Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Lè Tẹ̀ Lé Kristi

Bí A Ṣe Lè Tẹ̀ Lé Kristi

Ohun Tá A Rí Kọ́ Lọ́dọ̀ Jésù

Bí A Ṣe Lè Tẹ̀ Lé Kristi

Nígbà tí ẹnì kan bá gba Jésù gbọ́, ohun tí Jésù sábà máa ń sọ fún irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ni pé: “Di ọmọlẹ́yìn mi.” (Mátíù 9:9; 19:21) Kí lẹnì kan tó jẹ́ ọmọlẹ́yìn Jésù ní láti máa ṣe, ìyẹn ẹni tó jẹ́ Kristẹni? Ṣàgbéyẹ̀wò ìdáhùn ìbéèrè pàtàkì mẹ́ta yìí.

Báwo ló ṣe yẹ kó o máa ṣe sí àwọn èèyàn?

▪ Ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní láti máa tẹ̀ lé ìtọ́ni lórí bó ṣe yẹ kéèyàn máa ṣe sí àwọn ẹlòmíì. Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.” Tí ẹnì kan bá ṣẹ̀ ọ́ ńkọ́? Jésù sọ pé: “Bẹ̀rẹ̀ sí yanjú àwọn ọ̀ràn ní kíákíá pẹ̀lú ẹni tí ń fi ọ́ sùn.” Ó tún sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ kò bá dárí àṣemáṣe àwọn ènìyàn jì wọ́n, Baba yín kì yóò dárí àwọn àṣemáṣe yín jì yín.”—Mátíù 5:25; 6:15; 7:12.

Jésù gba àwọn tó ti gbéyàwó nímọ̀ràn yìí pé, “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà.’ Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé olúkúlùkù ẹni tí ń bá a nìṣó ní wíwo obìnrin kan láti ní ìfẹ́ onígbòónára sí i, ti ṣe panṣágà pẹ̀lú rẹ̀ ná nínú ọkàn-àyà rẹ̀.” Kristẹni tòótọ́ máa ń jẹ́ kí ẹ̀kọ́ Jésù nípa lórí èrò inú òun àti ọkàn òun.—Mátíù 5:27, 28.

Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń yááfì àwọn nǹkan tó máa mú ìrọ̀rùn wá fún wọn torí kí wọ́n lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. Jésù máa ń lo ara rẹ̀ fún àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rìnrìn àjò tó ń tánni lókun torí àtilọ wàásù, wọn kò ráyè jẹun. Nítorí náà, Jésù wọ ọkọ̀ ojú omi pẹ̀lú wọn lọ sí ibi àdádó láti sinmi. Ṣùgbọ́n nígbà táwọn èèyàn gbọ́ nípa ibi tó ń lọ, wọ́n sáré débẹ̀ ṣíwájú rẹ̀. Bíbélì sọ pé: “Ní jíjáde, ó rí ogunlọ́gọ̀ ńlá, ṣùgbọ́n àánú wọ́n ṣe é, nítorí wọ́n dà bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ wọn ní ohun púpọ̀.” (Máàkù 6:30-34) Ìwọ náà lè fara wé Jésù nípa ṣíṣe ohun tí Ọlọ́run ní kó o ṣe, àní bó o tiẹ̀ bá ìṣòro pàdé.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o sọ ìhìn rere fún àwọn èèyàn?

▪ Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ láti máa sọ ìhìn rere fún àwọn èèyàn. Ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mátíù 10:7) Iṣẹ́ táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ń jẹ́ ṣe pàtàkì gan-an ni. Jésù gbàdúrà pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú.”—Jòhánù 17:3.

Jésù sọ tẹ́lẹ̀ pé iṣẹ́ kan máa wà tí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ọmọlẹ́yìn òun máa ṣe. Ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.” (Mátíù 24:14) Bó o bá ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run tó o sì nígbàgbọ́ nínú ohun tí Bíbélì sọ, ó dájú pé tayọ̀tayọ̀ ni wàá máa fi sọ ohun tó o mọ̀ fún àwọn ẹlòmíì. Ọ̀pọ̀ lára ọmọlẹ́yìn Jésù ló jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run, àwọn ẹbí wọn ni wọ́n kọ́kọ́ wàásù fún.—Jòhánù 1:40, 41.

Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣèrìbọmi?

▪ Nígbà tí Jésù ṣèrìbọmi nínú odò Jọ́dánì, ó sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: ‘Mo dé láti ṣe ìfẹ́ rẹ, Ọlọ́run.’ (Hébérù 10:7) Tó o bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, ìwọ náà ní láti ṣèrìbọmi. Jésù pa á láṣẹ pé, “Kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn.”—Mátíù 28:19.

Àwọn iṣẹ́ àti àǹfààní wo ló wà fún ẹni tó bá ṣèrìbọmi? Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù tó bá ti ṣèrìbọmi máa ń fi gbogbo ọkàn sin Ọlọ́run. Jésù fa ọ̀rọ̀ yọ nínú Òfin Ọlọ́run pé: “Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ.” (Mátíù 22:37) Ó tún sọ pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ níní ara rẹ̀.” (Mátíù 16:24) Ìrìbọmi ṣàpẹẹrẹ ìpinnu téèyàn ṣe láti sẹ́ ara rẹ̀, tí ẹni náà sì wá di ti Ọlọ́run. Àwọn tí wọ́n ní àjọṣe pàtàkì yìí pẹ̀lú Ọlọ́run láǹfààní láti béèrè pé kó dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn kí àwọn bàa lè ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.—1 Pétérù 3:21.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 18 nínú ìwé yìí, Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.