̀ pípéye nípa Olúwa wa Jésù Kristi.” (2 Pétérù 1:8) A máa ní ìmọ̀ yìí tá a bá ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì. Wọ́n sọ òtítọ́ nípa Jésù, èyí tó jẹ́ ká mọ ìyàtọ̀ láàárín òtítọ́ àti irọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ nípa èrò táwọn èèyàn ní nípa Jésù bó ṣe wà ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí.

ÌGBÀGBỌ́: Wọ́n bí Jésù ní December 25.

ÌDÁHÙN: IRỌ́.

Kò sí gbólóhùn kan pàtó nínú Bíbélì tó sọ nípa oṣù tàbí ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù. Ibo wá ni déètì December 25 ti wá? Gẹ́gẹ́ bí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica ti wí, àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni “fẹ́ kí déètì náà ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú àjọyọ̀ ìbọ̀rìṣà àwọn ará Róòmù tí wọ́n fi ń ṣayẹyẹ . . . ìgbà òtútù lọ́jọ́ tí ilẹ̀ tètè máa ń ṣú, lẹ́yìn ọjọ́ yìí, ilẹ̀ ò ní tètè máa ṣú mọ́, oòrùn á sì máa mú ganrínganrín.” Ìwé ìwádìí yìí tún sọ pé, ọ̀pọ̀ àṣà Kérésìmesì ló wá látinú “àjọyọ̀ ìbọ̀rìṣà fún ohun ọ̀gbìn àti oòrùn ní àárín ìgbà òtútù.”

Ṣé Jésù á fọwọ́ sí i pé kí àwọn èèyàn máa ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí òun ní December 25? Rò ó wò ná, kò sẹ́ni tó mọ ọjọ́ tí wọ́n bí Jésù. Kò sí ibì kankan tí Ìwé Mímọ́ tí sọ pé ká máa ṣayẹyẹ ọjọ́ ìbí Jésù, bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé àwọn Kristẹni ìjímìjí ṣe ọjọ́ ìbí Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ ọjọ́ tí Jésù kú, òun fúnra rẹ̀ sì pàṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láti máa ṣèrántí ọjọ́ náà. a (Lúùkù 22:19) Ó ṣe kedere pé Jésù kò pe àfiyèsí sí ọjọ́ ìbí rẹ̀, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló tẹnu mọ́ bí ikú ìrúbọ tóun kú ti ṣeyebíye tó.—Mátíù 20:28.

ÌGBÀGBỌ́: Amòye mẹ́ta (tàbí àwọn ọba bí àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu kan ṣe sọ) ṣèbẹ̀wò sọ́dọ̀ Jésù nígbà ìbí rẹ̀.

ÌDÁHÙN: IRỌ́.

Ó ṣeé ṣe kó o ti rí àwọn àwòrán tó ń fi Jésù hàn nígbà tó wà lọ́mọdé jòjòló tí wọ́n tẹ́ ẹ sí ibùjẹ ẹran tí àwọn amòye mẹ́ta mú ẹ̀bùn wá fún un. Wọ́n kàn ya àwọn àwòrán yẹn ni, kì í ṣe òótọ́.

Òótọ́ ni pé àwọn aṣojú wá láti Ìlà Oòrùn ayé láti wá wárí fún Jésù nígbà tó wà lọ́mọdé. Àmọ́ ṣá o, awòràwọ̀ làwọn àlejò yìí. (Mátíù 2:1, The New English Bible; The Bible—An American Translation) Ǹjẹ́ wọ́n rí Jésù níbi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí ní ibùjẹ ẹran? Rárá o, inú ilé ni wọ́n ti wá kí i. Ó ṣe kedere nígbà náà pé oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti bí Jésù ni wọ́n débẹ̀.—Mátíù 2:9-11.

Mélòó ni àwọn àlejò náà, ṣé méjì, mẹ́ta, tàbí ọgbọ̀n ni wọ́n? Bíbélì kò sọ. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí oríṣi ẹ̀bùn mẹ́tà tí wọ́n fún Jésù làwọn èèyàn ṣe máa ń sọ pé mẹ́tà làwọn àlejò náà. b (Mátíù 2:11) Kódà àwọn kan tiẹ̀ sọ pé ńṣe ni ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn tí wọ́n pè ni amòye yìí ń ṣojú fún ẹ̀yà ìran kọ̀ọ̀kan. Àmọ́, a kò rí irú èrò bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹnì kan tó jẹ́ alálàyé lórí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ pé “òpìtàn ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ kan ló hùmọ̀” àròsọ yìí.

ÌGBÀGBỌ́: Jésù nìkan ṣoṣo ni òbí rẹ̀ bí.

ÌDÁHÙN: IRỌ́.

Àwọn ìwé Ìhìn Rere fi hàn kedere pé Jésù ní àwọn àbúrò. Ìwé Ìhìn Rere Lúùkù pe Jésù ní “àkọ́bí” Màríà, tó fi hàn pé ó bí àwọn ọmọ míì lẹ́yìn náà. c (Lúùkù 2:7) Ìwé Ìhìn Rere Máàkù ròyìn pé àwọn kan ní ìlú Násárétì dárúkọ Jésù pẹ̀lú ti àwọn àbúrò rẹ̀ láti fi hàn pé kò ṣe pàtàkì ju àwọn àbúrò rẹ̀ lọ. Wọ́n sọ pé ṣebí, “Arákùnrin Jákọ́bù àti Jósẹ́fù àti Júdásì àti Símónì [ni], àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Àwọn arábìnrin rẹ̀ sì wà pẹ̀lú wa níhìn-ín, àbí wọn kò sí?”—Máàkù 6:3; Mátíù 12:46; Jòhánù 7:5.

Láìka ohun tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ sí, ọ̀pọ̀ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ṣì ń sọ pé Jésù ni ọmọ kan ṣoṣo tí Màríà bí. Àwọn kan sọ pé àwọn ọmọ ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò òbí Jésù ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin Jésù tí wọ́n sọ níbi yìí. d Àwọn míì sọ pé àwọn ọmọ tí Màríà bí fún ọkọ tó fẹ́ tẹ́lẹ̀ ni àwọn arákùnrin àti arábìnrin Jésù. Àmọ́ rò ó wò ná, tó bá jẹ́ pé Jésù ni ọmọ kan ṣoṣo tí Màríà bí, ṣé àwọn ará Násárétì á sọ ohun tí wọ́n sọ yẹn? Rárá o, ó ṣeé ṣe kí àwọn kan lára wọn ti fojú ara wọn rí Màríà nígbà tó lóyún àwọn ọmọ rẹ̀ yòókù. Wọ́n mọ̀ dáadáa pé Jésù jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọ tí Màríà bí.

ÌGBÀGBỌ́: Jésù jẹ́ Ọlọ́run tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀.

ÌDÁHÙN: IRỌ́.

Èrò náà pé Ọlọ́run gbé ara èèyàn wọ̀ tó sì wá ń gbé ayé gẹ́gẹ́ bíi Jésù jẹ́ apá pàtàkì nínú ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ó sì ti wà tipẹ́tipẹ́, àmọ́ èrò yẹn kò sí ní ọjọ́ Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The Encyclopædia Britannica sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà, Mẹ́talọ́kan tàbí àlàyé rẹ̀ kò sí nínú Májẹ̀mú Tuntun . . . Ńṣe ni ẹ̀kọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ díẹ̀díẹ̀ láti ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún wá pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn.”

Ìsìn rẹ Jésù nípò wálẹ̀ bó ṣe ń kọ́ni pé Jésù jẹ́ Ọlọ́run tó gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀. e Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀? Gbé àpèjúwe yìí yẹ̀ wò. Àwọn òṣìṣẹ́ kan béèrè ohun kan lọ́wọ́ ọ̀gá wọn àmọ́ ọ̀gá náà sọ pé òun kò ní àṣẹ láti fún wọn. Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni ọ̀gá yìí sọ, á jẹ́ pé ó gbọ́n, ó sì fi hàn pé ó mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Tó bá jẹ́ pé ó fún wọn, àmọ́ tí ò kàn fẹ́ fún wọ́n ni, á jẹ́ pé ẹlẹ́tàn ni.

Wàyí o, kí ni Jésù ṣe nígbà tí méjì lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ ń wá ipò ńlá? Ó sọ fún wọn pé: “Jíjókòó yìí ní ọwọ́ ọ̀tún mi àti ní òsì mi kì í ṣe tèmi láti fi fúnni, ṣùgbọ́n ó jẹ́ ti àwọn tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ fún láti ọwọ́ Baba mi.” (Mátíù 20:23) Bí Jésù bá jẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́, ṣe kì í ṣe irọ́ ló ń pa yẹn? Bí Jésù ṣe tọ́ka wọn sí Ẹni tó ní àṣẹ tó ga jù lọ yẹn, ńṣe ló fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ nípa ìmọ̀wọ̀n ara ẹni, ó sì fi hàn pé òun kò bá Ọlọ́run dọ́gba.

ÌGBÀGBỌ́: Jésù kì í kàn ṣe èèyàn rere.

ÌDÁHÙN: ÒÓTỌ́.

Jésù jẹ́ ká mọ̀ ní kedere pé òun kì í kàn ṣe èèyàn rere. O sọ pé: “Ọmọ Ọlọ́run ni mí.” (Jòhánù 10:36) Kò burú, ẹnikẹ́ni ló lè sọ pé Ọmọ Ọlọ́run ni òun. Àmọ́ tó bá jẹ́ pé irọ́ ni Jésù pa, kí nìyẹn máa sọ ọ́ dà? Ká sòótọ́, kò ní sọ ọ́ di ẹni rere, kàkà bẹ́ẹ̀, oníjìbìtì paraku ló máa dà!

Ẹ̀rí tó ṣeé gbára lé jù lọ wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Ìgbà méjì ni Ọlọ́run sọ nípa Jésù pé: “Èyí ni Ọmọ mi.” (Mátíù 3:17; 17:5) Rò ó wò ná, ìgbà díẹ̀ ni Ìwé Mímọ́ sọ pé Ọlọ́run sọ̀rọ̀ láti ọ̀run tí àwọn ará ayé sì gbọ́ ohùn rẹ̀, síbẹ̀ ìgbà méjì lára àwọn ìgbà náà ni Ọlọ́run fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Ọmọ òun ni Jésù! Ẹ̀rí yìí ló tíì lágbára jù lọ pé Jésù jẹ́ ẹni tó sọ pé òun jẹ́.

Ǹjẹ́ àpilẹ̀kọ yìí ti jẹ́ kó o mọ àwọn òtítọ́ kan nípa Jésù èyí tí o kò mọ̀ tẹ́lẹ̀? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, o kò ṣe gbé àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì yẹ̀ wò síwájú sí i. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ lè gbádùn mọ́ni kó sì mú èrè wá. Ó ṣe tán, Jésù fúnra rẹ̀ sọ pé kíkọ́ òtítọ́ nípa òun àti Bàbá òun “túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 17:3.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Jésù kú ní Ọjọ́ Ìrékọjá tàbí Nísàn 14, gẹ́gẹ́ bí kàlẹ́ńdà àwọn Júù ti sọ.—Mátíù 26:2.

b Ìwé Mátíù sọ pé àwọn àjèjì náà “ṣí àwọn ìṣúra wọn,” wọ́n sì fún Jésù ní wúrà, oje igi tùràrí àti òjíá. Kẹ́ ẹ sì wá wò ó, ó ṣeé ṣe kí àwọn ẹ̀bùn olówó iyebíye yẹn bọ́ sákòókò gan-an, nítorí pé ó máa tó di dandan fún ìdílé Jésù tí kò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ láti sá kúrò nílùú.—Mátíù 2:11-15.

c Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ipasẹ̀ iṣẹ́ ìyanu ni Màríà fi lóyún Jésù, ipasẹ̀ Jósẹ́fù ni Màríà fi lóyún àwọn ọmọ yòókù.—Mátíù 1:25.

d Èròǹgbà tí Jerome gbé kalẹ̀ ní nǹkan bí ọdún 383 Sànmánì Kristẹni yìí, wọ́pọ̀ láàárín àwọn tí wọ́n gbà gbọ́ pé Màríà jẹ́ wúńdíá títí ọjọ́ ayé rẹ̀. Nígbà tó yá, Jerome sọ pé èròǹgbà òun yìí lè má tọ̀nà, àmọ́ lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn àti lọ́kàn àwọn aláṣẹ Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì, èrò náà ṣì tọ̀nà.

e Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan, ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àwọn Òtítọ́ Míì Tó Lè Yà Ẹ́ Lẹ́nu

Kí ni ìwà Jésù nígbà tó ń gbé ayé gẹ́gẹ́ bí èèyàn? Ṣé ó máa ń ṣẹ́ ara rẹ̀ níṣẹ̀ẹ́, ṣé kò lọ́yàyà, ṣé ẹni tó máa ń dá tiẹ̀ ṣe ni, tí kì í sì í bá àwọn èèyàn da nǹkan pọ̀? Àwọn kan lè dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni. Abájọ tí ẹnu fi yà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé Jésù  . . .

• lọ sí àwọn ibi ayẹyẹ.—Jòhánù 2:1-11.

• gbórí yìn fún àwọn èèyàn.—Máàkù 14:6-9.

• wá àyè láti gbọ́ ti àwọn ọmọdé.—Máàkù 10:13, 14.

• da omi lójú ní gbangba.—Jòhánù 11:35.

• ṣàánú àwọn èèyàn.—Máàkù 1:40, 41.