Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Wà?

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Wà?

Ṣé Òótọ́ Ni Pé Ọgbà Édẹ́nì Wà?

ṢÉ O mọ ìtàn Ádámù àti Éfà àti ti ọgbà Édẹ́nì? Kárí ayé ni àwọn èèyàn ti mọ ìtàn yìí. O ò ṣe ka ìtàn náà fúnra rẹ? Ó wà ní Jẹ́nẹ́sísì 1:26–3:24. Àwọn kókó inú ìtàn náà nìyí:

Jèhófà Ọlọ́run * dá ọkùnrin kan látinú erùpẹ̀, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Ádámù, ó sì fi í sínú ọgbà kan ní àgbègbè kan tó pè ní Édẹ́nì. Ọlọ́run fúnra rẹ̀ ló gbin ọgbà náà. Ọgbà náà máa ń rí omi dáadáa, àwọn igi ẹlẹ́wà tí wọ́n ń so èso pọ̀ níbẹ̀. “Igi ìmọ̀ rere àti búburú” sì wà láàárín ọgbà náà. Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn kò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi yìí, ó ní tí wọ́n bá ṣàìgbọràn, ikú ló máa yọrí sí. Nígbà tó yá, Jèhófà fi ọ̀kan lára egungun ìhà Ádámù dá Éfà láti jẹ́ ìyàwó rẹ̀. Ọlọ́run ní kí wọ́n máa bójú tó ọgbà náà, ó ní kí wọ́n bímọ kí wọ́n di púpọ̀ kí wọ́n sì kún ilẹ̀ ayé.

Nígbà tí Éfà wà lóun nìkan, ejò kan bá a sọ̀rọ̀, ó tàn án pé kó jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ, ó sọ fún un pé, ńṣe ni Ọlọ́run ń parọ́ fún un àti pé Ọlọ́run ń fawọ́ àwọn ohun rere kan sẹ́yìn lọ́dọ̀ Éfà, ìyẹn àwọn ohun tó máa jẹ́ kó dà bí Ọlọ́run. Ó gba ejò náà gbọ́, ó sì jẹ èso tí Ọlọ́run sọ pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ. Nígbà tó yá, Ádámù náà bá ìyàwó rẹ̀ lọ́wọ́ sí ṣíṣe àìgbọràn sí Ọlọ́run. Lẹ́yìn náà, Jèhófà ṣèdájọ́ Ádámù, Éfà àti ejò náà. Ọlọ́run sì lé àwọn ẹ̀dá èèyàn náà kúrò ní ọgbà Párádísè, àwọn áńgẹ́lì sì dí ọ̀nà ibẹ̀.

Tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé, olóye àtàwọn òpìtàn gbà pé ìtàn gidi ni ìtàn tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì inú Bíbélì, ó sì jẹ́ òótọ́. Àmọ́ lóde òní, ńṣe làwọn èèyàn wá ń ṣe iyè méjì nípa àwọn ìtàn náà. Kí wá nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe iyè méjì nípa ìtàn tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ nípa Ádámù àti Éfà àti ọgbà Édẹ́nì? Jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ohun mẹ́rin tó mú káwọn èèyàn máa ṣe iyè méjì.

1. Ṣé ibì kan wà tó ń jẹ́ ọgbà Édẹ́nì lóòtọ́?

Kí nìdí táwọn èèyàn fi ń ṣe iyè méjì lórí ọ̀ràn yìí? Ó lè jẹ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí ló ṣàkóbá fún wọn. Ó ti pẹ́ gan-an tí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ti ń sọ pé, ó ṣeé ṣe kí ọgbà tí Ọlọ́run gbìn yìí ṣì wà níbì kan. Àmọ́, èrò àwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì bíi Plato àti Aristotle, tí wọ́n gbà pé kò sí ohun tó lè jẹ́ pípé lórí ilẹ̀ ayé ló ṣàkóbá fún àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì. Wọ́n ní, ọ̀run nìkan ni ohun pípé lè wà. Ìyẹn ló mú kí àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn parí èrò sí pé, ibì kan tó sún mọ́ ọ̀run ni Párádísè ìbẹ̀rẹ̀ náà wà. * Àwọn kan sọ pé orí òkè kan tó ga gan-an ni ọgbà náà wà, tí ayé ẹlẹ́ṣẹ̀ yìí kò fi lè kó ẹ̀gbin bá a, àwọn míì sọ pé, ọgbà náà wà ní ìhà Ìpẹ̀kun Àríwá ayé tàbí ìhà Ìpẹ̀kun Gúúsù ayé, àwọn míì tún sọ pé, orí òṣùpá tàbí ìtòsí rẹ̀ ni ọgbà náà wà. Abájọ táwọn èèyàn fi ń wo ìtàn nípa ọgbà Édẹ́nì bí ìtàn àròsọ. Ọ̀rọ̀ tí kò mọ́gbọ́n dání láwọn ọ̀mọ̀wé kan lóde òní ka ọ̀rọ̀ nípa Édẹ́nì sí, wọ́n sọ pé kò sí ibì kankan tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.

Àmọ́, Bíbélì kò sọ̀rọ̀ nípa ọgbà náà lọ́nà yẹn. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì 2:8-14, jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan pàtàkì mélòó kan nípa ọgbà náà. Apá ìlà oòrùn agbègbè kan tó ń jẹ́ Édẹ́nì ló wà. Ọgbà náà máa ń rí omi dáadáa látinú odò kan ṣoṣo tó wá di orísun odò mẹ́rin. Ọ̀kọ̀ọ̀kan odò mẹ́rin yìí ló ní orúkọ àti àlàyé ṣókí nípa ibi tó gbà kọjá. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí ti ṣe kóríyá gan-an fún àwọn ọ̀mọ̀wé, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ti kẹ́kọ̀ọ́ apá Bíbélì yìí dáadáa kí wọ́n lè rí atọ́nà tí wọ́n á fi ṣàwárí ọ̀gangan ibi tí Édẹ́nì wà lóde òní. Àmọ́, lẹ́yìn ìwádìí wọn, oríṣiríṣi èrò tó ta kora ni wọ́n ní nípa ọ̀ràn náà. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé, irọ́ ni ibi tí Bíbélì sọ pé Édẹ́nì wà àti ibi tí ọ̀gbà náà àtàwọn odò mẹ́rin náà wà?

Rò ó wò náà, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ọdún sẹ́yìn làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì ṣẹlẹ̀. Ẹ̀rí fi hàn pé Mósè ló ṣàkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ látinú àwọn ìtàn àtẹnudẹ́nu tàbí àwọn àkọsílẹ̀ tó wà ṣáájú ìgbà yẹn ló ti ṣàkójọ ohun tó kọ. Síbẹ̀, lẹ́yìn nǹkan bí ẹgbẹ̀tàlá ó dín ọgọ́rùn-ún [2,500] ọdún táwọn ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé ni Mósè tó kọ wọ́n sílẹ̀. Lákòókò yẹn, ìtàn Édẹ́nì ti di ìtàn tó ti pẹ́. Nítorí náà, ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe kí àwọn odò téèyàn lè fi ṣàpèjúwe ibi tí ọgbà náà wà ti yí pa dà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún? Ojú ilẹ̀ lè yí pa dà nígbàkigbà. Àgbègbè ibi tó jọ pé Édẹ́nì wà jẹ́ ara ibi tí ìmìtìtì ilẹ̀ ti máa ń ṣẹlẹ̀ jù lọ láyé, ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé níbẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ìdá kan nínú márùn-ún nínú àwọn èyí tó lágbára jù lọ láyé. Nítorí náà, ìyípadà lè ṣẹlẹ̀ nígbàkigbà nírú agbègbè yìí. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, Ìkún Omi ọjọ́ Nóà lè ti mú àyípadà bá bí ojú ilẹ̀ ṣe rí, tí a kò fi ní lè dá ibẹ̀ mọ̀ mọ́ lóde òní. *

Àmọ́, àwọn nǹkan díẹ̀ tá a mọ̀ nìyí: Àkọsílẹ̀ ìtàn inú Jẹ́nẹ́sísì sọ pé ọgbà náà wà lóòótọ́. Méjì lára àwọn odò mẹ́rin tá a dárúkọ nínú ìtàn náà, ìyẹn odò Yúfírétì àti Tígírísì tàbí Hídẹ́kẹ́lì ṣì wà títí dòní, díẹ̀ lára orísun wọn sún mọ́ra gan-an. Ìtàn náà tiẹ̀ sọ orúkọ àwọn ilẹ̀ tí àwọn odò náà ṣàn gbà kọjá, ó sì sọ àwọn ohun àmúṣọrọ̀ tó wà nínú ilẹ̀ ibẹ̀. Lójú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́, ìyẹn àwọn tí wọ́n kọ́kọ́ ka àkọsílẹ̀ ìtàn yìí, àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ yìí kún fún ẹ̀kọ́.

Ṣé ìtàn àròsọ àti àlọ́ máa ń rí báyìí? Àbí kì í ṣe pé ńṣe ni wọ́n máa ń sọ àwọn ohun pàtàkì nù, èyí téèyàn lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó jóòótọ́ tàbí pé ó jẹ́ irọ́? Bí wọ́n ṣe máa ń bẹ̀rẹ̀ ìtàn àròsọ nìyí: “Nígbà láéláé, ìlú kan wà.” Àmọ́, ìtàn tòótọ́ máa ń ní àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tó ṣe pàtàkì, gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ìtàn nípa Édẹ́nì.

2. Ṣé òótọ́ ni pé Ọlọ́run fi erùpẹ̀ dá Ádámù tó sì fi ọ̀kan lára egungun ìhà Ádámù dá Éfà?

Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lóde òní ti ṣàwárí pé, oríṣiríṣi èròjà inú ilẹ̀, àwọn bíi hydrogen, oxygen àti carbon ló wà nínú ara èèyàn. Àmọ́ báwo làwọn èròjà inú ilẹ̀ yìí ṣe dénú ara èèyàn?

Ọ̀pọ̀ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì sọ pé ìwàláàyè ṣàdédé wà fúnra rẹ̀ ni, pé ó bẹ̀rẹ̀ látorí ohun kékeré kan tí kò díjú, tó sì wá di ohun tó túbọ̀ díjú gan-an lẹ́yìn ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù ọdún. Àmọ́, gbólóhùn náà, “ohun tí kò díjú” kò jẹ́ kéèyàn mọ òótọ́ ọ̀rọ̀ náà, nítorí pé gbogbo ohun alààyè, títí kan ohun tínńtín kan tí a kò lè fojú rí ló díjú gan-an. Kò sí ẹ̀rí pé ohun alààyè èyíkéyìí ti ṣàdédé wà fúnra rẹ̀ rí tàbí pé ó lè wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀rí tí kò láṣìṣe ló wà pé gbogbo ohun alààyè jẹ́ iṣẹ́ ọwọ́ ẹnì kan tí òye rẹ̀ ga ju ti ẹ̀dá èèyàn lọ fíìfíì.—Róòmù 1:20.

Fojú inú wò ó náà, pé ẹnì kan gbọ́ orin kan tó dùn gidigidi tàbí pé ó rí àwòrán kan tó jojú ní gbèsè tàbí pé ó rí ẹ̀rọ kan tó kàmàmà, ṣé ó bọ́gbọ́n mu kẹ́ni náà yarí kanlẹ̀ pé kò sí ẹni tó ṣe àwọn nǹkan yẹn? Rárá o, kò bọ́gbọ́n mu. Àmọ́, tá a bá fi bí àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe díjú tó, bí wọ́n ṣe lẹ́wà tó tàbí ọ̀nà tí wọ́n gbà ṣe wọ́n wéra pẹ̀lú ọ̀nà àrà tí Ọlọ́run gbà ṣẹ̀dá ara èèyàn, a ó rí i pé, ara èèyàn kò láfiwé rárá. Ǹjẹ́ ó yẹ kéèyàn ronú pé ńṣe ni ẹ̀dá èèyàn ṣàdédé wà, pé kò sí ẹni tó dá a? Síwájú sí i, ìtàn inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣàlàyé pé, nínú gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ẹ̀dá èèyàn nìkan ni Ọlọ́run dá ní àwòrán ara rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:26) Abájọ tó fi jẹ́ pé lára gbogbo ẹ̀dá orí ilẹ̀ ayé, ẹ̀dá èèyàn nìkan ló lè ṣàfarawé ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá nǹkan, ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé nígbà míì wọ́n máa ń ṣe oríṣiríṣi ohun èlò tó ń kọ orin tó gbádùn mọ́ni, tí wọ́n ń ṣe ẹ̀rọ tó kàmàmà, tí wọ́n sì ń ya àwòrán tó jojú ní gbèsè. Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Ọlọ́run lè ṣẹ̀dá àwọn nǹkan tó jẹ́ àgbàyanu ju èyí tí ẹ̀dá èèyàn lè ṣe?

Kí wá lohun tó ṣòro nínú fífi ọ̀kan lára egungun ìhà ọkùnrin ṣẹ̀dá obìnrin? * Ọlọ́run lè dá obìnrin náà lọ́nà míì, àmọ́ ó nídìí pàtàkì kan tó fi dá a lọ́nà yìí. Ó fẹ́ kí ọkùnrin àti obìnrin náà jẹ́ tọkọtaya, kí wọ́n sì jọ ní àjọṣe tímọ́tímọ́, bíi pé, wọ́n jẹ́ “ara kan.” (Jẹ́nẹ́sísì 2:24) Ṣé kì í ṣe ẹ̀rí tó lágbára ni pé Ẹlẹ́dàá jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti onífẹ̀ẹ́ bó ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin pé kí wọ́n máa gbé pọ̀ lálàáfíà gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, kí wọ́n sì máa ran ara wọn lọ́wọ́?

Síwájú sí i, àwọn onímọ̀ nípa àbùdá gbà pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé látọ̀dọ̀ ọkùnrin kan ṣoṣo àti obìnrin kan ṣoṣo ni gbogbo èèyàn ti wá. Nígbà náà, ṣé a wá lè sọ pé irọ́ ni àkọsílẹ̀ tó wà nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì?

3. Ó jọ pé àròsọ lásán ni igi ìmọ̀ àti igi ìyè

Ní tòdodo, àkọsílẹ̀ ìwé Jẹ́nẹ́sísì kò kọ́ni pé, àwọn igi yìí ní agbára àrà ọ̀tọ̀ kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni Jèhófà fi wọ́n ṣàpẹẹrẹ ohun kan.

Ó ṣe tán, àwa èèyàn náà máa ń ṣe irú ohun tó jọ èyí nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, adájọ́ lè kìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ rí ilé ẹjọ́ fín. Kì í ṣe àwọn ohun ọ̀ṣọ́ àti àga tó wà nínú ilé ẹjọ́ náà ni adájọ́ ní lọ́kàn pé wọn kò gbọ́dọ̀ rí fín, bí kò ṣe òfin ìdájọ́ tí wọ́n ń lò nílé ẹjọ́ náà. Bákan náà, àwọn Ọba máa ń lo ọ̀pá àṣẹ àti adé gẹ́gẹ́ bí àmì tó dúró fún àṣẹ wọn.

Kí wá ni àwọn igi méjì náà ṣàpẹẹrẹ? Àwọn èèyàn ti sọ onírúuru nǹkan tí wọ́n rò pé wọ́n jẹ́, àmọ́ àwọn ohun tí wọ́n sọ kò rọrùn láti lóye. Síbẹ̀ ìdáhùn tòótọ́ sí ìbéèrè náà kò ṣòro, àmọ́ ó lágbára. Igi ìmọ̀ rere àti búburú dúró fún ẹ̀tọ́ tí Ọlọ́run ní láti pinnu ohun tó jẹ́ rere àti búburú. (Jeremáyà 10:23) Abájọ tó fi jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ láti jí lára èso igi náà! Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, igi iye dúró fún ẹ̀bùn tí ó jẹ́ pé Ọlọ́run nìkan ló lè fúnni, ìyẹn ìyè àìnípẹ̀kun.—Róòmù 6:23.

4. Ó jọ pé àròsọ lásán ni pé ejò kan sọ̀rọ̀.

Ká sòótọ́, ìtàn inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì yìí lè rúni lójú, pàápàá téèyàn kò bá ṣàyẹ̀wò àwọn apá yòókù nínú Bíbélì. Àmọ́, Ìwé Mímọ́ ṣàlàyé àwọn ohun tó rúni lójú náà ni ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé.

Ta ló mú kó dà bíi pé ejò náà ló ń sọ̀rọ̀? Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì mọ àwọn nǹkan míì tó mú kí wọ́n túbọ̀ lóye ipa tí ejò náà kó. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n mọ̀ pé àwọn ẹranko kì í sọ̀rọ̀, àmọ́ áńgẹ́lì kan lè mú kó dà bíi pé ẹranko ń sọ̀rọ̀. Mósè pẹ̀lú ṣàkọsílẹ̀ ìtàn nípa Báláámù, Ọlọ́run rán áńgẹ́lì kan láti mú kí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ Báláámù sọ̀rọ̀ bí èèyàn.—Númérì 22:26-31; 2 Pétérù 2:15, 16.

Ǹjẹ́ àwọn áńgẹ́lì yòókù títí kan àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run lè ṣe iṣẹ́ ìyanu? Mósè rí bí àwọn àlùfáà pidánpidán Íjíbítì ṣe fi idán ṣe àwọn kan lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Ọlọ́run ṣe, irú bíi fífi idán sọ ọ̀pá di ejò. Ọ̀dọ̀ àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run ni agbára tí wọ́n fi dá irú àrà bẹ́ẹ̀ ti wá.—Ẹ́kísódù 7:8-12.

Ẹ̀rí fi hàn pé Mósè ni Ọlọ́run tún mí sí láti kọ ìwé Jóòbù. Ìwé yẹn sọ̀rọ̀ nípa Sátánì tó jẹ́ olórí ọ̀tá Ọlọ́run, ẹni tó purọ́ pé gbogbo àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà kò lè pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Ọlọ́run. (Jóòbù 1:6-11; 2:4, 5) Ǹjẹ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì rò pé, ńṣe ni Sátánì mú kó dà bíi pé ejò náà sọ̀rọ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì láti tan Éfà jẹ, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kó ba ìwà títọ́ rẹ̀ sí Ọlọ́run jẹ́? Ó jọ pé ohun tí wọ́n rò nìyẹn.

Ṣé Sátánì ló darí ejò náà? Nígbà tó yá, Jésù pe Sátánì ní “òpùrọ́” àti “baba irọ́.” (Jòhánù 8:44) Ó dájú pé “baba irọ́” yìí ló pa irọ́ àkọ́kọ́ náà, àbí òun kọ́? Irọ́ àkọ́kọ́ yẹn ni ọ̀rọ̀ tí ejò náà sọ fún Éfà. Ọlọ́run sọ pé tí wọ́n bá jẹ èso tóun ní wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ, wọ́n á kú, àmọ́ ejò náà ta ko ohun tí Ọlọ́run sọ, ó ní: “Dájúdájú ẹ̀yin kì yóò kú.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:4) Kò sí àní-àní pé, Jésù mọ̀ pé Sátánì ló darí ejò náà. Ìran tí Jésù fi han àpọ́sítélì Jòhánù yanjú ọ̀ràn náà, nínú ìran yìí, ó pe Sátánì ní “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà.”—Ìṣípayá 1:1; 12:9.

Ṣé irọ́ ni pé áńgẹ́lì alágbára kan lè lo ejò, kó sì mú kó dà bíi pé ó ń sọ̀rọ̀? Àwọn èèyàn tí agbára wọn kéré gan-an sí ti àwọn áńgẹ́lì pàápàá lè dá àwọn ọgbọ́n kan, tí wọ́n á sì mú kó dà bíi pé ọmọlangidi ń sọ̀rọ̀.

Ẹ̀rí Tó Dájú Jù Lọ

Ǹjẹ́ o kò gbà pé, iyè méjì táwọn èèyàn ń ṣe nípa ìtàn inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀? Àmọ́, ẹ̀rí tó lágbára wà pé, òótọ́ ni ìtàn náà.

Bí àpẹẹrẹ, a pe Jésù Kristi ní “ẹlẹ́rìí aṣeégbíyèlé àti olóòótọ́.” (Ìṣípayá 3:14) Ẹni pípé ni Jésù, kò tíì purọ́ rí, kì í sì í ṣini lọ́nà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó kọ́ni pé òun ti wà ṣáájú kí òun tó wá sí ayé, kódà, ó ti gbé lọ́dọ̀ Jèhófà tó jẹ́ Bàbá rẹ̀ “kí ayé tó wà.” (Jòhánù 17:5) Nítorí náà, ó ti wà nígbà tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá àwọn ohun alààyè sórí ilẹ̀ ayé. Kí ni ẹlẹ́rìí tó ju gbogbo ẹlẹ́rìí lọ yìí wá sọ?

Ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé ẹni gidi ni Ádámù àti Éfà. Ó tọ́ka sí tọkọtaya yìí nígbà tó ń ṣàlàyé ìlànà Jèhófà nípa ìgbéyàwó ọkọ-kan-aya-kan. (Mátíù 19:3-6) Tí ó bá jẹ́ pé Ádámù àti Éfà kì í ṣe ẹni gidi, tí ọgbà tí wọ́n gbé inú rẹ̀ náà sì jẹ́ ìtàn àròsọ, á jẹ́ pé irọ́ ni Jésù ń pa tàbí pé wọ́n tàn án jẹ ni. Ọ̀ràn náà kò rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ọ̀run ni Jésù wà, ó sì rí bí gbogbo ọ̀ràn náà ṣe ṣẹlẹ̀ nínú ọgbà náà. Ẹ̀rí wo ló tún lágbára ju ti Jésù yìí lọ?

Òótọ́ ibẹ̀ ni pé, téèyàn kò bá nígbàgbọ́ nínú ìtàn ìwé Jẹ́nẹ́sísì, kò ní jẹ́ kí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù lágbára. Àìnígbàgbọ́ yìí tún lè mú kí ẹni náà má ṣe lóye àwọn kókó pàtàkì kan tó wà nínú Bíbélì àtàwọn ìlérí tó ń fini lọ́kàn balẹ̀. Ẹ jẹ́ ká wo bí èyí ṣe lè rí bẹ́ẹ̀.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Nínú Bíbélì, Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

^ Èrò yìí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Bíbélì sọ pé, gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá ló jẹ́ pípé, ibòmíì ni ìdíbàjẹ́ ti wá. (Diutarónómì 32:4, 5) Nígbà tí Jèhófà dá gbogbo nǹkan tán sórí ilẹ̀ ayé, ó sọ pé, gbogbo wọn ló “dára gan-an.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:31.

^ Ẹ̀rí fi hàn pé Àkúnya Omi tó wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run ló pa ọgbà Édẹ́nì rẹ́ pátápátá. Ìwé Ìsíkíẹ́lì 31:18 sọ pé, “àwọn igi Édẹ́nì” ti pa rẹ́ tipẹ́tipẹ́ ní ọgọ́rùn-ún ọdún keje ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Nítorí náà, gbogbo àwọn tó ń wá ọgbà Édẹ́nì lẹ́yìn ìgbà náà kò lè rí i mọ́.

^ Ó gbàfiyèsí pé àwọn onímọ̀ ìṣègùn òde òní ti ṣàwárí pé egungun ìhà ní agbára tó kàmàmà láti wo ara rẹ̀ sàn. Egungun ìhà yàtọ̀ sí àwọn egungun inú ara yòókù, nítorí pé tuntun míì máa ń yọ jáde tí awọ ẹran tó yí i ká kò bá tíì bà jẹ́.