Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Wo Ló Ń Wàásù Ìhìn Rere Náà?

Àwọn Wo Ló Ń Wàásù Ìhìn Rere Náà?

Àwọn Wo Ló Ń Wàásù Ìhìn Rere Náà?

“A ó sì wàásù . . . ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.”—MÁTÍÙ 24:14.

ÀWỌN Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń wàásù ìhìn rere náà kárí ayé. Oríṣiríṣi ọ̀nà ni wọ́n ń gbà ṣe é. Ọ̀nà kan ni . . .

Ọ̀rọ̀ Ẹnu. Bíi ti Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń lọ wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn. (Lúùkù 8:1; 10:1) Wọn kò retí pé káwọn èèyàn wá bá àwọn. Gbogbo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù méje kárí ayé máa ń wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ń wàásù láti ilé dé ilé, lójú ọ̀nà, lórí tẹlifóònù àti láwọn ọ̀nà míì. Lọ́dún tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lo ohun tó lé ní bílíọ̀nù kan ààbọ̀ wákàtí lẹ́nu iṣẹ́ yìí.

Yàtọ̀ sí pé wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run, wọ́n tún ń kọ́ àwọn èèyàn ní “gbogbo ohun tí [Jésù] ti pa láṣẹ.” (Mátíù 28:20) Wọ́n ń kọ́ àwọn èèyàn tó lé ní mílíọ̀nù mẹ́jọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé nínú ilé wọn lọ́fẹ̀ẹ́.

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ní igba ó lé mẹ́rìndínlógójì [236] ilẹ̀. Wọ́n ń wàásù fún onírúurú èèyàn tí ìgbésí ayé wọn yàtọ̀ síra. Wọ́n ń wàásù láwọn orílẹ̀-èdè àti nínú ìlú, nínú igbó àgbègbè Amazon nílẹ̀ Brazil àti nínú igbó àwọn ará Siberia, ní àwọn aṣálẹ̀ ilẹ̀ Áfíríkà àti lórí àwọn Òkè Himalaya nílẹ̀ Éṣíà. Wọn kì í gba owó fún gbogbo ohun tí wọ́n ń ṣe yìí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń lo owó àti àkókò wọn lẹ́nu iṣẹ́ náà, ìyẹn sì jẹ́ nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Ọlọ́run àtàwọn aládùúgbò wọn. Wọ́n tún ń wàásù ìhìn rere nípasẹ̀ . . .

Àwọn Ìtẹ̀jáde. Àkọlé ìwé ìròyìn tó wà lọ́wọ́ rẹ yìí sọ pé, Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà, ní báyìí èdè igba ó dín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [185] la fi ń tẹ̀ ẹ́, a sì ń tẹ ẹ̀dà tó lé ní mílíọ̀nù méjìlélógójì [42,000,000] jáde lẹ́ẹ̀kan. Ìwé ìròyìn kan tún wà tó ṣèkejì èyí, Jí! lorúkọ rẹ̀, òun náà ń kéde Ìjọba Ọlọ́run, èdè mẹ́tàlélọ́gọ́rin [83] la fi ń tẹ̀ ẹ́, a sì ń tẹ ẹ̀dà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì mílíọ̀nù [40,000,000] jáde lẹ́ẹ̀kan.

Wọ́n ń ṣe àwọn ìwé, ìwé pẹlẹbẹ, ìwé àṣàrò kúkúrú, àwọn àwo CD àti MP3 àtàwọn àwo DVD tó ṣàlàyé nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì, wọ́n sì wà ní èdè tó tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún ó lé ogójì [540]. Lọ́dún mẹ́wàá sẹ́yìn, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ṣe ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan yìí jáde, wọ́n sì ti fún àwọn èèyàn ní iye tó lé ní ogún bílíọ̀nù lára rẹ̀, ìyẹn sì jẹ́ ìpíndọ́gba ẹ̀dà mẹ́ta fún ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà lórí ilẹ̀ ayé!

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ti tẹ Bíbélì jáde ní onírúurú èdè tàbí kí wọ́n gbé é fún àwọn èèyàn láti tẹ̀ ẹ́ jáde. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló túmọ̀ Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, àwọn ló tẹ̀ ẹ́ jáde, àwọn náà ló sì ń mú un lọ fún àwọn èèyàn nílé wọn, ní báyìí Bíbélì yìí ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè mẹ́rìndínlọ́gọ́rùn-ún [96]. Wọ́n ti pín ẹ̀dà tó lé ní igba mílíọ̀nù ó dín mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n [166,000,000] Bíbélì yìí fún àwọn èèyàn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń wàásù ìhìn rere Ìjọba náà . . .

Ní Àwọn Ìpàdé. Ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni wọ́n máa ń ṣe ìpàdé nínú àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò wọn, àwọn ìpàdé náà kì í ṣe ààtò ẹ̀sìn, kàkà bẹ́ẹ̀, ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ni wọ́n wà fún. Wọ́n máa ń sọ àsọyé tí wọ́n mú jáde látinú Bíbélì, wọ́n sì máa ń fi ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìtẹ̀jáde míì kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Láwọn ìpàdé náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ń kọ́ bí wọ́n ṣe lè di ọ̀jáfáfá nídìí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere.

Ohun kan náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú àwọn ìjọ wọn kárí ayé tí iye wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé méje [107,000], èyí sì ń mú kí ìṣọ̀kan wà láàárín wọn. Gbogbo èèyàn ni ìpàdé yìí wà fún. Wọn kì í gbé igbá owó. Àmọ́ ṣá o, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo èyí máa já sí, tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í bá fi ohun tí wọ́n ń wàásù ṣèwàhù. Nítorí náà, wọ́n ń wàásù ìhìn rere nípasẹ̀ . . .

Ìwà Wọn. Wọ́n ń sapá láti jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú ìwà wọn gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n lè ṣe láti rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n bá fẹ́ kí àwọn èèyàn máa ṣe sí wọn, ni wọ́n ń ṣe sí àwọn èèyàn. (Mátíù 7:12) Bí wọ́n tílẹ̀ jẹ́ aláìpé, tí wọ́n sì máa ń ṣe àṣìṣe lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo ọkàn ni wọ́n fi fẹ́ láti rí i pé àwọn ń hùwà tó fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn, kì í ṣe nípa wíwàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn nìkan, àmọ́ wọ́n tún ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì nígbà tó bá ṣeé ṣe.

Kì í ṣe pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ fi ìwàásù wọn yí gbogbo ayé pa dà o! Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà tí wọ́n bá ti ṣe iṣẹ́ náà dé ibi tó tẹ́ Jèhófà lọ́rùn, òpin máa dé gẹ́gẹ́ bí Jésù ti sọ. Kí ni àbájáde èyí máa jẹ́ fún ayé àtàwọn èèyàn tó wà nínú rẹ̀?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù ìhìn rere náà kárí ayé