Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ǹjẹ́ Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa Bá A Tiẹ̀ Jẹ́ Ará Íńdíà?”

“Ǹjẹ́ Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa Bá A Tiẹ̀ Jẹ́ Ará Íńdíà?”

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

“Ǹjẹ́ Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Wa Bá A Tiẹ̀ Jẹ́ Ará Íńdíà?”

ỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Melesio jẹ́ ara àwọn tó ń sọ èdè O’dam, orí àwọn òkè ńlá ló ń gbé, àmọ́ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ó máa ń wáṣẹ́ lọ, ìyẹn sì gba pé kó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ìsàlẹ̀. Ó máa ń lọ sí ìpàdé àwọn Kristẹni, ó sì máa ń gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti lọ fún àwọn èèyàn rẹ̀. Ó bẹ̀bẹ̀ pé kí ẹnì kan wá sọ́dọ̀ àwọn, kí ó wá túbọ̀ kọ́ àwọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Àwọn O’dam jẹ́ àwọn èèyàn kan tí wọ́n wà ní àdádó lórí àwọn òkè Sierra ní àríwá àárín gbùngbùn orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò, nǹkan bí òjìlérúgba [240] kìlómítà ni ọ̀dọ̀ wọn fi jìn sí ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó sún mọ́ wọn jù lọ. Àwa ọkùnrin mélòó kan pinnu pé a máa lọ sọ́dọ̀ wọn.

A gba ọkọ̀ akẹ́rù kékeré kan, a sì kó àwọn àgọ́, àpò tí a lè tẹ́ sùn àti oúnjẹ tó tó dání. A tún ra epo tí ọkọ̀ lè lò fún ọjọ́ mẹ́ta, a sì gbéra ìrìn àjò wa láti ìlú Durango. Aago mẹ́rin òwúrọ̀ la bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò náà, a sì fi wákàtí mẹ́jọ wakọ̀ gba ọ̀nà òkè eléruku kan títí tá a fi dé òpin ọ̀nà náà. Ibi tí ọ̀nà náà pin sí ni ìbẹ̀rẹ̀ ibi tí àwọn O’dam ń gbé. À ń wo kòtò ńlá àti òkè míì níwájú wa.

A fi ọkọ̀ akẹ́rù náà sílẹ̀ ní abúlé kan nítòsí, a sì fi ẹsẹ̀ rin ìrìn wákàtí mẹ́ta, a gbé àwọn nǹkan tá a mú wá lọ sí ìsàlẹ̀ kòtò ńlá náà. A pa àgọ́ síbẹ̀, a sì kó igi tó pọ̀ jọ láti dá iná ńlá láti lé àwọn ẹranko ẹhànnà sá, a pín ara wa, à ń sun oorun wákátì mẹ́ta-mẹ́ta láti lè máa ṣọ́ iná náà kí ó má bàa kú.

Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, a bẹ̀rẹ̀ sí i gun òkè náà. Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà níbẹ̀, a sì ṣìnà lọ́pọ̀ ìgbà. Ẹnì kan lára wa mọ èdè O’dam sọ díẹ̀díẹ̀, nítorí náà, a sọ ìhìn rere látinú Bíbélì fún àwọn tó ń gbé lẹ́bàá ọ̀nà. Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà táwọn èèyàn ń sọ fún wa pé àwọn kan wà ní Los Arenales, níbi tá à ń lọ, tí wọ́n pe ara wọn ní Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì ń ṣe ìpàdé láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìròyìn yìí yà wá lẹ́nu gan-an àmọ́ ó mórí wa wú.

Ẹsẹ̀ wa ti lé ròrò kí a tó dé Los Arenales. Inú ilé tó wà káàkiri tí wọ́n fi páálí bo orí wọn làwọn èèyàn ibẹ̀ ń gbé. Kò sí ilé ẹ̀kọ́ níbẹ̀, kò sì sí iná mànàmáná. Àdádó pátápátá ni wọ́n wà, tálákà paraku ni wọ́n, búrẹ́dì fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan tí wọ́n fi àgbàdo ṣe ni wọ́n máa ń jẹ àtàwọn nǹkan pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ míì. A rí Melesio, ọkùnrin tí kò fi bẹ́ẹ̀ lára yìí láyọ̀ gan-an nígbà tó rí wa. Ó mú wa lọ sínú ilé rẹ̀, ó sì sọ fún wa pé, ojoojúmọ́ lòun máa ń gbàdúrà sí Jèhófà pé kó rán àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ láti wá kọ́ ìdílé òun àtàwọn tí àwọn jọ ń sọ èdè O’dam lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé òun kò lè dáhùn gbogbo ìbéèrè táwọn èèyàn náà ń béèrè.

Àwọn O’dam máa ń ṣe ẹ̀sìn ìbílẹ̀. Wọ́n máa ń lo ìyẹ́ àti egungun ẹyẹ idì gẹ́gẹ́ bí oògùn ìṣọ́ra, wọ́n máa ń jọ́sìn àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá, wọ́n sì máa ń bẹ̀rù àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ìbílẹ̀, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn yìí máa ń kó àwọn èèyàn nífà. Melesio ṣàlàyé pé nígbà kan tóun lọ sí ìlú ńlá, òun kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́, látìgbà yẹn lòun ti kó gbogbo nǹkan ìbọ̀rìṣà tóun ní dà nù. Àwọn èèyàn àdúgbò náà retí pé kí àwọn òrìṣà wọn pà á nítorí ohun tó ṣe yẹn. Nígbà tí kò sí ohun tó ṣe é, wọ́n gbà pé Jèhófà lágbára ju àwọn òrìṣà wọn lọ fíìfíì. Nítorí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí Melesio máa ń fi àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ṣe fún ìdílé rẹ̀.

Melesio sọ pé: “Mo sọ fún wọn pé wọ́n ní láti kọ́kọ́ sun gbogbo oògùn tí wọ́n dè mọ́ra àtàwọn òrìṣà wọn.” Ọ̀pọ̀ wọn borí ìbẹ̀rù ìgbàgbọ́ nínú ohun àsán tí wọ́n ní, iye àwọn tó ń wá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ sì ju ọgọ́rin [80] lọ. Ó yà wá lẹ́nu gan-an nígbà tá a gbọ́, nítorí náà, a pinnu pé a máa ṣe ìpàdé lọ́sàn-án ọjọ́ yẹn. A rán àwọn èèyàn pé kí wọ́n gun ẹṣin, kí wọ́n sì lọ sọ fún àwọn tó máa ń pàdé déédéé nílé Melesio. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárín ọ̀sẹ̀ ni, tí ìpàdé náà sì bọ́ sí pàjáwìrì, àwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ló wá, àwọn kan fẹsẹ̀ rìn, àwọn kan sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

Melesio ló túmọ̀ ọ̀rọ̀ wa sí èdè wọn, a sì dáhùn àwọn ìbéèrè tí wọ́n ní nípa Bíbélì. Wọ́n béèrè àwọn ìbéèrè bíi: “Ǹjẹ́ Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa bá a tiẹ̀ jẹ́ ará Íńdíà?” “Ǹjẹ́ Jèhófà máa ń gbọ́ àdúrà tá a gbà ní èdè O’dam?” “Nígbà tí Ámẹ́gẹ́dónì bá dé, ṣé Jèhófà máa bìkítà nípa wa bó tilẹ̀ jẹ́ pé à ń gbé ní ibi tó jìnnà réré sí àwọn ìlú ńlá?” Inú wa dùn láti lo Bíbélì láti mú un dá àwọn èèyàn onírẹ̀lẹ̀ yìí lójú pé Jèhófà bìkítà fún àwọn ọlọ́kàn tútù, láìka èdè tí wọ́n ń sọ sí, tàbí bí ibi tí wọ́n ń gbé ṣe wà ní àdádó tó. Wọ́n bẹ̀ wá pé ká rán ẹnì kan wá láti kọ́ àwọn ní ohun púpọ̀ sí i.

Lẹ́yìn tí a parí ìpàdé, a fún àwọn ọ̀rẹ́ wa tuntun yìí lára oúnjẹ wa. Ilẹ̀ ti ṣú, ibi tá a wà sì tutù gan-an, nítorí náà, á dúpẹ́ púpọ̀ nígbà tí wọ́n sọ fún wa pé kí á lọ sùn nínú ilé kan tí wọ́n kò tíì kọ́ parí. Ní àárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n mú wa gba ọ̀nà àbùjá sọ̀kalẹ̀ lọ síbi tí ọkọ̀ wa wà, a sì pa dà sí ìlú Durango, ó rẹ̀ wá àmọ́ inú wa dùn gan-an.

Àǹfààní ńlá ló jẹ́ láti lọ sọ́dọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn yìí, àwọn tó jẹ́ pé ọ̀pọ̀ lára wọn kò mọ̀ọ́kọ mọ̀ọ́kà, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò lè sọ èdè Sípáníìṣì àmọ́ wọ́n fẹ́ láti kọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ wọ́n sì fẹ́ jọ́sìn rẹ̀! Lẹ́yìn ìgbà tá a lọ, àwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́fà ti lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn náà, tí wọ́n sì dúró síbẹ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Wọ́n ṣèrànwọ́ fún nǹkan bí èèyàn márùnlélógójì [45] tí wọ́n fẹ́ láti sin Jèhófà. Gbogbo wọn ń lọ sí ìpàdé déédéé.

Èyí tó tún jọni lójú ni pé, wọn kò ta sìgá mọ́ ní ṣọ́ọ̀bù kékeré kan ṣoṣo tó wà ní Los Arenales. Ohun tó sì jẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀ ni pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, wọn kò sì mu sìgá mọ́. Ọ̀pọ̀ lára wọn ló tún ti lọ ṣègbéyàwó wọn lábẹ́ òfin.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Melesio àti ìyàwó rẹ̀ àtàwọn ọmọbìnrin wọn mẹ́rin àti ìyá ìyàwó rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti ìpàdé ní Los Arenales

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 25]

Servicio Postal Mexicano, Correos de Mexico