Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ Fún Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún?

Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ Fún Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún?

Ṣé Ò Ń Múra Sílẹ̀ Fún Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ọdún?

NÍ WÁKÀTÍ díẹ̀ ṣáájú kí Jésù tó kú, ó dá ọ̀nà pàtàkì kan sílẹ̀ láti gbà máa ṣe ìrántí ikú rẹ̀. Ìrántí náà la wá mọ̀ sí “oúnjẹ alẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 11:20) Jésù fi hàn bí ohun tó dá sílẹ̀ náà ti ṣe pàtàkì tó, ó pàṣẹ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ṣé o fẹ́ láti ṣègbọràn sí Jésù? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá ka ọjọ́ ìrántí ikú Jésù sí ọjọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún.

Àmọ́ ìgbà wo gan-an ló yẹ kó o ṣe ìrántí yìí? Báwo sì lo ṣe lè rí i dájú pé o múra sílẹ̀ láti lóye bí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣe pàtàkì tó? Àwọn ìbéèrè yìí ló yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan fara balẹ̀ gbé yẹ̀ wò.

Ẹ̀ẹ̀melòó Lọ́dún?

Bó ṣe sábà máa ń rí, ọdọọdún la máa ń rántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. Bí àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó wáyé ní September 11, ọdún 2001 ṣì máa ń wà lọ́kàn àwọn olùgbé ìlú New York City tí wọ́n pàdánù àwọn èèyàn wọn nígbà tí àwọn apániláyà ya Ilé Ìtajà Tó Tóbi Jù lọ Lágbàáyé lulẹ̀, síbẹ̀, ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣe ìrántí ọjọ́ mánigbàgbé yẹn.

Bákan náà, lákòókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọdọọdún ni wọ́n máa ń ṣe ìrántí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì. (Ẹ́sítérì 9:21, 27) Jèhófà pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé ọdọọdún ni kí wọ́n máa ṣe àjọyọ̀ ìdáǹdè wọn kúrò ní oko ẹrú Íjíbítì, nígbà tó fi iṣẹ́ ìyanu dá wọn nídè. Bíbélì pe àjọyọ̀ yẹn ní Ìrékọjá, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì máa ń ṣe ìrántí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ní àyájọ́ ọjọ́ tí wọ́n rí ìdáǹdè.—Ẹ́kísódù 12:24-27; 13:10.

Kété lẹ́yìn tí Jésù parí àjọyọ̀ Ìrékọjá pẹ̀lú àwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ó ṣe ìdásílẹ̀ bí wọ́n á ṣe máa ṣe ìrántí ikú rẹ̀, oúnjẹ pàtàkì kan ló sì fi ṣe é. (Lúùkù 22:7-20) Ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ni wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá. Nítorí náà, a lè sọ pé, ẹ̀ẹ̀kan lọ́dún ló yẹ ká máa ṣe ohun tí Jésù ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀, èyí tó rọ́pò Ìrékọjá yìí. Àmọ́ ní ọjọ́ wo?

Nígbà Wo?

Ká tó dáhùn ìbéèrè yẹn, a ní láti lóye ohun méjì. Ohun àkọ́kọ́ ni pé, ní àkókò tí wọ́n ń kọ Bíbélì, ọjọ́ kan máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn bá wọ̀ ní ìrọ̀lẹ́, á sì parí nígbà tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ kejì. Nítorí náà, ọjọ́ kan jẹ́, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan sí ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kejì.—Léfítíkù 23:32.

Ohun kejì ni pé, Bíbélì kò lo kàlẹ́ńdà tí àwa ń lò lónìí. Dípò kí Bíbélì lo oṣù tá à ń pè ní March àti April, oṣù Ádárì àti Nísàn tó dúró fún àwọn oṣù yẹn ló lò. (Ẹ́sítérì 3:7) Àwọn Júù máa ń ka oṣù wọn láti òṣùpá tuntun dé òṣùpá tuntun. Wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù àkọ́kọ́, ìyẹn oṣù Nísàn nínú kàlẹ́ńdà wọn. (Léfítíkù 23:5; Númérì 28:16) Ọjọ́ Nísàn 14 yẹn kan náà ni ọjọ́ tí àwọn ará Róòmù kan Jésù Kristi Olúwa wa mọ́gi. Jésù kú ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ ọdún ó lé márùn dín ní àádọ́ta [1,545] lẹ́yìn tí wọ́n ṣe Ìrékọjá àkọ́kọ́. Ẹ ò rí i pé ọjọ́ pàtàkì ni Nísàn 14 jẹ́!

Àmọ́ ọjọ́ wo ló bá Nísàn 14 mu lórí kàlẹ́ńdà tiwa lóde òní? Ìṣirò ráńpẹ́ kan jẹ́ ká mọ ọjọ́ tó bá a mu wẹ́kú. Nísàn 1 máa ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí òṣùpá tuntun bá yọ níbẹ̀rẹ̀ ìgbà ìrúwé ní Àríwá Agbedeméjì ayé, tí wọ́n sì rí i ní Jerúsálẹ́mù nígbà tí oòrùn bá wọ̀. Tá a bá ka ọjọ́ mẹ́rìnlá láti ìgbà yẹn, a ó wá dé Nísàn 14. Ọjọ́ yìí sábà máa ń jẹ́ ọjọ́ òṣùpá àrànmọ́jú. Tí a bá lo kàlẹ́ńdà ti Bíbélì, Nísàn 14 ti ọdún yìí á bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀ ní ọjọ́ Sunday, April 17, 2011. *

Nítorí náà, lọ́dún yìí, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe ìrántí ikú Jésù, gbogbo àwọn tó bá sì fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ la pè. A ké sí ìwọ náà pé kó o dara pọ̀ mọ́ wa. Jọ̀wọ́ rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò rẹ láti mọ àkókò àti ibi tí wọ́n ti fẹ́ ṣe é. Ìrọ̀lẹ́ lẹ́yìn tí oòrùn bá ti wọ̀, la máa ṣe ìrántí yìí, kì í ṣe àárọ̀ tàbí ọ̀sán. Kí nìdí? Ìdí ni pé, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, “oúnjẹ alẹ́” ni. (1 Kọ́ríńtì 11:25) Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Sunday, April 17, 2011, ni àyájọ́ alẹ́ tí Jésù dá ìrántí pàtàkì yìí sílẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún méjì ó dín méjìlélógún [1,978] ọdún sẹ́yìn. Ọjọ́ yẹn náà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tí Jésù kú, ìyẹn Nísàn 14. Ọjọ́ wo ló dára ju ìyẹn lọ láti ṣe ìrántí ikú rẹ̀?

Bó O Ṣe Lè Múra Sílẹ̀

Kí lo lè ṣe nísinsìnyí láti múra sílẹ̀ fún ìrántí tá à ń ṣe lẹ́ẹ̀kan lọ́dún yìí? Ọ̀nà kan ni pé, kó o ṣàṣàrò lórí ohun tí Jésù ṣe fún wa. Ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? * ti ran ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn lọ́wọ́ láti mú kí ìmọrírì wọn pọ̀ sí i nípa bí ikú Jésù ti ṣe pàtàkì tó.—Mátíù 20:28.

Ọ̀nà míì tó o lè gbà múra ọkàn rẹ sílẹ̀ fún ìrántí pàtàkì yìí ni pé, kó o kà nípa àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ tó ṣáájú ikú Jésù. Ní àwọn ojú ìwé tí wọ́n tẹ̀ lé èyí, wàá rí àtẹ tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àtẹ yìí ní òpó mẹ́ta, nínú òpó àkọ́kọ́, wàá rí déètì orí kàlẹ́ńdà tiwa àtàwọn déètì kàlẹ́ńdà tí wọ́n ń lò nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì. Nínú òpó kejì, wàá rí àlàyé ṣókí nípa àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ ṣáájú ikú Jésù, òpó kẹta sì jẹ́ ká mọ ibi tá a ti lè rí ẹsẹ Bíbélì tó sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà kà nínú ìwé Ìhìn Rere àti ibi tá a ti lè rí àlàyé síwájú sí i nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí. * O ò ṣe wá àyè láti ka o kéré tán, díẹ̀ lára àyọkà látinú Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa ọjọ́ kọ̀ọ̀kan títí dé alẹ́ ọjọ́ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Èyí yóò ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti múra sílẹ̀ fún ọjọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ọdún.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ọjọ́ yìí lè máà bá ọjọ́ tí àwọn Júù òde òní ń ṣe Ìrékọjá wọn mu. Kí nìdí? Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn Júù òde òní máa ń ṣe Ìrékọjá ní Nísàn 15, ìgbàgbọ́ wọn ni pé ọjọ́ yẹn ni Ọlọ́run ń tọ́ka sí nígbà tó pa àṣẹ tó wà nínú Ẹ́kísódù 12:6. (Ka Ilé-Ìṣọ́nà February 15, 1990, ojú ìwé 14.) Àmọ́, Nísàn 14 ni Jésù ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá gẹ́gẹ́ bí ohun tí Òfin Mósè sọ. Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí a ṣe lè ka ọjọ́ yìí, ka Ile-Iṣọ Na December 15, 1977 ojú ìwé 767 sí 768.

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é. Ka ojú ìwé 47 sí 56 àti ojú ìwé 206 sí 208. O lè rí ìwé yìí ní orí ìkànnì wa, www.watchtower.org.

^ Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 22]

Ṣe ìrántí ikú Jésù Sunday, April 17, 2011

[Àtẹ Ìsọfúnnni/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23, 24]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ọ̀SẸ̀ TÓ KẸ́YÌN

2011 Tues. April 12 Sábáàtì Mátíù

2012 ․․․․․ Máàkù

2013 ․․․․․ Lúùkù

Jòhánù 11:55–12:1

gt orí 101, ìpínrọ̀ 2 sí 4 *

NISAN 9 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

Ní àkókò tí wọ́n ń kọ ▪ Ó lọ síbi àpèjẹ ní □ Mátíù 26:6-13

Bíbélì, ọjọ́ kan máa ilé Símónì adẹ́tẹ̀

ń bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn ▪ Màríà da òróró □ Máàkù 14:3-9

bá wọ̀ ní ìrọ̀lẹ́, á sì náádì sí i lórí Luke

parí nígbà tí oòrùn ▪ Àwọn Júù wá wo □ Jòhánù 12:2-11

bá wọ̀ lọ́jọ́ kejì Jésù àti Lásárù □ gt orí 101, ìpínrọ̀ 5 sí 9

2011 Wed. April 13 Ó wọ Jerúsálẹ́mù □ Mátíù 21:1-11, 14-17

2012 ․․․․․ tiyì-tẹ̀yẹ

2013 ․․․․․ ▪ Ó kọ́ àwọn èèyàn □ Máàkù 11:1-11

nínú tẹ́ńpìlì

Lúùkù 19:29-44

Jòhánù 12:12-19

gt orí 102

NISAN 10 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

▪ Ó sun Bẹ́tánì

mọ́jú

2011 Thurs. April 14 Ìrìn àjò ní kùtùkùtù □ Mátíù 21:12, 13,

2012 ․․․․․ sí Jerúsálẹ́mù 18, 19

2013 ․․․․․ ▪ Ó fọ tẹ́ńpìlì mọ́ □ Máàkù 11:12-19

▪ Jèhófà sọ̀rọ̀ □ Lúùkù 19:45-48

láti ọ̀run □ Jòhánù 12:20-50

gt orí 103 àti 104

NISAN 11 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

2011 Fri. April 15 ▪ Ó ń kọ́ni nínú □ Mátíù 21:19–25:46

2012 ․․․․․ tẹ́ńpìlì, ó ń lo

2013 ․․․․․ àpèjúwe

▪ Ó dá àwọn □ Máàkù 11:20–13:37

Farisí lẹ́bi

▪ Ó ṣàkíyèsí ọrẹ □ Lúùkù 20:1–21:38

tí opó kan ṣe

▪ Ó sọ tẹ́lẹ̀ nípa Jòhánù

ìṣubú Jerúsálẹ́mù

▪ Ó sọ àmì wíwàníhìn-ín □ gt orí 105 sí 112, ìpínrọ̀ 1

rẹ̀ lọ́jọ́ iwájú

NISAN 12 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

2011 Sat. April 16 Òun àtàwọn ọmọ □ Mátíù 26:1-5, 14-16

2012 ․․․․․ ẹ̀yìn rẹ̀ dá lo ọjọ́

2013 ․․․․․ kan ní Bẹ́tánì

▪ Júdásì ṣètò bí ó □ Máàkù 14:1, 2, 10, 11

ṣe máa da Jésù

Lúùkù 22:1-6

Jòhánù

gt orí 112, ìpínrọ̀ 2 sí 4

NISAN 13 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

2011 Sun. April 17 Pétérù àti Jòhánù □ Mátíù 26:17-19

2012 ․․․․․ lọ múra sílẹ̀ fún

2013 ․․․․․ Ìrékọjá

▪ Jésù àtàwọn □ Máàkù 14:12-16

àpọ́sítélì mẹ́wàá □ Lúùkù 22:7-13

yòókù lọ síbẹ̀ Jòhánù

ní ìrọ̀lẹ́ □ gt orí 112, ìpínrọ̀ 5 sí orí 113,

ìpínrọ̀ 1

NISAN 14 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

▪ Ó ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá □ Mátíù 26:20-35

▪ Ó wẹ ẹsẹ̀ àwọn □ Máàkù 14:17-31

àpọ́sítélì

▪ Ó ní kí Júdásì jáde □ Lúùkù 22:14-38

▪ Ó dá Ìrántí Ikú □ Jòhánù 13:1–17:26

rẹ̀ sílẹ̀ □ gt orí 113, ìpínrọ̀ 2 sí

ìparí orí 116

àárín òru Júdásì da Jésù, wọ́n □ Mátíù 26:36-75

2011 Mon. April 18 sì fàṣẹ ọba mú Jésù

2012 ․․․․․ nínú ọgbà Gẹtisémánì

2013 ․․․․․ ▪ Àwọn àpọ́sítélì sá lọ □ Máàkù 14:32-72

▪ Àwọn olórí àlùfáà àti □ Lúùkù 22:39-62

 

Sànhẹ́dírìn ṣèdájọ́ rẹ̀

▪ Pétérù sẹ́ Jésù □ Jòhánù 18:1-27

gt orí 117 sí

ìparí orí 120

▪ Ó jẹ́jọ́ níwájú □ Mátíù 27:1-61

Sànhẹ́dírìn lẹ́ẹ̀kàn sí i

▪ Wọ́n mú un lọ sọ́dọ̀ □ Máàkù 15:1-47

Pílátù, lẹ́yìn náà sọ́dọ̀

Hẹ́rọ́dù, nígbà tó yá, wọ́n

tún dá a pa dà sọ́dọ̀ Pílátù

▪ Wọ́n dájọ́ ikú fún un □ Lúùkù 22:63–23:56

wọ́n sì kàn án mọ́gi

▪ Ó kú ní nǹkan bí □ Jòhánù 18:28-40

aago mẹ́ta ọ̀sán

▪ Wọ́n gbé òkú rẹ̀ lọ □ gt orí 121 sí orí 127, ìpínrọ̀ 7

láti sin ín

NISAN 15 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

Sábáàtì

2011 Tues. April 19 Pílátù fọwọ́ sí i □ Mátíù 27:62-66

2012 ․․․․․ pé kí wọ́n fi àwọn ẹ̀ṣọ́ Máàkù

2013 ․․․․․ ṣọ́ ibojì Jésù Lúùkù

Jòhánù

gt orí 127, ìpínrọ̀ 8 àti 9

NISAN 16 (ó bẹ̀rẹ̀ nígbà tí oòrùn wọ̀)

2011 Wed. April 20 ▪ Ó jíǹde □ Mátíù 28:1-15

2012 ․․․․․ ▪ Ó fara han □ Máàkù 16:1-8

2013 ․․․․․ àwọn ọmọ ẹ̀yìn □ Lúùkù 24:1-49

Jòhánù 20:1-25

gt orí 127, ìpínrọ̀ 10

sí orí 129, ìpínrọ̀ 10

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwọn nọ́ńbà wọ̀nyí ń tọ́ka sí orí àti ìpínrọ̀ nínú ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí (gt). Tó o bá fẹ́ mọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ nípa àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó sọ nípa iṣẹ́ òjíṣẹ́ tí Jésù ṣe kẹ́yìn, wo àtẹ tó wà ní ojú ìwé 290 nínú ìwé “All Scripture Is Inspired of God and Beneficial,” lédè Gẹ̀ẹ́sì. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.