Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Fi Ọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ

Fi Ọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ

Ọ̀nà Kẹrin

Fi Ọgbọ́n Yan Àwọn Ọ̀rẹ́ Rẹ

KÍ NI BÍBÉLÌ FI KỌ́NI? “Ẹni tí ó bá ń bá àwọn ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n.”—Òwe 13:20.

KÍ NI ÌṢÒRO NÁÀ? Tó bá dọ̀ràn níní ìtẹ́lọ́rùn, àwọn ọ̀rẹ́ wa lè túbọ̀ ràn wá lọ́wọ́ tàbí kí wọ́n ṣàkóbá fún wa. Èrò wọn àti ohun tí wọ́n ń sọ máa ń nípa lórí ìgbésí ayé wa.—1 Kọ́ríńtì 15:33.

Bí àpẹẹrẹ, ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ọkùnrin méjìlá tí wọ́n dé látibi tí wọ́n ti lọ wo ilẹ̀ Kénáánì. Èyí tó pọ̀ jù lọ lára wọn sì “ń bá a nìṣó ní mímú ìròyìn búburú nípa ilẹ̀ náà tí wọ́n ṣe amí rẹ̀ wá fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.” Àmọ́, méjì lára wọn sọ̀rọ̀ tó dáa nípa ilẹ̀ Kénáánì, wọ́n pè é ní “ilẹ̀ tí ó dára gidigidi.” Ṣùgbọ́n èrò burúkú tí àwọn amí mẹ́wàá yòókù ní tàn kálẹ̀ láàárín àwọn èèyàn náà. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Nígbà náà ni gbogbo àpéjọ náà gbé ohùn wọn sókè,  . . . gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì bẹ̀rẹ̀ sí kùn.”—Númérì 13:30–14:9.

Bákan náà lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn jẹ́ “oníkùnsínú, àwọn olùráhùn nípa ìpín wọn nínú ìgbésí ayé.” (Júúdà 16) Ó máa ṣòro láti jẹ́ onítẹ̀ẹ́lọ́rùn láàárín àwọn ọ̀rẹ́ tí kò ní ìtẹ́lọ́rùn.

KÍ LO LÈ ṢE? Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí ìwọ àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa ń sọ. Ṣé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ sábà máa ń fọ́nnu nípa ohun tí wọ́n ní tàbí wọ́n máa ń ráhùn nípa ohun tí wọ́n kò ní? Irú ọ̀rẹ́ wo lo jẹ́ fún wọn? Ṣé o máa ń mú káwọn ọ̀rẹ́ rẹ máa jowú rẹ tàbí o máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jẹ́ kí ohun tí wọ́n ní tẹ́ wọn lọ́rùn?

Wo àpẹẹrẹ Dáfídì, ẹni tó máa tó di ọba àti àpẹẹrẹ Jónátánì ọmọ Sọ́ọ̀lù Ọba. Dáfídì di ìsáǹsá, ó sì ń gbé ní aginjù. Sọ́ọ̀lù Ọba ń bẹ̀rù Dáfídì, ó sì fẹ́ pa á. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jónátánì ló yẹ kí ọba kàn, síbẹ̀ ó ṣì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ fún Dáfídì. Jónátánì mọ̀ pé Ọlọ́run ti yan Dáfídì láti jẹ ọba lẹ́yìn bàbá òun, síbẹ̀ ó ní ìtẹ́lọ́rùn, ó sì ń ti ọ̀rẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn.—1 Sámúẹ́lì 19:1, 2; 20:30-33; 23:14-18.

Ìwọ náà nílò àwọn ọ̀rẹ́ bí ìyẹn, àwọn ọ̀rẹ́ tó ní ìtẹ́lọ́rùn tí wọ́n sì ń wá ire rẹ. (Òwe 17:17) Àmọ́, kó o tó lè ní irú àwọn ọ̀rẹ́ yẹn, o ní láti ní àwọn ìwà tó dára wọ̀nyẹn.—Fílípì 2:3, 4.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Tó bá dọ̀ràn níní ìtẹ́lọ́rùn, ṣé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ túbọ̀ ń ràn ẹ́ lọ́wọ́ ni àbí wọ́n ń ṣàkóbá fún ẹ?