Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Inú Mi Dùn Gan-an fún Àǹfààní Yìí”

“Inú Mi Dùn Gan-an fún Àǹfààní Yìí”

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-Èdè Haiti

“Inú Mi Dùn Gan-an fún Àǹfààní Yìí”

LẸ́YÌN ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti ní January 12, ọdún 2010, ó ṣòro fún mi gan-an láti wo àjálù náà nínú ìròyìn. Nígbà tó di ogúnjọ́ oṣù yẹn, ọ̀rẹ́ mi àtàtà tó ń jẹ́ Carmen pè mí, ó ní ká yọ̀ǹda ara wa láti lọ ràn wọ́n lọ́wọ́ ní Haiti. Ọdún mélòó kan sẹ́yìn ni mo ti mọ Carmen nígbà tá a yọ̀ǹda ara wa láti ṣe nọ́ọ̀sì níbi tí wọ́n ti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Látìgbà yẹn ni a ti jọ ń yọ̀ǹda ara wa láti lọ ṣiṣẹ́ láwọn ibòmíì, a sì ti wá di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́.

Mo sọ fún Carmen pé agbára mi kò gbé e láti ṣiṣẹ́ ní Haiti nítorí ohun tí ojú mi máa rí níbẹ̀. Ó rán mi létí pé àwa méjèèjì jọ ṣiṣẹ́ dáadáa nígbà kan, a sì ran ara wa lọ́wọ́. Ọ̀rọ̀ tó sọ yìí mú orí mi yá gágá, ni mo bá pe orílé-iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Brooklyn, New York, mo sì bá ẹni tó ń ṣètò ìrànwọ́ láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fún àwọn tí àjálù bá náà sọ̀rọ̀. Mo ní kó fi orúkọ mi sára àwọn tó fẹ́ yọ̀ǹda ara wọn láti lọ ṣèrànwọ́. Mo dárúkọ Carmen fún un, mo sì sọ pé á wù wá ká jọ ṣiṣẹ́. Ó sọ fún mi pé kò sí ìdánilójú pé wọ́n á pe èmi tàbí òun, bẹ́ẹ̀ sì ni kò dájú pé àwa méjèèjì jọ máa ṣiṣẹ́.

Nítorí náà, mò ń bá ohun tí mò ń ṣe lọ, èrò mi ni pé wọn kò ní pè mí. Ọjọ́ mẹ́rin lẹ́yìn náà, ìyẹn ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tí í ṣe ọjọ́ Monday, wọ́n pè mí láti Brooklyn pé, tó bá ṣeé ṣe, ṣé mo lè lọ sí Haiti lọ́jọ́ kejì? Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí mo gbọ́. Mo ní màá ṣe gbogbo ohun tí mo bá lè ṣe. Lákọ̀ọ́kọ́, mo ṣètò láti gba àyè lẹ́nu iṣẹ́. Lẹ́yìn náà, mo bá Carmen sọ̀rọ̀, ó sọ fún mi pé, wọn kò pe òun nítorí pé òun kò lè sọ èdè Faransé. Inú mi dùn, ẹ̀rù sì tún ń bà mí. Ní January 28, nígbà tí mo jàjà ra tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀ òfuurufú, mo wọ ọkọ̀ òfuurufú láti New York lọ sí Santo Domingo ní ilẹ̀ Dominican Republic, tó bá orílẹ̀-èdè Haiti pààlà.

Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ wá pàdé mi ní pápákọ̀ òfuurufú, ó sì fi ọkọ̀ gbé mi lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílẹ̀ Dominican Republic. Àwọn nọ́ọ̀sì méjì míì láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà dé lọ́jọ́ yẹn, gbogbo wa sì jọ sun inú yàrá kan mọ́jú. Lọ́jọ́ kejì, wọ́n fi ọkọ̀ gbé wa lọ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì Haiti tó wà ní ìlú Port-au-Prince, ó jẹ́ ìrìn àjò wákàtí méje àtààbọ̀.

Lẹ́yìn tá a kọjá lẹ́nu bodè tá a wọ orílẹ̀-èdè Haiti, a rí bí àjálù náà ṣe ba nǹkan jẹ́ lọ rẹpẹtẹ. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láti rí ọṣẹ́ tí ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé fún ìṣẹ́jú àáyá márùndínlógójì [35] ṣe fún ìlú tó jojú ní gbèsè yìí. Ó ṣòro fún mi gan-an láti wo àjálù náà lórí tẹlifíṣọ̀n, àmọ́ fífi ojú ara mi rí i kòrókòró gan-an ló wá burú jù. Ọ̀pọ̀ ilé, títí kan ilé ààrẹ orílẹ̀-èdè náà ló bà jẹ́, nígbà táwọn ilé yòókù sì wó lulẹ̀ bẹẹrẹbẹ. Gbogbo ohun tí àwọn kan rí nídìí iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ṣe nígbèésí ayé wọn ni wọ́n fi kọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé yìí, gbogbo wọn sì pa rẹ́ láàárín ìṣẹ́jú àáyá mélòó kan. Nǹkan tó ń wá sí mi lọ́kàn ṣáá ni pé, kì í ṣe ohun ìní ló ṣe pàtàkì jù láyé yìí.

Nígbà tá a dé ẹ̀ka ilé iṣẹ́ wa tó wà níbẹ̀, bá a ṣe ń rìn wọlé, olùgbàlejò tó wà níbẹ̀ rí wa, ó sì sáré kúrò nídìí tábìlì rẹ̀, ó wá pàdé wa lẹ́nu ọ̀nà, ó sì gbá wa mọ́ra pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ wa fún bá a ṣe pa gbogbo nǹkan tì, tá a sì wá síbẹ̀. Lẹ́yìn oúnjẹ ọ̀sán, a lọ sí Gbọ̀ngàn Àpéjọ tó wà nítòsí, èyí tí wọ́n ti sọ di ilé ìwòsàn. Níbẹ̀, mo pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì tí wọ́n yọ̀ǹda ara wọn láti wá ṣèrànwọ́, títí kan tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ oníṣègùn òyìnbó tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè Jámánì pẹ̀lú olùrànlọ́wọ́ wọn àti agbẹ̀bí kan láti orílẹ̀-èdè Switzerland.

Mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lálẹ́ ọjọ́ yẹn gangan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí tí gbogbo wọ́n jẹ́ méjìdínlógún [18] tí wọ́n fẹ́ gba ìtọ́jú ló wà lórí ibùsùn nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà. Gbogbo wọn làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tá a jẹ́ oníṣègùn òyìnbó bójú tó lọ́nà kan náà, a kò sì gbowó lọ́wọ́ wọn.

Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, bàbá kan tó jẹ́ ẹni ọgọ́rin [80] ọdún kú, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń gba ìtọ́jú. Ìyàwó bàbá náà, èmi àti arábìnrin tá a jọ ń gbé wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ bàbá náà. Lẹ́yìn náà, ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Ketly bẹ̀rẹ̀ sí í kérora. Wọ́n ti gé apá ọ̀tún rẹ̀ nítorí pé ó fi apá náà ṣèṣe nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà wáyé. Obìnrin kan tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń kọ́ Ketly lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé alaalẹ́ ni obìnrin yìí máa ń sùn lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibùsùn Ketly nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà.

Mo lọ sọ́dọ̀ Ketly, láti tù ú lára nítorí ara tó ń rò ó, àmọ́ ìrora náà ju ìrora ti ara lọ. Ó sọ fún mi pé ilé ọ̀rẹ́ òun kan lòun wà nígbà tí ìmìtìtì ilẹ̀ náà ṣẹlẹ̀. Wọn ò mọ ohun náà gan-an tó ń ṣẹlẹ̀. Àwọn méjèèjì di ara wọn lọ́wọ́ mú, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sá lọ sí ọ̀dẹ̀dẹ̀ pẹ̀tẹ́ẹ̀sì náà, àmọ́ ògiri ya lù wọ́n, ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀. Ó pe ọ̀rẹ́ rẹ̀, àmọ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ kò dáhùn. Ó sọ pé, lójú ẹsẹ̀ lòun mọ̀ pé ọ̀rẹ́ òun ti kú. Apá kan ara òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí sùn lé Ketly títí àwọn tó ń yọ èèyàn fi dé lẹ́yìn wákàtí mẹ́rin. Wọ́n gé apá ọ̀tún Ketly títí dé èjìká.

Lálẹ́ ọjọ́ tí mo débẹ̀, gbogbo ìgbà tí Ketly bá ti fẹ́ sùn ló ń rántí ohun tó ṣẹlẹ̀. Pẹ̀lú omijé lójú, ó sọ fún mi pé: “Mo mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa ọjọ́ ìkẹyìn àti ìmìtìtì ilẹ̀. Mo mọ̀ pé a ní ìrètí pé ọjọ́ ọ̀la máa dára. Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n máa dúpẹ́ pé mi ò bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Àmọ́, fi ọ̀rọ̀ mi ro ara rẹ wò fún ìṣẹ́jú kan, pé nǹkan ń lọ fún ẹ bó ṣe yẹ, ṣùgbọ́n lójijì, o wá bá ara rẹ nírú ipò yìí.” Mi ò mọ nǹkan tí ǹ bá ṣe, ńṣe ni mo dì í mú, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. Àwa méjèèjì sì ń sunkún títí tó fi sùn lọ.

Ojoojúmọ́ ni wọ́n máa ń rán dókítà kan àti nọ́ọ̀sì méjì jáde láti lọ ran àwọn tó nílò ìtọ́jú lọ́wọ́. Wọ́n rán mi lọ sí ìlú Petit Goave, ìyẹn sì tó nǹkan bí ìrìn àjò wákàtí méjì ààbọ̀ láti Port-au-Prince téèyàn bá gbé ọkọ̀. Èmi àtàwọn méjì míì táwọn náà yọ̀ǹda ara wọn la lọ, ọ̀kan jẹ́ nọ́ọ̀sì láti ìpínlẹ̀ Florida ti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, èkejì sì jẹ́ oníṣègùn òyìnbó láti ilẹ̀ Faransé. A dé ibẹ̀ ní aago mẹ́sàn-án ààbọ̀ àárọ̀, a já àwọn ẹrù wa sílẹ̀, a sì kó wọn sínú Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ní àdúgbò náà. Wọ́n ti sọ fún àwọn èèyàn pé à ń bọ̀, nítorí náà wọ́n jókòó, wọ́n sì ń retí wa.

A bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Kò rọrùn rárá, ńṣe ni iye àwọn èèyàn tí wọ́n nílò ìtọ́jú tí wọ́n wà lórí ìlà ń pọ̀ sí i. Nǹkan bí aago mẹ́ta ọ̀sán la tó ráyè sinmi díẹ̀. Àwa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta fún àwọn èèyàn ní abẹ́rẹ́ àjẹsára àádọ́fà ó lé mẹ́rin [114], a sì ṣàyẹ̀wò ìlera èèyàn márùnlélọ́gọ́rùn-ún [105]. Ó rẹ̀ mí, àmọ́ a láyọ̀ pé a lè ṣèrànwọ́ fún àwọn èèyàn.

Mo lo ohun tó lé díẹ̀ ní ọ̀sẹ̀ méjì ní Haiti láti ṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù bá. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé alaalẹ́ ni mo máa ń ṣe iṣẹ́ fún wákàtí méjìlá nínú Gbọ̀ngàn Àpéjọ náà. Iṣẹ́ ńlá ni, mi ò sì tíì ṣe irú rẹ̀ rí. Inú mi dùn gan-an pé mo ní àǹfààní láti wá síbí yìí. Inú mi dùn gan-an pé mo lè mú ìtura bá àwọn èèyàn Haiti tí àjálù bá.

Ọ̀pọ̀ nǹkan la kọ́ lára wọn. Bí àpẹẹrẹ, ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tó ń jẹ́ Eliser wà lára àwọn tí mo tọ́jú, wọ́n ti gé ọ̀kan lára ẹsẹ̀ rẹ̀. Mo kíyè sí i pé ó máa ń tọ́jú oúnjẹ rẹ̀ pa mọ́, á sì fún Jimmy lára oúnjẹ náà, ẹ̀gbẹ́ ibùsùn rẹ̀ ni Jimmy ń sùn. Ó ṣàlàyé fún mi pé, Jimmy máa ń wá sọ́dọ̀ òun ní alaalẹ́, kì í sì í sábà rí oúnjẹ jẹ kó tó wá. Ohun tí mo rí kọ́ lára Eliser túbọ̀ jẹ́ kó yé mi pé, kò dìgbà téèyàn bá lówó rẹpẹtẹ tàbí tí ara èèyàn bá le kéèyàn tó lè fún àwọn èèyàn ní nǹkan.

Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn tá a jọ ṣiṣẹ́ náà ní irú ẹ̀mí tó dáa yìí. Ara obìnrin kan nínú wa kò yá, ẹlòmíì sì wà tí ẹ̀yìn ń ro. Àmọ́, gbogbo wọn ló bójú tó àwọn tó ń gba ìtọ́jú láìka ohun tó ń dààmú àwọn fúnra wọn sí. Èyí fún mi ní ìṣírí tí mo nílò láti máa bá iṣẹ́ náà nìṣó. Gbogbo wa ló máa ń rẹ̀, tí ìrònú wa kì í já gaara, tí a sì máa ń ní ẹ̀dùn ọkàn, àmọ́, a máa ń ran ara wa lọ́wọ́, a sì ń bá iṣẹ́ náà nìṣó. Mi ò lè gbà gbé ìrírí tí mo ní yìí! Mo dúpẹ́ pé mo wà lára àwọn Kristẹni tí wọ́n wà nínú ètò Ọlọ́run, tí àwọn èèyàn ibẹ̀ jẹ́ aláàánú, onífẹ̀ẹ́, tí wọ́n sì ń lo ara wọn fún àwọn ẹlòmíì.

Kí n tó kúrò ní Haiti, méjì lára àwọn tó ń gba ìtọ́jú tí wọ́n ti gé apá ọ̀tún wọn gbìyànjú láti kọ lẹ́tà “o ṣeun,” wọ́n sì tẹnu mọ́ ọn fún mi pé, tí n bá ti wà nínú ọkọ̀ òfuurufú ni kí n tó kà wọ́n. Ohun tí mo sì ṣe nìyẹn. Àwọn lẹ́tà náà wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin, ńṣe ni mo bẹ̀rẹ̀ sí í da omi lójú.

Láti ìgbà tí mo ti pa dà délé ni mo ti ń bá àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ mi tuntun tí mo pàdé ní Haiti sọ̀rọ̀. A ti di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ a sì ti dúró ti ara wa gbágbáágbá lákòókò ìṣòro àti àjálù náà. Ó dá mi lójú pé, ìṣòro èyíkéyìí tí ì báà wáyé lọ́jọ́ iwájú kò lè ba àjọṣe tímọ́tímọ́ tá a ní yìí jẹ́. Inú mi dùn gan-an fún àǹfààní yìí.