Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ta Ni Ó Ti Wá Mọ Èrò Inú Jèhófà?”

“Ta Ni Ó Ti Wá Mọ Èrò Inú Jèhófà?”

“Ta Ni Ó Ti Wá Mọ Èrò Inú Jèhófà?”

“‘Ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè fún un ní ìtọ́ni?’ Ṣùgbọ́n àwa ní èrò inú ti Kristi.”—1 KỌ́R. 2:16.

1, 2. (a) Ìṣòro wo ló ń bá ọ̀pọ̀ èèyàn fínra? (b) Kí ló yẹ ká rántí nípa èrò inú tiwa àti ti Jèhófà?

 ǸJẸ́ ó ti ṣòro fún ẹ rí láti lóye ọ̀nà tí àwọn ẹlòmíì ń gbà ronú? Ó lè jẹ́ pé o ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni, ó sì ń ṣe ẹ́ bíi pé kò sí bó o ṣe lè mọ èrò inú ọkọ tàbí aya rẹ. Kò sí àní-àní pé, bí tọkùnrin tobìnrin ṣe ń ronú àti bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ yàtọ̀ síra. Kódà nínú àwọn àṣà ìbílẹ̀ kan, tọkùnrin tobìnrin tó ń sọ èdè kan náà tún máa ń ní èdè àdúgbò tó yàtọ̀ síra! Láfikún sí i, ìyàtọ̀ tó wà nínú àṣà ìbílẹ̀ àti èdè lè mú kí ọ̀nà tí àwọn èèyàn ń gbà ronú àti ìṣesí wọn yàtọ̀ síra. Àmọ́, bó o ṣe túbọ̀ ń mọ àwọn ẹlòmíì, bẹ́ẹ̀ ni wàá túbọ̀ máa láǹfààní láti bẹ̀rẹ̀ sí í lóye bí wọ́n ṣe ń ronú.

2 Nítorí náà, kò yẹ kó yà wá lẹ́nu pé èrò inú wa yàtọ̀ pátápátá sí ti Jèhófà. Ó tipasẹ̀ wòlíì Aísáyà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìrònú yín kì í ṣe ìrònú mi, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi kì í ṣe ọ̀nà yín.” Lẹ́yìn náà, Jèhófà wá ṣàpèjúwe òtítọ́ yìí, ó ní: “Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti ga ju ilẹ̀ ayé, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀nà mi ga ju ọ̀nà yín, bẹ́ẹ̀ sì ni ìrònú mi ga ju ìrònú yín.”—Aísá. 55:8, 9.

3. Àwọn ọ̀nà méjì wo la lè gbà ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà”?

3 Ǹjẹ́ èyí wá túmọ̀ sí pé a kò gbọ́dọ̀ sapá rárá láti mọ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ronú? Rárá o. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye nípa gbogbo èrò inú Jèhófà, síbẹ̀ Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká wà ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà.” (Ka Sáàmù 25:14; Òwe 3:32.) Ọ̀nà kan tá a lè gbà sún mọ́ Jèhófà tímọ́tímọ́ ni pé ká máa bọ̀wọ̀ fún ohun tí Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ nípa àwọn ìgbòkègbodò rẹ̀, ká sì máa fiyè sí wọn. (Sm. 28:5) Ọ̀nà míì ni pé ká mọ “èrò inú ti Kristi,” tó jẹ́ “àwòrán Ọlọ́run tí a kò lè rí.” (1 Kọ́r. 2:16; Kól. 1:15) Tá a bá ń fi àkókò sílẹ̀ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tá a sì ń ṣàṣàrò lórí ohun tá a kọ́, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í lóye àwọn ànímọ́ Jèhófà àti èrò inú rẹ̀.

Ṣọ́ra fún Èrò Tí Kò Tọ́

4, 5. (a) Èrò tí kò tọ́ wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún? Ṣàlàyé. (b) Èrò tí kò tọ́ wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ní?

4 Bá a ṣe ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìgbòkègbodò Jèhófà, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra fún fífi ojú èèyàn wo Ọlọ́run. Irú èrò yìí ni Jèhófà tọ́ka sí nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà nínú Sáàmù 50:21: “Ìwọ lérò pé ó dájú hán-ún pé èmi yóò dà bí tìrẹ.” Ńṣe ló dà bí ọ̀rọ̀ tí ọ̀mọ̀wé kan tó máa ń ṣèwádìí nípa Bíbélì sọ ní ọdún márùnléláàádọ́sàn-án [175] sẹ́yìn pé: “Àwọn èèyàn máa ń fẹ́ fi ìlànà tiwọn pinnu ohun tó yẹ kí Ọlọ́run máa ṣe, wọ́n sì máa ń ronú pé ó yẹ kí àwọn àti Ọlọ́run jọ máa pa òfin kan náà mọ́.”

5 A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má lọ yí ojú tá a fi ń wo Jèhófà pa dà, kó lè bá àwọn ìlànà tiwa àti ìfẹ́ ọkàn wa mu. Kí nìdí tí èyí fi ṣe pàtàkì? Bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Mímọ́, ó lè dà bíi pé àwọn ìgbésẹ̀ kan tí Jèhófà gbé kò tọ́ lójú àwa ẹ̀dá èèyàn aláìpé tó jẹ́ pé ó níbi tí òye wá mọ. Irú èrò yìí làwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í ní nípa ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bá wọn lò. Kíyè sí ohun tí Jèhófà sọ fún wọn: “Ẹ̀yin yóò sì sọ dájúdájú pé: ‘Ọ̀nà Jèhófà kò gún.’ Jọ̀wọ́, gbọ́ ilé Ísírẹ́lì. Ṣé ọ̀nà tèmi ni kò gún? Ọ̀nà yín ha kọ́ ni kò gún?”—Ìsík. 18:25.

6. Ẹ̀kọ́ wo ni Jóòbù kọ́, báwo la sì ṣe lè jàǹfààní látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i?

6 Ohun kan tí kò ní jẹ́ ká kó sínú pàkúté fífi ojú èèyàn wo Jèhófà ni mímọ̀ pé èrò wa kúrú àti pé nígbà míì ìrònú wa kì í mọ́gbọ́n dání. Ẹ̀kọ́ tó yẹ kí Jóòbù kọ́ nìyẹn. Ní gbogbo àkókò tí Jóòbù fi ń jìyà, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ̀rètí nù, ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ara rẹ̀ ṣáá. Kò ronú nípa ọ̀ràn pàtàkì tó wà nílẹ̀ mọ́. Àmọ́ Jèhófà ràn án lọ́wọ́ láti ní àròjinlẹ̀. Bí Jèhófà ṣe bi Jóòbù ní àwọn ìbéèrè tó lé ní àádọ́rin [70], èyí tí Jóòbù kò lè dáhùn rárá, mú kó ṣe kedere pé òye Jóòbù kò kún tó. Jóòbù fi ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ hàn, ó sì tún èrò inú rẹ̀ ṣe.—Ka Jóòbù 42:1-6.

Bí A Ṣe Lè Ní “Èrò Inú Ti Kristi”

7. Báwo ni ṣíṣàyẹ̀wò àwọn ìgbòkègbodò Jésù ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti mọ èrò inú Jèhófà?

7 Jésù tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Baba rẹ̀ nínú ohun gbogbo tó sọ àtèyí tó ṣe. (Jòh. 14:9) Torí náà, ṣíṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìgbòkègbodò Jésù máa ràn wá lọ́wọ́ láti mọ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ronú. (Róòmù 15:5; Fílí. 2:5) Wàyí o, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìṣẹ̀lẹ̀ méjì tó wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Ìhìn Rere.

8, 9. Bó ṣe wà nínú Jòhánù 6:1-5, kí ló mú kí Jésù bi Fílípì ní ìbéèrè, kí sì nìdí tí Jésù fi ṣe bẹ́ẹ̀?

8 Fi ojú inú wo ohun tó ṣẹlẹ̀. Ṣáájú ayẹyẹ Ìrékọjá ọdún 32 Sànmánì Kristẹni. Àwọn àpọ́sítélì Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ pa dà dé láti ibi tí wọ́n rìnrìn-àjò lọ láti lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù àrà ọ̀tọ̀ jákèjádò Gálílì ni. Torí pé iṣẹ́ náà mú kó rẹ̀ wọ́n, Jésù mú wọn lọ sí ibi àdádó kan ní apá àríwá ìlà oòrùn etí Òkun Gálílì. Àmọ́, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn ló tẹ̀ lé wọn. Lẹ́yìn tí Jésù ti wo ogunlọ́gọ̀ àwọn èèyàn náà sàn, tó sì tún kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́, ìṣòro kan wá jẹ yọ. Báwo ni gbogbo àwọn èèyàn yìí ṣe lè rí nǹkan jẹ ní irú àgbègbè àdádó bẹ́ẹ̀? Bí Jésù ti kíyè sí ọ̀ràn yìí, ó bi Fílípì tó wá láti àgbègbè yẹn pé: “Ibo ni a ó ti ra ìṣù búrẹ́dì fún àwọn wọ̀nyí láti jẹ?”—Jòh. 6:1-5.

9 Kí nìdí tí Jésù fi bi Fílípì ní ìbéèrè yìí? Ṣé Jésù kò mọ ohun tó máa ṣe ni? Rárá o. Kí wá ló ń rò? Àpọ́sítélì Jòhánù tí òun náà wà níbẹ̀ ṣàlàyé pé: “[Jésù] ń sọ èyí láti dán an wò, nítorí òun fúnra rẹ̀ mọ ohun tí òun máa tó ṣe.” (Jòh. 6:6) Jésù tipa bẹ́ẹ̀ wo ibi táwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tẹ̀ síwájú dé nípa tẹ̀mí. Bí Jésù ṣe béèrè ìbéèrè yìí gba àfiyèsí wọn, ó sì fún wọn láǹfààní láti sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ nípa ohun tí òun lè ṣe. Àmọ́, wọ́n pàdánù àǹfààní yìí láti fi hàn pé àwọ́n ní ìgbàgbọ́, ó sì hàn pé òye wọn kò kún tó. (Ka Jòhánù 6:7-9.) Jésù wá jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé òun lè ṣe ohun tí wọn ò tiẹ̀ ronú kàn rárá. Ó bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn tí ebi ń pa yẹn lọ́nà ìyanu.—Jòh. 6:10-13.

10-12. (a) Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Jésù kò fi ṣe ohun tí obìnrin tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì yẹn béèrè lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀? Ṣàlàyé. (b) Kí la máa gbé yẹ̀ wò báyìí?

10 Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lè mú ká mọ èrò inú Jésù nínú ọ̀ràn míì tó tún wáyé. Kété lẹ́yìn tí Jésù bọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn yìí, òun àti àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ rìnrìn-àjò lọ sí apá àríwá, ní ìkọjá ààlà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, lágbègbè ìlú Tírè àti Sídónì. Níbẹ̀, wọ́n pàdé obìnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì tó bẹ Jésù pé kó bá òun wo ọmọbìnrin òun sàn. Jésù kò kọ́kọ́ dá obìnrin náà lóhùn. Àmọ́ nígbà tó ṣáà ń tẹnu mọ́ ọn ṣáá, Jésù sọ fún un pé: “Kọ́kọ́ jẹ́ kí àwọn ọmọ yó ná, nítorí kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, kí a sì sọ ọ́ sí àwọn ajá kéékèèké.”—Máàkù 7:24-27.

11 Kí nìdí tí Jésù kò fi kọ́kọ́ fẹ́ ran obìnrin yìí lọ́wọ́? Ṣé Jésù ń dán an wò ni, bó ṣe ṣe fún Fílípì, kó lè mọ ohun tó máa ṣe, kó sì fún un láǹfààní láti fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ Bíbélì yẹn kò sọ irú ohùn tó fi bá a sọ̀rọ̀, síbẹ̀ a mọ̀ pé kò kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá a. Bó ṣe lo gbólóhùn náà, “ajá kéékèèké” rọ àfiwé tó ṣe yẹn lójú. Ó dà bíi pé ńṣe ni Jésù ń ṣe bí òbí kan tó fẹ́ fún ọmọ rẹ̀ ní ohun tó béèrè, àmọ́ tó kọ́kọ́ ṣe bíi pé kò ní fún un kó lè mọ bí ohun náà ṣe ń jẹ ọmọ náà lọ́kàn tó. Ohun yòówù kó wà lọ́kàn Jésù, nígbà tí obìnrin náà ti fi hàn pé òun ní ìgbàgbọ́, Jésù ṣe ohun tó fẹ́ fún un.—Ka Máàkù 7:28-30.

12 Ìṣẹ̀lẹ̀ méjèèjì tó wà nínú ìwé Ìhìn Rere yìí ti jẹ́ ká ní òye tó ṣe kedere nípa “èrò inú ti Kristi.” Ẹ jẹ́ ká wá wo bí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní òye tó sàn sí i nípa èrò inú Jèhófà.

Bí Jèhófà Ṣe Bá Mósè Sọ̀rọ̀

13. Báwo ni níní òye nípa ọ̀nà tí Jésù ń gbà ronú ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

13 Tá a bá mọ ọ̀nà tí Jésù ń gbà ronú, ó máa ràn wá lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan tó dà bíi pé ó ṣòro láti lóye. Bí àpẹẹrẹ, gbé ohun tí Jèhófà sọ fún Mósè lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ère ọmọ màlúù kan yẹ̀ wò. Ọlọ́run sọ pé: “Mo ti bojú wo àwọn ènìyàn yìí, sì kíyè sí i, ọlọ́rùn-líle ènìyàn ni wọ́n. Ǹjẹ́ nísinsìnyí, jọ̀wọ́ mi, kí ìbínú mi lè ru sí wọn, kí n lè pa wọ́n run pátápátá, kí o sì jẹ́ kí n sọ ìwọ di orílẹ̀-èdè ńlá.”—Ẹ́kís. 32:9, 10.

14. Kí ni Mósè ṣe nípa ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún un?

14 Àkọsílẹ̀ náà ń bá a lọ pé: “Mósè sì bẹ̀rẹ̀ sí tu Jèhófà Ọlọ́run rẹ̀ lójú, ó wí pé: ‘Jèhófà, èé ṣe tí ìbínú rẹ yóò fi ru sí àwọn ènìyàn rẹ tí o fi agbára ńlá àti ọwọ́ líle mú jáde kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì? Èé ṣe tí àwọn ará Íjíbítì yóò fi wí pe, “Ète ibi ni ó fi mú wọn jáde kí ó lè pa wọ́n láàárín àwọn òkè ńlá, kí ó sì lè pa wọ́n run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀”? Yí padà kúrò nínú ìbínú rẹ jíjófòfò, kí o sì pèrò dà ní ti ibi sí àwọn ènìyàn rẹ. Rántí Ábúráhámù, Ísákì àti Ísírẹ́lì, àwọn ìránṣẹ́ rẹ, àwọn tí o fi ara rẹ búra fún, ní ti pé, o wí fún wọn pé, “Èmi yóò sọ irú-ọmọ yín di púpọ̀ bí àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gbogbo ilẹ̀ yìí tí mo sì ti tọ́ka sí ni èmi yóò fi fún irú-ọmọ yín, kí wọ́n lè gbà á fún àkókò tí ó lọ kánrin.”’ Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí pèrò dà ní ti ibi tí ó sọ pé òun fẹ́ ṣe sí àwọn ènìyàn rẹ̀.”—Ẹ́kís. 32:11-14. a

15, 16. (a) Àǹfààní wo ló ṣí sílẹ̀ fún Mósè látàrí ohun tí Jèhófà sọ? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà “pèrò dà”?

15 Ǹjẹ́ Mósè tiẹ̀ ní láti yí Jèhófà lérò pa dà? Rárá o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà sọ ohun tó wù ú láti ṣe, síbẹ̀ ohun tó sọ yẹn kọ́ ni abẹ gé. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ni Jèhófà ń dán Mósè wò, bí Jésù ṣe wá ṣe fún Fílípì àti obìnrin ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì nígbà tó yá. Ọlọ́run yọ̀ǹda fún Mósè láti sọ èrò rẹ̀ jáde. b Jèhófà ti yan Mósè gẹ́gẹ́ bí alárinà láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àti Òun fúnra rẹ̀, Jèhófà kò sì fojú kékeré wo yíyàn tó yan Mósè sí ipò yẹn. Ǹjẹ́ Mósè á ṣe ohun tí kò tọ́ torí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì já a kulẹ̀. Ǹjẹ́ Mósè á lo àǹfààní yẹn láti rọ Jèhófà pé kó pa àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tì, kó sì sọ àwọn àtọmọdọ́mọ òun di orílẹ̀-èdè ńlá?

16 Bí Mósè ṣe fèsì ọ̀rọ̀ náà fi hàn pé ó nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, ó sì fọkàn tán ìdájọ́ òdodo rẹ̀. Ìwà tó hù fi hàn pé kì í ṣe onímọtara-ẹni-nìkan, kàkà bẹ́ẹ̀ orúkọ Jèhófà ló jẹ ẹ́ lógún. Kò fẹ́ kí orúkọ Jèhófà bà jẹ́. Mósè tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun mọ “èrò inú Jèhófà” lórí ọ̀ràn náà. (1 Kọ́r. 2:16) Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Torí pé Jèhófà ní onírúurú ọ̀nà láti gbà mú ètè rẹ̀ ṣẹ, àkọsílẹ̀ tí Ọlọ́run mí sí yẹn sọ pé, Ó sì “bẹ̀rẹ̀ sí pèrò dà.” Lédè Hébérù, ohun tí gbólóhùn yìí túmọ̀ sí ni pé Jèhófà kò mú àjálù tó fẹ́ mú wá sórí orílẹ̀-èdè náà tẹ́lẹ̀ wá sorí rẹ̀ mọ́.

Bí Jèhófà Ṣe Hùwà sí Ábúráhámù

17. Báwo ni Jèhófà ṣe fi sùúrù tí kò lẹ́gbẹ́ hàn nípa àwọn ohun tí Ábúráhámù béèrè fún?

17 Àpẹẹrẹ míì nípa bí Jèhófà ṣe yọ̀ǹda fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti fi hàn pé àwọn ní ìgbàgbọ́ àti pé àwọn fọkàn tán an ní í ṣe pẹ̀lú ohun tí Ábúráhámù béèrè nípa ìlú Sódómù. Nínú àkọsílẹ̀ yẹn, Jèhófà ṣe sùúrù gan-an fún Ábúráhámù bó ṣe ń béèrè oríṣi nǹkan mẹ́jọ nípa ìlú Sódómù. Lákòókò kan Ábúráhámù béèrè nǹkan yìí tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ní: “Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ pé o ń gbé ìgbésẹ̀ ní irú ọ̀nà yìí láti fi ikú pa olódodo pẹ̀lú ẹni burúkú tí ó fi jẹ́ pé ó ní láti ṣẹlẹ̀ sí olódodo bí ó ti ń rí fún ẹni burúkú! Kò ṣeé ronú kàn nípa rẹ. Onídàájọ́ gbogbo ilẹ̀ ayé kì yóò ha ṣe ohun tí ó tọ́ bí?”—Jẹ́n. 18:22-33.

18. Kí la rí kọ́ nínú ọ̀nà tí Jèhófà gbà hùwà sí Ábúráhámù?

18 Kí la rí kọ́ nípa èrò inú Jèhófà látinú àkọsílẹ̀ yìí? Ǹjẹ́ ó dìgbà tí Jèhófà bá fikùnlukùn pẹ̀lú Ábúráhámù kó tó lè ṣe ìpinnu tó tọ́? Ó tì o. Bí Jèhófà bá fẹ́, ó ti lè sọ ìdí tó fi pinnu láti pa Sódómù run fún Ábúráhámù látìbẹ̀rẹ̀. Àmọ́, bí Jèhófà ṣe gba Ábúráhámù láyè láti béèrè àwọn ìbéèrè yìí mú kí Ábúráhámù fara mọ́ ìpinnu náà, kó sì mọ ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà ronú. Ó tún jẹ́ kí Ábúráhámù mọ bí ìyọ́nú Jèhófà àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀ ṣe jinlẹ̀ tó. Ńṣe ni Jèhófà hùwà sí Ábúráhámù gẹ́gẹ́ bí ọ̀rẹ́.—Aísá. 41:8; Ják. 2:23.

Ẹ̀kọ́ Tá A Rí Kọ́

19. Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jóòbù?

19 Kí la ti rí kọ́ nípa “èrò inú Jèhófà”? A gbọ́dọ̀ jẹ́ kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàtúnṣe òye tá a ní nípa èrò inú Jèhófà. A kò gbọ́dọ̀ máa fi èrò kúkúrú tiwa díwọ̀n ohun tí Jèhófà ń ṣe ká sì máa fi àwọn ìlànà àti èrò inú tiwa pinnu ohun tó yẹ kó ṣe. Jóòbù sọ pé: “[Ọlọ́run] kì í ṣe ènìyàn bí èmi, tí èmi ì bá fi dá a lóhùn, tí àwa ì bá fi pàdé pọ̀ nínú ìdájọ́.” (Jóòbù 9:32) Bíi ti Jóòbù, tí àwa náà bá bẹ̀rẹ̀ sí í mọ èrò inú Jèhófà, kò sí ohun tá a máa lè ṣe ju ká fìtara sọ pé: “Wò ó! Ìwọ̀nyí jẹ́ bèbè àwọn ọ̀nà rẹ̀, àhegbọ́ mà ni ohun tí a sì gbọ́ nípa rẹ̀! Ṣùgbọ́n nípa ààrá agbára ńlá rẹ̀, ta ní lè lóye rẹ̀?”—Jóòbù 26:14.

20. Tá a bá ka ibì kan nínú Ìwé Mímọ́ tó ṣòro fún wa láti lóye, kí ló yẹ ká ṣe?

20 Bá a bá ń ka Ìwé Mímọ́, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá ka apá ibi tó ṣòro fún wa láti lóye, ní pàtàkì tó bá jẹ mọ́ èrò inú Jèhófà? Tó bá jẹ́ pé a kò rí ìdáhùn tó ṣe kedere sí wa lẹ́yìn tá a ti ṣe ìwádìí nípa rẹ̀, a lè wò ó bí ohun tó ń dán ìgbọ́kànlé tá a ní nínú Jèhófà wò. Má gbàgbé pé, nígbà míì àwọn gbólóhùn kan máa ń jẹ́ ká láǹfààní láti fi ìgbàgbọ́ wa nínú àwọn ànímọ́ Jèhófà hàn. Ẹ jẹ́ ká fìrẹ̀lẹ̀ gbà pé kì í ṣe gbogbo nǹkan tó ń ṣe ló yé wa. (Oníw. 11:5) A ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fohùn ṣọ̀kan pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí pé: “Ìjìnlẹ̀ àwọn ọrọ̀ àti ọgbọ́n àti ìmọ̀ Ọlọ́run mà pọ̀ o! Àwọn ìdájọ́ rẹ̀ ti jẹ́ àwámáridìí tó, àwọn ọ̀nà rẹ̀ sì ré kọjá àwákàn! Nítorí ‘ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, tàbí ta ní ti di agbani-nímọ̀ràn rẹ̀?’ Tàbí, ‘Ta ní ti kọ́kọ́ fi fún un, tí a fi gbọ́dọ̀ san án padà fún un?’ Nítorí pé láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ohun gbogbo ti wá àti nípasẹ̀ rẹ̀ àti fún un. Òun ni kí ògo wà fún títí láé. Àmín.”—Róòmù 11:33-36.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Irú àkọsílẹ̀ yìí wà nínú Númérì 14:11-20.

b Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ, àkànlò èdè Hébérù tá a túmọ̀ sí “jọ̀wọ́ mi” nínú Ẹ́kísódù 32:10 la lè wò ó gẹ́gẹ́ bí ìkésíni, ìyẹn ni pé kí Ọlọ́run gba Mósè láyè láti bá wọn bẹ̀bẹ̀, tàbí ‘kí ó dúró sí àlàfo,’ tó wà láàárín Jèhófà àti orílẹ̀-èdè náà. (Sm. 106:23; Ìsík. 22:30) Ohun yòówù kí ọ̀rọ̀ náà jẹ́, ará rọ Mósè láti sọ èrò rẹ̀ jáde fàlàlà fún Jèhófà.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí ni kò ní jẹ́ ká máa fi àwọn ìlànà tiwa pinnu ohun tó yẹ kí Jèhófà ṣe?

• Báwo ni lílóye àwọn ohun tí Jésù ṣe ṣe lè mú ká ní “ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà”?

• Ẹ̀kọ́ wo lo kọ́ látinú ìjíròrò tí Jèhófà ní pẹ̀lú Mósè àti Ábúráhámù?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Kí la rí kọ́ nípa èrò inú Jèhófà látinú ọ̀nà tó gbà hùwà sí Mósè àti Ábúráhámù?