Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ojútùú sí Àwọn Àròyé Tó Máa Ń Wáyé

Ojútùú sí Àwọn Àròyé Tó Máa Ń Wáyé

Ojútùú sí Àwọn Àròyé Tó Máa Ń Wáyé

BÍBÉLÌ kò sọ pé ìgbéyàwó kò ní ní ìṣòro. Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ̀wé pé, àwọn tọkọtaya á máa ní “ìṣòro ojoojúmọ́” tí wọ́n ní láti bójú tó. (1 Kọ́ríńtì 7:28, Bíbélì Today’s English Version) Àmọ́, tọkọtaya kan lè ṣe ohun tó pọ̀ láti dín ìṣòro wọn kù, tí wọ́n á sì máa fi kún ayọ̀ ẹnì kejì wọn. Ṣàgbéyẹ̀wò àròyé mẹ́fà tí tọkọtaya sábà máa ń ṣe àti bí fífi àwọn ìlànà Bíbélì sílò ṣe lè ràn wọ́n lọ́wọ́.

1

ÀRÒYÉ:

“Ọ̀rọ̀ èmi àti ẹnì kejì mi kò wọ̀ mọ́.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:

‘Kí ẹ máa wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù.’FÍLÍPÌ 1:10.

Ìgbéyàwó rẹ ni ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jú lọ ní ìgbésí ayé rẹ. Ó sì yẹ kó wà ní ipò pàtàkì. Nítorí náà, ṣàyẹ̀wò bóyá àwọn ohun tó ń mú kí ọwọ́ rẹ dí ló fa ìṣòro rẹ. Má ṣe jẹ́ kí àwọn nǹkan tó ò ń ṣe lójoojúmọ́ mú kí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ máa ṣe nǹkan lọ́tọ̀ọ̀tọ̀. Òótọ́ ni pé, lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, iṣẹ́ àtàwọn ipò tí kò ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ lè mú kí ẹ̀yin méjèèjì má ṣe wà pa pọ̀. Àmọ́, ó yẹ kó o lè wá nǹkan ṣe sáwọn nǹkan tó o lágbára lé lórí, irú bí àkókò tó ò ń lò nídìí eré ìdárayá tàbí lọ́dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ rẹ.

Àmọ́, àwọn ọkọ kan àtàwọn aya kan ti mọ̀ọ́mọ̀ gba àfikún iṣẹ́ tàbí kí wọ́n máa lo ọ̀pọ̀ àkókò nídìí eré ìnàjú torí pé wọn kò fẹ́ lo àkókò pẹ̀lú ẹnì kejì wọn. Kì í ṣe pé ọ̀rọ̀ wọn àti ti ẹnì kejì wọn kò wọ̀, ohun tí wọ́n ńṣe ni pé wọ́n ń sá fún ìṣòro ni. Tí ìwọ tàbí ẹnì kejì rẹ bá ń hu irú ìwà yìí, ó yẹ kó o mọ ohun tó fà á, kó o sì yanjú rẹ̀. Bí ìwọ àti ẹnì kejì rẹ bá ń ṣe nǹkan pa pọ̀ nìkan lẹ fi lè “di ara kan” ní ti gidi.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24.

Bí àwọn kan ṣe lo àmọ̀ràn yìí: Tọkọtaya kan láti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà tí wọ́n ń jẹ́ Andrew * àti Tanji, ti ṣègbéyàwó lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn. Andrew sọ pé: “Mo ti rí i pé, ewu ló máa jẹ́ fún ìgbéyàwó, téèyàn bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí iṣẹ́ àti pẹ̀lú àwọn ọ̀rẹ́. Nítorí náà, èmi àti ìyàwó mi ya àkókò kan sọ́tọ̀ láti máa fi bá ara wa sọ ohun tó wà lọ́kàn wa.”

Tọkọtaya kan láti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n ń jẹ́ Dave àti Jane, tí wọ́n ti ṣègbéyàwó lọ́dún méjìlélógún sẹ́yìn sọ pé, àwọn ti ya ọgbọ̀n ìṣẹ́jú sọ́tọ̀ ní gbogbo ìrọ̀lẹ́ láti fi sọ̀rọ̀ lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ náà àtàwọn ohun tí àwọn ń rò lọ́kàn. Jane sọ pé: “A kì í jẹ́ kí ohunkóhun ṣèdíwọ́ fún wa ní àkókò pàtàkì yìí.”

2

ÀRÒYÉ:

“Mi ò rí ohun tí mo fẹ́ nínú ìgbéyàwó yìí mọ́.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:

“Kí olúkúlùkù má ṣe máa wá àǹfààní ti ara rẹ̀, bí kò ṣe ti ẹnì kejì.”1 KỌ́RÍŃTÌ 10:24.

Ọkọ tàbí aya tó jẹ́ pé tara rẹ̀ nìkan ló mọ̀ kò lè láyọ̀, kódà bó bá tiẹ̀ ń pààrọ̀ ìyàwó tàbí ọkọ pàápàá. Ìgbéyàwó máa yọrí sí rere tó bá jẹ́ pé ṣíṣe nǹkan fún ẹnì kejì ẹni ni ọkọ tàbí aya kan gbájú mọ́, ju kó máa retí pé kí ẹnì kejì òun máa ṣe nǹkan fún òun. Jésù sọ ìdí tí ọ̀rọ̀ yìí fi rí bẹ́ẹ̀, ó ní: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—Ìṣe 20:35.

Bí àwọn kan ṣe lo àmọ̀ràn yìí: Tọkọtaya kan ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò tí wọ́n ń jẹ́ Maria àti Martin, ti ṣègbéyàwó lọ́dún mọ́kàndínlógójì sẹ́yìn. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo ìgbà ni ọ̀rọ̀ wọn máa ń wọ̀. Wọ́n rántí èdèkòyédè kan tó wáyé. Maria sọ pé, “nígbà tí ọ̀rọ̀ náà gbóná girigiri, mo sọ ọ̀rọ̀ kan tó kan Martin lábùkù. Inú bí i gan-an. Mo gbìyànjú láti jẹ́ kó mọ̀ pé, ìbínú ló jẹ́ kí n sọ ọ̀rọ̀ náà. Àmọ́ kò gbà.” Martin sọ pé, “Nígbà tí àríyànjiyàn náà ń lọ lọ́wọ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé, a ò lè jọ wà pa pọ̀ mọ́, nítorí náà, kí n kúkú jáwọ́ nínú ohun tó máa mú kí ìgbéyàwó náà yọrí sí rere.”

Martin fẹ́ kí aya òun bọ̀wọ̀ fún òun. Maria ní tiẹ̀ fẹ́ kí ọkọ òun lóye òun. Àmọ́ kò sí èyíkéyìí lára wọn tó rí ohun tó ń fẹ́.

Báwo ni wọ́n ṣe yanjú ìṣòro náà? Martin sọ pé, “Mo bu omi sùúrù mu, àwa méjèèjì sì pinnu láti lo ìlànà ọlọ́gbọ́n tó wà nínú Bíbélì pé, ká jẹ́ ẹni tó bọ̀wọ̀ fúnni àti ẹni pẹ̀lẹ́. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, a wá rí i pé, kò sí bí iye ìgbà tí ìṣòro wáyé ti lè pọ̀ tó, a lè borí wọn tá a bá gbàdúrà fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run tá a sì lo àmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì.”—Aísáyà 48:17, 18; Éfésù 4:31, 32.

3

ÀRÒYÉ:

“Ẹnì kejì mi kò ṣe ojúṣe rẹ̀.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:

“Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”RÓÒMÙ 14:12.

Kò sí àní-àní pé, ìgbéyàwó kan kò ní fi bẹ́ẹ̀ yọrí sí rere tó bá jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ló ń ṣe ohun tó yẹ. Àmọ́ ọ̀ràn náà á túbọ̀ burú táwọn méjèèjì kì í bá ṣe ojúṣe wọn, tí wọ́n sì ń dá ara wọn lẹ́bi.

Tó bá jẹ́ pé ohun tó yẹ kí ẹnì kejì rẹ ṣe lo máa ń retí ní gbogbo ìgbà, o kò lè láyọ̀. Bákan náà, o kò lè láyọ̀, àgàgà tí o kò bá ṣe ojúṣe rẹ nítorí pé ẹnì kejì rẹ kọ̀ láti ṣe ojúṣe tirẹ̀. Àmọ́, tó o bá sapá láti jẹ́ ọkọ tàbí aya rere, ìyẹn á jẹ́ kí àárín yín sunwọ̀n sí i. (1 Pétérù 3:1-3) Jù bẹ́ẹ̀ lọ, wàá fi hàn pé o bọ̀wọ̀ fún ètò ìgbéyàwó tí Ọlọ́run gbé kalẹ̀, ìwà rẹ yóò sì mú ọkàn rẹ̀ yọ̀.—1 Pétérù 2:19.

Bí àwọn kan ṣe lo àmọ̀ràn yìí: Obìnrin kan tó ń jẹ́ Kim tí òun àti ọkọ rẹ̀ ń gbé ní orílẹ̀-èdè Korea ti ṣègbéyàwó lọ́dún méjìdínlógójì sẹ́yìn. Kim sọ pé: “Nígbà míì, ọkọ mi máa ń bínú sí mi, kò sì ní bá mi sọ̀rọ̀, mi ò sì mọ ìdí tó fi ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ìyẹn mú kí n rò pé kò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ mi mọ́. Mo máa ń bi ara mi nígbà míì pé, ‘Kí nìdí tó fi retí pé kí n lóye ohun tó mú kó máa ṣe bẹ́ẹ̀ nígbà tí òun náà kò ṣe tán láti lóye mi?’”

Ó rọrùn fún Kim láti máa ronú lórí àìtọ́ náà àti lórí ohun tó yẹ kí ọkọ rẹ̀ ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun míì ló ṣe. Kim sọ pe, “Dípò kí n máa bínú, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tó dáa jù ni pé kí n gbé ìgbésẹ̀ láti wá àlàáfíà. Nígbẹ̀yìn, ọkàn àwa méjèèjì rọ̀, ó sì ṣeé ṣe fún wa láti yanjú ọ̀rọ̀ náà ní ìtùnbí ìnùbí.”—Jákọ́bù 3:18.

4

ÀRÒYÉ:

“Ìyàwó mi kì í tẹrí ba.”

ILÀNÀ BÍBÉLÌ:

“Orí olúkúlùkù ọkùnrin ni Kristi.”1 KỌ́RÍŃTÌ 11:3.

Ọkọ tó bá ń rò pé ìyàwó òun kò tẹrí ba, ní láti kọ́kọ́ ronú bóyá òun náà ṣe tán láti tẹrí ba fún Jésù Kristi tó jẹ́ Orí fún àwọn ọkùnrin. Ọkọ kan lè fi hàn pé òun ń tẹrí ba fún Jésù tó bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa bá a lọ ní nínífẹ̀ẹ́ àwọn aya yín, gan-an gẹ́gẹ́ bí Kristi pẹ̀lú ti nífẹ̀ẹ́ ìjọ, tí ó sì jọ̀wọ́ ara rẹ̀ lọ́wọ́ fún un.” (Éfésù 5:25) Jésù kò jẹ gàba lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lórí. (Máàkù 10:42-44) Ó sọ ohun tó yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣe, ó sì tọ́ wọn sọ́nà nígbà tó yẹ bẹ́ẹ̀. Àmọ́, kò sí ìgbà tó le koko mọ́ wọn. Kò hùwà òǹrorò sí wọn, kò sì retí ohun tó kọjá agbára wọn. (Mátíù 11:29, 30; Máàkù 6:30, 31; 14:37, 38) Gbogbo ìgbà ló máa ń fi ire wọn ṣáájú ti ara rẹ̀.—Mátíù 20:25-28.

Ó yẹ kí ọkọ kan béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé, ‘Èwo ló ń darí mi jù tó bá dọ̀ràn ojú tí mo fi ń wo ipò orí àtàwọn obìnrin, ṣé àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ ni àbí ìmọ̀ràn àti àwọn àpẹẹrẹ tó wà nínú Bíbélì?’ Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa jẹ́ èrò rẹ nípa obìnrin kan tí kò gba èrò ọkọ rẹ̀, àmọ́ tó fi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀ sọ fún ọkọ rẹ̀ pé òun ní èrò tó yàtọ̀ lórí ọ̀ràn kan? Nínú Bíbélì, Sárà ìyàwó Ábúráhámù jẹ́ àpẹẹrẹ aya tó ní ìtẹríba. (1 Pétérù 3:1, 6) Síbẹ̀ náà, obìnrin yìí sọ èrò rẹ̀ nígbà tó pọn dandan pé kó sọ ọ́, bí irú ìgbà tí Ábúráhámù kò kíyè sí àwọn ewu kan tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ sórí ìdílé wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 16:5; 21:9-12.

Ó dájú pé Ábúráhámù kò halẹ̀ mọ́ Sárà kó bàa lè pa á lẹ́nu mọ́. Kì í ṣe ẹni tí ń fojú ẹni gbolẹ̀. Bákan náà, ọkọ tó ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì kò ní fagídí mú ìyàwó rẹ̀ pé kó ṣe gbogbo nǹkan tóun bá ṣáà ti rò. Ìyàwó rẹ̀ á máa bọ̀wọ̀ fún un tó bá ń lo ipò orí rẹ̀ lọ́nà pẹ̀lẹ́tù.

Bí àwọn kan ṣe lo àmọ̀ràn yìí: Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ James, tó ń gbé ní England tó ti ṣègbéyàwó lọ́dún mẹ́jọ sẹ́yìn sọ pé: “Mò ń kọ́ láti má ṣe ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì láìjẹ́ pé mo ti bá ìyàwó mi sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Mò ń gbìyànjú láti má ṣe ro tara mi nìkan. Nítorí náà, mo máa ń fi ire rẹ̀ ṣáájú tèmi.”

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ George tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ti ṣègbéyàwó lọ́dún mọ́kàndínlọ́gọ́ta sẹ́yìn. Ọkùnrin yìí sọ pé: “Mo ti gbìyànjú láti má ṣe hùwà sí ìyàwó mi bíi pé kò jámọ́ nǹkan kan, kàkà bẹ́ẹ̀, mo kà á sí ọlọ́gbọ́n àti ẹni tó dáńgájíà.”—Òwe 31:10.

5

ÀRÒYÉ:

“Ọkọ mi kì í ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aṣáájú.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:

“Obìnrin tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀, ṣùgbọ́n èyí tí ó jẹ́ òmùgọ̀ a fi ọwọ́ ara rẹ̀ ya á lulẹ̀.”ÒWE 14:1.

Bí ọkọ rẹ bá ń lọ́ tìkọ̀ láti ṣe ìpinnu tàbí tí kì í bá mú ipò iwájú nínú bíbójú tó ìdílé rẹ̀, ohun mẹ́ta lo lè ṣe. (1) O lè máa sọ àṣìṣe rẹ̀ fún un nígbà gbogbo tàbí (2) kó o gba ipò orí mọ́ ọn lọ́wọ́ nínú ìdílé tàbí (3) kó o máa gbóríyìn fún un lórí àwọn ìsapá tó bá ń ṣe. Tó o bá ṣe ohun méjì àkọ́kọ́, ó dájú pé wàá fi ọwọ́ ara rẹ ya ilé rẹ lulẹ̀. Àmọ́, tó o bá ṣe ohun kẹta, ìyẹn á jẹ́ kó o gbé ìdílé rẹ ró, á sì fún ìgbéyàwó rẹ lókun.

Ọ̀pọ̀ ọkùnrin ló mọyì káwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún wọn ju káwọn èèyàn nífẹ̀ẹ́ wọn lọ. Nítorí náà, tó o bá ń bọ̀wọ̀ fún ọkọ rẹ, tó ò ń jẹ́ kó mọ̀ pé o mọrírì ìsapá rẹ̀ bó ti ń mú ipò iwájú nínú ìdílé yín, ìyẹn lè mú kó túbọ̀ ṣe ojúṣe rẹ̀ dáadáa. Àmọ́ ṣá o, nígbà míì, o lè má fara mọ́ èrò ọkọ rẹ lórí ọ̀ràn kan. Ó yẹ kí ẹ̀yin méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ lórí irú àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀. (Òwe 18:13) Àmọ́, àwọn ọ̀rọ̀ àti ohùn tó o fi sọ ọ́ lè fún ìgbéyàwó rẹ lókun tàbí kó ya á lulẹ̀. (Òwe 21:9; 27:15) Tó o bá sọ èrò rẹ tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, ó ṣeé ṣe kí ọkọ rẹ bẹ̀rẹ̀ sí í mú ipò iwájú nínú ìdílé bó ti yẹ.

Bí àwọn kan ṣe lo àmọ̀ràn yìí: Obìnrin kan tó ń jẹ́ Michele, tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tó ti wà nílé ọkọ láti ọgbọ̀n ọdún sẹ́yìn sọ pé: “Nítorí pé màmá mi ló tọ́ èmi àtàwọn àbúrò mi obìnrin méjì dàgbà láìsí ìrànlọ́wọ́ ọkọ, ìyẹn mú kó jẹ́ akínkanjú obìnrin tó ń dá ṣe ìpinnu. Mo gbìyànjú láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ màmá mi. Nítorí náà, mo ní láti ṣiṣẹ́ gan-an lórí bí èèyàn ṣe ń fi ìtẹríba tòótọ́ hàn. Bí àpẹẹrẹ, mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, ó yẹ kí n máa fi ọ̀ràn lọ ọkọ mi dípò kí n máa dá ṣe ìpinnu.”

Ibi tí wọ́n ti tọ́ Rachel dàgbà ní ipa lórí òun náà, orílẹ̀-èdè Ọsirélíà ló ń gbé, ó sì ti fẹ́ Mark lọ́dún mọ́kànlélógún sẹ́yìn. Obìnrin yìí sọ pé: “Màmá mi kò fìgbà kan rí tẹrí ba fún bàbá mi. Àríyànjiyàn ni ṣáá nígbà gbogbo, wọn kì í sì í bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó, mo tẹ̀ lé àpẹẹrẹ màmá mi. Àmọ́, bí ọdún ṣe ń gorí ọdún, mo ti kọ́ bó ṣe yẹ kéèyàn máa fọ̀wọ̀ hàn gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ. Nísinsìnyí, èmi àti ọkọ mi túbọ̀ ń gbádùn ìgbéyàwó wa gan-an.”

6

ÀRÒYÉ:

“Ìwà tí ẹnì kejì mi ń hù ń múnú bí mi, mi ò lè fara dà á mọ́.”

ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ:

“Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn.”KÓLÓSÈ 3:13.

Nígbà tẹ́ ẹ kọ́kọ́ ń fẹ́ra yín sọ́nà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ìwà dáadáa ẹni tó máa di ọkọ tàbí aya rẹ lò ń wò, tí o kò kíyè sí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ̀. Ṣé o ṣì lè máa wo àwọn ìwà dáadáa yẹn? Òótọ́ ni pé, ẹnì kejì rẹ ń ṣe àwọn nǹkan tó ń bí ẹ nínú. Àmọ́, bi ara rẹ pé, ‘Èwo nínú àwọn ìwà ẹnì kejì mi ni mo fẹ́ máa wò, ṣé èyí tó dáa ni àbí èyí tí kò dáa?’

Jésù lo àpèjúwe kan tó fa kíki láti jẹ́ ká mọ̀ pé ó yẹ ká máa gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ àwọn ẹlòmíì. Ó béèrè pé: “Èé ṣe tí ìwọ fi . . . ń wo èérún pòròpórò tí ó wà nínú ojú arákùnrin rẹ, ṣùgbọ́n tí o kò ronú nípa igi ìrólé tí ó wà nínú ojú ìwọ fúnra rẹ?” (Mátíù 7:3) Kò sí àní-àní pé, ìyàtọ̀ kékeré kọ́ ló wà láàárín èérún pòròpórò àti igi ìrólé. Abájọ tí Jésù fi sọ pé: “Kọ́kọ́ yọ igi ìrólé kúrò nínú ojú tìrẹ ná, nígbà náà ni ìwọ yóò sì ríran kedere ní ti bí o ṣe lè yọ èérún pòròpórò kúrò nínú ojú arákùnrin rẹ.”—Mátíù 7:5.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ kó tó sọ àpèjúwe yìí jẹ́ ìkìlọ̀ tó ń múni ronú jinlẹ̀. Ó ní: “Ẹ dẹ́kun dídánilẹ́jọ́ kí a má bàa dá yín lẹ́jọ́; nítorí irú ìdájọ́ tí ẹ fi ń dáni lẹ́jọ́, ni a ó fi dá yín lẹ́jọ́.” (Mátíù 7:1, 2) Nítorí náà, tó o bá fẹ́ kí Ọlọ́run gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ rẹ tó dà bí igi ìrólé, ohun tó dáa ni pé kó o gbójú fo kùdìẹ̀-kudiẹ ẹnì kejì rẹ.—Mátíù 6:14, 15.

Bí àwọn kan ṣe lo àmọ̀ràn yìí: Obìnrin kan tó ń jẹ́ Jenny, tó ń gbé ní England tó ti fẹ́ Simon lọ́dún mẹ́sàn-án sẹ́yìn sọ pé: “Mo rí i pé, ohun tí ọkọ mi máa ń ṣe tó máa ń bí mi nínú lọ́pọ̀ ìgbà ni pé kì í múra sílẹ̀ tó bá fẹ́ ṣe nǹkan, ó dìgbà tí nǹkan náà bá ti wọ imú tán kó tó ṣe é. Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, bó ṣe máa ń ṣe nǹkan tí kò múra sílẹ̀ láṣeyọrí ló mú kí n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ nígbà tí à ń fẹ́ ara wa sọ́nà. Àmọ́, mo wá rí i pé èmi náà ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ, ìyẹn ni pé, mó fẹ́ràn láti máa darí ẹlòmíì. Èmi àti ọkọ mi ti kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ ká máa gbójú fo àìpé wa pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́.”

Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Curt, tó fẹ́ Michele tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sọ pé: “Tó bá jẹ́ àwọn nǹkan tó ń bí ẹ nínú tí ẹnì kejì rẹ ń ṣe lò ń wò, ńṣe làwọn kùdìẹ̀-kudiẹ náà á dàbí pé wọ́n ń tóbi sí i. Mo pinnu láti máa wo ìwà tó mú kí ìfẹ́ Michele wọ̀ mí lọ́kàn níbẹ̀rẹ̀.”

Ohun Tó Lè Mú Kéèyàn Ṣàṣeyọrí

Àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ pé, àwọn ìṣòro á wà nínú ìgbéyàwó, àmọ́ wọn kì í ṣe èyí téèyàn kò lè yanjú. Kí ló lè mú kéèyàn ṣàṣeyọrí? Mú kí ìfẹ́ tó o ní fún Ọlọ́run máa pọ̀ sí i, kó o sì múra tán láti máa lo àwọn ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Tọkọtaya kan tí wọ́n ń jẹ́ Alex àti Itohan, tí wọ́n ń gbé lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà ti ṣègbéyàwó lóhun tó lé lógún ọdún sẹ́yìn, àwọn méjèèjì ti kọ́ ẹ̀kọ́ yìí. Alex sọ pé: “Mo ti rí i pé, kò sí ìṣòro náà nínú ìgbéyàwó tí kò ṣeé yanjú bí tọkọtaya bá ń fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.” Ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “A ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, ó ṣe pàtàkì pé ká jọ máa gbàdúrà déédéé, ká sì máa tẹ̀ lé àwọn ìmọ̀ràn Bíbélì tó sọ pé ká máa fi tinútinú nífẹ̀ẹ́ ara wa, ká sì máa ní sùúrù. Ní báyìí, ìṣòro tá a ni kò tó nǹkan mọ́ tá a bá fi wé ti ìgbà tá a kọ́kọ́ ṣègbéyàwó.”

Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa bí àwọn ìmọ̀ràn tó gbéṣẹ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè ṣe ìdílé rẹ láǹfààní? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, sọ fún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé kí wọ́n bá ẹ kẹ́kọ̀ọ́ orí 14 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? *

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣé a máa ń ya àkókò sọ́tọ̀ láti ṣe nǹkan pa pọ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]

Ṣé ohun tí mò ń fúnni pọ̀ ju èyí tí mò ń retí láti gbà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ṣé mo máa ń gbé ìgbésẹ̀ láti yanjú èdèkòyédè?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Ṣé mo máa ń gba èrò ìyàwó mi yẹ̀ wò kí n tó ṣèpinnu?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ṣé àwọn ìwà dáadáa ẹnì kejì mi ni mo máa ń wò?