Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Gbogbo Èèyàn La Pè!

Gbogbo Èèyàn La Pè!

Gbogbo Èèyàn La Pè!

GBOGBO èèyàn la pè fún kí ni? Láti ṣèbẹ̀wò sí ọ̀kan lára ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tá à ń pè ní Bẹ́tẹ́lì. Ẹ̀ka ọ́fíìsì méjìdínlọ́gọ́fà [118] la ní jákèjádò ayé. Àwọn tó ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì sábà máa ń sọ ọ̀rọ̀ ìmọrírì látọkànwá nítorí ohun tí wọ́n rí níbẹ̀.

Nígbà tí ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ó rí ọ̀pọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ tó ń ṣiṣẹ́ sin Jèhófà tayọ̀tayọ̀, èyí sì wú u lórí gan-an débi tó fi béèrè pé: “Kí ni mo lè ṣe kí wọ́n lè gbà mí síbí?” Wọ́n sọ fún un pé: “O ní láti kọ́kọ́ ṣe ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó dára kó o di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.” Ọ̀dọ́kùnrin náà ṣe ohun tí wọ́n sọ fún un, ọdún méjì lẹ́yìn náà ni wọ́n pè é sí Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, ó sì ti sìn níbẹ̀ fún ogún ọdún báyìí.

Kí Ló Ń Jẹ́ Bẹ́tẹ́lì?

Ohun tí “Bẹ́tẹ́lì” tó wá látinú èdè Hébérù túmọ̀ sí ni “Ilé Ọlọ́run.” (Jẹ́n. 28:19) Àwọn ilé àtàwọn ohun èlò míì tó wà káàkiri àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa là ń lò láti fi tẹ Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì tún fi ń pín wọn kiri, a sì tún ń lò wọ́n láti pèsè ìrànwọ́ nípa tẹ̀mí fún àwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ọ̀kẹ́ márùn-ún [100,000] jákèjádò ayé. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì lọ́kùnrin àti lóbìnrin fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọ̀kẹ́ kan [20,000], àṣà ìbílẹ̀ àti ipò wọn yàtọ̀ síra, wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún Jèhófà àtàwọn ará wọn tọkàntọkàn. Àwọn tó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Kristẹni yìí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ọ̀dọ́ tí eegun wọn ṣì le. Lọ́wọ́ ìrọ̀lẹ́ àti láwọn òpin ọ̀sẹ̀, àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń gbádùn ìfararora ní àwọn ìpàdé àti lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni pẹ̀lú ìjọ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ibi tí Bẹ́tẹ́lì wà. Wọ́n tún máa ń lo àkókò ọwọ́ dilẹ̀ wọn láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, láti ṣeré ìdárayá àti láti bójú tó àwọn nǹkan míì tó jẹ́ tara wọn.

Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé Bẹ́tẹ́lì máa ń gba owó ìtìlẹyìn táṣẹ́rẹ́ lóṣooṣù. Wọ́n máa ń jẹ oúnjẹ aládùn tó ṣara lóore, wọ́n sì ń gbé inú ilé tó mọ́ tónítóní, tó sì mọ níwọ̀n. Kì í ṣe ìdí tí wọ́n fi ń kọ́ àwọn ilé Bẹ́tẹ́lì ni pé kó lè jẹ́ ilé tó rẹwà jù lọ. Àmọ́, wọ́n wúlò fún iṣẹ́ tá à ń ṣe níbẹ̀. Orí àwọn àlejò máa ń wú tí wọ́n bá rí àwọn ilé àti ilẹ̀ tó mọ́ tónítóní àti bí nǹkan ṣe ń lọ létòletò ní Bẹ́tẹ́lì, àmọ́ kì í ṣe ìyẹn nìkan o, wọ́n tún mọrírì bí àwọn òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì ṣe jẹ́ onínúure tí wọ́n sì ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀. Olúkúlùkù ń ṣiṣẹ́ kára, síbẹ̀ iṣẹ́ wọn kò ní kí wọ́n má ṣọ̀yàyà. Ní Bẹ́tẹ́lì, kò sí ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́gbẹ́mẹgbẹ́ tàbí kéèyàn máa wò ó pé òun sàn ju àwọn míì lọ nítorí iṣẹ́ tó ń ṣe. Gbogbo iṣẹ́ tá à ń ṣe ló ṣe pàtàkì, ì báà jẹ́ iṣẹ́ ìmọ́tótó, títún ọgbà ṣe, oúnjẹ gbígbọ́, iṣẹ́ ìtẹ̀wé tàbí iṣẹ́ ọ́fíìsì. Ńṣe ni gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì ń ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan láti ṣètìlẹ́yìn fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà.—Kól. 3:23.

Gbọ́ Ohun Tí Àwọn Òṣìṣẹ́ Bẹ́tẹ́lì Kan Sọ

Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn tó jẹ́ ara ìdílé kan tó kárí ayé yìí. Kí ló mú kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ láti ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì? Jẹ́ ká gbé ọ̀ràn ti Mario yẹ̀ wò. Nígbà tí Mario ṣẹ̀ṣẹ̀ di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ń ṣiṣẹ́ ní ilé iṣẹ́ kan tó lókìkí lórílẹ̀-èdè Jámánì níbi tí wọ́n ti ń ṣe mọ́tò, iṣẹ́ náà sì ń mú owó gidi wọlé fún un, kódà ó láǹfààní láti túbọ̀ ní ìgbéga nílé iṣẹ́ náà. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó ṣe ìrìbọmi, ó yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ kan ní Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè rẹ̀. Wọ́n sì ní kó bá wọn ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń tẹ̀wé. Mario rí i pé ìyàtọ̀ gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ ló wà láàárín àwọn tí òun bá ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì àtàwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ níta. Torí náà, ó kọ̀wé béèrè fún iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí òṣìṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún àwọn mọ̀lẹ́bí àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ láti fara mọ́ ìpinnu tó ṣe yìí, síbẹ̀ Mario ń fayọ̀ ṣiṣẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Jámánì báyìí.

Ọ̀pọ̀ ni kò ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tàbí òye iṣẹ́ kan tó jẹ́ àkànṣe kí wọ́n tó dé Bẹ́tẹ́lì. Bí ọ̀rọ̀ Abel tó ti sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Mẹ́síkò fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún ṣe rí nìyẹn. Ó sọ pé: “Ilé ẹ̀kọ́ gidi ni Bẹ́tẹ́lì jẹ́ fún mi. Mo ti kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ẹ̀rọ ìtẹ̀wé tó díjú gan-an. Mo mọ̀ pé iṣẹ́ tí mo kọ́ yìí á máa mú owó gidi wọlé fún mi tí mo bá fẹ́ fi ṣiṣẹ́ ṣe níta, àmọ́ mi ò ní ní ohun tí mò ń gbádùn níbí yìí, ìyẹn ni ìfọ̀kànbalẹ̀ àti ìgbésí ayé tó dára tí kò ní pákáǹleke àti ẹ̀mí ìbánidíje tó wà nídìí iṣẹ́ ajé. Mo rí i pé mo ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó dára jù lọ, èyí tó ti mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú Ọlọ́run dára sí i, tó sì mú kí orí mi pé. Mi ò lè ní irú àǹfààní tẹ̀mí bẹ́ẹ̀, kódà kó jẹ́ yunifásítì tó dára jù lọ láyé ni mo lọ.”

Wàá Rí Ìṣírí Gbà Tó O Bá Ṣèbẹ̀wò Síbẹ̀

Ṣíṣe ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì lásán lè ní ipa rere lórí àjọṣe téèyàn ní pẹ̀lú Ọlọ́run. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Omar lórílẹ̀-èdè Mẹ́síkò nìyẹn. Ìyá rẹ̀ kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ látinú Bíbélì. Àmọ́ nígbà tí Omar pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, kò lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni àti òde ẹ̀rí mọ́. Ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú, ó sì ń lépa àtidi ọlọ́rọ̀. Lẹ́yìn náà, nígbà tí Omar ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ kan, ó wà lára àwọn aṣojú tó wá sí Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Mẹ́síkò láti wá fi bí wọ́n ṣe ń lo àwọn ohun èlò kan hàn wọ́n. Omar sọ pé: “Lẹ́yìn tá a parí ohun tá a wá ṣe, ẹni tó gbàlejò wa mú wa rìn yíká Bẹ́tẹ́lì. Ohun tí mo rí àti bí wọ́n ṣe fi inú rere hàn sí mi mú kí n ronú lórí irú ìgbésí ayé tí mò ń gbé, mo ti di àjèjì sí Jèhófà. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí ìpàdé, tí mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Oṣù mẹ́fà lẹ́yìn tí mo ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì ni mo ṣèrìbọmi. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún ìṣírí tí mo rí gbà látàrí ìbẹ̀wò tí mo ṣe sí Bẹ́tẹ́lì.”

Inú ìdílé Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ti tọ́ Masahiko dàgbà lórílẹ̀-èdè Japan. Àmọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wo gbígbé ìgbésí ayé Kristẹni gẹ́gẹ́ bí ohun tó ń ká èèyàn lọ́wọ́ kò jù. Ó tara bọ ìgbòkègbodò ilé ẹ̀kọ́ débi pé kò lọ sí ìpàdé mọ́, kò sì lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Masahiko sọ pé: “Lọ́jọ́ kan, ìdílé wa àtàwọn ará mélòó kan pinnu láti lọ ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì. Àwọn tó kù nínú ìdílé ní àfi kí n bá àwọn lọ, mo sì tẹ̀ lé wọn. Rírìn yíká ọgbà Bẹ́tẹ́lì fún mi ní ìṣírí gan-an. Ìtura tí ìfararora pẹ̀lú àwọn Kristẹni yòókù fún mi nígbà ìrìn àjò náà jẹ́ ohun tí mi ò kì ń rí lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í wù mí láti máa gbé ìgbésí ayé Kristẹni, torí náà mo ní kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ní báyìí Masahiko ti di òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ní ìjọ rẹ̀.

Ẹlẹ́rìí kan láti orílẹ̀-èdè Faransé lọ sí ìlú Moscow lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà láti lọ ṣiṣẹ́. Nígbà tó débẹ̀ kò rí àwọn ará, ó sì dẹni tó rẹ̀wẹ̀sì nípa tẹ̀mí. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú ìwàkiwà, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn ó fẹ́ ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Lọ́jọ́ kan arábìnrin kan láti orílẹ̀-èdè Faransé wá kí i, wọ́n sì jọ rìnrìn àjò lọ sí ìlú St. Petersburg, lórílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà láti lọ ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì tó wà níbẹ̀. Ó kọ̀wé pé: “Nígbà tá a dé Bẹ́tẹ́lì, wọ́n gbà wá tọwọ́ tẹsẹ̀, èyí sì wú mi lórí gan-an. Àlàáfíà wà níbẹ̀. Mo nímọ̀lára pé mo wà lábẹ́ ìdarí ẹ̀mí Jèhófà. Kí ló mú kí n fi ètò Jèhófà sílẹ̀? Lẹ́yìn ìbẹ̀wò tí mo ṣe sí Bẹ́tẹ́lì, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, pẹ̀lú ìpinnu mi tó ti di ọ̀tun.” Láfikún sí ìrànlọ́wọ́ míì tí Ẹlẹ́rìí tó ti fìgbà kan rí jẹ́ aláìlera yìí rí gbà nípa tẹ̀mí, ohun míì tó tún sọ ọ́ di alágbára nípa tẹ̀mí ni ìbẹ̀wò tó ṣe sí Bẹ́tẹ́lì, lẹ́yìn náà ó tẹ̀ síwájú dáadáa.

Ipa wo ni ṣíṣe ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì lè ní lórí àwọn tí wọn kò mọ̀ nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà? Lọ́dún 1988, Alberto tó jẹ́ ògbóǹkangí olóṣèlú ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè Brazil. Bí ibẹ̀ ṣe mọ́ tónítóní, tó wà létòlétò àti ní pàtàkì jù lọ, bí wọn kò ṣe ṣe iṣẹ́ wọn ní àṣírí wú u lórí gan-an. Kò pẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí Alberto ṣèbẹ̀wò sí ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà níbi tí àbúrò ìyàwó rẹ̀ ti jẹ́ àlùfáà ló ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì. Ohun tí Alberto rí ní Bẹ́tẹ́lì yàtọ̀, ó sọ pé: “Gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe ní ilé ẹ̀kọ́ṣẹ́ àlùfáà náà ni wọ́n ń ṣe ní àṣírí.” Kò pẹ́ lẹ́yìn ìbẹ̀wò rẹ̀ sí Bẹ́tẹ́lì tó fi tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó pa ìṣèlú tì, ó sì ti ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà báyìí.

Wá Ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì!

Ọ̀pọ̀ ló ti sapá lákànṣe kí wọ́n lè lọ ṣe ìbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. Bí àpẹẹrẹ lórílẹ̀-èdè Brazil, ọdún mẹ́rin gbáko ni Paulo àti Eugenia fi tọ́jú owó ọkọ̀ kí wọ́n lè rìnrìn àjò ọjọ́ méjì tó jẹ́ ìrìn ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] kìlómítà láti lọ ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. Wọ́n sọ pé: “Ìsapá náà tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. A ti wá túbọ̀ lóye ètò Jèhófà dáadáa. Tá a bá ṣàlàyé iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní Bẹ́tẹ́lì fún àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà míì wọ́n máa ń bi wá pé, ‘Ṣé ẹ ti dé ibẹ̀ rí?’ Ní báyìí, a lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni.”

Ǹjẹ́ ẹ̀ka ọ́fíìsì tàbí ilé Bẹ́tẹ́lì wà lórílẹ̀-èdè rẹ tàbí ní ilẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí ẹ? A ké sí ẹ pé kó o ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Ó dájú pé wọ́n á fi ọ̀yàyà kí ẹ káàbọ̀, wàá sì jàǹfààní nípa tẹ̀mí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ tó o bá ṣèbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Mario

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Abel

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Jámánì

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Japan

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

Brazil