Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà, Orúkọ Ọlọ́run, Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Íjíbítì Kan

Jèhófà, Orúkọ Ọlọ́run, Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Íjíbítì Kan

Jèhófà, Orúkọ Ọlọ́run, Wà Nínú Tẹ́ńpìlì Íjíbítì Kan

YÀTỌ̀ sí ti inú Bíbélì, báwo ni orúkọ náà Jèhófà tàbí Yáwè tó jẹ́ orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n rí níbòmíì ti pẹ́ tó? Àwọn ọ̀mọ̀wé kan fi ìdánilójú sọ pé, láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrìnlá ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni. Kí nìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀?

Nígbà tó fi máa di nǹkan bí ọdún 1370 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Íjíbítì ti ṣẹ́gun ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Alákòóso Íjíbítì ìgbà yẹn, Fáráò Amenhotep (Amenophis) Kẹta, kọ́ tẹ́ńpìlì àgbàyanu kan sí ìlú Soleb, nílẹ̀ Nubia, tá a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Sudan lónìí. Nígbà táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí tẹ́ńpìlì yẹn, wọ́n rí àwòrán tí àwọn ará Íjíbítì máa fi ń kọ ohun tó wà lọ́kàn wọn, lára àwòrán yìí, wọ́n rí lẹ́tà Hébérù mẹ́rin, (ìyẹn YHWH) tàbí Jèhófà. Ohun tí wọ́n rí náà ti pẹ́ gan-an, ó fi ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ọdún ju Òkúta Móábù olókìkí lọ, ìyẹn òkúta tó tíì pẹ́ jù lọ tí orúkọ Ọlọ́run wà lára rẹ̀. Kí nìdí tí wọ́n fi lè gbẹ́ orúkọ Ọlọ́run tó ni Bíbélì sára tẹ́ńpìlì Íjíbítì kan?

“Ṣásù ti Ilẹ̀ Jáhù”

Fáráò Amenhotep Kẹta ya tẹ́ńpìlì tó kọ́ sí mímọ́ fún ọlọ́run Amun-Ra. Tẹ́ńpìlì náà fi ọgọ́fà [120] mítà gùn, ó sì wà ní ìwọ̀ oòrùn etí Odò Náílì. Àwọn àwòrán tí wọ́n yà sí ìsàlẹ̀ ara àwọn òpó inú ọ̀kan lára àwọn gbọ̀ngàn tẹ́ńpìlì náà ní orúkọ àwọn àgbègbè tí Amenhotep sọ pé òun ṣẹ́gun. Nínú àwòrán náà, ẹlẹ́wọ̀n kọ̀ọ̀kan dúró fún agbègbè tó ti wá, wọ́n dì í lọ́wọ́ sẹ́yìn, apata kan tí wọ́n sì kọ orúkọ orílẹ̀-èdè tàbí orúkọ àwọn èèyàn ẹlẹ́wọ̀n náà sí wà lára rẹ̀. Àwọn ilẹ̀ àwọn èèyàn tí wọ́n ń pè ní Ṣásù tàbí Ṣósù wà lára àwọn tó wà nínú àwòrán náà. Àwọn wo ni Ṣásù?

Ṣásù jẹ́ orúkọ ẹ̀gàn tí àwọn ará Íjíbítì fi ń pe àwọn Bedouin, ìyẹn gbogbo ẹ̀yà èdè tí wọ́n ń gbé ní ìkọjá bodè Íjíbítì níhà ìlà oòrùn. Ilẹ̀ àwọn Ṣásù dé ìwọ̀ oòrùn Palẹ́sìnì, gúúsù Transjordan àti Sínáì. Àwọn aṣèwádìí kan sọ pé àwọn ilẹ̀ tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ ti àwọn Ṣásù lọ jìnnà lápá àríwá dé Lẹ́bánónì àti Síríà. Ọ̀kan lára àwọn ilẹ̀ tí orúkọ wọn wà nínú àwòrán tó wà nílùú Soleb ni wọ́n ń pè ní onírúurú orúkọ bíi, “Yáwè ní ilẹ̀ Ṣósù,” “Ṣásù ti ilẹ̀ Jáhù,” tàbí “Ilẹ̀ Ṣásù-yhw.” Onímọ̀ nípa àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé ilẹ̀ Íjíbítì, Jean Leclant, sọ pé orúkọ tó fara hàn lára apata tó wà ní Soleb “bá ‘lẹ́tà Hébérù mẹ́rin’ ìyẹn YHWH tó jẹ́ orúkọ ọlọ́run tó ni Bíbélì mu.”

Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọ̀mọ̀wé gbà pé orúkọ náà, Jáhù, Yáhù tàbí Yáwè nínú àyíká ọ̀rọ̀ yìí tàbí àwọn tó fara jọ ọ́ gbọ́dọ̀ máa tọ́ka sí ibì kan tàbí àgbègbè kan. Ọ̀mọ̀wé Shmuel Ahituv sọ pé àkọlé náà fi hàn pé àgbègbè náà jẹ́ “ibi táwọn olùjọ́sìn Yāhū, Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti ń ṣí kiri.” a Tó bá jẹ́ pé òótọ́ lohun tó sọ yìí, orúkọ ibi tó sọ yìí á jẹ́ ọ̀kan lára ìlú àwọn ará Arébíà àti àwọn Júù ayé àtijọ́, tó ń ṣàlàyé àgbègbè kan àti ọlọ́run tí wọ́n ń jọ́sìn. Àpẹẹrẹ míì ni Assur, tó ṣàpèjúwe ilẹ̀ Asíríà àti ọlọ́run àjúbàfún rẹ̀ tó lọ́lá jù lọ.

Ọ̀mọ̀wé Roland de Vaux tó ń ṣèwádìí nípa Bíbélì tó tún jẹ́ awalẹ̀pìtàn sọ nípa àkọlé tó wà ní tẹ́ńpìlì ní Nubia pé: “Ọ̀pọ̀ àgbègbè tí àwọn baba ńlá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mọ àwọn èèyàn sí dáadáa, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ni a ti rí orúkọ èèyàn tàbí orúkọ ìlú tó jọ orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì tàbí kó tiẹ̀ jẹ́ orúkọ náà gan-an.”

Orúkọ Tí A Ṣì Ń Bọ̀wọ̀ Fún

Ìlú Soleb kọ́ ni ibì kan ṣoṣo nílẹ̀ Nubia tí orúkọ náà, Yáwè ti fara hàn nínú àwòrán tí àwọn ará Íjíbítì yà. Wọ́n tún rí irú àwọn orúkọ tó wà ní ìlú Soleb nínú tẹ́ńpìlì Ramses Kejì ní Amarah Ìwọ̀ Oòrùn àti ní Aksha. Nínú àwọn orúkọ tó wà ní Amarah, àwòrán tó ní àkọlé náà “Yáwè ní ilẹ̀ Ṣósù” jọ ti àwọn ìpínlẹ̀ Ṣósù yòókù, tí wọ́n sọ pé ó jẹ́ ìlú Séírì àti ìlú Lábánì. Bíbélì sọ pé àwọn àgbègbè yẹn jẹ mọ́ gúúsù Palẹ́sìnì, Édómù àti Sínáì. (Jẹ́nẹ́sísì 36:8; Diutarónómì 1:1) Àwọn èèyàn tí wọ́n mọ Jèhófà tí wọ́n sì ń jọ́sìn rẹ̀ sábà máa ń lọ sáwọn àgbègbè yẹn ṣáájú àti lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé nílẹ̀ Íjíbítì.—Jẹ́nẹ́sísì 36:17, 18; Númérì 13:26.

Láìdà bí orúkọ àwọn ọlọ́run yòókù tí wọ́n fara hàn nínú àwọn àkọlé ayé àtijọ́, orúkọ Ọlọ́run tó ni Bíbélì, ìyẹn Jèhófà ni àwọn èèyàn ṣì ń lò káàkiri, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún un. Bí àpẹẹrẹ, ní igba ó lé ọgbọ̀n [230] ilẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọn ju mílíọ̀nù méje ti fi ìgbésí ayé wọn fún ríran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n bàa lè mọ orúkọ náà, kì í ṣe ìyẹn nìkan, wọ́n tún ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti sún mọ́ Ọlọ́run tó ń jẹ́ orúkọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ náà, Jèhófà.—Sáàmù 83:18; Jákọ́bù 4:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ọ̀mọ̀wé kan kò fara mọ́ ọn pé àwòrán táwọn ará Íjíbítì yà náà sọ pé àwọn Ṣásù “jẹ́ ọmọlẹ́yìn ọlọ́run Yáwè.” Wọ́n gbà pé orúkọ ilẹ̀ tí a kò mọ̀ náà kàn ṣe kòńgẹ́ pẹ̀lú orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ni, àmọ́, ó jọ ọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 21]

Kí nìdí tí wọ́n fi lè gbẹ́ orúkọ Ọlọ́run tó ni Bíbélì, ìyẹn Jèhófà sára tẹ́ńpìlì kèfèrí ní Íjíbítì?

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 21]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÍJÍBÍTÌ

Tẹ́ńpìlì tó wà ní Soleb

SUDAN

Odò Náílì

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Bí òpó tẹ́ńpìlì náà ṣe rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Ibi tí àwókù tẹ́ńpìlì ọlọ́run Amun-Ra wà nílùú Soleb, lórílẹ̀-èdè Sudan

[Credit Line]

Ed Scott/Pixtal/age fotostock

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 21]

Àwòrán apá ẹ̀yìn: Asian and Middle Eastern Division/The New York Public Library/Astor, Lenox and Tilden Foundations