Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Lo Ọjọ́ Kan Létíkun

A Lo Ọjọ́ Kan Létíkun

Lẹ́tà Láti Erékùṣù Grenada

A Lo Ọjọ́ Kan Létíkun

TÍ WỌ́N bá fún ẹ láǹfààní pé kó o lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní orílẹ̀-èdè míì, inú rẹ á dùn gan-an. Ńṣe lá máa ṣe ẹ́ bíi ti ọmọdé kan tó fẹ́ mọ gbogbo nǹkan, wàá máa ronú nípa àwọn èèyàn tó o fẹ́ lọ bá, àyíká ibẹ̀ àtàwọn ìrírí tó o máa ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tó o fẹ́ lọ ṣe.

Nígbà tí wọ́n rán èmi àti ìyàwó mi lọ sí erékùṣù Grenada, ìyẹn ìlú tó ní nǹkan bí etíkun márùndínláàádọ́ta [45] tó fani mọ́ra, ńṣe là ń ronú lórí bí àwọn etíkun náà ṣe máa rí. Àkókò wá tó báyìí láti lọ gbádùn ọjọ́ kan ní ọ̀kan lára àwọn etíkun náà, àmọ́ ohun tó fún wa láyọ̀ kọjá oòrùn àti ìgbì òkun, àwọn èèyàn ni ayọ̀ wa.

Tá a bá gbé ọkọ̀, ilé wa ní Grenada kò fi bẹ́ẹ̀ jìn sí etíkun Grand Anse, àmọ́ ìrìn àjò náà gbádùn mọ́ni gan-an! Nítorí pé ọ̀nà náà rí kọ́lọkọ̀lọ, èyí jẹ́ ká lè rí àwọn nǹkan mèremère tó jojú ní gbèsè. Àwọn òkè kún fún àwọn ewéko tó dúdú mìnìjọ̀. Bá a ṣe ń gba ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ náà lọ, là ń rí àwọn òkè ńláńlá, igbó kìjikìji, àwọn òkè tí omi ti ń ṣàn wálẹ̀, a sì ń wo òkun ní òréré. Abájọ táwọn arìnrìn-àjò afẹ́ láti ibi gbogbo láyé fi máa ń wá sí ibí yìí! Àwọn ohun tó wà ní ibi yìí rẹwà débi pé, tẹ́ni tó ń wakọ̀ kò bá ṣọ́ra wọ́n lè pín ọkàn rẹ̀ níyà. Ọ̀nà kọ́lọkọ̀lọ yìí rí tẹ́ẹ́rẹ́ débi pé, nígbà míì èèyàn á ṣe kàyéfì pé báwo ni ọkọ̀ méjì ṣe máa kọjá tí wọn kò fi ní ta lu ara wọn.

Nígbà tó yá, a dé ibì kan tí wọ́n ń pè ní Convention Trade Center, ó wà lójú ọ̀nà tó lọ sí etíkun Grand Anse. Kò pẹ́ tí àwùjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀ta [600], fi péjọ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí láti gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ àti láti gba ìtọ́ni látinú Bíbélì. Ọjọ́ àrà ọ̀tọ̀ ni ọjọ́ náà jẹ́ fún tọkọtaya kan tó ń jẹ́ Lesley àti Daphne, tí wọ́n ti lé lẹ́ni àádọ́rin ọdún. Lesley fẹ́ ṣe ìrìbọmi. Ó ti pẹ́ tí Daphne ti ń fojú sọ́nà fún ọjọ́ yìí, torí pé òun ní tiẹ̀ ti ṣe ìrìbọmi láti ọdún 1958, ó sì ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Ìrìbọmi ṣe pàtàkì gan-an fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, bí wọ́n sì ṣe máa ń ṣe é ni pé, wọ́n máa ń rini bọ inú omi pátápátá. Lẹ́yìn tí èèyàn bá ti ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì, tó sì ń fi í sílò lèèyàn tó lè ṣe ìrìbọmi. Iwájú àwọn èèyàn ni ẹni náà ti máa ṣe ìrìbọmi, kó lè fi hàn pé òun ti ya àrà òun sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run.

Èmi ni wọ́n ní kí n ṣàlàyé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ìrìbọmi fún àwùjọ àwọn èèyàn tó wà níbẹ̀. Nígbà ti àsọyé náà parí, Lesley àtàwọn méjì míì táwọn náà fẹ́ ṣe ìrìbọmi dìde dúró. Lesley wọ ṣẹ́ẹ̀tì funfun tí wọ́n lọ̀ dáadáa, ó sì de táì, bẹ́ẹ̀ ló sì ń rẹ́rìn-ín músẹ́. Mo béèrè pé: “Ǹjẹ́ o ti ronú pìwà dà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, ṣé o sì ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Jèhófà láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀?” Ẹ fojú inú wo bí Lesley àtàwọn yòókù ṣe dáhùn látọkàn wá, tó sì fi hàn pé wọ́n ti ya ara wọn sí mímọ́ nígbà tí wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni!”

Inú tèmi fúnra mi dùn gan-an, nítorí pé mo mọ ẹni tí Lesley jẹ́ láti ẹ̀yìn wá. Ó ti lé ní ogún ọdún tó ti pa ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tì. Lẹ́yìn náà, òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣèbẹ̀wò sí erékùṣù míì. Nígbà tí wọ́n wà níbẹ̀, wọ́n pinnu pé oníkálukú á máa lọ ṣe ìsìn pẹ̀lú àwọn ẹlẹ́sìn tiẹ̀. Lesley sọ fún Daphne ìyàwó rẹ̀ pé, “Máa lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì tìẹ, èmi náà á lọ sí tèmi.”

Lesley fi ọkọ̀ gbé Daphne wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba, òun náà sì lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì Áńgílíkà tó wà ládùúgbò náà. Nígbà tí wọ́n parí ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì, Lesley pa dà lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba láti gbé ìyàwó rẹ̀. Ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, àwọn èèyàn tó fẹ́ràn ẹni dénú yọ̀ mọ́ ọn, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò rí i rí. Nǹkan yìí mú kí Lesley ronú jinlẹ̀. Ní ṣọ́ọ̀ṣì tó lọ, kò sí ẹnì kankan tó bá a sọ̀rọ̀. Lesley sọ fún Daphne pé, “Mi ò tún pa dà lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì yẹn mọ́. Kò sí ẹnì kankan tó bá mi sọ̀rọ̀, títí kan àlùfáà pàápàá. Ẹnì kankan kò kí mi. Bí mo ṣe lọ náà ni mo ṣe pa dà.” Nígbà tí Lesley jáde, kò pa dà síbẹ̀ mọ́.

Lẹ́yìn náà, Lesley bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gan-an. Ní báyìí, ó ti múra tán láti ṣe ìrìbọmi. Àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi lọ sí etíkun, àwa náà sì ń bọ̀ lẹ́yìn wọn. Nítorí pé òkun kò jìnnà síbi tá a wà, a kò nílò ọpọ́n omi ràgàjì fún àwọn tó fẹ́ ṣe ìrìbọmi, irú àwọn èyí tá a máa ń lò ní ọ̀pọ̀ àpéjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ká kàn sọdá sí ibi tí òkun wà ni.

Omi tó mọ́ lóló létíkun Grand Anse yìí fẹ̀ tó ohun tó fi díẹ̀ lé ní kìlómítà mẹ́ta, iyẹ̀pẹ̀ funfun ló wà nísàlẹ̀ rẹ̀. Nígbà tí a dé etíkun náà, ńṣe làwọn arìnrìn-àjò afẹ́ tó wà níbẹ̀ ń wò wá pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, àwọn ọkùnrin wọ ṣẹ́ẹ̀tì, wọ́n sì de táì, àwọn obìnrin wọ ẹ̀wù àti síkẹ́ẹ̀tì. Lesley ti pààrọ̀ ẹ̀wù rẹ̀ sí aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ alápá péńpé àti ṣòkòtò péńpé. Ẹ wo bí inú Daphne ti dùn tó láti rí i pé ọkọ rẹ̀ ṣe ìrìbọmi, lẹ́yìn nǹkan bí àádọ́ta ọdún tí òun ti ṣe ìrìbọmi! Bí oòrùn ọ̀sán ọjọ́ náà ṣe bu ẹwà kún ojú ọjọ́, bẹ́ẹ̀ ni ìdùnnú ṣe bu ẹ̀rín kún ẹnu Daphne. Àwọn arìnrìn-àjò afẹ́ pàápàá bá wa yọ̀. Ńṣe ni wọ́n ń bá wa pàtẹ́wọ́ bí wọ́n ti ń ṣe ìrìbọmi fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.

Ojú ọjọ́ tó tuni lára, iyẹ̀pẹ̀ funfun àti ìgbì tó rọra ń fẹ́, gbogbo nǹkan wọ̀nyí mú kí etíkun yìí fògo fún Ẹlẹ́dàá. Àmọ́, etíkun yìí fi ògo tó jù bẹ́ẹ̀ lọ hàn, bí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìrìbọmi ṣe ń jáde látinú omi náà. Ayọ̀ ọkàn tá a ní bá a ṣe ń wò wọ́n pọ̀ ju ìtura ojú ọjọ́ tó tuni lára lọ. Ọjọ́ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ lọjọ́ náà. Ọjọ́ tó tíì ṣe pàtàkì jù lọ fún Lesley àti Daphne ni ọjọ́ tá a lò létíkun yìí.