Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Rírí Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run Ló Máa Mú Ká Jogún Ìyè Àìnípẹ̀kun

Rírí Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run Ló Máa Mú Ká Jogún Ìyè Àìnípẹ̀kun

Rírí Ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run Ló Máa Mú Ká Jogún Ìyè Àìnípẹ̀kun

“Ìwọ tìkára rẹ, Jèhófà, yóò bù kún olódodo; ìtẹ́wọ́gbà ni ìwọ yóò fi yí wọn ká bí apata ńlá.”—SM. 5:12.

1, 2. Kí ni Èlíjà tọrọ lọ́wọ́ opó ìlú Sáréfátì, kí ni Èlíjà sì mú kó dá obìnrin náà lójú?

 EBI ń pa opó kan àti ọmọkùnrin rẹ̀, ebi sì ń pa wòlíì Èlíjà tó dé bá wọn lálejò. Bí obìnrin opó Sáréfátì yìí ṣe ń múra láti dáná oúnjẹ, wòlíì Èlíjà sọ pé kó fún òun ní omi àti búrẹ́dì. Opó náà fẹ́ láti fún un ní omi, àmọ́ oúnjẹ tó ní kò kọjá “ẹ̀kúnwọ́ ìyẹ̀fun nínú ìṣà títóbi àti òróró díẹ̀ nínú ìṣà kékeré.” Opó náà rí i pé oúnjẹ tóun ní kò pọ̀ tó èyí tóun lè fún wòlíì náà lára rẹ̀, ó sì sọ fún un bẹ́ẹ̀.—1 Ọba 17:8-12.

2 Síbẹ̀, Èlíjà sọ fún un pé: “Kọ́kọ́ ṣe àkàrà ribiti kékeré kan fún mi lára ohun tí ó wà níbẹ̀, kí o sì mú un jáde tọ̀ mí wá, lẹ́yìn ìgbà náà, o lè ṣe nǹkan kan fún ara rẹ àti ọmọ rẹ. Nítorí èyí ni ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí, ‘Ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun kì yóò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró kì yóò sì gbẹ.’”—1 Ọba 17:13, 14.

3. Ìpinnu pàtàkì wo la gbọ́dọ̀ ṣe?

3 Bóyá obìnrin opó náà máa fún wòlíì náà lára oúnjẹ rẹ̀ tàbí kò ní fún un kò ṣe pàtàkì bí ìpinnu pàtàkì tó gbọ́dọ̀ ṣe. Ǹjẹ́ ó máa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa gba òun àti ọmọ òun là, tàbí ó máa fi ohun tó jẹ́ àìní rẹ̀ nípa tara ṣáájú rírí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run àti dídi ọ̀rẹ́ rẹ̀? Ó yẹ kí gbogbo wa náà wá ìdáhùn sí ìbéèrè tó fara jọ èyí. Ǹjẹ́ a máa fi hàn pé rírí ìtẹ́wọ́gbà Jèhófà ló jẹ wá lógún ju kíkó àwọn nǹkan ìní tara jọ? Kò sí ìdí kankan tí kò fi yẹ ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run ká sì máa sìn ín. Àwọn ìgbésẹ̀ tá a lè gbé wà ká bàa lè wá ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ ká sì rí i.

‘Ìwọ Ni Ó Yẹ Láti Gba Ìjọsìn’

4. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jèhófà ló yẹ láti gba ìjọsìn wa?

4 Jèhófà ní ẹ̀tọ́ láti retí pé kí àwa èèyàn máa sin òun lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà. Àgbájọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lókè ọ̀run sì gbà pé bó ṣe yẹ kó rí nìyẹn, torí náà wọ́n pa ohùn wọn pọ̀ láti sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣí. 4:11) Jèhófà ló yẹ ká máa jọ́sìn torí pé òun ni Ẹlẹ́dàá wa.

5. Kí nìdí tí ìfẹ́ tí Ọlọ́run ní sí wa fi yẹ kó mú ká máa sìn ín?

5 Ìdí mìíràn tó fi yẹ ká máa sin Jèhófà ni pé ìfẹ́ tó ní sí wa kò láfiwé. Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run sì bẹ̀rẹ̀ sí dá ènìyàn ní àwòrán rẹ̀, àwòrán Ọlọ́run ni ó dá a; akọ àti abo ni ó dá wọn.” (Jẹ́n. 1:27) Ẹ̀dá èèyàn ní òmìnira láti yan ohun tó wù wọ́n, Ọlọ́run sì tún fún wọn lágbára láti ronú kí wọ́n sì pinnu ohun tí wọ́n fẹ́. Torí pé Jèhófà ló mú ká wà láàyè, òun ni Baba gbogbo ìran èèyàn. (Lúùkù 3:38) Bá a ṣe lè retí pé kí bàbá rere èyíkéyìí ṣe, ó ti pèsè gbogbo nǹkan táwa ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin nílò ká lè gbádùn ìwàláàyè. Ó “ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn” ó sì “ń mú kí òjò rọ̀,” kí ilẹ̀ ayé lè máa mú ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ jáde nínú àyíká rírẹwà tó yí wa ká.—Mát. 5:45.

6, 7. (a) Ìpalára wo ni Ádámù ṣe fún gbogbo àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀? (b) Kí ni ẹbọ Kristi máa ṣe fún gbogbo àwọn tó bá ń wá ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

6 Jèhófà tún ti gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àbájáde búburú tí ẹ̀ṣẹ̀ mú wá. Nígbà tí Ádámù dẹ́ṣẹ̀, ńṣe ló dà bí atatẹ́tẹ́ tó ń jí owó tó jẹ́ ti ìdílé rẹ̀ láti fi ta tẹ́tẹ́. Bí Ádámù ṣe ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà mú kó fi ayọ̀ ayérayé du àwọn ọmọ rẹ̀. Ìwà ìmọtara-ẹni-nìkan tó hù mú kó sọ ìràn èèyàn di ẹrú àìpé. Ìdí rẹ̀ nìyẹn tí gbogbo èèyàn fi máa ń ṣàìsàn, tí wọ́n máa ń banú jẹ́ tí wọ́n á sì kú nígbẹ̀yìn gbẹ́yín. A mọ̀ pé wọn kì í dá ẹrú sílẹ̀ láìjẹ́ pé ẹnì kan san ohun kan láti fi rà á pa dà. Lọ́nà kan náà, Jèhófà ti san ohun tó lè gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn àbájáde búburú ti ẹ̀ṣẹ̀. (Ka Róòmù 5:21.) Jésù Kristi náà ṣe ohun tó bá ìfẹ́ Baba rẹ̀ mu nígbà tó fi “ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mát. 20:28) Láìpẹ́ àwọn tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run máa jàǹfààní ìràpadà yẹn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

7 Jèhófà tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa, ti ṣe ohun tó pọ̀ ju ti ẹnikẹ́ni mìíràn lọ ká bàa lè láyọ̀ kí ìgbésí ayé wa sì nítumọ̀. Bá a bá rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti rí bó ṣe máa fòpin sí gbogbo àdánù tó ti bá ìran èèyàn. Jèhófà á sì mú kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa rí bí òun ti jẹ́ “olùsẹ̀san fún àwọn tí ń fi taratara wá” òun.—Héb. 11:6.

“Àwọn Ènìyàn Rẹ Yóò Fi Tinútinú Yọ̀ǹda Ara Wọn”

8. Kí ni ìrírí Aísáyà kọ́ wa nípa sísin Ọlọ́run?

8 Bá a bá fẹ́ jèrè ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run a gbọ́dọ̀ lo òmìnira tá a ní láti yan ohun tó wù wá lọ́nà tó tọ́. Ìdí sì ni pé Jèhófà kì í fipá mú ẹnikẹ́ni láti sin òun. Nígbà ayé Aísáyà, Ọlọ́run béèrè pé: “Ta ni èmi yóò rán, ta sì ni yóò lọ fún wa?” Jèhófà fi ọ̀wọ̀ hàn fún ẹ̀tọ́ tí wòlíì náà ní láti pinnu ohun tó wù ú dípò kó wulẹ̀ pàṣẹ fún un. Sì wo bó ṣe tẹ́ Aísáyà lọ́rùn tó láti dáhùn pé: “Èmi nìyí! Rán mi.”—Aísá. 6:8.

9, 10. (a) Báwo ni ó ṣe yẹ ká máa sin Ọlọ́run? (b) Kí nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú pé ká máa sin Jèhófà tọkàntọkàn?

9 Àwọn èèyàn lè yàn láti sin Ọlọ́run tàbí kí wọ́n má sìn ín. Jèhófà fẹ́ ká máa fínnú fíndọ̀ sin òun. (Ka Jóṣúà 24:15.) Ẹnikẹ́ni tó bá ń lọ́ tìkọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run kò lè rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀; òun náà kì í sì í tẹ́wọ́ gba ìjọsìn àwọn tó ń sìn ín nítorí àtirí ojú rere ẹ̀dá èèyàn bíi tiwọn. (Kól. 3:22) Bá a bá ń fi “ìlọ́tìkọ̀” ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́, tá a sì ń jẹ́ káwọn nǹkan ti ayé dí ìjọsìn wa lọ́wọ́, a kò lè rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run. (Ẹ́kís. 22:29) Jèhófà mọ̀ pé ohun tó pé wa jù lọ ni pé ká máa sin òun tọkàntọkàn. Mósè rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n yan ìyè “nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run [wọn], nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.”—Diu. 30:19, 20.

10 Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì kọrin sí Jèhófà pé: “Àwọn ènìyàn rẹ yóò fi tinútinú yọ̀ǹda ara wọn ní ọjọ́ ẹgbẹ́ ológun rẹ. Nínú ọlá ńlá ìjẹ́mímọ́, láti inú ilé ọlẹ̀ ọ̀yẹ̀, ìwọ ní àwùjọ rẹ ti àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n rí bí ìrì tí ń sẹ̀.” (Sm. 110:3) Kíkó ohun ìní tara jọ àti wíwá ìgbádùn ni ọ̀pọ̀ èèyàn ń fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn lónìí. Àmọ́, ní ti àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wọn ni wọ́n fi ṣáájú ohun gbogbo. Ìtara tí wọ́n fi ń wàásù ìhìn rere jẹ́ ká mọ àwọn ohun tí wọ́n fi ṣáájú ní ìgbésí ayé wọn. Wọ́n ní ìgbọ́kànlé kíkún nínú Jèhófà pé ó lágbára láti máa pèsè àwọn nǹkan táwọn nílò lójoojúmọ́.—Mát. 6:33, 34.

Àwọn Ẹbọ Tí Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà

11. Àwọn ìbùkún wo ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nírètí láti rí gbà nípa rírú ẹbọ sí Jèhófà?

11 Lábẹ́ májẹ̀mú Òfin, àwọn èèyàn Ọlọ́run máa ń rú àwọn ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run kí wọ́n lè rí ojú rere rẹ̀. Ìwé Léfítíkù 19:5 sọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ rú ẹbọ ìdàpọ̀ sí Jèhófà, kí ẹ rú u láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún ara yín.” Nínú ìwé Bíbélì yìí kan náà, a kà pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ rú ẹbọ ìdúpẹ́ sí Jèhófà, kí ẹ rú u láti rí ìtẹ́wọ́gbà fún ara yín.” (Léf. 22:29) Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá fi ẹran tó ṣètẹ́wọ́gbà rúbọ lórí pẹpẹ Jèhófà, èéfín tó máa ń rú jáde láti ara ẹbọ náà máa ń dà bí “òórùn amáratuni” tó ń lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́. (Léf. 1:9, 13) Bí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣe ń fi ìfẹ́ tí wọ́n ní sí i hàn lọ́nà yìí máa ń gbádùn mọ́ ọn, ó sì máa ń mára tù ú. (Jẹ́n. 8:21) Nínú apá tó jẹ mọ́ ẹbọ rírú nínú Òfin yìí, a lè rí ìlànà kan tó ṣeé mú lò lónìí. Àwọn tó ń rú ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Jèhófà máa ń rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Irú ẹbọ wo ni Ọlọ́run máa ń tẹ́wọ́ gbà? Gbé apá méjì nínú ìgbésí ayé yẹ̀ wò. Ìyẹn ni ìwà wa àti ọ̀rọ̀ ẹnu wa.

12. Àwọn àṣà wo ló máa mú kí Ọlọ́run ka ‘fífi ara wa fún òun gẹ́gẹ́ bí ẹbọ’ sí ìríra?

12 Nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí àwọn ará Róòmù, ó sọ pé: “Ẹ fi ara yín fún Ọlọ́run ní ẹbọ ààyè, mímọ́, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ pẹ̀lú agbára ìmọnúúrò yín.” (Róòmù 12:1) Rírí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run gba pé kéèyàn mú kí ara rẹ̀ wà nípò tó ṣètẹ́wọ́gbà fún Ọlọ́run. Béèyàn bá ní láti sọ ara rẹ̀ dìbàjẹ́ nípa lílo tábà, jíjẹ ẹ̀pà betel, lílo oògùn olóró tàbí mímu ọtí àmujù, ẹbọ rẹ̀ kò ní já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. (2 Kọ́r. 7:1) Bákan náà, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ẹni tó bá “ń ṣe àgbèrè ń ṣẹ̀ sí ara òun fúnra rẹ̀,” ńṣe ni irú ìṣekúṣe yòówù kéèyàn máa lọ́wọ́ nínú rẹ̀ á sọ ẹbọ rẹ̀ di ìríra lójú Jèhófà. (1 Kọ́r. 6:18) Ẹni tó bá fẹ́ ṣe ohun tó máa múnú Ọlọ́run dùn gbọ́dọ̀ ‘di mímọ́ nínú gbogbo ìwà rẹ̀.’—1 Pét. 1:14-16.

13. Kí nìdí tó fi yẹ ká máa yin Jèhófà?

13 Ẹbọ míì tí inú Jèhófà máa ń dùn sí ní í ṣe pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu wa. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà máa ń sọ̀rọ̀ rere nípa rẹ̀ ní gbangba àti nínú ilé wọn. (Ka Sáàmù 34:1-3.) Ka Sáàmù kejìdínláàádọ́jọ [148] sí àádọ́jọ [150], kó o sì kíyè sí bí àwọn orí mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà ṣe fún wa ní ìṣírí láti máa yin Jèhófà. Dájúdájú, “ìyìn yẹ níhà ọ̀dọ̀ àwọn adúróṣánṣán.” (Sm. 33:1) Jésù Kristi tó jẹ́ Àwòfiṣàpẹẹrẹ wa sì tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká máa yin Ọlọ́run nípa wíwàásù ìhìn rere.—Lúùkù 4:18, 43, 44.

14, 15. Irú ẹbọ wo ni Hóséà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n rú, kí sì ni Jèhófà ṣe fún wọn?

14 Bá a ṣe ń fìtara wàásù, à ń fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà àti pé ó wù wá láti rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ọ̀rọ̀ ìyànjú tí wòlíì Hóséà sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó pàdánù ojú rere Ọlọ́run torí pé wọ́n lọ́wọ́ sí ìjọsìn èké. (Hós. 13:1-3) Hóséà ní kí wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé: “Kí [Jèhófà] dárí ìṣìnà jì; kí o sì tẹ́wọ́ gba ohun rere, àwa yóò sì fi ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa rúbọ ní ìdápadà.”—Hós. 14:1, 2.

15 Akọ màlúù ni ẹran tó wọ́nwó jù lọ tí ọmọ Ísírẹ́lì kan lè fi rúbọ sí Jèhófà. Torí náà, “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa” túmọ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ àtọkànwá, tó fi àròjinlẹ̀ hàn, tá a fi ń yin Ọlọ́run tòótọ́. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó mú irú ẹbọ yìí wá? Ó sọ pé: “Èmi yóò nífẹ̀ẹ́ wọn láti inú ìfẹ́ àtinúwá tèmi.” (Hós. 14:4) Jèhófà máa darí ẹ̀ṣẹ̀ ji àwọn tó ń mú irú ẹbọ ìyìn bẹ́ẹ̀ wá, ó máa tẹ́wọ́ gbà wọ́n, ó sì máa bá wọn dọ́rẹ̀ẹ́.

16, 17. Bí ìgbàgbọ́ tí ẹnì kan ní nínú Ọlọ́run bá mú kó máa wàásù ìhìn rere, báwo ni Jèhófà ṣe máa tẹ́wọ́ gba ìyìn onítọ̀hún?

16 Yíyin Jèhófà ní gbangba ti sábà máa ń jẹ́ apá pàtàkì nínú ìjọsìn tòótọ́. Yíyin Ọlọ́run tòótọ́ jẹ onísáàmù náà lógún débi tó fi bẹ Ọlọ́run pé: “Jọ̀wọ́, Jèhófà, ní ìdùnnú sí àwọn ọrẹ àfínnúfíndọ̀ṣe ti ẹnu mi.” (Sm. 119:108) Lónìí ńkọ́? Aísáyà sọ asọtẹ́lẹ̀ nípa àwọn ogunlọ́gọ̀ èèyàn ní ọjọ́ wa pé: “Ìyìn Jèhófà sì ni wọn yóò máa kéde. . . . Pẹ̀lú ìtẹ́wọ́gbà ni wọn [ìyẹn, ẹ̀bùn wọn] yóò fi gòkè wá sórí pẹpẹ [Ọlọ́run].” (Aísá. 60:6, 7) Ní ìmúṣẹ àsọtẹ́lẹ̀ yìí, àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló ń rú “ẹbọ ìyìn sí Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyíinì ni, èso ètè tí ń ṣe ìpolongo ní gbangba sí orúkọ rẹ̀.”—Héb. 13:15.

17 Ìwọ náà ńkọ́? Ṣé ò ń rú ẹbọ tó ṣètẹ́wọ́gbà sí Ọlọ́run? Bí o kì í bá ṣe bẹ́ẹ̀, ṣé o máa ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ, kó o sì bẹ̀rẹ̀ sí í yin Jèhófà ní gbangba? Bí ìgbàgbọ́ tó o ní bá mú kó o bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere, ẹbọ rẹ á “wu Jèhófà ju akọ màlúù” lọ. (Ka Sáàmù 69:30, 31.) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé “òórùn amáratuni” látinú ẹbọ ìyìn rẹ máa dé ọ̀dọ̀ Jèhófà, wàá rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀. (Ìsík. 20:41) Wàá sì wá ní ayọ̀ tó kọyọyọ.

‘Jèhófà Tìkára Rẹ Yóò Bù Kún Olódodo’

18, 19. (a) Ojú wo ni ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo jíjọ́sìn Ọlọ́run lónìí? (b) Kí ló máa ṣẹlẹ̀ béèyàn bá pàdánù ojú rere Ọlọ́run?

18 Lónìí, ọ̀pọ̀ èèyàn máa ń ronú bíi tàwọn kan nígbà ayé Málákì, tí wọ́n sọ pé: “Asan ni lati sin Ọlọrun: anfani kinni o si wa, ti awa ti pa ilana rẹ mọ?” (Mál. 3:14, Bibeli Ajuwe) Àwọn tí ìfẹ́ fún ohun ìní tara ti gbà lọ́kàn máa ń ronú pé Ọlọ́run kò lè mú àwọn ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ àti pé àwọn òfin rẹ̀ kò bágbà mu mọ́. Lójú wọn, fífi àkókò ṣòfò ló jẹ́ láti máa wàásù ìhìn rere, ó sì máa ń bí wọn nínú.

19 Inú ọgbà Édẹ́nì ni irú ìṣarasíhùwà yìí ti bẹ̀rẹ̀. Sátánì mú kí Éfà wo ìwàláàyè àgbàyanu tí Jèhófà fi jíǹkí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò já mọ́ nǹkan kan, ó sì mú kó fojú tẹ́ńbẹ́lú rírí ìtẹ́wọ́gbà Rẹ̀. Lóde òní, lemọ́lemọ́ ni Sátánì ń sún àwọn èèyàn láti gbà gbọ́ pé kò sí àǹfààní kankan nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run. Àmọ́ ṣá o, Éfà àti ọkọ rẹ̀ wá rí i pé báwọn ṣe pàdánù ojú rere Ọlọ́run, ńṣe làwọn pàdánù ìwàláàyè àwọn. Àwọn tó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ búburú wọn nísinsìnyí náà máa tó rí i pé báwọn bá pàdánù ojú rere Ọlọ́run, ìwàláàyè àwọn làwọn pàdánù yẹn.—Jẹ́n. 3:1-7, 17-19.

20, 21. (a) Kí ni opó Sáréfátì ṣe, kí sì ni ìyọrísí rẹ̀? (b) Báwo la ṣe lè fara wé opó Sáréfátì náà, kí sì nìdí tó fi yẹ ká ṣe bẹ́ẹ̀?

20 Fi àbájáde búburú ìwà ọ̀tẹ̀ Ádámù àti Éfà wé ohun tó wá ṣẹlẹ̀ nínú ọ̀ràn Èlíjà àti opó Sáréfátì tá a mẹ́nu kàn nínú àpilẹ̀kọ yìí. Ó ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn tí obìnrin náà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ ìṣírí tí Èlíjà sọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe búrẹ́dì, nígbà tó sì ṣe é tán ó kọ́kọ́ fún wòlíì náà ní búrẹ́dì díẹ̀. Lẹ́yìn náà ni Jèhófà wá mú ìlérí tó ṣe nípasẹ̀ wòlíì Èlíjà ṣẹ. Àkọsílẹ̀ náà sọ pé: “Obìnrin náà sì ń jẹun lọ, òun pa pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀ àti agbo ilé obìnrin náà, fún ọ̀pọ̀ ọjọ́. Ìṣà títóbi ti ìyẹ̀fun náà kò ṣófo, ìṣà kékeré ti òróró náà kò sì gbẹ, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Jèhófà tí ó sọ nípasẹ̀ Èlíjà.”—1 Ọba 17:15, 16.

21 Ìwọ̀nba díẹ̀ péré lára ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù èèyàn tó ń gbé ayé lónìí ló máa fẹ́ láti ṣe ohun tí opó Sáréfátì yìí ṣe. Ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọ́run ìgbàlà, Ọlọ́run pẹ̀lú sì ràn án lọ́wọ́. Ìtàn yìí àtàwọn ìtàn míì tó wà nínú Bíbélì fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé Jèhófà ló yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé. (Ka Jóṣúà 21:43-45; 23:14.) Ohun tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní tún fún wa ní ẹ̀rí síwájú sí i pé kò ní kọ àwọn tó bá rí ìtẹ́wọ́gbà rẹ̀ sílẹ̀ láé.—Sm. 34:6, 7, 17-19. *

22. Kí nìdí tó fi jẹ́ kánjúkánjú pé ká wá ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run láìfi àkókò falẹ̀?

22 Ọjọ́ tí ìdájọ́ Ọlọ́run máa “dé bá gbogbo àwọn tí ń gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé” ti kù sí dẹ̀dẹ̀ báyìí. (Lúùkù 21:34, 35) Kò sí ọ̀nà àbùjá kankan. Kò sí ọrọ̀ tàbí ìtẹ́lọ́rùn tí ohun ìní tara lè fúnni tá a lè fi wé bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí Onídàájọ́ tí Ọlọ́run yàn sọ fúnni pé: “Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bù kún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè sílẹ̀ fún yín.” (Mát. 25:34) Ó dájú pé ‘Jèhófà fúnra rẹ̀ yóò bù kún olódodo; ìtẹ́wọ́gbà ni yóò sì fi yí wọn ká bí apata ńlá.’ (Sm. 5:12) Ṣé kò wá yẹ ká wá ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Wo Ilé Ìṣọ́, March 15, 2005, ojú ìwé 13, ìpínrọ̀ 15; August 1, 1997, ojú ìwé 20 sí 25.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa sin Jèhófà tọkàntọkàn?

• Irú ẹbọ wo ni Jèhófà ń tẹ́wọ́ gbà lónìí?

• Kí ni gbólóhùn náà, “ẹgbọrọ akọ màlúù ètè wa” túmọ̀ sí, kí sì nìdí tó fi yẹ ká máa fi irú ẹbọ bẹ́ẹ̀ fún Jèhófà?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká máa wá ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Ìpinnu pàtàkì wo ni wòlíì Ọlọ́run gbé ka iwájú ìyá kan tó jẹ́ aláìní?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àǹfààní wo là ń rí gbà nípa ríru ẹbọ ìyìn sì Jèhófà?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

O kò ní kábàámọ̀ láé bó o bá ní ojúlówó ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà