Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí ìwé 1 Kọ́ríńtì nínú Bíbélì fi jíròrò nípa ẹran tí wọ́n ti fi rúbọ sáwọn òrìṣà?

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ohun gbogbo tí a ń tà ní ọjà ẹran ni kí ẹ máa jẹ, láìṣe ìwádìí kankan ní tìtorí ẹ̀rí-ọkàn yín.” (1 Kọ́ríńtì 10:25) Ibo ni irú àwọn ẹran bẹ́ẹ̀ ti wá?

Fífi ẹran rúbọ jẹ́ apá pàtàkì ayẹyẹ tí wọ́n máa ń ṣe nínú tẹ́ńpìlì àwọn Gíríìkì àtàwọn ará Róòmù, àmọ́ kì í ṣe gbogbo ẹran tí wọ́n bá fi rúbọ nígbà ayẹyẹ náà ni wọ́n máa ń jẹ. Wọ́n máa ń gbé àwọn ẹran tó ṣẹ́ kù nínú tẹ́ńpìlì èké yìí lọ sọ́jà tí wọ́n ti ń ta ẹran. Ìwé kan tó sọ̀rọ̀ nípa ẹran tí wọ́n fi ń rúbọ, ìyẹn Idol Meat in Corinth sọ pé: “Àwọn kan tí wọ́n jẹ́ aṣáájú nínú ayẹyẹ ẹ̀sìn . . . tún jẹ́ alásè tàbí ẹni tó ń pa ẹran. Àwọn èèyàn máa ń fún wọn lára ẹran tí wọ́n fẹ́ fi rúbọ tí wọ́n bá wọn pa, àwọn ọkùnrin yìí sì máa ń tà lára ẹran náà lọ́jà.”

Nítorí náà, kì í ṣe gbogbo ẹran tí wọ́n ń tà lọ́jà ló jẹ́ èyí tó ṣẹ́ kù lẹ́yìn ayẹyẹ ìsìn. Nígbà tí wọ́n hú ilẹ̀ ọjà ẹran ọ̀gbẹ́ni Pompeii, (Látìn, macellum) wọ́n rí egungun odindi òkú àgùntàn. Ọ̀mọ̀wé Henry J. Cadbury, sọ pé èyí fi hàn pé “ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òòyẹ̀ ni wọ́n ta ẹran yìí tàbí kó jẹ́ pé ọjà ẹran náà ni wọ́n ti pa á, tí wọ́n sì gé e tà tàbí kó jẹ́ èyí tó ṣẹ́ kù lára ẹran tí wọ́n fi rúbọ ní tẹ́ńpìlì.”

Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ni pé, lóòótọ́ àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ bá wọn lọ́wọ́ nínú ìjọsìn èké, àmọ́, pé wọ́n fi ẹran kan rúbọ nínú tẹ́ńpìlì kò túmọ̀ sí pé ẹran náà fúnra rẹ̀ ti di aláìmọ́.

Kí nìdí tí aáwọ̀ fi wà láàárín àwọn Júù àtàwọn ará Samáríà nígbà ayé Jésù?

Ìwé Jòhánù 4:9 sọ pé “àwọn Júù kì í ní ìbálò kankan pẹ̀lú àwọn ará Samáríà.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìgbà tí Jèróbóámù dá ìjọsìn òrìṣà sílẹ̀ láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì mẹ́wàá tó wà ní àríwá ni aáwọ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 12:26-30) Ìlú Samáríà tó jẹ́ olú ìlú ìjọba ẹ̀yà Ísírẹ́lì tó wà ní àríwá ni àwọn ará Samáríà ti wá. Ní ọdún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn Asíríà ṣẹ́gun ẹ̀yà Ísírẹ́lì mẹ́wàá, wọ́n sì kó àwọn kèfèrí tó jẹ́ àjèjì wá sí Samáríà. Bí àwọn ará Samáríà ṣe wá ń fẹ́ àwọn tó wá tẹ̀dó sáàárín wọn yìí túbọ̀ wá ṣàkóbá fún ìjọsìn wọn.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, àwọn ará Samáríà gbéjà ko àwọn Júù tó dé láti ìgbèkùn Bábílónì láti wá tún tẹ́ńpìlì Jèhófà àti odi ìlú Jerúsálẹ́mù kọ́. (Ẹ́sírà 4:1-23; Nehemáyà 4:1-8) Ìjà ẹ̀sìn tó wà láàárín wọn wá gbóná sí i nígbà táwọn ará Samáríà kọ́ tẹ́ńpìlì wọn sí orí Òkè Gérísímù, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Nígbà ayé Jésù, ọ̀rọ̀ náà “Samáríà” ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn gan-an ju orúkọ ìlú lọ, ó sì ń tọ́ka sí ẹ̀ya ìsìn kan tó gbilẹ̀ ní Samáríà. Àwọn ará Samáríà ṣì ń jọ́sìn lórí Òkè Gérísímù, ojú ẹ̀gàn làwọn Júù sì fi ń wò wọ́n.—Jòhánù 4:20-22; 8:48.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àwo pẹrẹsẹ tó ní àwòrán bí wọ́n ṣe ń pa ẹran ìrúbọ ní ọgọ́rùn-ún ọdún kẹfà Ṣáájú Sànmánì Kristẹni

[Credit Line]

Ilé Ìkóhun Ìṣẹ̀ǹbáyé Sí ti Louvre, ní Paris

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Jèróbóámù dá ìjọsìn òrìṣà sílẹ̀