Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

3 Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?

3 Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?

3 Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Máa Gbàdúrà?

Ọ̀PỌ̀ ẹ̀sìn ló máa ń rin kinkin mọ́ bó ṣe yẹ kéèyàn wà téèyàn bá fẹ́ gbàdúrà, ọ̀rọ̀ tó yẹ kéèyàn lò àtàwọn ààtò tó yẹ ní ṣíṣe. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ìyẹn kọ́ ló ṣe pàtàkì, ó sì ràn wá lọ́wọ́ lórí kókó tó túbọ̀ ṣe pàtàkì, ìyẹn ìbéèrè náà pé, “Báwo ló ṣe yẹ ká máa gbàdúrà?”

Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa onírúurú ibi táwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti gbàdúrà àti bí wọ́n ṣe wà nígbà tí wọ́n fẹ́ gbàdúrà. Wọ́n máa ń gbàdúrà ní ìdákẹ́jẹ́ẹ́ tàbí kí wọ́n gbàdúrà sókè, ìyẹn sì sinmi lórí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́. Wọ́n máa ń gbójú sókè tàbí tẹrí ba nígbà tí wọ́n bá fẹ́ gbàdúrà. Kàkà kí wọ́n máa lo ère, ìlẹ̀kẹ̀ tàbí ìwé àdúrà, ńṣe ni wọ́n máa ń gbàdúrà látọkàn wá, tí wọ́n á sì sọ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára wọn. Kí ló mú kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà wọn?

Bá a ṣe sọ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Ọlọ́run kan ṣoṣo tó ń jẹ́ Jèhófà ni wọ́n máa ń gbàdúrà sí. Nǹkan míì wà tó tún ṣe pàtàkì. Ìwé 1 Jòhánù 5:14 sọ pé: “Èyí sì ni ìgbọ́kànlé tí àwa ní sí i, pé, ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, ó ń gbọ́ tiwa.” Àdúrà wa ní láti bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Kí ni ìyẹn túmọ̀ sí?

Ká tó lè gbàdúrà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, a ní láti mọ ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́. Nítorí náà, ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe kókó nínú ọ̀ràn àdúrà gbígbà. Ṣé ìyẹn wá túmọ̀ sí pé ó dìgbà tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ kí Ọlọ́run tó lè gbọ́ àdúrà wa? Rárá, àmọ́ Ọlọ́run fẹ́ ká mọ ohun tí ìfẹ́ òun jẹ́, ká sapá láti lóye rẹ̀, ká sì fi ohun tá a bá kọ́ sílò. (Mátíù 7:21-23) A ní láti gbàdúrà tó bá ohun tá a kọ́ mu.

Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà àti ìfẹ́ rẹ̀, ìgbàgbọ́ wa á máa lágbára sí i, èyí sì jẹ́ ohun míì tó ṣe pàtàkì nínú ọ̀ràn àdúrà. Jésù sọ pé: “Gbogbo ohun tí ẹ bá sì béèrè nínú àdúrà, pẹ̀lú ìgbàgbọ́, ni ẹ óò rí gbà.” (Mátíù 21:22) Kéèyàn ní ìgbàgbọ́ kò túmọ̀ sí pé òpònú lèèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó túmọ̀ sí kéèyàn gba ohun kan gbọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé èèyàn kò rí nǹkan náà sójú, àmọ́ táwọn ẹ̀rí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ fi hàn pé nǹkan náà wà. (Hébérù 11:1) Ọ̀pọ̀ ẹ̀rí ló wà nínú Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà tí a kò lè rí jẹ́ ẹni gidi, pé ó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé, ó sì ṣe tán láti dáhùn àdúrà àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀. Síwájú sí i, a lè gbàdúrà pé kí Jèhófà fún wa ní ìgbàgbọ́ sí i, ó sì ṣe tán láti fún wa lóhun tá a nílò.—Lúùkù 17:5; Jákọ́bù 1:17.

Ohun míì tún wà tó ṣe pàtàkì tó bá dọ̀rọ̀ bó ṣe yẹ ká máa gbàdúrà. Jésù sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń wá sọ́dọ̀ Baba bí kò ṣe nípasẹ̀ mi.” (Jòhánù 14:6) Nítorí náà, ipasẹ̀ Jésù la lè gbà dé ọ̀dọ̀ Bàbá, ìyẹn Jèhófà. Àmọ́ Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa gbàdúrà lórúkọ òun. (Jòhánù 14:13; 15:16) Ìyẹn kò wá túmọ̀ sí pé Jésù la ó máa gbàdúrà sí. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó máa gbàdúrà ní orúkọ Jésù, má gbàgbé pé Jésù ló jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa tá a fi lè bá Bàbá wa pípé tó sì jẹ́ ẹni mímọ́ jù lọ sọ̀rọ̀.

Àwọn ọmọlẹ́yìn tí wọ́n sún mọ́ Jésù jù lọ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà kan pé: “Kọ́ wa bí a ṣe ń gbàdúrà.” (Lúùkù 11:1) Ó dájú pé kì í ṣe irú àwọn nǹkan tá a ti ń sọ bọ̀ yìí ni wọ́n béèrè nípa rẹ̀. Ohun tí wọ́n fẹ́ mọ̀ ní ti gidi ni, ‘Kí la lè gbàdúrà nípa rẹ̀?’

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]

Àdúrà tó ní ìtẹ́wọ́gbà máa ń jẹ́ èyí tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, téèyàn fi ìgbàgbọ́ gbà, tó sì jẹ́ lórúkọ Jésù