Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ jíròrò àwọn ìdáhùn náà.

1. Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Kó O Kẹ́kọ̀ọ́ Lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Ọlọ́run ní ìròyìn ayọ̀ nípa àwọn ohun tó dára fún aráyé. Ó sọ fún wa nípa rẹ̀ nínú Bíbélì. Bíbélì dà bíi lẹ́tà láti ọ̀dọ́ Bàbá wa onífẹ̀ẹ́ tó wà lọ́run.—Ka Jeremáyà 29:11.

2. Kí ni ìròyìn ayọ̀ náà?

Aráyé nílò ìjọba rere. Kò tíì sí ìjọba èèyàn tó tíì mú ìwà ipá, ìwà ìrẹ́jẹ, àìsàn tàbí ikú kúrò. Àmọ́ ìròyìn ayọ̀ wà. Ọlọ́run máa fún aráyé ní ìjọba rere tó máa mú káwọn èèyàn bọ́ lọ́wọ́ ìyà.—Ka Dáníẹ́lì 2:44.

3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run?

Láìpẹ́, Ọlọ́run máa pa àwọn tó ń fa ìyà fún àwọn èèyàn run. Àmọ́ ní báyìí, ó ń kọ́ ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ọlọ́kàn tútù lẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n lè máa fi ìfẹ́ gbádùn ìgbésí ayé aláyọ̀. Àwọn èèyàn ń kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí wọ́n lè mọ bí wọ́n ṣe máa fara da ìṣòro ìgbésí ayé, bí wọ́n ṣe lè rí ayọ̀ tòótọ́ àti bí wọ́n ṣe lè wu Ọlọ́run.—Ka Sefanáyà 2:3.

4. Ọ̀dọ̀ ta ni Bíbélì ti wá?

Ìwé kéékèèké mẹ́rìndínláàádọ́rin [66] ló para pọ̀ di Bíbélì. Àwọn ogójì ọkùnrin ló kọ ọ́. Mósè ló kọ ìwé márùn-ún àkọ́kọ́ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọdún [3,500] sẹ́yìn. Àpọ́sítélì Jòhánù ló kọ èyí tó kẹ́yìn ní ohun tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀wá [1,900] ọdún sẹ́yìn. Àmọ́, èrò Ọlọ́run làwọn òǹkọ̀wé Bíbélì kọ, kì í ṣe èrò tara wọn. Nítorí náà, ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá.—Ka 2 Tímótì 3:16; 2 Pétérù 1:21.

A mọ̀ pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì ti wá nítorí pé ó sọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ nípa ọjọ́ ọ̀la. Kò sí ẹ̀dá èèyàn tó lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Aísáyà 46:9, 10) Bíbélì tún sọ àwọn ànímọ́ onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní. Bíbélì lágbára láti yí ìgbésí ayé èèyàn pa dà sí rere. Òtítọ́ yìí mú kó dá ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lójú pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì.—Ka Jóṣúà 23:14; 1 Tẹsalóníkà 2:13.

5. Báwo lo ṣe lè lóye Bíbélì?

Àwọn èèyàn níbi gbogbo mọ Jésù sí olùkọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn tó bá sọ̀rọ̀ ló mọ Bíbélì, àmọ́ wọ́n nílò ẹni tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye rẹ̀. Kí Jésù lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ó tọ́ka sáwọn ẹsẹ Bíbélì lóríṣiríṣi, ó sì ṣàlàyé “ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́” fún wọn. Àpilẹ̀kọ yìí tá a pè ní, “Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run,” náà yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ lọ́nà kan náà.—Ka Lúùkù 24:27, 45.

Ṣàṣà lohun tó dára tó kéèyàn kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípa ìdí tá a fi wà láàyè. Àmọ́, inú àwọn èèyàn kan lè má dùn torí pé ò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Má ṣe jẹ́ kí ìyẹn kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá ẹ. Tó o bá fẹ́ wà láàyè títí láé, o ní láti mọ Ọlọ́run.—Ka Mátíù 5:10-12; Jòhánù 17:3.

Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, ka orí 2 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.