Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

2 Ta Ló Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Sí?

2 Ta Ló Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Sí?

2 Ta Ló Yẹ Ká Máa Gbàdúrà Sí?

ǸJẸ́ ibì kan náà ni gbogbo àdúrà ń lọ láìka ẹni tí wọ́n darí àdúrà náà sí? Nínú ayé lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn ló sábà máa ń rò bẹ́ẹ̀. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí i pé kí oríṣiríṣi ẹ̀sìn máa jọ́sìn pa pọ̀ fara mọ́ èrò yìí, wọ́n gbà pé gbogbo ẹ̀sìn ló ní ìtẹ́wọ́gbà láìka bí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra wọn sí. Àmọ́ ṣé òótọ́ ni?

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé àwọn èèyàn kì í darí àdúrà wọn sí ibi tó tọ́. Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ó jẹ́ àṣà àwọn èèyàn láti máa gbàdúrà sí àwọn ère. Léraléra ni Ọlọ́run dẹ́bi fún àṣà yìí. Bí àpẹẹrẹ, ìwé Sáàmù 115:4-6 sọ nípa àwọn òrìṣà pé: “Wọ́n ní etí, ṣùgbọ́n wọn kò lè gbọ́ran.” Kókó náà ṣe kedere. Kò ní bọ́gbọ́n mu láti gbàdúrà sí ọlọ́run tí kò lè gbọ́ ohun tó ò ń sọ.

Ìtàn kan nínú Bíbélì sọ ohun tó pọ̀ lórí kókó yìí. Èlíjà tó jẹ́ wòlíì tòótọ́ pe àwọn wòlíì Báálì níjà, ó ní kí wọ́n gbàdúrà sí ọlọ́run wọn, òun náà á sì gbàdúrà sí Ọlọ́run tòun. Èlíjà sọ pé Ọlọ́run tòótọ́ á dáhùn àdúrà, àmọ́ ọlọ́run èké kò ní dáhùn. Àwọn wòlíì Báálì gbà láti gbàdúrà, wọ́n fi taratara gbàdúrà fún àkókò gígùn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń lọgun tòò, àmọ́ òfo ló já sí! Ìtàn náà sọ pé: “Kò sì sí ẹnì kankan tí ó dáhùn, kò sì sí fífetísílẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 18:29) Àmọ́, kí ni àbájáde àdúrà Èlíjà?

Lẹ́yìn tí Èlíjà gbàdúrà, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ni Ọlọ́run rẹ̀ dáhùn, ó jẹ́ kí iná bọ́ láti ọ̀run, ó sì jó ẹbọ tí Èlíjà gbé kalẹ̀. Kí ni ìyàtọ̀ láàárín àdúrà méjèèjì? Àdúrà Èlíjà tó wà nínú 1 Àwọn Ọba 18:36, 37 jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì kan. Àdúrà yẹn kúrú gan-an torí pé nǹkan bí ọgbọ̀n ọ̀rọ̀ péré ni lédè Hébérù ìpilẹ̀ṣẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àdúrà yìí kúrú, ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Èlíjà dárúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà.

Báálì tó túmọ̀ sí “oní-nǹkan” tàbí “ọ̀gá,” ni ọlọ́run àwọn ọmọ Kénáánì, òrìṣà yìí sì wà lóríṣiríṣi lágbègbè náà. Àmọ́, Ẹnì kan ṣoṣo láyé àti lọ́run ló ń jẹ́ orúkọ àrà ọ̀tọ̀ náà, Jèhófà. Ọlọ́run yìí sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.”—Aísáyà 42:8.

Kí nìdí tí àdúrà Èlíjà fi ní ìtẹ́wọ́gbà nígbà tí tàwọn wòlíì Báálì kò ní ìtẹ́wọ́gbà? Ìbálòpọ̀ bíi tàwọn aṣẹ́wó tó máa ń wáyé nígbà ààtò ìjọsìn Báálì máa ń tàbùkù èèyàn, àní wọ́n tiẹ̀ máa ń fi àwọn èèyàn rúbọ pàápàá. Àmọ́, ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ èèyàn Jèhófà yàtọ̀, ó kọ́ wọn pé kí wọ́n yàgò fún àwọn àṣà ìjọsìn tó ń tàbùkù ẹni. Nítorí náà, rò ó wò náà, ká sọ pé o kọ lẹ́tà sí ọ̀rẹ́ rẹ kan tó o bọ̀wọ̀ fún gan-an, ǹjẹ́ wàá fẹ́ kí wọ́n mú lẹ́tà náà fún ẹlòmíì tí èrò rẹ̀ àti ìgbàgbọ́ rẹ̀ yàtọ̀ pátápátá sí ti ọ̀rẹ́ rẹ? Ó dájú pé o kò ní ṣe bẹ́ẹ̀!

Tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà, Ẹlẹ́dàá tó jẹ́ Bàbá gbogbo ẹ̀dá lò ń gbàdúrà sí yẹn. a Wòlíì Aísáyà sọ nínú àdúrà rẹ̀ pé: “Jèhófà, ni Baba wa.” (Aísáyà 63:16) Ẹni yìí gan-an ni Jésù Kristi ní lọ́kàn nígbà tó sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń gòkè lọ sọ́dọ̀ Baba mi àti Baba yín àti sọ́dọ̀ Ọlọ́run mi àti Ọlọ́run yín.” (Jòhánù 20:17) Jèhófà ni Bàbá Jésù. Ọlọ́run yìí ni Jésù gbàdúrà sí, òun náà ló sì kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà sí.—Mátíù 6:9.

Ǹjẹ́ Bíbélì sọ pé ká máa gbàdúrà sí Jésù, Màríà, àwọn ẹni mímọ́ tàbí àwọn áńgẹ́lì? Rárá, Jèhófà nìkan ló ní ká máa gbàdúrà sí. Wo ẹ̀rí méjì tó fi rí bẹ́ẹ̀. Àkọ́kọ́ ni pé, àdúrà jẹ́ ara ìjọsìn wa, Bíbélì sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà nìkan ló yẹ ká máa jọ́sìn. (Ẹ́kísódù 20:5) Èkejì ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé òun ló ń jẹ́ orúkọ oyè náà, “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà gbé ohun tó pọ̀ fún àwọn ẹlòmíì láti bójú tó, kò gbé èyí fún ẹnikẹ́ni nígbà kankan. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló ṣèlérí pé òun á máa gbọ́ àdúrà wa.

Nítorí náà, fi ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́ yìí sọ́kàn tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà rẹ, ó ní: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá sì ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.” (Ìṣe 2:21) Àmọ́, ṣé gbogbo àdúrà ni Jèhófà ń gbọ́ láì retí pé ká ṣe nǹkan kan? Àbí ohun kan wà tó yẹ ká mọ̀ tá a bá fẹ́ kí Jèhófà gbọ́ àdúrà wa?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn kan sọ pé kò yẹ kéèyàn máa pe orúkọ tí Ọlọ́run ń jẹ́, àní nínú àdúrà pàápàá. Àmọ́, orúkọ náà fara hàn ní ohun tó lé ní ìgbà ẹgbẹ̀rún méje [7,000] nínú èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ló sì jẹ́ nínú àdúrà tí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà gbà àti nínú àwọn sáàmù tí wọ́n kọ.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ìpèníjà tí Èlíjà gbé síwájú àwọn wòlíì Báálì fi hàn pé kì í ṣe ibì kan náà ni gbogbo àdúrà ń lọ