Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ó Mọ Ọkàn-Àyà Ọmọ Aráyé”

“Ó Mọ Ọkàn-Àyà Ọmọ Aráyé”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Ó Mọ Ọkàn-Àyà Ọmọ Aráyé”

2 KÍRÓNÍKÀ 6:29, 30

TA LÓ lè sọ pé àwọn ìpèníjà àti ìṣòro ìgbésí ayé kò kó ìbànújẹ́ bá òun rí? Nígbà míì, ó lè dà bíi pé kò sí ẹni tó lè lóye bí ohun tó ń bá wa fínra ṣe pọ̀ tó tàbí bí ìrora ọkàn wa ṣe pọ̀ tó. Síbẹ̀, ẹnì kan wà tó lóye lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára wa, ẹni náà ni Jèhófà Ọlọ́run. A lè rí ìtùnú gbà látinú ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì sọ ní 2 Kíróníkà 6:29, 30.

Sólómọ́nì gbàdúrà níbi ayẹyẹ ṣíṣí tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù ní ọdún 1026 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nínú àdúrà tí kò ju ìṣẹ́jú mẹ́wàá lọ tí Sólómọ́nì gbà, ó yin Jèhófà Ọlọ́run, ó pè é ní adúróṣinṣin, Ẹni tó ń mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ àti Olùgbọ́ àdúrà.—1 Àwọn Ọba 8:23-53; 2 Kíróníkà 6:14-42.

Sólómọ́nì bẹ Ọlọ́run pé kó gbọ́ àdúrà àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀. (Ẹsẹ 29) Òótọ́ ni pé Sólómọ́nì mẹ́nu kan oríṣiríṣi ìpọ́njú (Ẹsẹ 28), ó tọ́ka sí i pé, olùjọsìn kọ̀ọ̀kan mọ “ìyọnu” àti “ìrora” tirẹ̀. Ohun kan lè máa kó ẹ̀dùn ọkàn bá ẹnì kan, nígbà tí ohun míì sì lè jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún ẹlòmíì.

Èyí tó wù kó jẹ́, àwọn olùbẹ̀rù Ọlọ́run á rí ìrànlọ́wọ́ gbà láti borí ẹ̀dùn ọkàn wọn. Àwọn olùjọ́sìn Ọlọ́run tí wọ́n “tẹ́ àtẹ́lẹwọ́” wọn láti gbàdúrà àtọkànwá sí Jèhófà ni Sólómọ́nì ní lọ́kàn nínú àdúrà rẹ̀. a Ó ṣeé ṣe kí Sólómọ́nì rántí ọ̀rọ̀ Dáfídì baba rẹ̀, lákòókò tí inú Dáfídì bàjẹ́ gidigidi, èyí tó sọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀.”—Sáàmù 55:4, 22.

Báwo ni Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà àtọkànwá tẹ́nì kan gbà fún ìrànlọ́wọ́? Sólómọ́nì fi taratara bẹ Jèhófà pé: “Kí ìwọ alára gbọ́ láti ọ̀run, ibi tí o ń gbé, kí o sì dárí jì, kí o sì fi fún olúkúlùkù ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Ẹsẹ 30) Sólómọ́nì mọ̀ pé, yàtọ̀ sí pé “Olùgbọ́ àdúrà” ń bójú tó àwọn olùjọsìn rẹ̀ lápapọ̀, ó tún ń bójú tó wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. (Sáàmù 65:2) Jèhófà ń pèsè ìrànlọ́wọ́ tó yẹ, títí kan ìdáríjì fún ẹlẹ́ṣẹ̀ tó fẹ́ pa dà sọ́dọ̀ Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀.—2 Kíróníkà 6:36-39.

Kí ló jẹ́ kó dá Sólómọ́nì lójú pé Jèhófà á dáhùn ẹ̀bẹ̀ olùjọsìn kan tó ronú pìwà dà? Bí Sólómọ́nì ti ń bá àdúrà rẹ̀ lọ, ó sọ pé: “Nítorí pé [Jèhófà] mọ ọkàn-àyà rẹ̀ (nítorí ìwọ fúnra rẹ nìkan ṣoṣo ni ó mọ ọkàn-àyà ọmọ aráyé ní àmọ̀dunjú).” Jèhófà mọ ìyọnu tàbí ìrora tó lè jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn fún olóòótọ́ kọ̀ọ̀kan tó ń jọ́sìn rẹ̀, kò sì ní ṣàì bójú tó ẹni náà.—Sáàmù 37:4.

A lè rí ìtùnú gbà nínú àdúrà Sólómọ́nì. Àwọn èèyàn bíi tiwa lè máà lóye “ìyọnu” àti “ìrora” wa lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. (Òwe 14:10) Àmọ́ Jèhófà mọ ọkàn wa, ó sì ń bójú tó wa gan-an. Tá a bá ń gbàdúrà sí i, èyí á mú kó rọrùn fún wa láti máa fara da ẹ̀dùn ọkàn wa. Nítorí Bíbélì sọ pé, Ẹ “kó gbogbo àníyàn yín lé e, nítorí ó bìkítà fún yín.”—1 Pétérù 5:7.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì ‘títẹ́ àtẹ́lẹwọ́,’ jẹ́ àmì pé èèyàn ń gbàdúrà.—2 Kíróníkà 6:13.