Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Wá “Òdodo Rẹ̀” Lákọ̀ọ́kọ́

Ẹ Máa Wá “Òdodo Rẹ̀” Lákọ̀ọ́kọ́

Ẹ Máa Wá “Òdodo Rẹ̀” Lákọ̀ọ́kọ́

“Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—MÁT. 6:33.

1, 2. Kí ni òdodo Ọlọ́run, kí ló sì dá lé?

 “Ẹ MÁA bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà . . . lákọ̀ọ́kọ́.” (Mát. 6:33) Ìṣílétí yìí tí Jésù Kristi fúnni nínú Ìwàásù Orí Òkè kò ṣàjèjì sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní. Nínú gbogbo ohun tá à ń ṣe nígbèésí ayé wa, a máa ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Ìjọba yẹn àti pé òun la fara mọ́. Àmọ́ a tún gbọ́dọ̀ fi apá kejì ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yẹn sọ́kàn, pé ká máa wá “òdodo rẹ̀.” Kí ni òdodo Ọlọ́run, kí ló sì túmọ̀ sí láti máa wá a lákọ̀ọ́kọ́?

2 Ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a túmọ̀ sí “òdodo” tún lè túmọ̀ sí “àìṣègbè” tàbí “ìdúróṣánṣán.” Torí náà, òdodo Ọlọ́run jẹ́ ìdúróṣánṣán tá a bá fojú àwọn ìlànà rẹ̀ àtàwọn ohun tó kà sí pàtàkì wò ó. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá, Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìlànà tí a ó máa tẹ̀ lé lélẹ̀ fún wa tó bá dọ̀ràn ohun tó dáa àti ohun tí kò dáa, ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. (Ìṣí. 4:11) Àmọ́ ṣá o, òdodo Ọlọ́run kò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run jẹ́ aláìláàánú o, kì í ṣe àwọn òfin má-ṣu-má-tọ̀ tàbí àwọn òfin àti ìlànà gígùn jàǹrànjanran. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dá lórí irú ẹni tí Jèhófà jẹ́ àti ìdájọ́ òdodo rẹ̀ tó jẹ́ ànímọ́ rẹ̀ pàtàkì, àtàwọn ànímọ́ rẹ̀ pàtàkì yòókùbí ìfẹ́, ọgbọ́n àti agbára. Nítorí náà, òdodo Ọlọ́run ní í ṣe pẹ̀lú ìfẹ́-inú Ọlọ́run àti ète rẹ̀. Ó sì tún kan ohun tó ń fẹ́ kí àwọn tó wù láti sin òun máa ṣe.

3. (a) Kí ló túmọ̀ sí láti máa wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́? (b) Kí nìdí tá a fi ń rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà òdodo Jèhófà?

3 Kí ló túmọ̀ sí láti máa wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́? Ní kúkúrú, ó túmọ̀ sí pé ká máa ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́, ká lè múnú rẹ̀ dùn. Wíwá òdodo rẹ̀ gba pé ká máa sapá láti gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ inú Ọlọ́run àti ìlànà pípé rẹ̀ mu, ká má ṣe máa ṣe ìfẹ́ inú ara wa. (Ka Róòmù 12:2.) Gbígbé ìgbé ayé wa lọ́nà yẹn kan àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. Kì í ṣe ọ̀ràn pé ká máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́, torí pé a kò fẹ́ kó fìyà jẹ wá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run ń mú ká ṣe ohun tó fẹ́ nípa títẹ̀lé àwọn ìlànà rẹ̀, ká má sì máa gbé àwọn ìlànà tara wa kalẹ̀. A mọ̀ pé ohun tó tọ́ láti ṣe gan-an nìyẹn, torí pé ó dá wa ká lè máa ṣègbọràn sí òun. Bíi ti Jésù Kristi, Ọba Ìjọba Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ nífẹ̀ẹ́ òdodo.—Héb. 1:8, 9.

4. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì gan-an pé ká máa wá òdodo Ọlọ́run?

4 Báwo ló ti ṣe pàtàkì tó láti máa wá òdodo Jèhófà? Gbé òtítọ́ yìí yẹ̀ wò: Ìdánwò àkọ́kọ́ pàá nínú ọgbà Édẹ́nì dá lórí bóyá Ádámù àti Éfà máa fara mọ́ ẹ̀tọ́ tí Jèhófà ní láti fi ìlànà lélẹ̀ tàbí wọn kò ní fara mọ́ ọn. (Jẹ́n. 2:17; 3:5) Bí wọ́n ṣe kùnà láti fara mọ́ ọn ti mú ìyà àti ikú wá fún àwa àtọmọdọ́mọ wọn. (Róòmù 5:12) Lọ́wọ́ kejì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Ẹni tí ń lépa òdodo àti inú-rere-onífẹ̀ẹ́ yóò rí ìyè, òdodo àti ògo.” (Òwe 21:21) Dájúdájú, tá a bá ń wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́, ó máa jẹ́ ká ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ìyẹn ló sì máa jẹ́ ká rí ìgbàlà.—Róòmù 3:23, 24.

Ewu Tó Wà Nínú Dídi Olódodo Lójú Ara Ẹni

5. Ewu wo la gbọ́dọ̀ yẹra fún?

5 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn Kristẹni tó wà nílùú Róòmù, ó sọ ewu tó yẹ kí gbogbo wa yẹra fún, tá a bá fẹ́ kẹ́sẹ járí nínú wíwá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Júù, ó sọ pé: “Mo jẹ́rìí wọn pé wọ́n ní ìtara fún Ọlọ́run; ṣùgbọ́n kì í ṣe ní ìbámu pẹ̀lú ìmọ̀ pípéye; nítorí, fún ìdí náà pé wọn kò mọ òdodo Ọlọ́run, ṣùgbọ́n tí wọ́n ń wá ọ̀nà láti gbé tiwọn kalẹ̀, wọn kò fi ara wọn sábẹ́ òdodo Ọlọ́run.” (Róòmù 10:2, 3) Bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, àwọn olùjọsìn yẹn kò mọ òdodo Ọlọ́run torí pé bí wọ́n ṣe máa gbé òdodo tara wọn kalẹ̀ ni wọ́n ń lépa. a

6. Ìwà wo ló yẹ ká yẹra fún, kí sì nìdí?

6 Ọ̀kan lára ọ̀nà tá a lè gbà kó sínú ìdẹkùn yìí ni pé ká máa fi iṣẹ́ ìsìn wa sí Ọlọ́run bá ara wa díje, ìyẹn ni pé ká máa fi ara wa wé àwọn ẹlòmíì. Irú ìwà yìí lè mú kéèyàn dẹni tó ń dá ara rẹ̀ lójú jù nípa àwọn ohun tó lè ṣe. Àmọ́, tá a bá ń hùwà lọ́nà yẹn, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ gbàgbé òdodo Jèhófà. (Gál. 6:3, 4) Ohun tó yẹ kó máa mú wa ṣe ohun tó tọ́ ni ìfẹ́ tá a ní fún Jèhófà. Tá a bá gbìyànjú láti fi hàn pé a jẹ́ olódodo, ńṣe ni ìyẹn á fi hàn pé ẹnu lásán la fi ń sọ pé a nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run.—Ka Lúùkù 16:15.

7. Báwo ni Jésù ṣe ṣàlàyé nípa àwọn tó jẹ́ olódodo lójú ara wọn?

7 Jésù sọ nípa àwọn tó “gbẹ́kẹ̀ lé ara wọn pé àwọn jẹ́ olódodo, tí wọ́n sì ka àwọn yòókù sí aláìjámọ́ nǹkan kan.” Ó sọ àpèjúwe kan láti fi ṣàlàyé nípa àwọn tó jẹ́ olódodo lójú ara wọn, ó ní: “Ọkùnrin méjì gòkè lọ sínú tẹ́ńpìlì láti gbàdúrà, ọ̀kan Farisí àti èkejì agbowó orí. Farisí náà dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí gba nǹkan wọ̀nyí ní àdúrà sí ara rẹ̀, ‘Ọlọ́run, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ pé èmi kò rí bí àwọn ènìyàn yòókù, àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà, aláìṣòdodo, panṣágà, tàbí bí agbowó orí yìí pàápàá. Mo ń gbààwẹ̀ lẹ́ẹ̀méjì lọ́sẹ̀, mo ń fúnni ní ìdá mẹ́wàá gbogbo ohun tí mo ní.’ Ṣùgbọ́n agbowó orí tí ó dúró ní òkèèrè kò fẹ́ láti gbé ojú rẹ̀ sókè sí ọ̀run pàápàá, ṣùgbọ́n ó sáà ń lu igẹ̀ rẹ̀ ṣáá, ó ń wí pé, ‘Ọlọ́run, fi oore ọ̀fẹ́ hàn sí èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’” Jésù parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ nípa sísọ pé: “Mo sọ fún yín, Ọkùnrin yìí sọ̀ kalẹ̀ lọ sí ilé rẹ̀ ní ẹni tí a fi hàn ní olódodo ju ọkùnrin yẹn; nítorí pé olúkúlùkù ẹni tí ó bá gbé ara rẹ̀ ga ni a óò tẹ́ lógo, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá rẹ ara rẹ̀ sílẹ̀ ni a óò gbé ga.”—Lúùkù 18:9-14.

Ṣọ́ra fún Ewu Jíjẹ́ “Olódodo Àṣelékè”

8, 9. Kí ló túmọ̀ sí láti jẹ́ “olódodo àṣelékè,” ibo ló sì lè bá wa dé?

8 Ìwé Oníwàásù 7:16 sọ ewu míì tá a tún gbọ́dọ̀ yẹra fún, ó wí pé: “Má di olódodo àṣelékè, tàbí kí o fi ara rẹ hàn ní ẹni tí ó gbọ́n ní àgbọ́njù. Èé ṣe tí ìwọ yóò fi fa ìsọdahoro wá bá ara rẹ?” Ẹni tí Ọlọ́run mí sí láti kọ ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ìdí tó fi yẹ ká yẹra fún ìwà yìí, bá a ṣe rí i ní ẹsẹ 20, ó ní: “Nítorí kò sí olódodo kankan ní ilẹ̀ ayé tí ń ṣe rere tí kì í dẹ́ṣẹ̀.” Ẹni tó di “olódodo àṣelékè” máa ń gbé ìlànà ohun tí ó kà sí òdodo kalẹ̀, á sì máa dá àwọn èèyàn lẹ́jọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìlànà ọ̀hún. Ó sì ti gbàgbé pé, nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ni òun ń gbé ìlànà òun ga ju ti Ọlọ́run lọ, ó sì ń tipa bẹ́ẹ̀ fi ara rẹ̀ hàn ní aláìṣòdodo lójú Ọlọ́run.

9 Jíjẹ́ “olódodo àṣelékè” tàbí “olódodo àṣejù” bí àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì èdè Gẹ̀ẹ́sì kan ṣe sọ, lè mú kéèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàríwísí ọ̀nà tí Jèhófà ń gbà bójú tó àwọn ọ̀ràn. Àmọ́, a gbọ́dọ̀ rántí pé tá a bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àríwísí lórí bóyá Jèhófà ṣègbè tàbí bóyá kò ṣẹ̀tọ́ nínú àwọn ìpinnu rẹ̀, ńṣe là ń tipa bẹ́ẹ̀ gbé ìlànà tá a kà sí òdodo lékè ìlànà Jèhófà. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí a pe Jèhófà lẹ́jọ́, tá a sì wá fi àwọn ìlànà tiwa lórí ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ dá a lẹ́jọ́. Àmọ́ Jèhófà ló lẹ́tọ̀ọ́ láti fi ìlànà òdodo lélẹ̀, kì í ṣe àwa!—Róòmù 14:10.

10. Kí ló lè mú ká dá Ọlọ́run lẹ́jọ́, bí Jóòbù ti ṣe?

10 Lóòótọ́, kò sí ẹni tó máa fẹ́ dá Ọlọ́run lẹ́jọ́ nínú wa, àmọ́ jíjẹ́ tá a jẹ́ aláìpé lè sún wa ṣe é. Èyí lè ṣẹlẹ̀ tá a bá rí ohun kan tá a ronú pé ó jẹ́ ìṣègbè tàbí tí àwa fúnra wa bá rí ìnira. Kódà Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ ṣe irú àṣìṣe yìí. Níbẹ̀rẹ̀, Bíbélì sọ pé Jóòbù jẹ́ “aláìlẹ́bi àti adúróṣánṣán, ó ń bẹ̀rù Ọlọ́run, ó sì ń yà kúrò nínú ohun búburú.” (Jóòbù 1:1) Àmọ́, àwọn àjálù ọ̀kan-ò-jọ̀kan wá kọ lu Jóòbù, ó sì kà á sí ìṣègbè. Èyí mú kí Jóòbù polongo “ọkàn ara rẹ̀ ní olódodo dípò Ọlọ́run.” (Jóòbù 32:1, 2) Ó pọn dandan wàyí kí ẹnì kan pe orí Jóòbù wálé. Torí náà kò yẹ kó yà wá lẹ́nu, tí a bá bá ara wa nínú irú ipò yẹn nígbà míì. Tó bá wá ṣẹlẹ̀, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti pe orí ara wa wálé?

Kì Í Ṣe Gbogbo Ìgbà La Máa Ń Mọ Bí Ọ̀rọ̀ Ṣe Rí

11, 12. (a) Tá a bá rò pé ohun kan jẹ́ ìṣègbè, kí ló yẹ ká rántí? (b) Kí ló lè mú kí ẹnì kan rò pé àkàwé Jésù nípa àwọn tó lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà jẹ́ àpẹẹrẹ ìṣègbè?

11 Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ ká rántí ni pé, kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ Jóòbù gan-an nìyẹn. Kò mọ̀ nípa ìpàdé àwọn ańgẹ́lì tó jẹ́ ọmọ Ọlọ́run tó wáyé lọ́run níbi tí Sátánì ti fẹ̀sùn kàn án. (Jóòbù 1:7-12; 2:1-6) Jóòbù kò mọ̀ pé Sátánì gan-an ló fa ìṣòro òun. Kódà, a kò lè fi gbogbo ẹnu sọ pé Jóòbù tiẹ̀ mọ irú ẹni tí Sátánì jẹ́! Torí náà, ó gbà pé Ọlọ́run ló fa àwọn ìṣòro tí òun ní, bẹ́ẹ̀ ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Dájúdájú, ó rọrùn láti parí èrò síbi tí kò tọ́, tí a kò bá mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí.

12 Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àpèjúwe Jésù nípa àwọn tó lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà. (Ka Mátíù 20:8-16.) Nínú àpèjúwe yẹn, Jésù sọ nípa onílé kan tó san iye owó kan náà fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀, yálà wọ́n ṣiṣẹ́ fún odindi ọjọ́ kan tàbí wákàtí kan péré. Kí lo ti rí ọ̀rọ̀ yẹn sí? Ṣé kò sí ojúsàájú nínú ohun tó ṣe yẹn? Ó ṣeé ṣe kí àánú àwọn òṣìṣẹ́ tó ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀ nínú oòrùn tó mú gan-an ṣe ẹ́. Ó dájú pé ó yẹ kí wọ́n gba owó tó pọ̀! Tó bá jẹ́ ibi tá a parí èrò sí nìyẹn, a lè máa wo onílé yẹn bí aláìláàánú àti aláìṣẹ̀tọ́. Kódà bó ṣe dá àwọn òṣìṣẹ́ tó ṣàròyé lóhùn lè mú kó jọ pé ó ń lo àṣẹ rẹ̀ nílòkulò. Àmọ́, ṣé a mọ gbogbo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí?

13. Báwo la ṣe lè fi ojú míì wo àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa àwọn òṣìṣẹ́ tó lọ ṣiṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà?

13 Ẹ jẹ́ ká ṣe àgbéyẹ̀wò àpèjúwe náà lọ́nà míì. Kò sí iyè méjì pé onílé inú àpèjúwe náà mọ̀ pé gbogbo àwọn ọkùnrin yẹn ló máa gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Nígbà ayé Jésù, owó ojúmọ́ ni wọ́n máa ń san fún àwọn lébìrà. Ohun tí wọ́n bá san fún wọn lọ́jọ́ kan ni àwọn ìdílé wọn gbọ́kàn lé. Pẹ̀lú èyí lọ́kàn, ronú nípa àwọn òṣìṣẹ́ tí onílé náà rí nígbà tí iṣẹ́ ọjọ́ yẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí, tó sì jẹ́ pé iṣẹ́ wákàtí kan péré ni wọ́n ṣe. Owó iṣẹ́ wákàtí kan péré lè máà tó bọ́ ìdílé wọn; síbẹ̀, wọ́n múra tán láti ṣiṣẹ́, wọ́n sì ti ń wáṣẹ́ kiri látàárọ̀. (Mát. 20:1-7) Kì í ṣe ẹ̀bi wọn pé wọn kò gbà wọ́n síṣẹ́ fún odindi ọjọ́ kan. Kò sì sí ẹ̀rí pé ńṣe ni wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ sá fún iṣẹ́. Ká sọ pé o ní láti máa wáṣẹ́ tó o máa ṣe látàárọ̀, tó o sì mọ̀ pé ohun tó o bá mú wálé lo máa fi bọ́ àwọn ìdílé rẹ, ó dájú pé inú rẹ máa dùn tó o bá rí iṣẹ́ ṣe, ó sì máa yà ẹ́ lẹ́nu gan-an tí wọ́n bá fún ẹ lówó tó máa tó ẹ gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ!

14. Ẹ̀kọ́ pàtàkì wo la rí kọ́ látinú àpèjúwe ọgbà àjàrà?

14 Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká wá gbé bí ọ̀ràn náà ṣe rí gan-an yẹ̀ wò. Kò sẹ́ni tí kò gba owó rẹ̀ pé nínú wọn. Kàkà bẹ́ẹ̀, onílé náà hùwà tó fi hàn pé òṣìṣẹ́ kọ̀ọ̀kan ló yẹ kó rí owó táá fi gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Torí pé àwọn òṣìṣẹ́ pọ̀, onílé yìí ì bá ti lo àǹfààní yẹn láti wá àwọn òṣìṣẹ́ tó máa sanwó táṣẹ́rẹ́ fún, àmọ́ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ló san owó tó pọ̀ tó fún tí wọ́n á fi lè bọ́ ìdílé wọn. Tá a bá ronú lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí, ó lè mú ká yí èrò tá a ní nípa ohun tí onílé yẹn ṣe pa dà. Ìfẹ́ ló mú kó ṣe ìpinnu tó ṣe, kì í ṣe pé ó fẹ́ lo àṣẹ tó ní nílòkulò. Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ nínú èyí? Tá a bá kàn ronú lórí díẹ̀ lára ohun tó wáyé, ó lè mú ká parí èrò síbi tí kò tọ́. Láìsí àní-àní, àkàwé yìí jẹ́ ká rí i pé òdodo Ọlọ́run ló tayọ jù lọ, kò sì dá lórí òfin tàbí ìtọ́ni àwọn èèyàn àti pé bóyá wọ́n lẹ́tọ̀ọ́ sí i tàbí pé wọn kò lẹ́tọ̀ọ́ sí i.

Èrò Wa Lè Máà Tọ́ Tàbí Kó Máà Kún Tó

15. Kí nìdí tí èrò tá a ní nípa àìṣègbè fi lè máà tọ́ tàbí kó máà kún tó?

15 Ohun kejì tó yẹ ká rántí nígbà tá a bá ń ronú nípa ọ̀ràn kan tó dà bí ìṣègbè ni pé èrò wa lè máà tọ́ tàbí kó máà kún tó. Àìpé, ẹ̀tanú, tàbí àṣà ìbílẹ̀ lè mú ká ní èrò tí kò tọ́. Èrò wa sì lè máà kún tó torí pé kò ṣeé ṣe fún wa láti fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn. Àmọ́, Jèhófà àti Jésù kò ní irú ìkùdíẹ̀ káàtó yẹn.—Òwe 24:12; Mát. 9:4; Lúùkù 5:22.

16, 17. Kí ló ṣeé ṣe kó fà á tí Jèhófà kò fi pa Dáfídì bí òfin ṣe sọ nígbà tó ṣe panṣágà pẹ̀lú Bátí-ṣébà?

16 Ẹ jẹ́ ká wo bí ẹ̀ṣẹ̀ panṣágà tí Dáfídì dá pẹ̀lú Bátí-ṣébà ṣe rí gan-an. (2 Sám. 11:2-5) Gẹ́gẹ́ bí Òfin Mósè ṣe sọ, ńṣe ló yẹ kí wọ́n pa wọ́n. (Léf. 20:10; Diu. 22:22) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà fìyà jẹ wọ́n, kò pa wọ́n bí òfin ṣe sọ. Ṣé Jèhófà ṣègbè ni? Ṣé ó ṣojúsàájú sí Dáfídì ni, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ tàpá sí ìlànà òdodo ti Òun fúnra rẹ̀? Èrò tí àwọn òǹkàwé Bíbélì kan ní nìyẹn.

17 Àmọ́, àwọn adájọ́ tó jẹ́ aláìpé, tí wọn kò lè rí ohun tó wà lọ́kàn àwọn èèyàn ni Jèhófà fún ní òfin bí wọ́n ṣe máa dájọ́ ẹni tó bá ṣe panṣágà. Láìka kùdìẹ̀-kudiẹ wọn sí, òfin yìí jẹ́ kí wọ́n lè máa ṣe irú ìdájọ́ kan náà fún gbogbo èèyàn. Àmọ́, Jèhófà máa ń rí ohun tó wà lọ́kàn èèyàn. (Jẹ́n. 18:25; 1 Kíró. 29:17) Torí náà, kò yẹ ká retí pé òfin tí Jèhófà ṣe fún àwọn adájọ́ tí wọ́n jẹ́ aláìpé á tún de òun fúnra rẹ̀ tí kò sì ní jẹ́ kó ṣe ohun tó tọ́. Tó bá ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ìyẹn kò ní dà bí ìgbà tá à ń fipá mú ẹnì kan tójú rẹ̀ ríran kedere láti lo ìgò ojú tí wọ́n ṣe láti ṣàtúnṣe ìṣòro ẹni tí ojú rẹ̀ kò ríran dáadáa? Jèhófà lè rí ọkàn Dáfídì àti Bátí-ṣébà, kó sì rí i pé wọ́n ti ronú pìwà dà látọkànwá. Níwọ̀n ìgbà tí Jèhófà mọ àwọn nǹkan yẹn, ó ṣèdájọ́ wọn bó ṣe tọ́, ó fi àánú àti ìfẹ́ hàn sí wọn.

Máa Bá A Nìṣó Ní Wíwá Òdodo Jèhófà

18, 19. Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ tí a kò fi ní máa fi ìlànà àwa èèyàn dá Jèhófà lẹ́jọ́?

18 Nígbà míì tá a bá rí ohun kan tá a lérò pé kò dáa bí Jèhófà ṣe bójú tó o, yálà ńṣe la kà á nínú Bíbélì tàbí kó ṣẹlẹ̀ sí àwa fúnra wa, ẹ má ṣe jẹ́ ká fojú ìlànà tí àwa èèyàn ń tẹ̀ lé nípa òdodo wo ìlànà tí Ọlọ́run lò. Máa rántí pé kì í ṣe gbogbo ìgbà la máa ń mọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gan-an àti pé èrò wa lè máà tọ́ tàbí kó máà kún tó. Má sì ṣe gbàgbé pé “ìrunú ènìyàn kì í ṣiṣẹ́ yọrí sí òdodo Ọlọ́run.” (Ják. 1:19, 20) Lọ́nà yẹn, ọkàn wa kò ní di èyí tó “kún fún ìhónú sí Jèhófà.”—Òwe 19:3.

19 Bíi ti Jésù, ẹ jẹ́ ká gbà pé Jèhófà nìkan ló lẹ́tọ̀ọ́ láti fún wa ní ìlànà lórí ohun tó jẹ́ òdodo, tó sì dára. (Máàkù 10:17, 18) Ẹ jẹ́ ká sapá láti ní “ìmọ̀ pípéye” tàbí “ìmọ otitọ” nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Róòmù 10:2; 2 Tím. 3:7, Bibeli Mimọ) Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, tá a sì ń gbé ìgbé ayé wa lọ́nà tó bá ìfẹ́ Jèhófà mu, a fi hàn pé a ń wá “òdodo rẹ̀” lákọ̀ọ́kọ́.—Mát. 6:33.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bí ọ̀mọ̀wé kan ṣe sọ, ọ̀rọ̀ ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n túmọ̀ sí “gbé kalẹ̀” tún lè túmọ̀ sí ‘láti gbé ère ìrántí kalẹ̀.’ Torí náà, a kúkú lè sọ pé ńṣe làwọn Júù wọ̀nyẹn ń gbé ère ìrántí kan kalẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ fún ìyìn ara wọn, kì í ṣe láti yin Ọlọ́run.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti wá òdodo Jèhófà?

• Ewu méjì wo la ní láti ṣọ́ra fún?

• Báwo la ṣe lè máa wá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ẹ̀kọ́ wo la rí kọ́ látinú àpèjúwe Jésù nípa àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n gbàdúrà nínú tẹ́ńpìlì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ṣé àìṣẹ̀tọ́ ni láti san iye owó kan náà fún àwọn tó ṣiṣẹ́ wákàtí kan àtàwọn tó ṣiṣẹ́ odindi ọjọ́ kan?