Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀
Ohun Tó Lè Mú Kí Ìdílé Láyọ̀
Bá Ọmọ Rẹ Sọ̀rọ̀ Nípa Ìbálòpọ̀
Alicia, a ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún sọ pé: “Nígbà míì, mo máa ń fẹ́ mọ nǹkan nípa ìbálòpọ̀, àmọ́, ó máa ń ṣe mí bíi pé tí mo bá béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí mi, wọ́n á rò pé mo ti ń ṣe ohun tí kò dáa.”
Inez, ìyá Alicia sọ pé: “Ì bá wù mí kí n jókòó kí n sì bá ọmọbìnrin mi sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, àmọ́ ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí jù. Ó ṣòro láti mọ ìgbà tí ọwọ́ rẹ̀ dilẹ̀.”
LÓDE òní, ibi gbogbo ni wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Wọ́n máa ń sọ ọ́ lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú ère sinimá, ó sì tún pọ̀ nínú ìpolówó ọjà. Ó jọ pé ibì kan ṣoṣo tí ọ̀rọ̀ náà ṣì jẹ́ èèwọ̀ ni ìgbà tí àwọn òbí àtàwọn ọmọ bá ń sọ̀rọ̀. Ní orílẹ̀-èdè Kánádà, ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́rìndínlógún kan tó ń jẹ́ Michael sọ pé: “Ì bá wù mí káwọn òbí mọ bí ẹ̀rù ṣe máa ń bani tó àti bó ṣe máa ń tini lójú tó láti bá wọn sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Ó rọrùn gan-an láti bá ọ̀rẹ́ ẹni sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”
Lọ́pọ̀ ìgbà, bí kò ṣe rọrùn fún àwọn ọmọ láti dẹ́nu lé ọ̀ràn náà ni kì í rọrùn fún àwọn òbí wọn. Ìwé kan tó sọ nípa bíbá ọmọ ẹni sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, ìyẹn Beyond the Big Talk, èyí tí olùkọ́ nípa ìlera tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Debra W. Haffner kọ, sọ pé: “Ọ̀pọ̀ òbí ti sọ fún mi pé àwọn ra ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ tàbí ìgbà ìbàlágà fún àwọn ọmọ àwọn, wọ́n sì fi àwọn ìwé náà sínú yàrá àwọn ọmọ wọn tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún, wọn kò sì ní bá àwọn ọmọ náà sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ mọ́.” Haffner sọ pé ohun tí wọ́n ń sọ fún àwọn ọmọ náà ni pé: “A fẹ́ kó o mọ̀ nípa ara rẹ àti nípa ìbálòpọ̀, àmọ́ a ò kàn fẹ́ bá ẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ni.”
Tó o bá jẹ́ òbí, ó yẹ kó o ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn. Àní, ó ṣe pàtàkì gan-an pé kó o fúnra rẹ bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Ṣàgbéyẹ̀wò ìdí mẹ́ta tó fi yẹ kó o ṣe bẹ́ẹ̀.
1. Ìbálòpọ̀ ti ré kọjá bá a ṣe mọ̀ ọ́n sí tẹ́lẹ̀. Ọmọ ogún ọdún tó ń jẹ́ James sọ pé, “Kò sí ìtumọ̀ kan ṣoṣo fún ìbálòpọ̀ mọ́, ìyẹn kí ọkọ ba aya rẹ̀ sùn. Àmọ́ nísinsìnyí, ó tún jẹ́ fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì, títi ihò ìdí báni lòpọ̀, ìbálòpọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti fífi ohun tó ń mú ọkàn fà sí ìṣekúṣe ránṣẹ́ lórí ẹ̀rọ.”
2. Ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ rẹ gbọ́ ohun tí kì í ṣòótọ́ nípa ìbálòpọ̀ láti kékeré. Ìyá kan tó ń jẹ́ Sheila sọ pé, “Wọ́n máa gbọ́ nípa ìbálòpọ̀ ní gbàrà tí wọ́n bá ti bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé, wọn kò sì ní mọ ohun tí ìwọ fẹ́ kí wọ́n mọ̀.”
3. Àwọn ọmọ rẹ ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè nípa ìbálòpọ̀ àmọ́ wọ́n lè máà fẹ́ dẹ́nu lé ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ rẹ. Ana ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún láti orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé, “Kí n sòótọ́, mi ò mọ bí mo ṣe lè dá ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ sílẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn òbí mi.”
Ní tòótọ́, bíbá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ jẹ́ ara ojúṣe tí Ọlọ́run gbé fún ẹ gẹ́gẹ́ bí òbí. (Éfésù 6:4) Lóòótọ́, ó lè má rọrùn fún ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ láti bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ yìí. Àmọ́, àǹfààní tó wà níbẹ̀ pọ̀, ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ ló fara mọ́ ohun tí ọmọbìnrin kan tó ń jẹ́ Danielle tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlá sọ, ó ní: “Àwọn òbí wa la fẹ́ kí wọ́n sọ fún wa nípa ìbálòpọ̀, kì í ṣe olùkọ́ kan tàbí ètò orí tẹlifíṣọ̀n kan.” Nígbà náà, báwo lo ṣe máa bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn tí kò rọrùn àmọ́ tó ṣe pàtàkì yìí? b
Kọ́ Wọn Bí Ọjọ́ Orí Wọn Ti Tó
Àwọn ọmọdé máa ń gbọ́ nípa ìbálòpọ̀ láti kékeré, àyàfi tí wọ́n bá ń gbé níbi tí kò sí èèyàn. Kódà ohun tó ń dáyà jáni ni pé, ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí, àwọn èèyàn burúkú ti tẹ̀ síwájú láti inú “búburú sínú búburú jù.” (2 Tímótì 3:1, 13) Ó bani nínú jẹ́ pé àwọn àgbàlagbà ń tan ọ̀pọ̀ ọmọdé jẹ láti bá wọn ṣe ìṣekúṣe.
Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì kó o bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọ rẹ nígbà tọ́jọ́ orí rẹ̀ ṣì kéré gan-an. Ìyá kan láti ilẹ̀ Jámánì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Renate sọ pé, “Tó o bá dúró títí dìgbà tí wọ́n wà ní ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún, wọ́n lè máà fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn fún ẹ mọ́ nítorí wọn kì í fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn wọn tí wọ́n bá ti bàlágà.” Ohun tó ṣe pàtàkì ni pé, kí o kọ́ ọmọ kan bí ọjọ́ orí rẹ̀ ti tó.
Àwọn ọmọ tí kò tíì bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé: Gbájú mọ́ kíkọ́ wọn ní orúkọ tá à ń pe àwọn ẹ̀yà ìbímọ, kí o sì tẹ̀ ẹ́ mọ́ wọn lọ́kàn pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kàn wọ́n. Ìyá kan tó ń jẹ́ Julia láti orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò sọ pé: “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọmọkùnrin mi nígbà tó wà ní ọmọ ọdún mẹ́ta. Ẹ̀rù ń bà mí gan-an ni, nítorí mo mọ̀ pé àwọn olùkọ́, abánitọ́mọ tàbí àwọn ọmọ tí wọ́n ti dàgbà lè fẹ́ fi ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ ṣeré. Ó yẹ kí ó mọ bó ṣe lè dáàbò bo ara rẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àjèjì.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Kọ́ ọmọ rẹ bó ṣe máa dáhùn lọ́nà tó lágbára bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ fi ẹ̀yà ìbímọ rẹ̀ ṣeré. Bí àpẹẹrẹ, o lè kọ́ ọmọ rẹ láti sọ pé: “Rárá o! Màá fẹjọ́ yín sùn!” Fi dá ọmọ rẹ lójú pé sísọ ohun tí ẹni náà ṣe ló dára jù, àní bí ẹni náà bá tiẹ̀ sọ pé òun fẹ́ fún un lẹ́bùn tàbí tó bá halẹ̀ mọ́ ọn. c
Àwọn ọmọ ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀: Lo àǹfààní ọjọ́ orí ọmọ rẹ yìí láti máa fi kún ìmọ̀ rẹ̀ díẹ̀díẹ̀. Bàbá kan tó ń jẹ́ Peter dábàá pé, “Kó o tó bá wọn sọ̀rọ̀, kọ́kọ́ wo ohun tí wọ́n mọ̀ bóyá ó yẹ kí wọ́n mọ̀ sí i. Má ṣe fipá mú wọn sọ̀rọ̀. Tó o bá ti ń lo àkókò láti máa bá wọ́n sọ̀rọ̀ déédéé, ńṣe ni ọ̀rọ̀ náà á kàn wáyé fúnra rẹ̀.”
GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Dípò tí wàá fi sọ gbogbo ọ̀rọ̀ náà lọ́jọ́ kan ṣoṣo, ńṣe ni kó o máa sọ ọ́ díẹ̀díẹ̀. (Diutarónómì 6:6-9) Nípa báyìí, o kò ní fi ọ̀rọ̀ náà sú àwọn ọmọ rẹ. Síwájú sí i, bí wọ́n bá ṣe ń dàgbà, wàá máa fún wọn ní ìsọfúnni tí wọ́n nílò tó bá ọjọ́ orí wọn mu.
Àwọn ọmọ tó ti bàlágà: Ìgbà yìí ló yẹ kó o rí i dájú pé ọmọ rẹ ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó nípa ìbálòpọ̀, ìyẹn bí ìbálòpọ̀ ṣe jẹ́ gan-an, ìmọ̀lára téèyàn máa ń ní nípa rẹ̀ àti irú ìbálòpọ̀ tó dáa àtèyí tí kò dáa. Ana ọmọbìnrin ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé, “Àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin ilé ìwé mi ti ń gbé ara wọn sùn. Mo rò pé gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, ó yẹ kí n ní ìmọ̀ tó pọ̀ tó nípa ọ̀ràn náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í rọrùn láti sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, síbẹ̀, mo gbọ́dọ̀ mọ̀ nípa rẹ̀.” d
Àkíyèsí: Àwọn ọmọ ọdún mẹ́tàlá sí ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún lè máà fẹ́ béèrè ìbéèrè nítorí pé wọ́n máa ń bẹ̀rù pé àwọn òbí àwọn á rò pé àwọn ti ń hùwà burúkú. Èyí ni ohun tí bàbá kan tó ń jẹ́ Steven rí. Ó sọ pé, “Ọmọkùnrin
wa kò fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Àmọ́ nígbà tó yá, a rí ohun tó fà á, èrò rẹ̀ ni pé ńṣe là ń rò pé òun ti ń hùwà burúkú. A jẹ́ kó mọ̀ pé kì í ṣe pé à ń rò pé ó ti ń hùwà tí kò tọ́ la ṣe ń bá a sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Ìdí tá a fi ń bá a sọ̀rọ̀ ni pé, a fẹ́ kó gbára dì láti yẹra fún ìwà burúkú tó ti gbilẹ̀.”GBÌYÀNJÚ ÈYÍ WÒ: Dípò kí o máa bi ọmọ rẹ tó ti bàlágà ní ìbéèrè pàtó kan nípa ìbálòpọ̀, béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ nípa ojú tí ọmọ kíláàsì rẹ̀ fi ń wo ọ̀ràn náà. Bí àpẹẹrẹ, o lè sọ pé: “Ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí rò pé fífi ẹnu lá ẹ̀yà ìbímọ ẹlòmíì kì í ṣe ìbálòpọ̀ gangan. Ṣé bí àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ ṣe rò náà nìyẹn?” Irú àwọn ìbéèrè tí kò lọ tààrà yìí lè mú kí ọmọ rẹ tó ti bàlágà sọ èrò rẹ̀ nípa ìbálòpọ̀.
Bí O Ṣe Lè Borí Ìnira Náà
Lóòótọ́, bíbá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ lè jẹ́ ọ̀kan lára iṣẹ́ tó nira jù lọ fún ẹ gẹ́gẹ́ bí òbí. Àmọ́, ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ìyá kan tó ń jẹ́ Diane sọ pé, “Nígbà tó bá yá, ìnira yẹn á pòórá, lẹ́yìn náà bíbá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ á wá jẹ́ àǹfààní kan tó máa mú kí àjọṣe yín túbọ̀ dára sí i.” Steven tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ tẹ́lẹ̀ gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Tó bá ti jẹ́ àṣà rẹ láti máa sọ̀rọ̀ fàlàlà bí ìjíròrò èyíkéyìí bá wáyé nínú ìdílé rẹ, ó máa rọrùn fún ẹ láti sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀rọ̀ náà kò rọrùn.” Ó fi kún un pé: “Kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ náà á wá rọrùn pátápátá láti máa sọ o, àmọ́ jíjùmọ̀ sọ̀rọ̀ fàlàlà ló ń jẹ́ kí ìdílé Kristẹni wà lálàáfíà.”
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí àwọn orúkọ tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí pa dà.
b Àpilẹ̀kọ yìí á sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kó o bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Àpilẹ̀kọ kejì nínú ọ̀wọ́ yìí á sọ bó o ṣe lè fi ìwà rere kọ́ wọn nígbà tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀.
c Wo ọ̀rọ̀ yìí ní ojú ìwé 171 nínú ìwé Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Olùkọ́ Ńlá Náà. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
d Lo orí 1 sí 5, 28, 29, àti 33 nínú ìwé Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Awọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, láti bá àwọn ọmọ rẹ tó ti bàlágà sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]
BÁWO LO ṢE MÁA DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ . . .
Ka ohun táwọn ọ̀dọ́ sọ kárí ayé, kó o sì ronú lórí bó o ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nísàlẹ̀ yìí.
• “Àwọn òbí mi sọ pé kí n ka àwọn àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, wọ́n sì ní kí n wá bá àwọn tí mo bá ní ìbéèrè èyíkéyìí. Àmọ́ ì bá wù mí kí wọ́n bá mi sọ ohun púpọ̀ sí i nípa ọ̀ràn yìí.”—Ana, orílẹ̀-èdè Brazil.
Kí nìdí tó o fi rò pé, ó ṣe pàtàkì kó o ṣe ju fífún ọmọ rẹ ní ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀?
• “Mo mọ ọ̀pọ̀ ohun tí kò dára nípa ìbálòpọ̀, èyí tí bàbá mi kò mọ ohunkóhun nípa wọn. Àyà rẹ̀ á já gan-an tí mo bá béèrè nípa wọn lọ́wọ́ rẹ̀.”—Ken, orílẹ̀-èdè Kánádà.
Kí lo rò pé ó lè mú kí ẹ̀rù máa ba ọmọ rẹ láti sọ àwọn ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún ẹ?
• “Nígbà tí mo jàjà ní ìgboyà láti béèrè ìbéèrè kan lọ́wọ́ àwọn òbí mi nípa ìbálòpọ̀, wọ́n dáhùn bí ẹní fẹ̀sùn kàn mí pé, ‘Kí ló dé tó o béèrè ìbéèrè yìí? Àbí nǹkan kan ti ṣẹlẹ̀ ni?’”—Masami, orílẹ̀-èdè Japan.
Nígbà tí ọmọ rẹ bá béèrè ohun kan nípa ìbálòpọ̀, báwo ni ìṣarasíhùwà rẹ ṣe lè mú kí ó máa sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tàbí kí ó má ṣe fẹ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ mọ́?
• “Ó máa dára gan-an táwọn òbí mi bá lè fi dá mi lójú pé nígbà táwọn náà wà ní ọjọ́ orí mi, àwọn náà béèrè irú àwọn ìbéèrè yìí àti pé kò burú tí èmi náà bá béèrè ìbéèrè.”—Lisette, orílẹ̀-èdè Faransé.
Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí ara ọmọ rẹ balẹ̀ tí á fi lè máa bá ẹ sọ̀rọ̀ fàlàlà nípa ìbálòpọ̀?
• “Mọ́mì mi máa ń fi ohùn pẹ̀lẹ́ béèrè ìbéèrè tó ní í ṣe pẹ̀lú ìbálòpọ̀ lọ́wọ́ mi. Èrò mi ni pé ó yẹ bẹ́ẹ̀, nítorí ìyẹn ni kò ní jẹ́ kí ọmọ máa rò pé wọ́n ń dá òun lẹ́bi.”—Gerald, orílẹ̀-èdè Faransé.
Irú ohùn wo lo fi ń bá ọmọ rẹ sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀? Ǹjẹ́ o ní láti ṣàtúnṣe lórí ọ̀ràn yìí?