Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

7 Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dáhùn Àdúrà Wa?

7 Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dáhùn Àdúrà Wa?

7 Ṣé Ọlọ́run Máa Ń Dáhùn Àdúrà Wa?

Ó MÁA ń wu àwọn èèyàn gan-an láti mọ̀ nípa ìbéèrè tó wà lókè yìí. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ń fetí sí àdúrà lóde òní. Ọwọ́ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló kù sí bóyá ó máa fetí sí àdúrà wa tàbí kò ní fetí sí i.

Jésù bá àwọn aṣáájú ìsìn ìgbà ayé rẹ̀ wí nítorí pé wọ́n máa ń gbàdúrà àgàbàgebè, wọ́n ń ṣe àṣehàn pé àwọn jẹ́ olùfọkànsìn. Ó sọ pé, àwọn ọkùnrin yìí “ń gba èrè wọn ní kíkún,” èyí tó túmọ̀ sí pé, wọ́n á gbayì lójú àwọn èèyàn, ìyẹn sì ni ohun tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí jù, àmọ́ wọ́n pàdánù ohun tí wọ́n nílò, ìyẹn pé kí Ọlọ́run fetí sí wọn. (Mátíù 6:5) Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ ló ń gbàdúrà lọ́nà tó bá ìfẹ́ tara wọn mu, àmọ́ tí kò bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu. Wọ́n ń kọ etí dídi sí àwọn ìlànà Bíbélì tá a ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, Ọlọ́run kì í sì í fetí sí àdúrà wọn.

Ìwọ ńkọ́? Ṣé Ọlọ́run á fetí sí àdúrà rẹ, tí á sì dáhùn rẹ̀? Kì í ṣe ẹ̀yà, orílẹ̀-èdè tàbí ipò rẹ láwùjọ ló máa pinnu bóyá Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà rẹ. Bíbélì jẹ́ kó dá wa lójú pé: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35) Ǹjẹ́ irú ẹni tó o jẹ́ nìyẹn? Tó o bá bẹ̀rù Ọlọ́run, wàá kà á sí gan-an, o kò sì ní ṣe ohun tó máa dùn ún. Tó o bá ń ṣiṣẹ́ òdodo, wàá máa sapá láti ṣe ohun tí Ọlọ́run sọ pé ó tọ́ dípò tí wàá fi máa ṣe ìfẹ́ ara rẹ tàbí tàwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o fẹ́ kí Ọlọ́run fetí sí àdúrà rẹ? Bíbélì sọ bá a ṣe lè gbàdúrà lọ́nà tí Ọlọ́run á fi gbọ́. a

Òótọ́ ni pé, ọ̀pọ̀ máa ń fẹ́ kí Ọlọ́run dáhùn àdúrà wọn lọ́nà ìyanu. Nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì pàápàá, Ọlọ́run kì í sábà ṣe irú àwọn iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀. Nígbà míì, àkọsílẹ̀ Bíbélì máa ń fi hàn pé ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún máa ń kọjá lẹ́yìn tí iṣẹ́ ìyanu kan bá ti ṣẹlẹ̀ kí òmíràn tó wáyé. Síwájú sí i, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àkókò ṣíṣe iṣẹ́ ìyanu dópin lẹ́yìn táwọn àpọ́sítélì ti kú tán. (1 Kọ́ríńtì 13:8-10) Àmọ́, ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé, Ọlọ́run kì í dáhùn àdúrà lóde òní? Rárá! Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àdúrà kan tó dáhùn.

Ọlọ́run ń fúnni ní Ọgbọ́n. Jèhófà ni Orísun ọgbọ́n gidi. Ó ṣe tán láti fi ọgbọ́n fún àwọn tó ń wá ìtọ́sọ́nà rẹ̀ tí wọ́n sì ń fẹ́ láti máa fi gbé ìgbé ayé wọn.—Jákọ́bù 1:5.

Ọlọ́run ń fúnni ní ẹ̀mí mímọ́ àtàwọn àǹfààní rẹ̀. Ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ agbára ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run. Kò sí nǹkan míì tó lágbára tó o. Ó lè ràn wá lọ́wọ́ láti fara da àdánwò. Ó lè jẹ́ ká ní àlàáfíà ọkàn nígbà tá a bá wà nínú ìdààmú. Ó tún lè jẹ́ ká ní àwọn ànímọ́ tó dára tó sì máa wà pẹ́. (Gálátíà 5:22, 23) Jésù fi dá àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lójú pé Ọlọ́run máa ń fúnni ní ẹ̀bùn yìí ní fàlàlà.—Lúùkù 11:13.

Ọlọ́run ń fún àwọn tó ń sapá láti mọ̀ ọ́n ní ìmọ̀. (Ìṣe 17:26, 27) Kárí ayé, àwọn èèyàn wà tó jẹ́ pé tọkàntọkàn ni wọ́n fẹ́ láti mọ òtítọ́. Wọ́n fẹ́ láti mọ̀ nípa Ọlọ́run, ìyẹn orúkọ rẹ̀, ohun tó fẹ́ ṣe fún ilẹ̀ ayé àti aráyé àti bí wọ́n ṣe lè sún mọ́ ọn. (Jákọ́bù 4:8) Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń bá irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ pàdé, inú wọn sì máa ń dùn láti fi Bíbélì dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀.

Ṣé ohun tó mú kó o gba ìwé ìròyìn yìí nìyẹn? Ṣé o fẹ́ láti mọ Ọlọ́run? Ó lè jẹ́ pé ọ̀nà yìí ni Ọlọ́run gbà dáhùn àdúrà rẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé lórí bá a ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á gbọ́, ka orí 17 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.