Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Má Ṣe Fàyè Gba Ẹ̀mí Ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Má Ṣe Fàyè Gba Ẹ̀mí Ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́, Ẹ Má Ṣe Fàyè Gba Ẹ̀mí Ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe

‘Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín jẹ́ èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.’—KÓL. 4:6.

1, 2. Ojú wo ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi ń wo dídá yàtọ̀, kí sì nìdí?

 KÒ SÍ iyè méjì pé o ti gbọ́ gbólóhùn náà “ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe” rí àti pé ó ti ṣe ìwọ náà rí bíi pé kó o ṣe ohun táwọn ẹgbẹ́ rẹ ń ṣe. Ó ṣeé ṣe kí ẹnì kan ti rọ̀ ẹ́ pé kó o ṣe ohun kan tó o mọ̀ pé ó lòdì. Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ bí irú rẹ̀ bá wáyé? Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan tó ń jẹ́ Christopher sọ pé: “Nígbà míì ńṣe ló máa ń ṣe mí bíi pé kí n pòórá, láìjẹ́ bẹ́ẹ̀ màá ní láti ṣe ohun táwọn ọmọ iléèwé ẹlẹgbẹ́ mi ń ṣe kí n má bàa dá yàtọ̀.”

2 Ǹjẹ́ ó ń wù ẹ́ láti ṣe ohun tí àwọn ojúgbà rẹ ń fẹ́ kó o ṣe? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kí nìdí? Ṣé ó lè jẹ́ torí pé o fẹ́ kí wọ́n máa gba tìẹ ni? Kì í ṣe pé ó burú pé kó o fẹ́ kí àwọn ojúgbà rẹ gba tìẹ. Ká sòótọ́, àwọn tó ti dàgbà náà ń fẹ́ kí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ẹgbẹ́ gba tiwọn. Kò sí ẹni tó máa ń fẹ́ kí àwọn èèyàn pa òun tì, yálà ó jẹ́ ọ̀dọ́ tàbí àgbàlagbà. Àmọ́ ṣá o, gbogbo ìgbà kọ́ làwọn èèyàn máa gba tìẹ tó o bá dúró lórí òtítọ́. Kódà Jésù náà dojú kọ irú ìṣòro yìí. Ohun tó tọ́ ni Jésù máa ń ṣe nígbà gbogbo. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan ń tẹ̀ lé e, tí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn tó kù tẹ́ńbẹ́lú Ọmọ Ọlọ́run yìí, wọ́n sì “kà á sí aláìjámọ́ nǹkan kan.”—Aísá. 53:3.

Báwo Ni Ẹ̀mí Ṣohun-Tẹ́gbẹ́-Ń-Ṣe Ṣe Lágbára Tó?

3. Kí nìdí tó fi jẹ́ àṣìṣe láti fara mọ́ àwọn ìlànà tí àwọn ojúgbà rẹ ń tẹ̀ lé?

3 Nígbà míì, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé kó o fara mọ́ àwọn ìlànà tí àwọn ojúgbà rẹ ń tẹ̀ lé, kí wọ́n bàa lè máa gba tìẹ. Àṣìṣe nìyẹn máa jẹ́ tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ ‘ìkókó, tí a ń bì kiri gẹ́gẹ́ bí nípasẹ̀ àwọn ìgbì òkun.’ (Éfé. 4:14) Àwọn èèyàn lè tètè nípa lórí àwọn ọmọdé. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, àgbà lò ń dà lọ yẹn. Torí náà, tó o bá gbà pé ire rẹ ni àwọn ìlànà Jèhófà wà fún, ó máa ṣe ẹ́ láǹfààní tó o bá ń gbé ìgbésí ayé rẹ lọ́nà tó bá ohun tó o gbà gbọ́ mu. (Diu. 10:12, 13) Tó o bá ṣe ohun tó yàtọ̀ síyẹn, ohun tó túmọ̀ sí ni pé o fẹ́ kí àwọn ẹlòmíì máa darí ìgbésí ayé rẹ. Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, tó o bá ń ṣe ohun táwọn ẹlòmíì ń fẹ́ kó o máa ṣe, a jẹ́ pé o kò yàtọ̀ sí nǹkan ìṣeré lọ́wọ́ wọn.—Ka 2 Pétérù 2:19.

4, 5. (a) Báwo ni Áárónì ṣe juwọ́ sílẹ̀ láti ṣe ohun táwọn ẹlòmíì fẹ́, ẹ̀kọ́ wo sì nìyẹn kọ́ ẹ? (b) Ọgbọ́n wo ni àwọn ojúgbà rẹ lè dá kó o lè ṣe ohun tí wọ́n fẹ́?

4 Nígbà kan, Áárónì arákùnrin Mósè juwọ́ sílẹ̀ láti ṣe ohun tí àwọn ẹlòmíì fẹ́ kó ṣe. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rọ̀ ọ́ pé kó ṣe òrìṣà fún àwọn, ó gbà láti ṣe é. Kì í ṣe pé Áárónì jẹ́ ojo ló mú kó ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣáájú àkókò yẹn, òun àti Mósè ni wọ́n jọ kojú Fáráò tó jẹ́ ọkùnrin tó lágbára jù lọ ní ilẹ̀ Íjíbítì. Áárónì sì fi ìgboyà jíṣẹ́ tí Ọlọ́run rán wọn fún un. Àmọ́ nígbà tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì fúngun mọ́ Áárónì, ó gbà láti ṣe ohun tí wọ́n fẹ́. Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe mà lágbára gan-an ni o! Ó rọrùn fún Áárónì láti kojú ọba Íjíbítì ju láti kọ ohun tí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè kan náà fẹ́ kó ṣe.—Ẹ́kís. 7:1, 2; 32:1-4.

5 Bí àpẹẹrẹ Áárónì ṣe fi hàn, kì í ṣe àwọn ọ̀dọ́ nìkan ni ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè nípa lé lórí, kì í sì í ṣe ìṣòro kìkì àwọn tó fẹ́ láti ṣe ohun tó burú. Ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè nípa lórí àwọn tó ń wù látọkàn wá láti ṣe ohun tó tọ́, títí kan ìwọ náà. Àwọn ojúgbà rẹ lè gbìyànjú láti mú kó o hùwà àìtọ́, wọ́n lè sọ pé o kò lè ṣe ohun kan, wọ́n lè fẹ̀sùn kàn ẹ́ tàbí kí wọ́n bú ẹ. Ọ̀nà yòówù kí wọ́n gbà yọ sí ẹ, ó máa ń ṣòro láti kọ ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe. Láti lè kẹ́sẹ járí nínú kíkọ ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, ohun tó o gbà gbọ́ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dá ìwọ fúnra rẹ lójú.

“Ẹ Máa Wádìí Ohun Tí Ẹ̀yin Fúnra Yín Jẹ́”

6, 7. (a) Kí nìdí tó fi yẹ kí ohun tó o gbà gbọ́ dá ẹ lójú, báwo lo sì ṣe lè mú kó dá ẹ lójú? (b) Àwọn ìbéèrè wo lo lè bi ara rẹ kí ohun tó o gbà gbọ́ lè túbọ̀ dá ẹ lójú?

6 Kó o tó lè dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, ó gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ dá ìwọ fúnra rẹ lójú pé ohun tó tọ́ lo gbà gbọ́ àti pé ìlànà tó yẹ lò ń tẹ̀ lé. (Ka 2 Kọ́ríńtì 13:5.) Ìdánilójú tó o ní yìí máa jẹ́ kó o ní ìgboyà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó o jẹ́ onítìjú èèyàn. (2 Tím. 1:7, 8) Kódà béèyàn bá jẹ́ onígboyà, ó máa ṣòro fún onítọ̀hún láti ṣe ohun tó tọ́, bí ohun tó gbà gbọ́ kó bá fi bẹ́ẹ̀ dá a lójú. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló dé tí o kò fi mú un dá ara rẹ lójú pé ohun tó o kọ́ nínú Bíbélì gan-an ló jẹ́ òtítọ́? Bẹ̀rẹ̀ látorí àwọn àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, o ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, o sì ti gbọ́ tí àwọn èèyàn ń sọ ìdí tí wọ́n fi gbà gbọ́ pé Ọlọ́run wà. Nígbà náà, bi ara rẹ pé, ‘Kí ló jẹ́ kó dá mi lójú pé Ọlọ́run wà?’ Kì í ṣe nítorí kó o lè wá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe iyè méjì lo ṣe ń bi ara rẹ ní ìbéèrè yìí o, àmọ́ ó jẹ́ láti mú kí ìgbàgbọ́ rẹ lókun. O tún lè bi ara rẹ pé, ‘Báwo ni mo ṣe mọ̀ pé Ìwé Mímọ́ ní ìmísí Ọlọ́run?’ (2 Tím. 3:16) ‘Kí nìdí tó fi dá mi lójú pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí?’ (2 Tím. 3:1-5) ‘Kí ló mú kí n gbà pé àǹfààní mi làwọn ìlànà Jèhófà wà fún?’—Aísá. 48:17, 18.

7 O lè máa lọ́ra láti bi ara rẹ láwọn ìbéèrè wọ̀nyí, torí pé ẹ̀rù ń bà ẹ́ pé o kò ní rí ìdáhùn. Ńṣe ló dà bí ìgbà tó o bá ń lọ́ra láti wo bí èpò tó kù nínú ọkọ̀ rẹ ṣe pọ̀ tó, tí ẹ̀rù sì ń bà ẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí epo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tán nínú táǹkì ọkọ̀ rẹ. Bí kò bá sí epo nínú táǹkì ọkọ̀ rẹ mọ́, ó yẹ kó o mọ̀, kó o lè wá nǹkan ṣe sí i. Bákan náà, ó dára kí ìwọ náà mọ àwọn nǹkan tí kò dá ẹ lójú dáadáa nípa ohun tó o gbà gbọ́, kó o lè ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.—Ìṣe 17:11.

8. Ṣàlàyé bí o ṣe lè túbọ̀ mú kó dá ẹ lójú pé àṣẹ Ọlọ́run tó sọ pé kó o ta kété sí àgbèrè mọ́gbọ́n dání.

8 Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Bíbélì rọ̀ ẹ́ pé kó o “sá fún àgbèrè.” Bi ara rẹ pé, ‘Kí nìdí tí àṣẹ yẹn fi mọ́gbọ́n dání?’ Ronú nípa gbogbo ohun tó mú kí àwọn ojúgbà rẹ máa lọ́wọ́ nínú irú àṣà bẹ́ẹ̀. Tún ronú nípa onírúurú ìdí tí ẹni tó ń ṣe àgbèrè fi ń “ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀.” (1 Kọ́r. 6:18) Ní báyìí, gbé àwọn ìdí náà yẹ̀ wò dáadáa, kó o wá bi ara rẹ pé: ‘Èwo ló dára jù lọ láti tẹ̀ lé nínú méjèèjì? Èrè wo ló tiẹ̀ wà nínú kéèyàn máa lọ́wọ́ nínú ìwà ìṣekúṣe?’ Tún ronú síwájú sí i nípa ọ̀ràn náà, kó o sì bi ara rẹ pé, ‘Báwo ló ṣe máa rí lára mi tí mo bá lọ́wọ́ nínú ìwà ìṣekúṣe?’ Lákòókò yẹn inú àwọn ojúgbà rẹ lè dùn sí ẹ, àmọ́ báwo lọ̀rọ̀ ṣe máa rí lára rẹ nígbà tó o bá wà lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ tàbí tó o bá wà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ Kristẹni? Báwo ni ìmọ̀lára rẹ ṣe máa rí nígbà tó o bá ń gbìyànjú láti gbàdúrà sí Ọlọ́run? Ṣé wàá fẹ́ láti fi àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run tàfàlà nítorí kó o lè tẹ́ àwọn ọmọ kíláàsì rẹ lọ́rùn?

9, 10. Báwo ni dídá tí ohun tó o gbà gbọ́ dá ẹ lójú ṣe lè mú kó o ní ìgboyà nígbà tó o bá wà pẹ̀lú àwọn ojúgbà rẹ?

9 Tó bá jẹ́ pé ńṣe lo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń bàlágà, àkókò yìí jẹ́ àkókò kan nínú ìgbésí ayé rẹ tí “agbára ìmọnúúrò” rẹ á máa pọ̀ sí i ju ti ìgbàkígbà rí lọ. (Ka Róòmù 12:1, 2.) Lo àkókò yìí láti ronú jinlẹ̀ nípa ohun tí jíjẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túmọ̀ sí fún ìwọ fúnra rẹ. Irú àṣàrò bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ kí ohun tó o gbà gbọ́ túbọ̀ dá ẹ lójú. Lẹ́yìn náà, tó o bá wá dojú kọ ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe, wàá lè dáhùn láìjáfara àti pẹ̀lú ìgboyà. Ọ̀rọ̀ rẹ á wá dà bíi ti ọ̀dọ́bìnrin Kristẹni kan, ó sọ pé: “Tí mo bá kọ̀ láti ṣe ohun táwọn ẹgbẹ́ mi ń ṣe, ńṣe ni mò ń jẹ́ kí àwọn ẹlòmíì mọ ẹni tí mo jẹ́. Èyí kì í ṣe ọ̀rọ̀ ‘ẹ̀sìn kan ṣá.’ Orí rẹ̀ ni mo gbé ìrònú, àfojúsùn, ìwà rere àti gbogbo ìgbésí ayé mi kà.”

10 Bẹ́ẹ̀ ni o, ó gba ìsapá láti dúró gbọin-in lórí ohun tó o mọ̀ pé ó tọ́. (Lúùkù 13:24) O sì lè máa wò ó pé ṣé ó tó kó o dúró gbọin-in lórí ohun tó o gbà gbọ́ lóòótọ́? Àmọ́ rántí pé: “Tó o bá ń ṣe kámi-kàmì-kámi tàbí tí ojú ń tì ẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, àwọn míì máa kíyè sí i, wọ́n sì lè túbọ̀ fúngun mọ́ ẹ. Àmọ́, tó o bá sọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú, ó máa yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé kíá làwọn ojúgbà rẹ máa fi ẹ́ sílẹ̀.—Fi wé Lúùkù 4:12, 13.

‘Ṣàṣàrò Kó O Lè Dáhùn’

11. Àǹfààní wo ló wà nínú kó o ti múra sílẹ̀ láti dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?

11 Ohun pàtàkì míì tó o lè ṣe láti dènà ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe ni pé kó o máa wà ní ìmúrasílẹ̀. (Ka Òwe 15:28.) Wíwà ní ìmúrasílẹ̀ gba pé kó o ti ronú ṣáájú nípa ohun tó ṣeé ṣe kó wáyé. Nígbà míì, ìmúrasílẹ̀ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe bọ́ sọ́wọ́ àwọn tó máa gbéjà kò ẹ́. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé o rí àwọn ọmọ ilé ìwé rẹ lọ́ọ̀ọ́kán tí wọ́n kóra jọ, tí wọ́n sì ń fa sìgá. Ǹjẹ́ kò ṣeé ṣe kí wọ́n ní kí ìwọ náà wá mu sìgá? O ti mọ̀ pé ìṣòro nìyẹn jẹ́, kí lo máa wá ṣe? Òwe 22:3 sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà ni ẹni tí ó ti rí ìyọnu àjálù, tí ó sì bẹ̀rẹ̀ sí fi ara rẹ̀ pa mọ́, ṣùgbọ́n aláìní ìrírí gba ibẹ̀ kọjá, yóò sì jìyà àbájáde rẹ̀.” Tó o bá gba ọ̀nà míì, o lè tipa bẹ́ẹ̀ bọ́ lọ́wọ́ wọn. Ìyẹn kì í ṣe ọ̀rọ̀ pé o jẹ́ ojo; ìwà ọgbọ́n ló jẹ́.

12. Báwo lo ṣe lè fèsì nígbà tí àwọn ojúgbà rẹ bá fẹ́ mú ẹ ṣe ohun tí kò tọ́?

12 Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé o kò lè sá fún ìṣòro náà ńkọ́? Ká sọ pé ojúgbà rẹ kan bi ẹ́ pé, “Ṣé òótọ́ ni pé o kò tíì ní ìbálòpọ̀ rí?” Ohun tó o máa ṣe kò ju pé kó o tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Kólósè 4:6, tó sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí àsọjáde yín máa fìgbà gbogbo jẹ́ pẹ̀lú oore ọ̀fẹ́, tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ kí ẹ fi ìdáhùn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan.” Bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yẹn ṣe fi hàn, bí ipò nǹkan bá ṣe rí ló máa pinnu bó o ṣe máa fèsì. Kò ní pọn dandan kó o wá da ìwàásù palẹ̀. Ó ṣeé ṣe kí ìdáhùn ṣókí tó sojú abẹ níkòó ti tó. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá fẹ́ dáhùn ìbéèrè tí ojúgbà rẹ yẹn bi ẹ́, o lè sọ pé, “Rárá mi ò tíì ní ìbálòpọ̀ rí,” tàbí kó o sọ pé, “Ọ̀rọ̀ ara tèmi nìyẹn kò sí èyí tó kàn ẹ́ níbẹ̀.”

13. Kí nìdí tí ìfòyemọ̀ fi ṣe pàtàkì tó o bá fẹ́ fèsì nígbà tí àwọn ojúgbà rẹ bá ń fi ẹ́ ṣe yẹ̀yẹ́?

13 Ìdáhùn ṣókí ni Jésù máa ń fún àwọn èèyàn tó bá ti mọ̀ pé tí òun bá sọ jù bẹ́ẹ̀ lọ, kò sí àǹfààní kankan tó máa tìdí rẹ̀ yọ. Kódà nígbà tí Hẹ́rọ́dù bi í ní ìbéèrè, kò fún un lésì rárá. (Lúùkù 23:8, 9) Nígbà míì ohun tó dáa jù ni pé kéèyàn má ṣe dá àwọn tó béèrè ìbéèrè òmùgọ̀ lóhùn. (Òwe 26:4; Oníw. 3:1, 7) Bí àpẹẹrẹ, ó kàn lè jẹ́ pé ńṣe lẹnì kan fẹ́ mọ ohun tó o gbà gbọ́ lórí ọ̀ràn ìwà ìṣekúṣe, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti lè kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ rẹ láìdáa. (1 Pét. 4:4) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, ó máa dára kó o ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé fún onítọ̀hún nípa ohun tí Bíbélì sọ. Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ má ṣe jẹ́ kí ìbẹ̀rù mú kó o fà sẹ́yìn. Múra tán nígbà gbogbo “láti ṣe ìgbèjà.”—1 Pét. 3:15.

14. Bí ojúgbà rẹ kan bá fẹ́ mú kó o ṣe ohun tí kò dáa báwo lo ṣe lè fọgbọ́n dà á sí i lára?

14 Nínú àwọn ọ̀ràn kan, bí àwọn ojúgbà rẹ bá fẹ́ mú kó o ṣe ohun tí kò dáa, o lè dà á sí wọn lára. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ fọgbọ́n ṣe é. Bí àpẹẹrẹ, bí ẹnì kan tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ọmọléèwé bá sọ pé o kò lè mu sìgá, tó sì sọ pé tó o bá tó bẹ́ẹ̀, ìwọ gbà kó o mú un, o lè sọ pé, “O ṣeun mi ò fẹ́” kó o wá fi kún un pé, “Èmi ò rò pé irú ẹ ló yẹ kó máa mu sìgá!” Ṣé o ti rí bí wàá ṣe dà á sí i lára? Dípò tí wàá fi bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàlàyé ìdí tí o kò fi mu sìgá, ojúgbà rẹ yẹn ló máa bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí ìdí tí òun fi ń mu ún. a

15. Ìgbà wo ló dára jù lọ láti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ojúgbà rẹ tó fẹ́ mú kó o ṣe ohun tí kò tọ́, kí sì nìdí?

15 Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé pẹ̀lú gbogbo ìsapá rẹ, àwọn ojúgbà rẹ ṣì ń fẹ́ kó o ṣe ohun tí wọ́n sọ ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ohun tó dára jù ni pé kó o kúrò láàárín wọn. Bó o bá ṣe pẹ́ tó láàárín wọn bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe máa rọrùn fún ẹ tó láti ṣe ohun tí kò tọ́ láwọn ọ̀nà kan. Torí náà fi ibẹ̀ sílẹ̀. Ìyẹn kò túmọ̀ sí pé wọ́n ti borí rẹ. Ó ṣe tán, ìwọ fúnra rẹ lo pinnu láti kúrò láàárín wọn. O kò jẹ́ kí àwọn ojúgbà rẹ sọ ẹ́ dà bí wọ́n ṣe dà, o sì ṣe ohun tó múnú Jèhófà dùn.—Òwe 27:11.

Ní ‘Ìwéwèé Tó Máa Yọrí sí Àǹfààní’

16. Báwo ni àwọn kan tó sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni ṣe lè fẹ́ kó o ṣe ohun tí kò tọ́?

16 Nígbà míì, àwọn ọ̀dọ́ tó sọ pé àwọn ń sin Jèhófà lè fẹ́ kó o lọ́wọ́ sí àwọn ìgbòkègbodò kan tí kò bójú mu. Bí àpẹẹrẹ, tó bá ṣẹlẹ̀ pé o dé ibi àpèjẹ kan tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ ṣètò tó o sì wá rí i pé kò sí àgbàlagbà kankan níbẹ̀ tó máa bójú tó o ńkọ́? Tó bá sì ṣẹlẹ̀ pé ọ̀dọ́ kan tó pe ara rẹ̀ ní Kristẹni gbé ọtí lílé wá síbi àpèjẹ náà, tó sì jẹ́ pé ìwọ àtàwọn míì tẹ́ ẹ jọ wà níbẹ̀ kò tíì dàgbà tó ẹni tí òfin yọ̀ǹda fún láti mu ọtí ńkọ́? Àwọn ọ̀ràn mélòó kan lè yọjú tó máa gba pé kó o lo ẹ̀rí ọkàn rẹ tó o ti fi Bíbélì kọ́. Kristẹni kan tí kò tíì pé ọmọ ogún ọdún sọ pé: “Èmi àti ẹ̀gbọ́n mi obìnrin kúrò níbi tá a ti lọ wo fíìmù torí pé wọ́n lo èdè rírùn nínú rẹ̀. Àwọn tó kù sì pinnu láti dúró wò ó. Àwọn òbí wa gbóríyìn fún wa nítorí ohun tá a ṣe. Àmọ́, àwọn tó kù bínú sí wa torí pé ohun tá a ṣe mú kí wọ́n dà bí èèyàn burúkú.”

17. Nígbà tó o bá lọ síbi àpèjẹ, kí làwọn ohun tó o lè ṣe kó o lè fi ìlànà Ọlọ́run sílò?

17 Bí ìrírí tá a sọ yìí ṣe fi hàn, títẹ̀lé ẹ̀rí ọkàn rẹ tó o ti fi Bíbélì kọ́ lè mú kí nǹkan ṣòro fún ẹ. Àmọ́, má ṣe fi ohun tó o gbà pé ó tọ́ sílẹ̀. Múra sílẹ̀. Bó o bá fẹ́ lọ sí ibi àpèjẹ, múra bó o ṣe máa kúrò níbẹ̀, tó bá ṣẹlẹ̀ pé nǹkan kò lọ bó o ṣe rò. Àwọn ọ̀dọ́ kan ti ṣètò pé ńṣe làwọn kàn máa fi fóònù pe àwọn òbí àwọn, kí wọ́n lè tètè wá fi mọ́tò gbé àwọn kúrò níbẹ̀. (Sm. 26:4, 5) Irú ìwéwèé bẹ́ẹ̀ “máa ń yọrí sí àǹfààní.”—Òwe 21:5.

“Máa Yọ̀ Nígbà Èwe Rẹ”

18, 19. (a) Kí nìdí tó fi lè dá ẹ lójú pé Jèhófà fẹ́ kó o láyọ̀? (b) Ojú wo ni Ọlọ́run fi ń wo àwọn tí kò gbà láti ṣe ohun tẹ́gbẹ́ ń ṣe?

18 Jèhófà dá ẹ lọ́nà tí wàá fi gbádùn ìgbésí ayé rẹ, ó sì fẹ́ kó o láyọ̀. (Ka Oníwàásù 11:9.) Máa rántí pé ohun tí ọ̀pọ̀ àwọn ojúgbà rẹ ń ṣe jẹ́ “ìgbádùn ẹ̀ṣẹ̀ fún ìgbà díẹ̀.” (Héb. 11:25) Ọlọ́run tòótọ́ fẹ́ kó o ní ohun tó dára fíìfíì ju ìyẹn lọ. Ó fẹ́ kó o máa láyọ̀ títí láé. Torí náà, tó o bá dojú kọ àdánwò láti ṣe ohun tó o mọ̀ pé ó burú lójú Ọlọ́run, rántí pé ní àsẹ̀yìnwá-àsẹ̀yìnbọ̀, ohun tí Jèhófà ní kó o ṣe jẹ́ fún àǹfààní rẹ.

19 Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́, o ní láti mọ̀ pé tó o bá tiẹ̀ rí ojúure àwọn ojúgbà rẹ ní báyìí, lọ́dún mélòó kan sí i, ó ṣeé ṣe kí ọ̀pọ̀ lára wọn má tiẹ̀ rántí orúkọ rẹ mọ́. Ṣùgbọ́n, tí o kò bá jẹ́ kí àwọn ojúgbà rẹ mú kó o ṣe ohun tí kò tọ́, Jèhófà ń kíyè sí i, kò sì ní gbàgbé rẹ tàbí ìṣòtítọ́ rẹ títí láé. Ó máa ‘ṣí ibodè ibú omi ọ̀run fún ẹ, yóò sì tú ìbùkún dà sórí rẹ ní ti tòótọ́ títí kì yóò fi sí àìní mọ́.’ (Mál. 3:10) Síwájú sí i, ó máa fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti fi dí ohun tó o bá ṣaláìní nísinsìnyí. Dájúdájú, Jèhófà lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí àwọn ojúgbà rẹ mú kó o ṣe ohun tí kò tọ́!

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àtẹ ìsọfúnni tí àkòrí rẹ̀ jẹ́ “Mímúra Sílẹ̀ De Ìṣòro” nínú ìwé Àwọn Ìbéèrè Tí Àwọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè—Àwọn Ìdáhùn Tí Ó Gbéṣẹ́, Apá Kejì, ojú ìwé 132 àti 133.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Ipa wo ni ẹ̀mí ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe lè ní lórí ẹni?

• Báwo ni mímọ ohun téèyàn gbà gbọ́ dunjú ṣe lè ranni lọ́wọ́ láti dènà ẹ̀mí-ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?

• Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ láti kojú ẹ̀mí-ṣohun-tẹ́gbẹ́-ń-ṣe?

• Báwo lo ṣe mọ̀ pé Jèhófà mọyì ìṣòtítọ́ rẹ?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

Kí ló mú kí Áárónì gbà láti ṣe ère ọmọ màlúù oníwúrà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Múra sílẹ̀, pinnu ohun tó o máa sọ ṣáájú àkókò