Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Bá Àwọn Tó Wà ní Ọ̀run Sọ̀rọ̀

Bá A Ṣe Lè Bá Àwọn Tó Wà ní Ọ̀run Sọ̀rọ̀

Bá A Ṣe Lè Bá Àwọn Tó Wà ní Ọ̀run Sọ̀rọ̀

ỌLỌ́RUN OLÓDÙMARÈ ti gbé àwọn ojúṣe kan lé àwọn ẹni ẹ̀mí yòókù lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, ó ti gbé àkóso ayé lé Jésù Kristi lọ́wọ́, ó sì yan àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ pé kí wọ́n máa darí iṣẹ́ ìwàásù. (Ìṣípayá 14:6) Àmọ́, ti àdúrà yàtọ̀. Kò gbé gbígbọ́ àdúrà lé ẹnikẹ́ni lọ́wọ́. Ọlọ́run nìkan ṣoṣo la gbọ́dọ̀ máa gbàdúrà sí.

Jèhófà ni “Olùgbọ́ àdúrà.” (Sáàmù 65:2) Ó ń tẹ́tí sí àdúrà wa, ó sì ń dáhùn wọn. Nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù kọ̀wé nípa àdúrà sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ olùjọsìn Jèhófà, ó ní: “Ohun yòówù tí ì báà jẹ́ tí a bá béèrè ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀, [Ọlọ́run] ń gbọ́ tiwa. Síwájú sí i, bí a bá mọ̀ pé ó ń gbọ́ tiwa nípa ohun yòówù tí a ń béèrè, a mọ̀ pé dájúdájú a óò rí àwọn ohun tí a béèrè gbà níwọ̀n bí a ti béèrè wọn lọ́wọ́ rẹ̀.”—1 Jòhánù 5:14, 15.

Àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ kò retí pé ká bá àwọn sọ̀rọ̀ tàbí gbàdúrà sí àwọn. Wọ́n lóye ètò tí Ọlọ́run ṣe lórí ọ̀ràn àdúrà, wọ́n sì fara mọ́ ọn, àwọn náà sì máa ń kópa nínú ètò náà nígbà míì. Lọ́nà wo? Nígbà kan tí wòlíì Dáníẹ́lì gbàdúrà sí Jèhófà nípa ìlú Jerúsálẹ́mù tó ti dahoro, Ọlọ́run dáhùn àdúrà Dáníẹ́lì nípa rírán áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì pé kó lọ sọ ọ̀rọ̀ amọ́kànyọ̀ fún un.—Dáníẹ́lì 9:3, 20-22.

Ṣé Àwọn Òkú Lè Bá Àwọn Alààyè Sọ̀rọ̀?

Ǹjẹ́ ó yẹ ká gbìyànjú láti bá àwọn òkú sọ̀rọ̀? Ọ̀pọ̀ ìtàn ló wà tó sọ pé àwọn èèyàn ti bá àwọn òkú sọ̀rọ̀. Bí àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó jẹ́ aláwo sọ fún obìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Ireland pé, òun bá Fred, ọkọ obìnrin náà sọ̀rọ̀ lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tó wá bá obìnrin náà. Àmọ́, Fred ti kú ní ọ̀sẹ̀ bíi mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn. Obìnrin aláwo náà wá ń sọ ohun tí “Fred” ti sọ nígbà kan, èyí tí ìyàwó rẹ̀ gbà pé òun nìkan lòun mọ̀ nípa ọ̀rọ̀ náà. Ẹ ò rí i pé ó máa rọrùn fún obìnrin yìí láti gbà pé Fred ṣì wà láàyè ní ọ̀run, ó sì fẹ́ máa bá òun sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àjèjì náà. Àmọ́, ńṣe ni irú èrò bẹ́ẹ̀ máa ta ko ohun tó ṣe kedere tí Bíbélì sọ nípa ipò tí àwọn òkú wà.—Wo àpótí tó wà nísàlẹ̀ yìí.

Kí la máa sọ nípa irú àwọn ìtàn yìí? Ohun kan táwọn ẹ̀mí èṣù máa ń lò láti ṣini lọ́nà ni pé, wọ́n máa ń ṣe bí àwọn tó ti kú, bó sì ṣe rí nínú ọ̀ràn Fred nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé, wọ́n fẹ́ mú ọkàn àwọn èèyàn kúrò lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n sì fẹ́ sọ ìgbàgbọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé àwọn èèyàn nínú Jèhófà di èyí tí kò lágbára. Kò sí iyè méjì pé Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà “pẹ̀lú gbogbo iṣẹ́ agbára àti àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn àmì àgbàyanu irọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ẹ̀tàn àìṣòdodo fún àwọn tí ń ṣègbé.”—2 Tẹsalóníkà 2:9, 10.

Òótọ́ ni pé àwọn kan wà tí wọ́n jẹ́ aláwo àtàwọn tó ní àjọṣe pẹ̀lú wọn, tí wọ́n gbà pé àwọn ń bá àwọn òkú sọ̀rọ̀. Àmọ́, tí wọ́n bá tiẹ̀ máa bá nǹkan kan sọ̀rọ̀, àwọn ẹ̀mí tó ń ta ko Jèhófà ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Bákan náà, àwọn kan rò pé Ọlọ́run làwọn ń jọ́sìn, àmọ́ tí wọ́n ti ṣìnà. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ ìkìlọ̀ alágbára yìí pé: “Àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, wọ́n fi ń rúbọ sí àwọn ẹ̀mí èṣù, kì í sì í ṣe sí Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:20, 21.

Níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé a lè gbàdúrà sí Onípò Àjùlọ, tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì ń bójú tó wa, ṣé ó tún yẹ ká gbàdúrà sí ẹlòmíì? Ó ṣe tán, Bíbélì fi ọkàn wa balẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ yìí, ó ní: “Nítorí, ní ti Jèhófà, ojú rẹ̀ ń lọ káàkiri ní gbogbo ilẹ̀ ayé láti fi okun rẹ̀ hàn nítorí àwọn tí ọkàn-àyà wọn pé pérépéré síhà ọ̀dọ̀ rẹ̀.”—2 Kíróníkà 16:9.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 9]

Níwọ̀n bá a ti mọ̀ pé a lè gbàdúrà sí Onípò Àjùlọ, tó nífẹ̀ẹ́ wa tó sì ń bójú tó wa, ṣé ó tún yẹ ká gbàdúrà sí ẹlòmíì?

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Èwo Ni Òtítọ́, Èwo sì Ni Irọ́?

ẸNI GIDI NI SÁTÁNÌ: ÒTÍTỌ́

“Sátánì fúnra rẹ̀ a máa pa ara rẹ̀ dà di áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀.”—2 Kọ́ríńtì 11:14.

“Ẹ pa agbára ìmòye yín mọ́, ẹ máa kíyè sára. Elénìní yín, Èṣù, ń rìn káàkiri bí kìnnìún tí ń ké ramúramù, ó ń wá ọ̀nà láti pani jẹ.”—1 Pétérù 5:8.

“Ẹni tí ń bá a lọ ní dídá ẹ̀ṣẹ̀ pilẹ̀ṣẹ̀ láti ọ̀dọ̀ Èṣù, nítorí Èṣù ti ń dẹ́ṣẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀.”—1 Jòhánù 3:8.

“Nítorí náà, ẹ fi ara yín sábẹ́ Ọlọ́run; ṣùgbọ́n ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.”—Jákọ́bù 4:7.

“Apànìyàn ni [Èṣù] nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀, kò sì dúró ṣinṣin nínú òtítọ́, nítorí pé òtítọ́ kò sí nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń pa irọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìtẹ̀sí-ọkàn ara rẹ̀, nítorí pé òpùrọ́ ni àti baba irọ́.”—Jòhánù 8:44.

Ọ̀RUN NI ÈÈYÀN Ń LỌ LẸ́YÌN IKÚ: IRỌ́

“Inú òógùn ojú rẹ ni ìwọ yóò ti máa jẹ oúnjẹ títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀, nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ jáde. Nítorí ekuru ni ọ́, ìwọ yóò sì padà sí ekuru.”—Jẹ́nẹ́sísì 3:19.

“Nítorí àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5.

“Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é, nítorí pé kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù [sàréè], ibi tí ìwọ ń lọ.”—Oníwàásù 9:10.

“Ẹ̀mí rẹ̀ jáde lọ, ó padà sínú ilẹ̀ rẹ̀; ní ọjọ́ yẹn ni àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.”—Sáàmù 146:4.

ÀWỌN ÁŃGẸ́LÌ OLÓÒÓTỌ́ Ń WÁ IRE WA: ÒTÍTỌ́

“Áńgẹ́lì Jèhófà dó yí àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀ ká, ó sì ń gbà wọ́n sílẹ̀.”—Sáàmù 34:7; 91:11.

“Gbogbo wọn [áńgẹ́lì] kì í ha ṣe ẹ̀mí fún iṣẹ́ ìsìn gbogbo ènìyàn, tí a rán jáde láti ṣe ìránṣẹ́ fún àwọn tí yóò jogún ìgbàlà?”—Hébérù 1:14.

“Mo . . . rí áńgẹ́lì mìíràn tí ń fò ní agbedeméjì ọ̀run, ó sì ní ìhìn rere àìnípẹ̀kun láti polongo gẹ́gẹ́ bí làbárè amúniyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ fún àwọn tí ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà àti ahọ́n àti ènìyàn, ó ń sọ ní ohùn rara pé: ‘Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un.’”—Ìṣípayá 14:6, 7.

JÉSÙ BÁ ỌLỌ́RUN DỌ́GBA: IRỌ́

“Ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi; ẹ̀wẹ̀, orí obìnrin ni ọkùnrin; ẹ̀wẹ̀, orí Kristi ni Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 11:3.

“Ṣùgbọ́n nígbà tí a bá ti fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀ tán, nígbà náà ni Ọmọ fúnra rẹ̀ pẹ̀lú yóò fi ara rẹ̀ sábẹ́ Ẹni tí ó fi ohun gbogbo sábẹ́ rẹ̀, kí Ọlọ́run lè jẹ́ ohun gbogbo fún olúkúlùkù.”—1 Kọ́ríńtì 15:28.

“Lóòótọ́-lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ọmọ kò lè ṣe ẹyọ ohun kan ní àdáṣe ti ara rẹ̀, bí kò ṣe kìkì ohun tí ó rí tí Baba ń ṣe.”—Jòhánù 5:19.