Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí O Ṣe Lè Rí Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin

Bí O Ṣe Lè Rí Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Bí O Ṣe Lè Rí Àwọn Ọ̀rẹ́ Tó Jẹ́ Adúróṣinṣin

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Jónátánì, Dáfídì àti Sọ́ọ̀lù

Àkópọ̀: Lẹ́yìn tí Dáfídì pa Gòláyátì, Jónátánì di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn Dáfídì.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA 1 SÁMÚẸ́LÌ 17:57–18:11; 19:1; 20:1-17, 41, 42.

Ṣàpèjúwe bí o ṣe rò pé Sọ́ọ̀lù ṣe rí. (Ojútùú: Ka 1 Sámúẹ́lì 10:20-23.)

․․․․․

Ó ṣeé ṣe kí Dáfídì ṣì wà lọ́dọ̀ọ́ nígbà tó bá Jónátánì pàdé. Báwo lo ṣe rò pé ó rí nígbà yẹn? (Ojútùú: Ka 1 Sámúẹ́lì 16:12, 13.)

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Dáfídì àti Jónátánì nígbà tí wọ́n fẹ́ fi ara wọn sílẹ̀ ní ìparí 1 Sámúẹ́lì orí 20?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Àkọsílẹ̀ náà sọ pé, “ọkàn Jónátánì pàápàá wá fà mọ́ ọkàn Dáfídì,” tàbí gẹ́gẹ́ bí Bíbélì Contemporary English Version ṣe sọ ọ́, ó ní, “Dáfídì àti Jónátánì di ọ̀rẹ́ kòríkòsùn.” (1 Sámúẹ́lì 18:1) Àwọn ànímọ́ wo ni Dáfídì ní tó ti lè fa Jónátánì mọ́ra? (Ojútùú: Ka 1 Sámúẹ́lì 17:45, 46.)

․․․․․

Jónátánì fi nǹkan bí ọgbọ̀n ọdún ju Dáfídì lọ. Kí lo rò pé ó mú kí wọ́n di “ọ̀rẹ́ kòríkòsùn,” láìka ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọjọ́ orí wọn sí?

․․․․․

Irú ìwà wo ni àwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ máa ń hù, gẹ́gẹ́ bí a ti rí i nínú ìtàn alárinrin yìí? (Ojútùú: Ka Òwe 17:17; 18:24.)

․․․․․

Kí nìdí tí ìdúróṣinṣin tí Jónátánì ní sí Dáfídì fi ju èyí tó ní sí bàbá òun fúnra rẹ̀ lọ?

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . . 

Jíjẹ́ ọ̀rẹ́.

․․․․․

Ìdúróṣinṣin.

․․․․․

Bíbá ẹni tó dàgbà juni lọ ṣọ̀rẹ́.

․․․․․

Kí lo lè ṣe tó o fi lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tó dára jù lọ?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

KẸ́KỌ̀Ọ́ SÍ I NÍPA BÍBÉLÌ, LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA www.watchtower.org ÀTI www.pr418.com