Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èèyàn Kì Í Dàgbà Jù Láti Sin Ọlọ́run

Èèyàn Kì Í Dàgbà Jù Láti Sin Ọlọ́run

Èèyàn Kì Í Dàgbà Jù Láti Sin Ọlọ́run

Ní ìlú Málaga, lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Sípéènì, màmá kan àti ọmọ rẹ̀ obìnrin tí àwọn méjèèjì ń jẹ́ Ana, ṣe ìrìbọmi ní December 19, ọdún 2009. Wọ́n wà lára egbèjìlá ó dín méjìdínláàádọ́ta [2,352] èèyàn tó ṣe ìrìbọmi lórílẹ̀-èdè Sípéènì lọ́dún 2009. Àmọ́ ohun kan wà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nípa màmá yìí àti ọmọ rẹ̀, ìyẹn ni ọjọ́ orí wọn. Ìyá jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́fà [107], ọmọ sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83]!

Kí ló mú kí wọ́n ṣe ìrìbọmi láti fi hàn pé àwọn ti ya ara àwọn sí mímọ́ fún Jèhófà? Láàárín ọdún 1970 sí ọdún 1974, arábìnrin kan tó ń gbé àdúgbò kan náà pẹ̀lú Ana, tó jẹ́ ọmọ màmá yẹn, máa ń pè é sí ìpàdé Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ìwé Ìjọ tí wọ́n ń ṣe ní ilé Ẹlẹ́rìí kan. Ó sábà máa ń lọ sí ìpàdé náà. Àmọ́, iṣẹ́ tó ń ṣe kò jẹ́ kó lè tẹ̀ síwájú.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà, a rí lára àwọn ọmọ Ana tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì di ìránṣẹ́ Jèhófà. Ọ̀kan lára wọn tó ń jẹ́ Mari Carmen, ta ìfẹ́ tí màmá rẹ̀ ní fún òtítọ́ Bíbélì jí, ó sì ràn án lọ́wọ́ láti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tó yá ìyà wọn àgbà, ìyẹn Ana àgbà náà bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ èèyàn mẹ́wàá ló ṣe ìrìbọmi nínú ìdílé yìí.

Ìdùnnú ṣubú layọ̀ fún ìyá àtọmọ yìí, ìyẹn àwọn Ana méjèèjì, lọ́jọ́ tí wọ́n ṣe ìrìbọmi. Ana àgbà, tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàdínláàádọ́fà sọ pé: “Oore tí Jèhófà ṣe fún mi mà pọ̀ o, ó ti jẹ́ kí n mọ òun.” Ana kékeré sọ pé: “Mo fẹ́ sin Jèhófà kí Párádísè tó dé, kí n máa ṣe ìfẹ́ rẹ̀, kí n sì máa wàásù ìhìn rere débi tí mo bá lè ṣé e dé.”

Ohun tó ń fún àwọn opó méjèèjì yìí láyọ̀ jù lọ ni wíwá sí àwọn ìpàdé. Ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ wọn sọ pé: “Wọn kì í pa ìpàdé jẹ rárá. Wọ́n sì máa ń múra tán láti dáhùn nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́.

Àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ wọn mú wa rántí opó kan nínú Bíbélì tó ń jẹ́ Ánà, ẹni “tí kì í pa wíwà ní tẹ́ńpìlì jẹ, tí ń ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ lóru àti lọ́sàn-án pẹ̀lú ààwẹ̀ àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀.” Èyí ló mú kó láǹfààní láti rí ọmọ jòjòló náà Jésù nígbà tí wọ́n bí i. (Lúùkù 2:36-38) Nígbà tí Ánà wà lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlélọ́gọ́rin [84], kò sọ pé òun ti dàgbà jù láti sin Jèhófà, bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn olóókọ rẹ̀ lóde òní.

Ǹjẹ́ o ní àwọn mọ̀lẹ́bí tí wọ́n múra tán láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Bíbélì? Àbí o ti bá arúgbó kan tó fẹ́ láti gbọ́ ohun tó o fẹ́ sọ pàdé nígbà tó o wàásù dé ilé rẹ̀? Ọ̀rọ̀ irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lè jọ ti àwọn Ana méjèèjì tá a sọ ìrírí wọn yìí, torí pé èèyàn kì í dàgbà jù láti bẹ̀rẹ̀ sí í sin Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

“Oore tí Jèhófà ṣe fún mi mà pọ̀ o”

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 25]

“Mo fẹ́ sin Jèhófà kí Párádísè tó dé”