Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ilẹ̀ Kan Tí Ń Ṣàn Fún Wàrà àti Oyin”

“Ilẹ̀ Kan Tí Ń Ṣàn Fún Wàrà àti Oyin”

“Ilẹ̀ Kan Tí Ń Ṣàn Fún Wàrà àti Oyin”

NÍGBÀ tí Jèhófà Ọlọ́run dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì, ó ṣèlérí fún wọn pé òun á mú wọ́n lọ sí “ilẹ̀ kan tí ó dára tí ó sì ní àyè gbígbòòrò, sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.”—Ẹ́kísódù 3:8.

Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bẹ̀rẹ̀ sí í gbé Ilẹ̀ Ìlérí, wọ́n ní àwọn ẹran ọ̀sìn, ìyẹn àwọn màlúù, àgùntàn àti ewúrẹ́, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ní wàrà tó pọ̀ gan-an. Àmọ́, oyin ńkọ́? Àwọn kan gbà pé gbólóhùn náà ń sọ nípa àwọn ohun àdídùn tí wọ́n fi èso déètì, èso ọ̀pọ̀tọ́ tàbí èso àjàrà ṣe. Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ ibi tí Bíbélì ti mẹ́nu kan oyin, ló jẹ́ pé oyin tó wá látara kòkòrò oyin ló ń tọ́ka sí, kì í ṣe èyí tó wá látara èso igi. (Àwọn Onídàájọ́ 14:8, 9; 1 Sámúẹ́lì 14:27; Mátíù 3:1, 4) Ṣé ilẹ̀ náà “ń ṣàn fún” oyin lóòótọ́ bí ó ṣe ń ṣàn fún wàrà?

Ohun tí àwọn awalẹ̀pìtàn ṣẹ̀ṣẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì òde òní jẹ́ ká lóye ọ̀ràn náà kedere. Ilé ìtẹ̀wé Hebrew University sọ ọ̀rọ̀ kan nípa àwárí náà, ó ní: “Èyí ni ibi tí wọ́n ti ń ṣe oyin [ilé oyin] tó tíì pẹ́ jù lọ tí wọ́n rí, èyí táwọn awalẹ̀pìtàn hú jáde nílẹ̀ àwọn èèyàn ayé àtijọ́ tó wà nítòsí àárín gbùngbùn Ìlà Oòrùn, gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n (Amihai) Mazar ti sọ ọ́. Ó ti wà láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹwàá sí ìbẹ̀rẹ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún kẹsàn-án ṣáájú Sànmánì Kristẹni.”

Àwọn awalẹ̀pìtàn rí ilé oyin tó ju ọgbọ̀n lọ ní ipele mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, wọ́n sì fojú bù ú pé agbègbè náà lè ní nǹkan bí ilé oyin ọgọ́rùn-ún. Nínú àyẹ̀wò tí wọ́n ṣe nípa àwọn ilé oyin yẹn, wọ́n rí àwọn àjákù ara kòkòrò oyin àti ìda oyin. Àwọn ọ̀mọ̀wé fojú bù ú pé, “á tó ìdajì tọ́ọ̀nù oyin tí wọ́n ń mú jáde látinú àwọn ilé oyin yìí lọ́dọọdún.”

Ní ayé àtijọ́, yàtọ̀ sí pé oyin jẹ́ oúnjẹ aládùn, wọ́n tún máa ń lo ìda oyin ní àwọn ilé iṣẹ́ irin àti awọ. Wọ́n tún máa ń fi kun pátákó ìkọ̀wé, wọ́n sì lè yọ́ ìda náà kúrò lójú pátákó tí wọ́n á sì tún ìda náà lò. Kí wá ni èrò àwọn awalẹ̀pìtàn látinú àwárí tí wọ́n ṣe yìí?

Ilé Ìtẹ̀wé yẹn ń bá ọ̀rọ̀ lọ nípa àwárí yìí, ó ní, “Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ ohunkóhun nípa bóyá wọ́n ń sin oyin nígbà yẹn lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì, rírí tí wọ́n rí ibi tí wọ́n ti ń sin oyin ní Tel Rehov fi hàn pé sísin oyin àti kíkó oyin àti afárá oyin jẹ́ iṣẹ́ kan tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ láti ìgbà tí Tẹ́ńpìlì Àkọ́kọ́ ti wà [èyí tí Sólómọ́nì kọ́]. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé oyin tó wá látara kòkòrò oyin ni ọ̀rọ̀ Bíbélì náà, ‘oyin’ ń tọ́ka sí.”

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 15]

Institute of Archaeology/Hebrew University © Tel Rehov Excavations