Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ǹjẹ́ O Rántí?

Ṣó o gbádùn kíka àwọn Ilé Ìṣọ́ tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí? Wò ó bóyá wàá lè dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí:

• Kí ló máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ di ọmọ tó dáńgájíá?

“Fi àwòṣe lélẹ̀” fún ọmọ rẹ nípa béèyàn ṣe ń di ẹni tó dáńgájíá. (Jòh. 13:15) Má ṣe retí ohun tó pọ̀ jù; bó bá ṣe ń dàgbà, o lè bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ láti ṣe púpọ̀ sí i ní bíbójú tó ìmọ́tótó ara rẹ̀, láti tọ́jú yàrá rẹ̀, láti máa tètè dé síbi tí wọ́n bá pè é sí àti láti máa fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ilé ẹ̀kọ́. Máa fún un ní ìtọ́ni tó ṣe pàtó kó lè mọ bí á ṣe máa ṣe ojúṣe rẹ̀.—5/1, ojú ìwé 19 sí 20.

• Kí nìdí tí Ọlọ́run kò fi fìyà jẹ Áárónì nítorí pé ó ṣe ère ọmọ màlúù?

Áárónì rú òfin Ọlọ́run tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kís. 20:3-5) Síbẹ̀, Mósè rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Ọlọ́run ní tìtorí Áárónì, ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ rẹ̀ sì “ní ipa púpọ̀.” (Ják. 5:16) Áárónì jẹ́ olóòótọ́ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn náà ló sún Áárónì tó fi ṣe èrè ọmọ màlúù, ó hàn nígbà tó yá pé kò ti ọkàn rẹ̀ wá, ìyẹn ló fi dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ Léfì láti dúró sì ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà. (Ẹ́kís. 32:25-29)—5/15, ojú ìwé 21.

• Ibo ni Ófírì tí Bíbélì sọ pé wọ́n ti ń rí ojúlówó wúrà wà?

Sólómọ́nì ṣe àwọn ọkọ̀ òkun ní Esioni-gébérì, tó jẹ́ ibùdó ọkọ̀ òkun, láti máa fi kó wúrà wọ̀lú láti Ófírì. (1 Ọba 9:26-28) Ibùdó ọkọ̀ òkun náà wà ní ibi tí omi ti ya wọ ilẹ̀ ní Aqaba, ní ìtòsí Élátì àti Aqaba òde òní, létí Òkun Pupa. Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Arébíà, nítòsí Òkun Pupa, ni Ófírì wà tàbí kó wà ní etíkun ilẹ̀ Áfíríkà tàbí ilẹ̀ Íńdíà.—6/1, ojú ìwé 15.

• Kí ni ‘básámù ní Gílíádì’ túmọ̀ sí? (Jer. 8:22)

Básámù jẹ́ oje tí wọ́n ń rí látara onírúurú igi, ó rí bí òróró, ó sì ní òórùn dídùn. Igi yìí wà káàkiri, wọ́n sì tún máa ń rí i ní Gílíádì, ní ìlà oòrùn Odò Jọ́dánì. Èròjà tó wà nínú rẹ̀ wúlò fún ìṣègùn, torí náà wọ́n máa ń fi sójú ọgbẹ́. Ó yẹ kí ipò ẹni téèyàn ń káàánú fún tí Ísírẹ́lì wà ti sún orílẹ̀-èdè náà láti wá ìwòsàn, àmọ́ wọ́n kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Jer. 8:9)—6/1, ojú ìwé 21 sí 22.

• Kí ló lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti fara dà á bí ọkọ tàbí aya rẹ̀ bá ṣe panṣágà?

Tí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìmọwọ́mẹsẹ̀ náà bá ti ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ní ìgbésí ayé rẹ̀, kò sí ìdí fún un láti máa dá ara rẹ̀ lẹ́bi nítorí ìwà ọ̀dàlẹ̀ tí onípanṣágà náà hù. Ọlọ́run mọ̀ pé o nílò ìtùnú àti ìṣírí. Ó lè lo àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni láti pèsè irú ìtùnú bẹ́ẹ̀.—6/15, ojú ìwé 30 sí 31.

• Báwo lo ṣe lè ran ẹni kan tó ń ṣàìsàn lọ́wọ́?

Máa fetí sílẹ̀ dáadáa. (Oníw. 3:1, 7) Máa gba tiẹ̀ rò. (Róòmù 12:15) Máa gbé e ró kó o sì máa ràn án lọ́wọ́. (Kól. 4:6; 1 Jòh. 3:18) Má jìnnà sí i. (Òwe 17:17)—7/1, ojú ìwé 10 sí 13.

• Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kò ní ìbẹ̀rẹ̀?

Mósè sọ èyí di mímọ̀ nínú àdúrà. (Sm. 90:2) Ó bá a mu nígbà náà pé Jèhófà nìkan ló ń jẹ́ orúkọ aláìlẹ́gbẹ́ náà, “Ọba ayérayé.” (1 Tím. 1:17)—7/1, ojú ìwé 28.

• Báwo lo ṣe lè mú kí àwọn ọmọ rẹ nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà?

Bí àwọn òbí bá mú kí ẹ̀kọ́ kíkọ́ gbádùn mọ́ni tí wọ́n sì fi àpẹẹrẹ lélẹ̀, á ṣeé ṣe fún wọn láti mú kí àwọn ọmọ nífẹ̀ẹ́ sí ìwé kíkà. Bákan náà, ẹ jẹ́ kí ìwé máa wà fún wọn láti kà. Ẹ máa kàwé sókè ketekete. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa lóhùn sí i, kẹ́ ẹ sì máa jíròrò ohun tẹ́ ẹ bá kà. Ẹ ní káwọn ọmọ yín kàwé fún yín, kẹ́ ẹ sì rọ̀ wọ́n láti máa béèrè ìbéèrè.—7/15, ojú ìwé 26.

• Kí nìdí tí Jésù kò fi tètè lọ mú Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ lara dá kó tó kú?

Nígbà tí Jésù fi máa débẹ̀, Lásárù ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin. Bí Jésù ṣe dúró di ìgbà yẹn kó tó lọ jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti jẹ́rìí púpọ̀ sí i nípa Baba rẹ̀. Nítorí náà, ọ̀pọ̀ èèyàn di onígbàgbọ́. (Jòh. 11:45)—8/1, ojú ìwé 14 sí 15.

• Kí ló ń jẹ́ “àwọn ibi gíga”?

Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí máa ń tọ́ka sí àwọn ibi gbalasa tó wà lórí òkè tàbí àwọn ibòmíì tí wọ́n ti ń ṣe ìsìn èké. Nígbà míì wọ́n máa ń gbé àwọn pẹpẹ, àwọn òpó ọlọ́wọ̀ àtàwọn nǹkan mìíràn táwọn èèyàn ń lò fún ìjọsìn kalẹ̀ láwọn ibi táwọn èèyàn ti ń ṣe ìjọsìn tí Ọlọ́run kórìíra. (Núm. 33:52)—8/1, ojú ìwé 23.