Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjọba Tó Máa Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Ìjọba Tó Máa Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ìjọba Tó Máa Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

ǸJẸ́ o mọ ìjọba náà?— a Ìjọba tí Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà nípa rẹ̀ ni. Ó ní ká béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run pé: “Kí ìjọba rẹ dé.” (Mátíù 6:9, 10) Ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún méjì báyìí tí àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ti ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí Ìjọba Rẹ̀ dé. Ṣé ìwọ náà ti gbàdúrà yẹn?—

Kó o tó lè lóye ohun tí ìjọba yìí jẹ́, o ní láti mọ ohun tí ọba jẹ́. Ọba ni ẹni tó máa ń ṣàkóso. Ibi tó máa ń ṣàkóso lé lórí là ń pè ní ilẹ̀ ọba. Ara ibi tí Ìjọba Ọlọ́run ń ṣàkóso lé lorí ni gbogbo ilẹ̀ ayé. Nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá dé, gbogbo èèyàn tó ń gbé lórí ilẹ̀ ayé ló máa gbádùn àwọn ìbùkún tí ìṣàkóso Ọlọ́run máa mú wá fún àwọn èèyàn.

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba ọ̀run. Ní Aísáyà 9:6, Bíbélì sọ nípa Olùṣàkóso ìjọba yìí. Kíyè sí ohun tó sọ nípa rẹ̀, ó ní: “A ti bí ọmọ kan fún wa, . . . ìṣàkóso ọmọ aládé yóò sì wà ní èjìká rẹ̀. Orúkọ rẹ̀ ni a ó sì máa pè ní . . . Ọmọ Aládé Àlàáfíà.”

Ǹjẹ́ o mọ ẹni tí ọmọ aládé jẹ́?— Òun ni ọmọ ọba. Ta ni Ọba ọ̀run tó wà nípò tó ga jù lọ?— O gbà á, tó o bá sọ pé Jèhófà ni. Bíbélì pè é ní “Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 83:18) Nínú Bíbélì, wọ́n sábà máa ń pe Jésù ní “Ọmọ Ọlọ́run.” Ìdí kan ni pé Jèhófà ló fún Jésù ní ìwàláàyè. Jèhófà gangan ni Bàbá Jésù.—Lúùkù 1:34, 35; Jòhánù 1:34, 49; 3:17; 11:27; 20:31; Ìṣe 9:20.

Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù ní ká máa gbàdúrà fún jẹ́ irú ìjọba pàtàkì kan. Ó jẹ́ “ìṣàkóso ọmọ aládé” nítorí pé Jèhófà fi Jésù Ọmọ rẹ̀ ṣe Olùṣàkóso tàbí Ọba Ìjọba náà. Àmọ́, ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn kan wà tá a yàn láti ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba Bàbá rẹ̀?— Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa wọn.

Kété kí Jésù tó kú, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ olóòótọ́ pé òun ń lọ sí “ilé” Bàbá òun ní ọ̀run. Ó sọ pé, “Mo ń bá ọ̀nà mi lọ láti pèsè ibì kan sílẹ̀ fún yín,  . . . pé níbi tí mo bá wà kí ẹ̀yin pẹ̀lú lè wà níbẹ̀.” (Jòhánù 14:1-3) Ǹjẹ́ o mọ ohun tí àwọn àpọ́sítélì àtàwọn míì tá a yàn yóò máa ṣe ní ọ̀run pẹ̀lú Jésù?— Wọ́n ‘yóò ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú rẹ̀.’ Kódà Bíbélì sọ iye àwọn tó máa ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba pẹ̀lú Jésù. Iye wọn yóò jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000].—Ìṣípayá 14:1, 3; 20:6.

Báwo ni nǹkan ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Ọmọ Aládé Àlàáfíà àtàwọn 144,000 tá a yàn bá ń ṣàkóso?— Àgbàyanu ló máa jẹ́! Kò ní sí ogun mọ́. Àwọn ẹranko á máa gbé pọ̀ ní àlàáfíà pẹ̀lú ara wọn àti pẹ̀lú àwa èèyàn. Ẹnì kankan kò ní ṣàìsàn tàbí kú. Ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití yóò gbọ́ràn, àwọn arọ yóò sáré wọ́n á sì fò sókè bí àgbọ̀nrín. Ilẹ̀ ayé yóò mú oúnjẹ jáde fún gbogbo èèyàn láti jẹ. Gbogbo èèyàn yóò sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn gẹ́gẹ́ bí Jésù ti kọ́ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa ṣe. (Jòhánù 13:34, 35) Ẹ jẹ́ ká ṣí Bíbélì wa sí àwọn ẹsẹ tó wà nínú ìwé Aísáyà tó wà níbí yìí láti kà nípa àwọn ohun àgbàyanu tó máa ṣẹlẹ̀.—Aísáyà 2:4; 11:6-11; 25:8; 33:24; 35:5, 6; 65:21-24.

Láti ìgbà tí Jésù ti kọ́ àwọn èèyàn láti máa gbàdúrà pé, “kí ìjọba rẹ dé,” ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ló ti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ìjọba náà. Ìmọ̀ yìí ti yí ìgbésí ayé wọn pa dà. Láìpẹ́, nígbà tí Ìjọba yẹn bá dé tó sì rọ́pò gbogbo ìjọba ayé yìí, gbogbo èèyàn tó bá ń sin Jèhófà Ọlọ́run àti Olùṣàkóso tó yàn, ìyẹn Jésù Kristi, yóò gbádùn àlàáfíà, ìlera pípé àti ayọ̀.—Jòhánù 17:3.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.

ÌBÉÈRÈ:

▪ Kí nìdí tá a tún fi ń pe Ìjọba Ọlọ́run ní “ìṣàkóso ọmọ aládé”?

▪ Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba Bàbá rẹ̀?

▪ Báwo ni nǹkan ṣe máa rí lórí ilẹ̀ ayé lábẹ́ ìṣàkóso ọmọ aládé tí í ṣe Jésù?