Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Jọ̀wọ́, Ọlọ́run Mi, Rántí Mi fún Rere”

“Jọ̀wọ́, Ọlọ́run Mi, Rántí Mi fún Rere”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Jọ̀wọ́, Ọlọ́run Mi, Rántí Mi fún Rere”

OBÌNRIN olóòótọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni sọ pé, “Èrò mi ni pé, Jèhófà mọ̀ mí dáadáa, kò lè nífẹ̀ẹ́ mi láé kò sì lè tẹ́wọ́ gbà mí.” Èrò pé òun kò já mọ́ nǹkan kan tó ní ló ń dà á láàmú. Ǹjẹ́ irú èrò bẹ́ẹ̀ ti dà ọ́ láàmú rí, tí ò ń rò pé Ọlọ́run kò rí ẹ dépò pé kó tẹ́wọ́ gbà ẹ́? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Nehemáyà 13:31 lè fún ọ́ ní ìṣírí.

Nehemáyà tó jẹ́ gómìnà àwọn Júù ní ọgọ́rùn-ún ọdún karùn-ún ṣáájú Sànmánì Kristẹni ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe láti wu Ọlọ́run. Ó mú ipò iwájú nínú kíkọ́ odi Jerúsálẹ́mù láìka àtakò àwọn ọ̀tá sí. Ó mú káwọn èèyàn pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́, ó bìkítà fún àwọn tí àwọn èèyàn ń pọ́n lójú, ó sì ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe láti gbé ìgbàgbọ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ró. Ǹjẹ́ Ọlọ́run rí gbogbo rere tí ọkùnrin olóòótọ́ yìí ṣe? Ǹjẹ́ Nehemáyà rí ojú rere Jèhófà? A lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè yìí nínú àwọn ọ̀rọ̀ tó parí ìwé Bíbélì tó ń jẹ́ orúkọ ọkùnrin yìí.

Nehemáyà gbàdúrà pé: “Jọ̀wọ́, Ọlọ́run mi, rántí mi fún rere.” * Ṣé ẹ̀rù ń ba Nehemáyà pé Ọlọ́run kò rí àwọn iṣẹ́ rere tó ṣe ni àbí pé Ọlọ́run máa gbàgbé òun? Rárá. Kò sí àní-àní pé, Nehemáyà mọ ohun tí àwọn tó kọ Bíbélì ṣáájú rẹ̀ sọ nípa bí Jèhófà ṣe nífẹ̀ẹ́ àwọn olóòótọ́ olùjọ́sìn rẹ̀ àtàwọn iṣẹ́ rere tí wọ́n ṣe. (Ẹ́kísódù 32:32, 33; Sáàmù 56:8) Kí ló wá ń bẹ Ọlọ́run pé kó ṣe? Ìwé kan tí wọ́n ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé, ọ̀rọ̀ Hébérù náà tí wọ́n túmọ̀ sí “rántí” ní ìtumọ̀ “ìfẹ́ni látọkànwá àti ohun tí ẹnì kan ṣe nígbà tó ronú kan nǹkan kan.” Nehemáyà ní ìgbàgbọ́ kíkún nínú àdúrà, ìyẹn sì mú kó bẹ Ọlọ́run pé kó fìfẹ́ rántí òun, kó sì bù kún òun.—Nehemáyà 2:4.

Ǹjẹ́ Jèhófà máa dáhùn àdúrà tí Nehemáyà gbà pé kó rántí òun? Ní ọ̀nà kan, Ọlọ́run ti dáhùn àdúrà náà. Bí Jèhófà ṣe jẹ́ kí wọ́n kọ àdúrà Nehemáyà sílẹ̀, tó sì wà di apá kan Ìwé Mímọ́ mú kó dá wa lójú pé Ọlọ́run rántí Nehemáyà, ó sì fẹ́ràn rẹ̀. Yàtọ̀ sí ìyẹn, “Olùgbọ́ àdúrà” ṣì máa dáhùn àdúrà àtọkànwá Nehemáyà jù bẹ́ẹ̀ lọ.—Sáàmù 65:2.

Ọlọ́run ṣì tún máa san èrè fún Nehemáyà nítorí gbogbo rere tó ti ṣe nítorí ìjọsìn tòótọ́. (Hébérù 11:6) Nínú ayé tuntun òdodo tí Jèhófà ṣèlérí, ó máa bù kún Nehemáyà nípa jíjí i dìde kúrò nínú ikú. * (2 Pétérù 3:13; Ìṣípayá 21:3, 4) Lákòókò yẹn, Nehemáyà á ní ìrètí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé, yóò sì mọ̀ pé lóòótọ́ ni Jèhófà ti rántí òun sí rere.

Àdúrà tí Nehemáyà gbà, jẹ́rìí sí i pé òótọ́ ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Dáfídì Ọba sọ pé: “Ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, yóò bù kún olódodo; ìtẹ́wọ́gbà ni ìwọ yóò fi yí wọn ká bí apata ńlá.” (Sáàmù 5:12) Ó dájú pé, Ọlọ́run ń rí ìsapá àtọkànwá tá à ń ṣe láti ṣe ohun tó wù ú, ó sì mọyì rẹ̀. Tó bá jẹ́ pé gbogbo ohun tí agbára rẹ gbé lò ń ṣe láti sin Ọlọ́run, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, Ọlọ́run á fìfẹ́ rántí rẹ, á sì bù kún ẹ jìngbìnnì.

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún February:

Nehemáyà 1-13

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Nínu ìwé Nehemáyà inú Bíbélì, èyí ni ìgbà kẹrin tí Nehemáyà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run rántí òun tàbí kó ṣojú rere sí òun nítorí ìṣòtítọ́ òun, ìgbà tó sì sọ̀rọ̀ yìí kẹ́yìn nìyẹn.—Nehemáyà 5:19; 13:14, 22, 31.

^ Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún àwọn olóòótọ́ tó wà lórí ilẹ̀ ayé, ka orí 3 àti 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.