Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ nípa “ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun”?

Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ọlọ́run . . . ń ṣamọ̀nà wa . . . nínú ìtọ́wọ̀ọ́rìn aláyọ̀ ìṣẹ́gun ní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú Kristi, tí ó sì ń mú kí a tipasẹ̀ wa gbọ́ òórùn ìmọ̀ nípa rẹ̀ ní ibi gbogbo! Nítorí fún Ọlọ́run, àwa jẹ́ òórùn dídùn Kristi láàárín àwọn tí a ń gbà là àti láàárín àwọn tí ń ṣègbé; fún àwọn ti ìkẹyìn yìí, òórùn tí ń jáde láti inú ikú sí ikú, fún àwọn ti ìṣáájú òórùn tí ń jáde láti inú ìyè sí ìyè.”—2 Kọ́ríńtì 2:14-16.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń tọ́ka sí ayẹyẹ táwọn ará Róòmù máa ń ṣe láti ṣàyẹ́sí ọ̀gágun kan fún àṣeyọrí rẹ̀ lórí àwọn ọ̀tá orílẹ̀-èdè wọn. Lákòókò ayẹyẹ yìí, wọ́n máa ń ṣàfihàn àwọn ohun tí wọ́n kó ti ogun bọ̀ àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n, àwọn akọ màlúù tí wọ́n máa fi rúbọ náà máa ń wà níbẹ̀, bẹ́ẹ̀ sì làwọn èèyàn á máa yin ọ̀gágun náà pẹ̀lú àwọn ọmọ ogun rẹ̀. Lẹ́yìn àfihàn yìí, wọ́n á wá fi àwọn akọ màlúù náà rúbọ, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n pa ọ̀pọ̀ lára àwọn ẹlẹ́wọ̀n náà.

Ìwé The International Standard Bible Encyclopedia sọ pé, àfiwé nípa “òórùn dídùn Kristi” tó ń ṣàpẹẹrẹ ìyè fún àwọn kan àti ikú fún àwọn míì yìí “ṣeé ṣe kó jẹ́ pé láti inú bí àwọn ará Róòmù ṣe máa ń fi ohun olóòórùn rúbọ nígbà ìtọ́wọ̀ọ́rìn ni ọ̀rọ̀ yìí ti wá.” “Òórùn dídùn tó ń ṣàpẹẹrẹ àṣeyọrí aṣẹ́gun náà ń rán àwọn tí wọ́n mú lẹ́rú náà létí ikú tó ṣeé ṣe kó máa dúró dè wọ́n.” a

Kí ni “àwọn ibi gíga” tá a máa ń mẹ́nu kàn nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù?

Nígbà tó kù díẹ̀ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí, Jèhófà sọ fún wọn pé kí wọ́n mú àwọn ibi táwọn ọmọ Kénáánì tó ń gbé níbẹ̀ ti ń jọ́sìn kúrò. Ọlọ́run pàṣẹ pé: “Kí ẹ sì pa gbogbo àwòrán àfòkútaṣe wọn run, gbogbo àwọn ère wọn tí a fi irin dídà ṣe sì ni kí ẹ pa run, gbogbo àwọn ibi gíga ọlọ́wọ̀ wọn sì ni kí ẹ pa rẹ́ ráúráú.” (Númérì 33:52) Ó lè jẹ́ ibi gbalasa lórí àwọn òkè ni wọ́n ti ń ṣe ìjọsìn èké yìí tàbí orí pèpéle tó wà láwọn ibòmíì, irú bí abẹ́ igi tàbí láwọn ìlú. (1 Àwọn Ọba 14:23; 2 Àwọn Ọba 17:29; Ìsíkíẹ́lì 6:3) Ó ṣeé ṣe kí àwọn pẹpẹ, ọwọ̀n ọlọ́wọ̀ tàbí òpó ọlọ́wọ̀, àwòrán, pẹpẹ tùràrí àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa ń lò níbi ìjọsìn wọn wà níbẹ̀.

Ṣáájú kí wọ́n tó kọ́ tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù, ibi tí Jèhófà fọwọ́ sí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń jọ́sìn rẹ̀ ni Ìwé Mímọ́ pè ní àwọn ibi gíga. Sámúẹ́lì tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run rúbọ ní “ibi gíga” kan ní ìlú tí a kò dárúkọ ní ilẹ̀ Súfì. (1 Sámúẹ́lì 9:11-14) Lẹ́yìn tí wọ́n ti kọ́ tẹ́ńpìlì náà tán, ọ̀pọ̀ ọba tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà sapá láti mú “àwọn ibi gíga” kúrò.—2 Àwọn Ọba 21:3; 23:5-8, 15-20; 2 Kíróníkà 17:1, 6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí ìtúmọ̀ tẹ̀mí tí àpèjúwe Pọ́ọ̀lù yìí ní, ka Ilé Ìṣọ́, November 15, 1990, ojú ìwé 27.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àwòrán àtijọ́ nípa ìtọ́wọ̀ọ́rìn ìṣẹ́gun ti àwọn ará Róòmù ní ọ̀gọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni

[Credit Line]

British Museum ló yọ̀ǹda ká ya fọ́tò yìí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Àfọ́kù àwọn òpó ọlọ́wọ̀ tó wà ní Gésérì