Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan—Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan—Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?

Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan—Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?

INÚ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ máa ń dùn láti jíròrò Bíbélì pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ǹjẹ́ o ní ìbéèrè kan nínú Bíbélì tó ò ń ṣe kàyéfì nípa rẹ̀? Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ̀ nípa ọ̀kan lára ohun tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, má ṣe lọ́ra láti béèrè ohun náà lọ́wọ́ Ẹlẹ́rìí kan tó o bá bá pàdé. Inú rẹ̀ yóò dùn láti jíròrò ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú rẹ.

Irú ìjíròrò bẹ́ẹ̀ tó lè wáyé láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan àti ẹnì kan la fẹ́ gbé yẹ̀ wò yìí. Ẹ jẹ́ ká sọ pé Scott ni orúkọ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lọ sí ilé ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Brad.

Báwo Ní Ọ̀rọ̀ Náà “Ẹ̀mí Mímọ́” Ṣe Yé Ọ Sí?

Brad: Mo gbọ́ táwọn èèyàn máa ń sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe Kristẹni. Ẹ kò gbà pé ẹ̀mí mímọ́ wà.

Scott: Lákọ̀ọ́kọ́ ná, mo fẹ́ kó o mọ̀ pé Kristẹni ni wá. Ìgbàgbọ́ tí mo ní nínú Jésù Kristi ló jẹ́ kí n wá sẹ́nu ọ̀nà rẹ ní òwúrọ̀ yìí. Ó ṣe tán, Kristi ló pàṣẹ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa wàásù. Àmọ́, mo fẹ́ kó o sọ fún mi bí ọ̀rọ̀ náà, “ẹ̀mí mímọ́” ṣe yé ọ sí?

Brad: Ẹ̀mí mímọ́ ni ẹnì kẹta nínú Mẹ́talọ́kan, òun ni olùrànlọ́wọ́ tí Jésù ṣèlérí pé òun máa rán sí wa. Olùrànlọ́wọ́ yìí ṣe pàtàkì sí mi gan-an, nítorí mo fẹ́ kó wà nínú ìgbésí ayé mi.

Scott: Ohun tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ẹ̀mí mímọ́ sí nìyẹn. Ní àwọn àkókò kan sẹ́yìn, mo láǹfààní láti ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì kọ́ni nípa ọ̀rọ̀ yìí. Tó o bá lè fún mi ní ìṣẹ́jú díẹ̀, inú mi á dùn láti fi ohun tí mo kọ́ hàn ẹ́.

Brad: Ó dára, o lè lo ìṣẹ́jú díẹ̀ pẹ̀lú mi.

Scott: Orúkọ mi ni Scott. Jọ̀ọ́, kí ni orúkọ rẹ?

Brad: Orúkọ mi ni Brad. Inú mi dùn láti rí ẹ níbí.

Scott: Inú mi dùn láti rí ìwọ náà, Brad. Mi ò fẹ́ gba àkókò rẹ, nítorí náà, jẹ́ kí n sọ kókó kan péré nípa ọ̀ràn yìí. O sọ pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ Olùrànlọ́wọ́ tí Jésù ṣèlérí fún wa. Mo gbà pẹ̀lú rẹ. Àmọ́, ṣé òye rẹ ni pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan tó sì bá Ọlọ́run dọ́gba?

Brad: Bẹ́ẹ̀ ni, ohun tí wọ́n kọ́ mi nìyẹn.

Ṣé Ẹ̀mí Mímọ́ Jẹ́ Ẹnì Kan?

Scott: Jẹ́ ká wo apá kan nínú Bíbélì tó máa jẹ́ ká mọ̀ bóyá ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan tàbí kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó o ti mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì náà. Ní Ìṣe 2:1-4, a kà pé: “Wàyí o, bí ọjọ́ àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ń lọ lọ́wọ́, gbogbo wọ́n wà pa pọ̀ ní ibì kan náà, lójijì, ariwo kan dún láti ọ̀run gan-an gẹ́gẹ́ bí ti atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì, ó sì kún inú gbogbo ilé tí wọ́n jókòó sí. Àwọn ahọ́n bí ti iná sì di rírí fún wọn, ó sì pín káàkiri, ọ̀kọ̀ọ̀kan sì bà lé ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn, gbogbo wọ́n sì wá kún fún ẹ̀mí mímọ́, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi onírúurú ahọ́n àjèjì sọ̀rọ̀, gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹ̀mí ti ń yọ̀ǹda fún wọn láti sọ̀rọ̀ jáde.”

Brad: Mo mọ àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn dáadáa.

Scott: Ó dára, Brad, ṣé ẹnì kan lè kún fún ẹlòmíì?

Brad: Rárá o.

Scott: Jẹ́ ká tún wo ẹsẹ 17 ní orí kan náà. Apá àkọ́kọ́ lára ẹsẹ náà kà pé: “‘Ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,’ ni Ọlọ́run wí, ‘èmi yóò sì tú lára ẹ̀mí mi jáde sára gbogbo onírúurú ẹran ara.’” Jẹ́ kí n bi ẹ́, Brad, ṣé Ọlọ́run lè tú apá kan lára ara rẹ̀ jáde?

Brad: Rárá o.

Scott: Jòhánù Oníbatisí ṣe àlàyé tó yàtọ̀ nípa bí èèyàn ṣé ń kún fún ẹ̀mí mímọ́. Àlàyé yìí wà nínú Mátíù 3:11. Jọ̀ọ́, ṣé wàá fẹ́ láti ka ẹsẹ náà?

Brad: “Èmi, ní tèmi, ń fi omi batisí yín nítorí ìrònúpìwàdà yín; ṣùgbọ́n ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn mi lágbára jù mí lọ, ẹni tí èmi kò tó láti bọ́ sálúbàtà rẹ̀ kúrò. Ẹni yẹn yóò fi ẹ̀mí mímọ́ àti iná batisí yín.”

Scott: O ṣeun. Ǹjẹ́ o fiyè sí ohun tí Jòhánù Oníbatisí sọ pé ẹnì kan máa fi ẹ̀mí mímọ́ ṣe?

Brad: Ó sọ pé ẹnì kan máa fi ẹ̀mí mímọ́ batisí àwọn èèyàn.

Scott: Bẹ́ẹ̀ ni. Fiyè sí i pé ó tún ní ó máa fi iná batisí àwọn èèyàn. Ó hàn kedere pé iná kì í ṣe ẹnì kan. Ǹjẹ́ o rò pé ẹsẹ yìí ń sọ pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan?

Brad: Rárá o.

Scott: Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a ti gbé yẹ̀ wò ṣe sọ, ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan.

Brad: Ó jọ pé òótọ́ ni.

Báwo Ló Ṣe Jẹ́ “Olùrànlọ́wọ́”?

Scott: Àmọ́, ní ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ wa, o mẹ́nu kan ọ̀rọ̀ náà “olùrànlọ́wọ́.” Jésù pe ẹ̀mí mímọ́ ní “olùrànlọ́wọ́” nínú Jòhánù 14:26. Jẹ́ ká jọ kà á: “Olùrànlọ́wọ́ náà, ẹ̀mí mímọ́, èyí tí Baba yóò rán ní orúkọ mi, èyíinì ni yóò kọ́ yín ní ohun gbogbo, tí yóò sì mú gbogbo ohun tí mo ti sọ fún yín padà wá sí ìrántí yín.” Àwọn kan rò pé ẹsẹ Bíbélì yìí ń ti èrò pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan lẹ́yìn, pé ó jẹ́ ẹnì kan tó ń ranni lọ́wọ́ tó sì ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́.

Brad: Bẹ́ẹ̀ ni, èrò tèmi náà nìyẹn.

Scott: Àmọ́, ṣé kì í ṣe pé àkànlò èdè ni Jésù lò? Wàyí o, wo ohun tí Jésù sọ nípa ọgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí Lúùkù 7:35 ṣe sọ. Ó ní, “Síbẹ̀ náà, a fi ọgbọ́n hàn ní olódodo nípasẹ̀ gbogbo àwọn ọmọ rẹ̀.” Ṣé wàá sọ pé ọgbọ́n jẹ́ èèyàn, tí ó ní àwọn ọmọ lóòótọ́?

Brad: Rárá. Ó dájú pé àkànlò èdè ni.

Scott: Bẹ́ẹ̀ ni. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ló máa jẹ́ ká mọ bí ọgbọ́n ti wúlò tó. Bíbélì sábà máa ń lo àkànlò èdè tí wọ́n ń pè ní fífi nǹkan wé èèyàn, ìyẹn sísọ̀rọ̀ ohun kan tí kò lẹ́mìí bíi pé èèyàn ni. A sábà máa ń lo irú àkànlò èdè yẹn nígbà táwa náà bá ń sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí ilẹ̀ bá mọ́, a máa ń sọ pé ká ṣí wíńdò kí oòrùn lè wọlé.

Brad: Èmi náà máa ń sọ bẹ́ẹ̀.

Scott: Ṣé ohun tó ò ń sọ ni pé oòrùn jẹ́ èèyàn tó fẹ́ wọnú ilé rẹ?

Brad: Rárá o, kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Àkànlò èdè ni.

Scott: Nítorí náà, nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ tàbí olùkọ́, ǹjẹ́ kì í ṣe pé àkànlò èdè ló ń lò?

Brad: Ohun tó máa jẹ́ náà nìyẹn. Èyí bá àwọn ẹsẹ Bíbélì tó o kà mu, àwọn tó sọ nípa títú ẹ̀mí mímọ́ jáde àti fífi ẹ̀mí mímọ́ batisí àwọn èèyàn. Àmọ́, tí ẹ̀mí mímọ́ kì í bá ṣe ẹnì kan, kí wá ni?

Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?

Scott: Nínú Ìṣe 1:8, Jésù sọ ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́. Ṣé wàá fẹ́ kà á?

Brad: “Ẹ ó gba agbára nígbà tí ẹ̀mí mímọ́ bá bà lé yín, ẹ ó sì jẹ́ ẹlẹ́rìí mi ní Jerúsálẹ́mù àti ní gbogbo Jùdíà àti Samáríà àti títí dé apá ibi jíjìnnà jù lọ ní ilẹ̀ ayé.”

Scott: Ṣàkíyèsí pé Jésù sọ pé ẹ̀mí mímọ́ àti agbára wọnú ara wọn. Látinú àwọn ẹsẹ tá a ti kà, ibo lo rò pé agbára yẹn ti máa wá?

Brad: Látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Bàbá ni.

Scott: Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára kan náà tí Ọlọ́run lò láti dá ayé àtọ̀run. Nínú orí àkọ́kọ́ inú Bíbélì, ẹsẹ kejì rẹ̀ sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 1:2 sọ pé: “Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run sì ń lọ síwá-sẹ́yìn lójú omi.” Ọ̀rọ̀ Hébérù tí wọ́n túmọ̀ sí “ipá ìṣiṣẹ́” níbi yìí ni wọ́n tún túmọ̀ sí “ẹ̀mí.” Ipá ìṣiṣẹ́ tí a kò lè fojú rí ni Ọlọ́run fi ń ṣe ohun tó bá fẹ́, tó sì fi ń mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ. Jẹ́ ká wo ẹsẹ Bíbélì kan sí i. Ìwé Lúùkù 11:13. Jọ̀ọ́, ṣé wàá kà á?

Brad: “Nígbà náà, bí ẹ̀yin, tí ẹ tilẹ̀ jẹ́ ẹni burúkú, bá mọ bí ẹ ṣe ń fi ẹ̀bùn rere fún àwọn ọmọ yín, mélòómélòó ni Baba tí ń bẹ ní ọ̀run yóò fi ẹ̀mí mímọ́ fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”

Scott: Tó bá jẹ́ pé Bàbá ní ọ̀run ló ń darí ẹ̀mí mímọ́, tó sì ń fún àwọn tó ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ṣé ẹ̀mí mímọ́ náà lè wá dọ́gba pẹ̀lú Bàbá?

Brad: Rárá o. Ó ti yé mi wàyí.

Scott: Mi ò fẹ́ gba àkókò rẹ, Brad. O sọ pé ìṣẹ́jú díẹ̀ lo fún mi. Àmọ́ jẹ́ kí n béèrè ìbéèrè kan láti fi ṣàkópọ̀ ìjíròrò wa. Látinú àwọn ẹsẹ Bíbélì tá a ti gbé yẹ̀ wò, kí ni èrò rẹ nípa ẹ̀mí mímọ́?

Brad: Ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run ni.

Scott: Bẹ́ẹ̀ gan-an ló ṣe jẹ́. Nígbà tí Jésù bá ń sọ̀rọ̀ ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí olùrànlọ́wọ́ tàbí olùkọ́ bó ṣe wà nínú Jòhánù 14:26, ńṣe ló kàn ń lo àkànlò èdè tá à ń pè ní fífi nǹkan wé èèyàn.

Brad: Mi ò mọ ìyẹn tẹ́lẹ̀.

Scott: Ohun kan wà tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ tá a rí kọ́ nínú ọ̀rọ̀ Jésù.

Brad: Kí ni?

Scott: Ohun náà ni pé a lè béèrè pé kí Ọlọ́run fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti borí ìṣòro. A tún lè gbàdúrà fún ẹ̀mí mímọ́ pé kó ràn wá lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run.

Brad: Ìyẹn mà dára gan-an ni o. Mo ní láti ronú nípa rẹ̀.

Scott: Kí n tó lọ, jẹ́ kí n sọ nǹkan míì tó o lè máa ronú lé lórí. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ipá ìṣiṣẹ́ Ọlọ́run, a ní láti gbà pé Ọlọ́run lè lò ó láti ṣe àṣeparí ohunkóhun tó bá fẹ́.

Brad: Bẹ́ẹ̀ ni.

Scott: Kí ló dé nígbà náà tí kò tíì lo agbára tí kò láàlà yìí láti fòpin sí gbogbo ìṣẹ́ àti ìwà ibi tá à ń rí nínú ayé lónìí? Ǹjẹ́ o ti ṣe kàyéfì nípa ìyẹn rí? a

Brad: Mo ti ṣe kàyéfì nípa rẹ̀ rí.

Scott: Ṣé wàá fẹ́ kí n pa dà wá lọ́sẹ̀ tó ń bọ̀ ní àkókò kan náà yìí láti jọ jíròrò rẹ̀?

Brad: Ó wù mí gan-an kó o pa dà wá. Màá máa retí rẹ nígbà yẹn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.